Pípa Iwatitọ Kristẹni Mọ́ Ni Liberia Ti Ogun Ti Fàya
Gẹgẹ bi ẹni ti ọran ṣoju rẹ̀ ti sọ ọ
“NIGBA ti awọn àjànàkú bá jà, korikopẹlu yoo jiya.” Ẹ wo bi owe Iwọ-oorun Africa yẹn ti ṣakopọ ohun ti ó ṣẹlẹ ni akoko ogun aipẹ yii ni Liberia daradara tó! Nǹkan bi 20,000 eniyan padanu ẹmi wọn, ilaji awọn eniyan ti ń gbe orilẹ-ede naa ti ó jẹ́ 2.6 million ni a sì fi ipa lé jade kuro ni ilu. Ọpọ julọ awọn wọnni ti wọn jiya kii ṣe awọn ologun; wọn jẹ “koriko”—awọn ọkunrin, obinrin, ati ọmọde alailepanilara.
Nigba ti ogun bẹ́ silẹ ni December 1989, ohun ti ó sunmọ 2,000 awọn Ẹlẹ́rìí ni Liberia ń gbadun awọn ibisi ti ń lọ deedee ni iye wọn sì ń fojusọna si ọjọ-ọla pẹlu igbọkanle. Lọna ti ó banininujẹ, wọn jẹ́ apakan ‘koriko ti ó jiya naa.’
Ìtànkálẹ̀ Ogun
Ogun naa bẹrẹ lẹbaa bode Liberia pẹlu Côte d’Ivoire, ati laipẹ awọn olùwá ibi ìsádi bẹrẹ sii salọ si olu ilu, Monrovia, ilu kan ti o ni ju ilaji million awọn olùgbé. Lati oṣu March titi di May 1990, gẹgẹ bi ìjà naa ti ń sún lọ si guusu, awọn ojihin iṣẹ Ọlọrun awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni a ṣí lọ kuro ni Ganta ati lẹhin naa ni Gbarnga. Wọn wà lara awọn eniyan ilu ti ó kẹhin lati fi ilu wọnyi silẹ. Ogun naa dé ogogoro rẹ̀ nigba ti awọn ipá ologun ṣí wọnu Monrovia ni July 2, 1990.
Kò si ẹni ti ó murasilẹ fun ipaya ti ó tẹle e. Awọn ẹgbẹ́ ologun mẹta ọtọọtọ wàákò loju popo pẹlu awọn ohun ìjà ńlá, àgbá, rọkẹẹti, ati ohun ìjà ti ń fi awọn bọmbu keekeeke sọ̀kò. Awọn wọnni ti a kò pa nitori pe wọn jẹ́ mẹmba ẹya ti a koriira ni a fi sabẹ ìfòòró ati ìtúlẹ́rù lemọlemọ. Ni alẹ oṣu August kan iye ti ó ju 600 awọn ọkunrin, obinrin, ati awọn ọmọde tí wọn ti wá aabo ni St. Peter’s Lutheran Church ni a pa lati ọwọ awujọ awọn ti ogun ti sínníwín.
Ọgọrọọrun sá loju ìjà naa pẹlu kiki aṣọ ti wọn wọ̀ sara. Awọn idile ni a yasọtọọtọ ti kò sì ṣeeṣe fun wọn lati tun wà papọ ni ọpọ oṣu lẹhin naa. Gbogbo awọn eniyan ti ń gbé Monrovia jọ bii pe wọn sú lọ, pẹlu awọn ile ofifo tí awọn ologun ati awọn olùwá ibi ìsádi ti wọn sá kuro ni awọn apa miiran ni ilu yẹn ń gbé. Iye ti o ju ilaji awọn eniyan ti ń gbe Monrovia ni a fipa lé kuro. Ọpọ julọ padanu ohun gbogbo tí wọn ní ati bakan naa pẹlu ó keretan ibatan kan ninu iku. Awọn kan padanu pupọ sii.
Ipo ọran naa dori yanpọnyanrin tobẹẹ ti awọn orilẹ-ede Iwọ-oorun Africa marun-un miiran fi awọn ologun ranṣẹ lati gbiyanju lati mu alaafia padabọsipo. Ni opin October 1990, ọpọ julọ ìjà naa ni o ti rọlẹ. Ṣugbọn lẹhin naa ironu ìyàn bo ilu ti a ti jẹrun naa bii aṣọ oku kan. Awọn aṣoju ajọ ti ń bojuto ire alaafia rohin pe nigba ti o dori koko kan ohun ti ó fẹrẹẹ tó idamẹta awọn ọmọ Monrovia ti wọn jẹ́ ẹni ọdun marun-un si isalẹ ni kò rí ounjẹ ti ó dara jẹ iye ti ó sì ju ọgọrun-un kan awọn eniyan ń kú lojoojumọ. Awọn ajìfà kò mu nǹkan rọrun sii rárá; ọpọlọpọ ji irẹsi afiṣeranwọ ti wọn sì ń ta agolo kan lẹhin naa fun 20 owo dọla ati ju bẹẹ lọ. Àrùn wà nibẹ nigba gbogbo, paapaa àrùn kọlẹra, niwọn bi a ti pa ipese omi, eto imọtoto, ati ina manamana ilu naa run patapata.
Iye ti ó tó ẹgbẹrun kan awọn Ẹlẹ́rìí ti ń gbé ni Monrovia jiya gidigidi pẹlu. Ọpọ julọ sá kuro ninu ilu wọn sì lọ si igberiko, nigba ti awọn miiran fi ibẹ silẹ nipasẹ ọkọ oju omi lọ si Ghana ati Nigeria tabi nipasẹ ọkọ oju ọna lọ si Côte d’Ivoire tabi Sierra Leone. Lati July si December 1990, iye ti o ju 30 awọn Ẹlẹ́rìí padanu ẹmi wọn. A yinbọn pa awọn awọn kan, nigba ti awọn miiran kú lati inu iyọrisi aisan ati ebi. Alan Battey ati Arthur Lawson, awọn ara America ti wọn jẹ́ ojihin iṣẹ Ọlọrun akẹkọọyege lati Ile-ẹkọ Idanilẹkọọ Iṣẹ-ojiṣẹ ni o han gbangba pe wọn wa lara awọn wọnni ti a pa. Óò, ireti ajinde ti a gbekari Bibeli ti jẹ itunu tó fun awa ti a padanu awọn ibatan ati ọrẹ laaarin akoko buburu yẹn!—Iṣe 24:15.
Ẹgbẹ́ Ara Kristẹni Lẹnu Iṣẹ
Gẹgẹ bi ogun naa ti ń baa lọ, ọpọlọpọ awọn Ẹlẹ́rìí ti a fipa lé kuro salọ si ẹka ọfiisi awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ati ile ojihin iṣẹ Ọlọrun kan ni odikeji ilu fun ibi ìsádi. Awọn kan wá aabo nitori pe wọn jẹ́ mẹmba ẹ̀yà tí awọn ọmọ ogun ní agbegbe naa ń pa. Ọpọ julọ ni a fun ni iṣẹ ayanfunni ni ẹka ọfiisi wọn sì jẹ́ koṣeemani ninu ṣiṣeranwọ pẹlu ounjẹ sísè ati imọtoto, nigba ti a yan awọn miiran lati wá ẹ̀fọ́ ti ó ṣee jẹ kiri ninu irà ti ó wà nitosi nigba ti awọn ipo ẹhin ode ba yọnda.
Awọn eniyan ń sun nibi gbogbo, ninu yàrá ibuwọ awọn ojihin iṣẹ Ọlọrun, ni ọ̀dẹ̀dẹ̀, ni Ẹka Ikẹruranṣẹ, ati ninu ọfiisi. Awọn ṣáláńgá ni a gbẹ́ ti a sì ń tọju deedee. Awọn obinrin ni a yan lati ṣiṣẹsin gẹgẹ bii nọ́ọ̀sì, wọn sì bojuto ọpọlọpọ ọran àmódi ati ibà. Ìgbẹ́ ọ̀rìn ni ó saba maa ń jẹ iṣoro.
A ṣeto awọn ọna igbekalẹ ile akanṣe, papọ pẹlu itọni nipa bọmbu. Nipa bayii, nigba ti awọn ipá olódì ba yin awọn bọmbu àgbá nla, a kọ́ wa lati tete sare lọ agbegbe ẹka ofiisi naa. Bi o tilẹ jẹ pe ogiri wa ẹlẹsẹ bata mẹwaa ni giga jẹ́ aabo kan, kò tó lati sé awọn ọta ibọn arọjo ọta. Orule wa laipẹ ni irisi ajere nitori gbogbo awọn iho ti ó ti ni!
Ọpọlọpọ fi ẹmi wọn wewu lati daabobo awọn Ẹlẹ́rìí ẹlẹgbẹ wọn kuro lọwọ awọn wọnni ti wọn ń wa ọna lati pa wọn nitori pe wọn jẹ́ ti ẹ̀yà ti a koriira kan. Ni ọjọ kan Kristẹni arabinrin kan pẹlu omije loju dé si ọfiisi ẹka pẹlu awọn ọmọ rẹ ti ń bẹ laaye, ọ̀kan jẹ́ ọmọ ọwọ ọlọsẹ meji. Ọkọ rẹ̀ ati ọmọkunrin rẹ̀ ọdọlangba ni a ṣẹṣẹ yinbọn lù ni oju rẹ̀ gan-an. Oun ati awọn ọmọ rẹ̀ yooku ni Ẹlẹ́rìí miiran ti tọju pamọ lọna yiyọrisi rere nigba ti awọn apani naa pada wá lati wá wọn.
Idile miiran dé si ẹka ọfiisi pẹlu akede ti a kò tii bamtisi kan ti ó ti ṣeranlọwọ lati daabobo wọn kuro lọwọ didi ẹni ti a pa lati ọwọ awọn ara ilu rẹ̀. Lẹhin naa, nigba ti ipo naa yipada ti akede ti a kò tii bamtisi naa sì wá wà ninu ewu, idile naa daabobo o kuro lọwọ awọn ara ilu wọn.
Leralera, awọn ojihin iṣẹ Ọlọrun yoo ba awọn ọkunrin adihamọra ogun sọrọ lẹnu ọna abawọle si ẹka ọfiisi naa lati gbiyanju lati dá wọn duro kuro ninu titu tabi jiji nǹkan ninu ile naa. Lẹẹkanri awujọ onibiinu kan ya wọ inu ile, ni didawa duro pẹlu ibọn ti wọn sì ń fi dandan sọ pe a ń tọju awọn mẹmba ẹ̀yà pato kan pamọ. A yà wọn lẹnu lati ri bi awọn Ẹlẹ́rìí adugbo ti huwa lọna jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ tó, ni jijokoo ni idakẹjẹẹ ti wọn sì ń fetisilẹ ní ipade Kristẹni ti a ń ṣe. Wọn tú ile naa ṣugbọn wọn kò ri ohun ti wọn ń wá. Ó ṣeeṣe fun wa nigba gbogbo lati mu un dá awọn alatojubọ naa loju pe awa kò tọju awọn ọmọ ogun tabi ọta wọn eyikeyii. Gẹgẹ bii Kristẹni a jẹ́ alaidasi tọtuntosi.
Lẹẹkanri lakooko ìjà kikankikan, awujọ awọn Ẹlẹ́rìí kan dé si ẹka ọfiisi wọn gbe arakunrin kan ti o ní àrùn kansa ayọrisi iku dani. Lọna ti ó banininujẹ, ó kú laipẹ lẹhin naa. Isà oku ni a gbẹ́ ninu agbala naa, aato isinku arumọlara soke wo ni a sì ṣe! Arakunrin naa ti jẹ ọ̀kan lara awọn alagba didara julọ ni adugbo, pẹlu ọpọlọpọ awọn ọdun iṣẹ-isin oloootọ. Nǹkan bii ọgọrun-un awọn eniyan ti a fipa lé kuro pejọpọ ninu ìloro fun ọrọ asọye isinku naa, eyi ti a sọ nigba ti ìró ibọn ń dun labẹlẹ.
Riri Ounjẹ Ati Omi Gba
Awọn ipese ounjẹ mọniwọn gan-an. Ani ṣaaju ki ogun tó bẹrẹ paapaa, awọn oniṣowo ti dawọ kiko ọja wọle duro. Nipa bayii iwọnba ounjẹ ti o kere ni ó ṣẹku ninu ilu. Ipese ounjẹ wa ni ẹka ọfiisi ìbá ti tó mẹmba idile wa ti a jẹ́ 12 fun ọpọlọpọ oṣu, ṣugbọn nigba miiran a ni awọn eniyan ti ó to 200 ti wọn ń gbe pẹlu wa, ti ó ni awọn aladuugbo ti kii ṣe Ẹlẹ́rìí ti wọn fi igbekuta nilo iranlọwọ. Olukuluku ni a fi mọ si ounjẹ kekere kan loojọ; a walaaye lori iru ounjẹ bẹẹ fun awọn osu melookan. Olukuluku ni ebi ń pa. Awọn ọmọ ti rù kan eegun, ti wọn rọ̀ jọwọrọ si apá awọn obi wọn.
Laipẹ ipese ounjẹ wa ń tan lọ. Nibo ni a o ti ri sii? Kò si ile itaja kankan ti a ṣí ni Monrovia. Ibikibi ti ẹnikan bá yiju si, awọn eniyan ti ebi ń pa ń rin gbéregbère ni oju popo ni wiwa ounjẹ. Awọn eniyan ń jẹ ohunkohun—ti o ni ninu awọn aja, ologbo, ati eku. Awọn ojihin iṣẹ Ọlọrun meji lati ẹka pinnu lati gbiyanju lati lọ si Kakata, ilu kan ti ó jinna to nǹkan bii 40 ibusọ, nibi ti ìjà jíjà ti dawọduro.
Wọn kó awọn iwe irohin Ilé-ìṣọ́nà ati awọn ami soju ferese ọkọ ayọkẹlẹ naa lati fi araawọn han gẹgẹ bi Ẹlẹ́rìí Jehofa. Lẹhin kikọja awọn oniruuru ibi iṣayẹwo ọkọ irinna, ọkunrin titobi kan, ti ó taagun dá wọn duro, ó bi wọn nibeere pẹlu awọn bọmbu keekeeke ti ó so kọ́ àyà rẹ̀ ati ibọn revolver kan ni ẹgbẹ rẹ̀. Wọn fi araawọn han gẹgẹ bi Ẹlẹ́rìí Jehofa wọn sì sọ fun un pe wọn fẹ lọ si Kakata lati ra ounjẹ diẹ.
Ó sọ pe, “ẹ tẹle mi. Emi ni olori ogun nihin-in.” Ó mu wọn lọ si orile-iṣẹ rẹ̀. Nigba ti ó mọ pe awọn eniyan ti a fipa lé kuro ni ile wọn ń bẹ lọdọ wọn, ó paṣẹ fun awọn okunrin rẹ̀ lati kó 20 apo irẹsi lọ si ẹka ọfiisi wa, ti ọkọọkan wọ̀n 100 pounds! Pẹlupẹlu, iyọnda ni a fifun wọn lati lọ si Kakata, a sì yan ẹ̀ṣọ́ adihamọra kan lati mu wọn kọja laisewu ni ibi iṣayẹwo ọkọ irinna ti ó kù.
Ni Kakata wọn ri Kristẹni arakunrin wa Abraham ti ó ni ile itaja kan. Ó ti kó awọn paali ounjẹ jọ pelemọ silẹ fun wa, papọ pẹlu miliiki oniyẹfun, ṣuga, ẹfọ inu agolo, ati awọn ohun koṣeemani miiran. Ó jẹ́ agbayanu nitootọ lati ri ọna ti a gbà bojuto awọn arakunrin wa ninu irin ajo wọn. Inu Jehofa ti nilati dun pe a ṣajọpin ounjẹ wa pẹlu awọn ọrẹ ati aladuugbo, nitori nisinsinyi awọn ipese wa ni a tun mu di ẹkunrẹrẹ.—Owe 11:25.
Ni apa Monrovia miiran, awọn ojihin iṣẹ Ọlọrun ti wọn wà ninu ile ojihin iṣẹ Ọlọrun kan ń bojuto awọn ti a fipa lé kuro pẹlu, awọn pẹlu sì gba itilẹhin lati awọn orisun ti a kò reti tẹlẹ. Fun apẹẹrẹ, ojihin iṣẹ Ọlọrun kan ri apo irẹsi mẹta gbà lati ọdọ ọmọ ogun kan ẹni ti ó ranti rẹ̀ lati igba ti ó ti ṣiṣẹsin ní agbegbe ọmọ ogun naa ni nǹkan bii 16 ọdun ṣaaju. Ojihin iṣẹ Ọlọrun miiran ri apo irẹsi mẹrin gba lẹhin ifọrọwani lẹnuwo ti ó nikan ṣe pẹlu aṣaaju ọ̀kan lara awọn ẹgbẹ ti ń jagun.
Lori koko kan ó dabi pe a nilati ṣí kuro ni ẹka ọfiisi naa nitori aito omi. Kanga wa ni ó jẹ́ kiki orisun omi mimu fun ọpọlọpọ eniyan ni adugbo fun akoko kan. Bi o ti wu ki o ri, ipese epo fun ẹrọ ti ń pese ina ẹlẹtiriki fun ẹrọ ìfami wa bẹrẹ sii tan lọ. Nigba ti ọkunrin kan ti o ti ri idaabobo gba ni ẹka ọfiisi ni awọn ọjọ akọkọ ìjà jija gbọ nipa iṣoro wa, ó wa epo rí fun wa nititori imọriri fun ohun ti a ti ṣe fun un, nitori naa ipese omi wa kò tan.
Titọju Okun Tẹmi
Nigba ti a rọ awa ojihin iṣẹ Ọlọrun ti o ṣẹ́kù lati fi Liberia silẹ ni October 1990, ohun ti ó wa loke ọkàn wa ni, Bawo ni awọn arakunrin ati arabinrin wa yoo ṣe koju ipo naa? Lati inu irohin ti a ti rí gba lati akoko yẹn, ó ṣe kedere pe ọwọ́ wọn ti dí ninu iṣẹ-ojiṣẹ.
Ṣaaju ogun ipindọgba wakati ti Ẹlẹ́rìí kọọkan lo ninu iṣẹ-ojiṣẹ jẹ nǹkan bi 17 ni oṣooṣu. Sibẹ, lakooko ogun naa, laika aini igba gbogbo lati wá ounjẹ kaakiri ninu igbó sí, awọn Ẹlẹ́rìí ni awọn ijọ kan ni ipindọgba 20 wakati fun akede kan! Ju bẹẹ lọ, nitori aito iwe irohin Ilé-ìṣọ́nà, ọpọlọpọ awọn arabinrin wa ṣe àdàkọ ọrọ-ẹkọ ikẹkọọ pẹlu ọwọ ki awọn ẹ̀dà pupọ sii ba lè wà lati lọ yika fun ikẹkọọ ni ọjọ Sunday.
Awọn ijọ mẹrin ti wọn sunmọ Monrovia julọ ń kun àkúnya fun awọn Ẹlẹ́rìí ti wọn ti sá fun ìjà ninu ilu naa. Awọn ọrẹ wọnyi padanu ohun gbogbo ti wọn ni, niwọn bi kò ti ṣeeṣe fun wọn lati pada lọ sinu ile wọn lati mu ohunkohun. Nitootọ, fun ọpọlọpọ oṣu ọpọlọpọ wà ni ìhà didojukọra ninu ìjà naa kuro lọdọ awọn ọmọ ati obi tiwọn funraawọn! Fun Iṣe-iranti iku Jesu ni March 30, ijọ mẹrin wọnyi ni apapọ 1,473 awọn eniyan ti wọn wá.
Awọn Ẹlẹ́rìí 300 tabi ti ó sunmọ ọn ti wọn ṣẹku ni Monrovia ṣe akanṣe isapa lati ṣe aṣaaju-ọna oluranlọwọ laaarin oṣu Iṣe-iranti naa, ani bi o tilẹ jẹ pe ni kiki iwọnba awọn ọsẹ diẹ ṣaaju, wọn ti jẹ alailera niti ara ìyára nitori ebi debi pe wọn fẹrẹẹ ma lè rin. Wọn ṣiṣẹ kára gan-an lati ké si awọn eniyan si Iṣe-iranti, 1,116 ni wọn sì wá.
Kristẹni alagba kan ni Monrovia ṣalaye pe: “A pinnu lati bẹrẹ ipade ninu Gbọngan Ijọba wa lẹẹkansi bẹrẹ ni December 1990. Iye awọn eniyan ti wọn wa lakọọkọ jẹ 17. Lẹhin naa ó lọ soke si 40, ó sì wà ni 40 fun igba kan. Lẹhin naa ni February 24, iye awọn eniyan ti wọn wá ga soke si 65 ati ni ọsẹ kan lẹhin naa si 85. Pẹlupẹlu, ó fẹrẹẹ jẹ́ gbogbo eniyan ninu ijọ ni wọn dahunpada si ikesini lati ṣe aṣaaju-ọna oluranlọwọ ni March.”
Titọju Awọn Ẹlomiran
Ibatan Ẹlẹ́rìí kan ti oun funraarẹ kii ṣe Ẹlẹ́rìí sọ pe, “awọn arakunrin wa ni ṣọọṣi ni ọwọ wọn dí ni pipa araawọn ẹnikinni keji [lati inu awọn ẹ̀yà ti wọn dojukọra] lakooko ogun naa, laini akoko fun awọn onigbagbọ ẹlẹgbẹ wọn lae.” Ṣugbọn ipo naa ti yatọ tó pẹlu awọn eniyan Jehofa!
Fun apẹẹrẹ, alaga ẹgbẹ́ iranlọwọ itura kan ni adugbo kọwe si awọn ará ti wọn ń bojuto ẹka ọfiisi ni February 1991 pe: “Lẹta yii jẹ́ gẹgẹ bi àmì ọpẹ ati imọriri si yin ati eto idasilẹ yin fun ipese ìkóúnjẹpamọ́ ti ẹ ń baa lọ lati fun wa lakooko ipinkiri ounjẹ fun awọn eniyan. Iṣesi afẹ́nifẹ́re yin fi imuratan yin han gẹgẹ bi Ẹgbẹ́ kan lati mu alaafia ati ifẹ inurere wá fun orilẹ-ede. Ẹ jọwọ ẹ maa bá iṣẹ-isin rere yin lọ.”
Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni awọn orilẹ-ede miiran yara dahunpada kanmọkanmọ si aini awọn arakunrin wọn ni Liberia. Aranṣe itura ni a ti pese lati iru awọn orilẹ-ede bii Sierra Leone ati Côte d’Ivoire ni Iwọ-oorun Africa, Netherlands ati Italy ni Europe, ati United States.
Ọmọbinrin kekere kan, ẹni ti a pa iya rẹ̀ nitori pe ó jẹ́ mẹmba ẹ̀yà ti a koriira sọ imoore rẹ̀ fun aranṣe ti ó rí gba. Ó kọwe pe: “Ẹ ṣeun pupọ fun gbogbo ohun ti ẹ fi ranṣẹ si mi. Ẹ mu mi nimọlara bii pe iya mi wà nitosi mi. Mo padanu rẹ̀ ati arakunrin mi kekere ninu ogun. Mo beere pe ki Jehofa bukun gbogbo yin. Mo jẹ́ ẹni ọdun 11.”
Arakunrin kan ti o ni idile ẹlẹni mẹfa ti iyawo rẹ̀ sì nilati sapamọ fun ọpọlọpọ oṣu nitori ipilẹṣẹ ẹ̀yà rẹ̀, ti o tun kun fun ọpẹ fun aranṣe ti ó rí gba kọwe pe: “Awa kò tii fọ́ ile awọn eniyan lati jí ki a sì ta awọn ohun ìní wọn ati sibẹ, laidabi awọn aladuugbo wa, a ni ohun jijẹ lojoojumọ nitori pe a mọ bi a tii lo iwọnba ohun ti a ni lọna ọgbọn. Eyi ni a ti kọ lati ọdọ Jehofa.”
Eyi ti ó tun wuni lori ni ẹmi arakunrin kan ti ó ti salọ si Côte d’Ivoire pẹlu aya rẹ̀ ati awọn ọmọ rẹ̀ meji. Ó ti fi ile daradara kan silẹ sẹhin ti a jó kanlẹ lẹhin naa. Sibẹ ó sọ pe ohun ti ó dun oun julọ ni ipadanu ibi ìkówèésí iṣakoso Ọlọrun rẹ̀, kii ṣe ile rẹ̀!
Awọn Ẹkọ Ṣiṣeyebiye Ti A Kọ́
Ni wiwẹhin pada, mo lè mọ lẹkun-unrẹrẹ pe Jehofa kọ́ wa ni ọpọlọpọ awọn ẹkọ ṣiṣeyebiye. Ni fifunraami mọ̀ ọpọlọpọ ti wọn pa iwatitọ wọn mọ́ ti wọn sì laaja, ati bakan naa awọn diẹ ti wọn pa iwatitọ wọn mọ ti wọn sì kú, mo kẹkọọ lati mọriri ijẹpataki nini ẹmi ironu ero ori apọsiteli Pọọlu ẹni ti ó kọwe pe: “Nitori bi a bá walaaye, awa walaaye fun Oluwa [“Jehofa,” NW]; bi a bá sì kú, awa kú fun Oluwa [“Jehofa,” NW]: nitori naa bi a walaaye, tabi bi a kú ni, ti Oluwa [“Jehofa,” NW] ni awa ń ṣe.”—Roomu 14:8.
Ojihin iṣẹ Ọlọrun alakooko pipẹ miiran sọ pe: “La gbogbo eyi já, a kẹkọọ pe Jehofa jẹ́ Oluranlọwọ ti kò lẹgbẹ. Gan-an gẹgẹ bi Pọọlu ti sọ: ‘A ni idalẹbi ikú ninu araawa, ki awa ki ó ma baa gbẹkẹle araawa, bikoṣe Ọlọrun ti ń jí oku dide.’ (2 Kọrinti 1:9; Saamu 30:10) Ó fikun un pe: “Ogun naa mu un ṣe kedere fun wa pe awọn eniyan Jehofa jẹ́ ẹgbẹ́ ará kan nitootọ, ti a fi ifẹ ifara-ẹni rubọ tí Jesu tẹnumọ wọ̀ ni aṣọ.”—Johanu 13:35.
Lẹta kan lati ọdọ arabinrin ara Liberia kan si diẹ lara awa ojihin iṣẹ Ọlọrun ti a ti fi orilẹ-ede naa silẹ lakooko ìjà ni October 1990 ṣapejuwe okun ẹgbẹ́ ará Kristẹni wa daradara. “Ó jẹ́ adura mi pe ki gbogbo yin pada si Liberia laipẹ ki awa si lè ni apejọ kan,” ni ó kọwe. “Óò! Emi kò lè duro fun ọjọ yẹn. Ani ironu nipa rẹ̀ gan-an ń mu mi layọ.”
Bẹẹni, yoo jẹ́ agbayanu lati ri ẹkunrẹrẹ imupadabọsipo ọna igbaṣe deedee ti igbokegbodo Kristẹni ni Liberia. Arabinrin wa tọna; apejọ akọkọ ni Monrovia lẹhin ipada awọn ojihin iṣẹ Ọlọrun ati awọn olùwá ibi ìsádi miiran yoo jẹ́ alayọ kan. Kò si iyemeji nipa iyẹn!
[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 27]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an.)
LIBERIA
Monrovia
Kakata
Gbarnga
Ganta
SIERRA LEONE
GUINEA
CÔTE D’IVOIRE
Atlantic Ocean
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]
Awọn ọmọ Ẹlẹ́rìí ti a fipa lé kuro ni ẹka ọfiisi ni akoko ogun naa
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]
Awọn olùwá ibi ìsádi ara Liberia ń ṣeto awọn aṣọ ti awọn Ẹlẹ́rìí ni Côte d’Ivoire fi tọrẹ