Mímú Eyi Ti Ó Kẹhin Ninu Awọn Akajọ-iwe Okun Oku Jade
NI September ti ó kọja, idena ti ń bẹ niwaju awọn ọmọwe ti ó ti wà fun ọpọ ẹ̀wádún já nikẹhin. Ọpẹ́ alayé laaarin awọn akẹkọọ Akajọ-iwe Okun Oku jọ pe ó ti dopin, bi o tilẹ jẹ pe ọpẹ́ alayé titun ti lè bẹrẹ.
Awọn Akajọ-iwe Okun oku ni a ri ninu awọn ihò lẹbaa Okun Oku ni 1947 ati ni awọn ọdun ti wọn tẹle e. Wọn jẹ́ iyebiye gan-an ni fifi ipeye ṣiṣekoko ti ọrọ iwe Iwe Mimọ lede Heberu han ati ni títan imọlẹ sori awọn ipo isin ni Palẹstini nigba ti Jesu wà lori ilẹ-aye. (Aisaya 40:8) Nigba ti o jẹ pe awọn iwe afọwọkọ kan ni a tẹjade ni kiakia lọna ti o lọgbọn-ninu, ni 1991 ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó 400 iwe afọwọkọ ti a ko tii tẹjade sibẹ ti kò sì sí larọọwọto ọpọjulọ awọn ọmọwe. Ọpọlọpọ, bii Ọjọgbọn Ben Zion Wacholder, nimọlara “ijakulẹ nipa wíwá mọ̀ pe ni iwọn ìyára ìtẹ̀wé ti lọ́ọ́lọ́ọ́ gbogbo wa ni a o ti kú nigba ti akojọ ọrọ ẹsẹ iwe Okun Oku bá fi maa walarọọwọto gbogbo eniyan.”
Ṣugbọn ipo yẹn yipada ni September ti ó kọja. Lakọọkọ, Ọjọgbọn Wacholder ati olubakẹgbẹ kan, Martin Abegg, kéde pe wọn ti lo ẹrọ kọmputa lọna ihumọ lati ṣe ìtúntẹ̀ awọn ọrọ iwe ti a ṣọ́ loju mejeeji naa. Lẹhin naa, Ibi Akojọ Iwe Kíkà Huntington ni San Marino, California, U.S.A., kéde pe wọn ni aworan iwe afọwọkọ ipilẹṣẹ naa ati pe wọn yoo mu iwọnyi wà larọọwọto lọfẹẹ fun awọn lóókọlóókọ ọmọwe. Ó ṣe kedere pe iye awọn ẹ̀dà akajọ-iwe naa ti a yaworan rẹ̀ ni a ti ṣe lati mu ipamọ wọn daju. Ọ̀wọ́ awọn aworan ni a ti kopamọ si ọgangan ọtọọtọ, ati lẹhin-ọ-rẹhin ọkan di eyi ti o wà ni Ibi Akojọ Iwe Kíkà Huntington.
Ọmọwe kan pe iyipada awọn iṣẹlẹ yii ni ‘ibadọgba iyalulẹ Ogiri Berlin niti awọn ọmọwe.’ Awọn ọtẹwe ti a faṣẹ tilẹhin pe itẹjade ọrọ iwe ti a fi kọmputa ṣe naa ati imujade awọn aworan naa ni ‘ole jija.’ O ṣeeṣe, ìjiyàn naa nipa ilana iwahihu yoo maa jà ràn-ìnràn-ìn lọ fun ọpọlọpọ ọdun. Ni akoko yii ná, ó dabi ẹni pe awọn ọmọwe pupọ sii yoo lè lọ sinu odidi Akajọ-iwe Okun Oku naa nikẹhin.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 32]
Apẹẹrẹ iwe alaye lori Habakuku, ọ̀kan lara awọn Akajọ-iwe Okun Oku