Ó Jà Fun Igbagbọ Rẹ̀
NI ỌDUN mẹta sẹhin Caridad Bazán Listán, ọ̀kan lara awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni Cádiz, Spain, nilo iṣẹ-abẹ ni kanjukanju. Awọn okuta inú àpò-ìtọ̀ ń fa ibà wọn sì ń ba ojú ìṣàn-ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ jẹ́. Nigba ti a gbà á si ile-iwosan adugbo, ó ṣalaye ipo rẹ̀ ti a gbekari Bibeli nipa kíkọ̀ lati gba ìfàjẹ̀sínilára. Awọn dokita gbà lati ṣe iṣẹ́-abẹ naa laisi ẹ̀jẹ̀. Bi o ti wu ki o ri, gẹ́rẹ́ ṣaaju ki wọn tó gbé e wọnu yàra iṣẹ́-abẹ, awọn dokita naa sọ fun un pe ki o fọwọsi iwe-adehun kan. Ó fihàn pe wọn ń fẹ́ lati bọ̀wọ̀ fun ipinnu rẹ̀ nipa ẹ̀jẹ̀ ṣugbọn pe bi ipo pajawiri bá wáyé, wọn fẹ́ ifọwọsi rẹ̀ lati lo itọju yoowu ti wọn bá rí pe ó pọndandan.
Ọmọkunrin Caridad, ti oun pẹlu jẹ́ Ẹlẹ́rìí ati alagba ijọ kan ti o wà nibẹ ni ile-iwosan naa, fi awọn ohun ti fifọwọsi iru fọọmu bẹẹ tumọsi tó Caridad leti. Ifọwọsi rẹ̀ yoo ti fun awọn dokita láṣẹ lati fa ẹ̀jẹ̀ sí i lára bi ipo pajawiri bá lọ ṣẹlẹ. Nigba ti awọn oṣiṣẹ itọju iṣegun dé lati gbé e lọ sinu yàrá iṣẹ́-abẹ, ó ṣalaye pe oun kò ni fọwọ si iwe naa. Ni kukuru ṣá oun ni a dá pada sinu yàrá rẹ̀ ti a sì fi sabẹ ikimọlẹ lati yí ero-inu rẹ̀ pada.
Lẹhin ọpọlọpọ ijumọsọrọpọ wọn pinnu lati pe adajọ ọ̀ràn iṣegun ki ó baa lè yii lero pada, ṣugbọn asan ni ó jásí. Caridad ṣalaye pe oun mọ̀ pe oun yoo jẹbi niwaju Ọlọrun bi oun bá yọnda fun wọn lati fun oun ni ẹ̀jẹ̀. Ó ṣalaye pe labẹ Ofin Mose, bi a bá fi ipá bá obinrin kan lòpọ̀, a kò kà á si ẹni ti o jẹbi bi ó bá yarí nipa kikigbe fun iranlọwọ. (Deuteronomi 22:23-27) “Awọn dokita ń ṣaifiyesi awọn idaniyan mi wọn sì ń gbidanwo lati ba ẹ̀rí-ọkàn mi jẹ́,” ni ó sọ, “nitori naa mo gbọdọ yarí gan-an gẹgẹ bi ẹni pe wọn ń fipá bá mi lòpọ̀.”
Ọpọ wakati kọja, ati nikẹhin awọn dokita gbà lati ṣe iṣẹ́-abẹ fun un laisi ẹ̀jẹ̀. Ninu yàrá iṣẹ́-abẹ, Caridad beere fun iyọọda lati gbadura si Jehofa. Eyi ni oun ṣe, iṣẹ́-abẹ naa sì kẹ́ṣejárí.
Laika eyiini si, lẹhin ìgbà naa ipo Caridad buru sii, awọn dokita sì pinnu lati ṣaika awọn idaniyan rẹ̀ sí ki wọn sì fipa fa ẹ̀jẹ̀ sí i lára. Nipa bayii, dokita kan ati nọọsi kan mura lati fun un ni ẹ̀jẹ̀. Laika ipo rẹ̀ ti kò lera si, Caridad yarí pẹlu gbogbo okun rẹ̀. Ó tilẹ dọgbọn lati gé rọ́bà oníhò ti ẹ̀jẹ̀ naa yoo gbà jẹ. Nikẹhin, oju ti dokita naa gan-an debi pe ó jáwọ́ ninu ohun ti wọn ń ṣe. “Emi kò lè ṣe eyi. Mo yọwọ́-yọsẹ̀!” ni ó sọ.
Caridad la yanpọnyanrin naa já ara rẹ̀ sì yá laini awọn iṣoro miiran mọ́. Ati awọn dokita ati awọn nọọsi ni igbagbọ ati igboya rẹ̀ kò lè ṣai mú ori wọn wú. Gbogbo eyi ṣẹlẹ nigba ti Caridad jẹ́ ẹni ọdun 94.