ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w92 12/15 ojú ìwé 30
  • Iwọ Ha Ranti bi?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Iwọ Ha Ranti bi?
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • “Ẹ Mú Gbogbo Idamẹwaa Wá Sí Ile-Iṣura”
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Ìdá Mẹ́wàá?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • “Awa Ti Rí Messia”!
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Ibukun Jehofa Níí Múniílà
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
w92 12/15 ojú ìwé 30

Iwọ Ha Ranti bi?

Iwọ ha ti gbadun kika awọn itẹjade Ilé-Ìṣọ́nà ti ẹnu aipẹ yii bi? Bi o ba jẹ bẹẹ, iwọ laisi àníàní yoo ri i gẹgẹ bi eyi ti ń fanilọkan mọra lati pada ranti awọn ti o tẹ̀lé e yii:

▫ Ẹ̀rí ayinileropada wo ni a fi funni nipasẹ oniruuru ọ̀nà ìṣiṣẹ́ ẹmi mimọ ni ọrundun kìn-ín-ní? Ìṣiṣẹ́ wọnyi pese ẹ̀rí ti o ṣeefojuri pe Ọlọrun kò tún lo ijọ Israeli ọlọdun 1,500 mọ́ gẹgẹ bi awọn eniyan akanṣe, ṣugbọn ifọwọsi rẹ̀ nisinsinyi wà pẹlu ijọ Kristian titun naa, tí Ọmọkunrin bíbí-kanṣoṣo rẹ̀ dasilẹ. (Fiwe Heberu 2:2-4.)—8/15, oju-iwe 5.

▫ Ki ni o ṣalaye idi fun idagbasoke àrà-ọ̀tọ̀ tí awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa niriiri rẹ̀? Ni pataki, eyi jẹ́ nitori ibukun Ọlọrun. Iṣẹ Ọlọrun ni. Ohun ti awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa fi ń kọni ninu iṣẹ́ ijihinrere wọn ni a gbekari Bibeli. Kọkọrọ miiran si aṣeyọri wọn ní mimọ Kristi Jesu daju gẹgẹ bi Ori ijọ Kristian ti a yàn sipo.—9/1, oju-iwe 19.

▫ Eeṣe ti Jehofa fi fi aanu hàn fun Dafidi nipa ti ẹṣẹ nla rẹ̀ pẹlu Batṣeba? Ni pataki eyi jẹ́ nitori majẹmu Ijọba naa ti Ọlọrun ti ṣe pẹlu Dafidi, ṣugbọn o tún jẹ́ nitori ìláàánú ti Dafidi funraarẹ ati ojulowo ironupiwada rẹ̀. (1 Samueli 24:4-7; 2 Samueli 7:12; 12:13; Orin Dafidi 51:1, 2, 17)—9/15, oju-iwe 10, 11.

▫ Ki ni oriṣi mẹta awọn ẹ̀rí ti Iwe Mimọ Kristian Lede Griki fi funni ni itilẹhin fun ipo Messiah Jesu? Ìlà-ìran Jesu ni ẹ̀rí akọkọ. (Matteu 1:1-16; Luku 3:23-38) Ẹ̀rí miiran ni asọtẹlẹ ti a muṣẹ. Ọpọ jaburata awọn asọtẹlẹ gidi ni o wà, iru eyi ti a ri ninu Danieli 9:25, eyi ti o fi Jesu hàn gẹgẹ bii Messia naa. Ẹ̀rí kẹta ni ẹ̀rí Ọlọrun funraarẹ; o pese eyi ni awọn akoko iṣẹlẹ mẹta pẹlu ohùn rẹ̀ funraarẹ. (Matteu 17:5; Luku 3:21, 22; Johannu 12:28)—10/1, oju-iwe 10, 12.

▫ Ki ni ohun ti Jesu ní lọ́kàn nigba ti o sọ, gẹgẹ bi a ti ṣakọsilẹ rẹ̀ ninu Matteu 24:37 pe: “Gẹgẹ bi ọjọ Noa si ti ri, bẹẹni wíwá ọmọ-eniyan yoo si ri”? Noa ń kan ọkọ̀ áàkì ó sì ń kilọ fun awọn eniyan buburu fun ọpọ ẹwadun ṣaaju ki Ikun-omi naa tó dé ti ó sì gbá eto-igbekalẹ ayé oniwapalapala yẹn lọ. Bẹẹ gẹgẹ, wíwà-níhìn-ín alaiṣeefojuri ti Kristi wà fun ohun ti o ju sáà ọpọ ẹwadun lọ ṣaaju kí ó tó pari sí iparun ńláǹlà pẹlu.—10/1, oju-iwe 16.

▫ Ki ni diẹ ninu awọn ohun ṣiṣe pataki fun ikẹkọọ Bibeli idile daradara kan? A nilati ya akoko sọtọ fun ikẹkọọ naa. A kò nilati yọọda ki tẹlifiṣọn tabi ohun ipinya miiran dipo rẹ̀. Awọn aini pataki idile naa ni a nilati gbeyẹwo. Lo awọn ibeere olójú-ìwòye lati rii daju pe awọn ọmọde naa loye ohun ti wọn ń kẹkọọ. (Matteu 17:25) Jẹ ki ayika naa jẹ eyi ti o dẹnilara. Jẹ onitara-ọkan, ki o sì jẹ ki olukuluku lọwọ ninu ikẹkọọ naa.—10/15, oju-iwe 17.

▫ Bawo ni awọn Kristian ṣe nilati daniyan tó nipa pe awọn èròjà inu ẹ̀jẹ̀ ni o ti ṣeeṣe ki a pòpọ̀ mọ́ awọn ounjẹ kan ti a ń mújáde? Awọn Kristian nilati ṣọra fun didi ẹni ti a kó idaamu bá nipa iṣeeṣe tabi àgbọ́sọ lasan, a sì nilo ilọgbọn-ninu paapaa nipa ṣiṣayẹwo awọn lébẹ́ẹ̀lì tabi ṣiṣe iwadii nipa awọn alápatà. Bi o ti wu ki o ri, bi o ba di mímọ̀ pe ẹ̀jẹ̀ ni a lò lọna gbigbooro ládùúgbò—yala ninu ounjẹ tabi ninu itọju iṣegun—awọn Kristian nilati ṣọra lati ṣegbọran si aṣẹ Ọlọrun lati fasẹhin kuro ninu ẹ̀jẹ̀. (Iṣe 15:28, 29)—10/15, oju-iwe 30 sí 31.

▫ Bawo ni iwe Owe ṣe tẹnumọ ijinlẹ tẹmi ninu ọ̀nà igbakọni ti a lò ní Israeli? Iwe Owe fihàn pe ète naa ni lati kọ́ “alaimọkan” ni iru awọn nǹkan ti a gbega bii ọgbọ́n, ìbáwí, òye, ijinlẹ-oye, idajọ, ìgbọ́nféfé, ìmọ̀, ati agbara ìrònú—gbogbo eyi ninu “ibẹru Oluwa.” (Owe 1:1-7; 2:1-14)—11/1, oju-iwe 12.

▫ Ki ni ojú-ìwòye wiwadeedee nipa ẹ̀kọ́-ìwé ti awọn ọ̀dọ́ lonii gbọdọ ní? Awọn Kristian nilati ka ẹ̀kọ́-ìwé si ọ̀nà àti rí iyọrisi kan. Ète wọn ní awọn ọjọ ikẹhin wọnyi ni lati ṣiṣẹsin Jehofa gidigidi ati bi o ba ti lè ṣeeṣe ki o gbeṣẹ tó ninu iṣẹ-isin alakooko kíkún bi wọn bá lè ṣe bẹẹ.—11/1, oju-iwe 18.

▫ Eeṣe ti Jehofa fi beere lọwọ orilẹ-ede Israeli lati san idamẹwaa? Lakọọkọ, ki wọn baa lè fi imọriri wọn hàn fun iwarere-iṣeun Jehofa lọna titobi kan. Ekeji, ki wọn baa lè ṣe iranlọwọ fun itilẹhin awọn ọmọ Lefi, ti wọn yoo tipa bẹẹ pọkanpọ sori iṣẹ́ aigbọdọmaṣe wọn, ti o ní ninu kikọni ní Ofin. (Wo 2 Kronika 17:7-9.)—12/1, oju-iwe 9.

▫ Ki ni idamẹwaa ti a kesi awọn Kristian lati mú wá? (Malaki 3:10) Idamẹwaa naa duro fun apa naa ti o jẹ tiwa ti a mú tọ Jehofa wá tabi ti a lò ninu iṣẹ-isin rẹ̀. Eyi jẹ àmì apẹẹrẹ ifẹ wa fun un ati mimọ otitọ naa pe a jẹ tirẹ̀.—12/1, oju-iwe 15.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́