ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w94 4/1 ojú ìwé 4-7
  • Ayé Dídára Jù Kan—Ó Kù Sí Dẹ̀dẹ̀!

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ayé Dídára Jù Kan—Ó Kù Sí Dẹ̀dẹ̀!
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • “Ìyánhànhàn fún Paradise”​—⁠Èéṣe?
  • Wíwá Paradise Kiri​—⁠Ìtàn Èròǹgbà Kan
  • Àwọn Ibi Aláìlálèébù​—⁠Wọ́n Ha Jẹ́ Ibi Dídárawẹ́kú Bí?
  • Àwọn Kristian àti Ayé Dídára Jù Kan
  • Ṣé Ayé Máa Di Párádísè Lóòótọ́?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2017
  • “Àá Pàdé ní Párádísè!”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2018
  • Ibo Ni Párádísè Tí Bíbélì Sọ Máa Wà?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
  • Párádísè
    Jí!—2013
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
w94 4/1 ojú ìwé 4-7

Ayé Dídára Jù Kan​—⁠Ó Kù Sí Dẹ̀dẹ̀!

“ÌYÁNHÀNHÀN náà fún paradise wà lára àwọn ìyánhànhàn lílágbára tí ó dàbí ẹni pé ó wà lọ́kàn àwọn ènìyàn nígbà gbogbo. Ó lè jẹ́ èyí tí ó lágbára tí ó sì wà pẹ́ jùlọ. Òòfà ọkàn pàtó fún paradise farahàn kedere nínú gbogbo ìpele ìgbésí-ayé ìsìn,” ni The Encyclopedia of Religion sọ.

Ó dàbí ẹni pé gbogbo ẹ̀yà ìran ni ó ní ìfẹ́-ọkàn kan náà fún gbígbé nínú ayé dídára jù kan, bí ẹni pé wọ́n ń dárò èrò-ọkàn ìpilẹ̀ṣẹ̀ kan tí kò sí mọ́. Èyí dábàá ṣíṣeéṣe pé paradise kan wà ní ìpilẹ̀ṣẹ̀, ṣùgbọ́n níbo? Onímọ̀ nípa èrò-inú ènìyàn kan lè sọ pé ìfẹ́-ọkàn lílágbára yìí fi ìfẹ́-ọkàn láti jèrè ààbò tí ẹnìkan ti pàdánù nínú ọlẹ̀ ìyá rẹ̀ hàn. Síbẹ̀ àlàyé yìí kò tẹ́ àwọn ọ̀mọ̀wé tí wọ́n ti kọ́ nípa ìtàn ìsìn lọ́rùn.

“Ìyánhànhàn fún Paradise”​—⁠Èéṣe?

Ǹjẹ́ wíwà tí irú ìyánhànhàn bẹ́ẹ̀ wà, gẹ́gẹ́ bí àwọn kan ti dábàá, wulẹ̀ jẹ́ láti mú kí ìṣòro àti òtítọ́ náà pé ìwàláàyè ènìyàn kúrú túbọ̀ ṣeégbà bí? Tàbí àlàyé mìíràn ha wà bí?

Èéṣe tí aráyé fi ń ṣàfẹ́rí ayé dídára jù kan? Bibeli fúnni ní ìdáhùn ṣíṣe kedere síbẹ̀ tí ó sì rọrùn pé: Aráyé wá láti inú ayé dídára jù kan! Paradise ìpilẹ̀ṣẹ̀ kan ti wà rí níti gidi. Ọ̀rọ̀ Ọlọrun ṣàpèjúwe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí “ọgbà kan” tí ó wà ní agbègbè pàtó kan ní Àárín Gbùngbùn Ìlà-Oòrùn Ayé, tí a fi “onírúurú igi . . . tí ó dára ní wíwò, tí ó sì dára fún oúnjẹ” jíǹkí. Ọlọrun fi í síkàáwọ́ tọkọtaya ènìyàn kìn-⁠ín-ní. (Genesisi 2:​7-⁠15) Ó jẹ́ ìgbékalẹ̀ gbígbámúṣé kan nínú èyí tí àwọn ènìyàn ti lè láyọ̀ níti tòótọ́.

Èéṣe tí àwọn ipò Paradise wọnnì kò fi tọ́jọ́? Lákọ̀ọ́kọ́ nítorí ìṣọ̀tẹ̀ ti ẹ̀dá ẹ̀mí kan àti lẹ́yìn náà ti tọkọtaya ènìyàn kìn-⁠ín-⁠ní. (Genesisi 2:16, 17; 3:1-⁠6, 17-⁠19) Nípa bẹ́ẹ̀, kìí ṣe Paradise nìkan ni ènìyàn pàdánù ṣùgbọ́n ìjẹ́pípé, ìlera, àti ìwàláàyè tí kò lópin pẹ̀lú. Dájúdájú àwọn ipò tí ó wá gbòde kò mú ìgbésí-ayé ènìyàn sunwọ̀n síi. Kàkà bẹ́ẹ̀, ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ èyí ti yọrísí ipò tí a wà nísinsìnyí tí ó burú ju ti ìgbàkígbà rí lọ.​—⁠Oniwasu 3:​18-⁠20; Romu 5:12; 2 Timoteu 3:​1-5, 13.

Wíwá Paradise Kiri​—⁠Ìtàn Èròǹgbà Kan

Gẹ́gẹ́ bí a ti lè rò ó, “ìyánhànhàn fún paradise” ní ìtàn gígùn gan-⁠an ni. Àwọn ara Sumeria rántí àkókò kan nígbà tí ìṣọ̀kan wà ní gbogbo àgbáyé: “Kò sí ìbẹ̀rù, kò sí ìpayà, ènìyàn kò ní alábàádíje. . . . Gbogbo àgbáyé pátá, àwọn ènìyàn ní ìṣọ̀kanpọ̀, fi ìyìn fún Enlil ní èdè kan,” ni èwí Mesopotamia ìgbàanì kan mú wá sí ìrántí. Àwọn kan, gẹ́gẹ́ àwọn ara Egipti ìgbàanì, nírètí láti dé ayé dídára jù kan lẹ́yìn ikú wọn. Wọ́n gbàgbọ́ pé ọkàn àìlèkú kan ń dé ohun tí wọ́n pè ni pápá Aaru. Ṣùgbọ́n tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, ìrètí yìí wà fún ó kérétán kìkì àwọn ọ̀tọ̀kùlú onípò ọlá; àwọn òtòṣì kò lè lálàá dídé ayé aláyọ̀ pípé pérépéré bẹ́ẹ̀.

Ní apá agbègbè ìsìn mìíràn, fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún àwọn Hindu ti dúró de bíbọ̀wá sànmánì ayé dídára jù kan (yuga). Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀kọ́ Hindu ti sọ, àwọn yuga mẹ́rin ni wọ́n ń tẹ̀lé araawọn nínú àyípoyípo aláìlópin, a sì ń gbé nínú èyí tí ó burú jùlọ báyìí. Ó ṣeniláàánú pé, Kali Yuga yìí (sànmánì ojú dúdú), pẹ̀lú gbogbo àwọn ìyà àti ìwà ibi rẹ̀, yóò wà gẹ́gẹ́ bí àwọn kan ti sọ fún 432,000 ọdún. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, àwọn Hindu olùṣòtítọ́ ń dúró de sànmánì aláásìkí náà, Krita Yuga.

Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, àwọn Griki àti Romu lálàá dídé Àwọn Erékùṣù Agbérekoni inú ìtàn àròsọ tí ó wà ní Agbami Òkun Atlantic. Ọ̀pọ̀ àwọn òǹkọ̀wé bíi Hesiod, Virgil, àti Ovid, sọ̀rọ̀ nípa sànmánì aláásìkí àgbàyanu, ní ríretí pé lọ́jọ́ kan a óò mú un padàbọ̀sípò. Ní apá ìparí ọ̀rúndún kìn-⁠ín-⁠ní B.C.E., Virgil, akéwì ọmọ ilẹ̀ Latin sàsọtẹ́lẹ̀ dídé aetas aurea (sànmánì aláásìkí) titun tí yóò tọ́jọ́ tí ó súnmọ́lé. Ní àwọn ọ̀rúndún tí ó tẹ̀lé e, “kò dín ní mẹ́rìndínlógún lára àwọn olú-ọba ilẹ̀ Romu tí wọ́n jẹ́wọ́ pé àkóso wọn ti fìdí Sànmánì Aláásìkí múlẹ̀ lẹ́ẹ̀kan síi,” ni ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The Encyclopedia of Religion sọ. Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí a ti mọ̀ dáradára lónìí, ìyẹn wulẹ̀ jẹ́ ìgbékèéyíde òṣèlú lásán.

Ọ̀pọ̀ àwọn Celt lépa ohun tí wọn rò pé ó jẹ́ ilẹ̀ rírẹwà lórí erékùṣù kan (tàbí ní àgbájọ àwọn erékùṣù) ní òdìkejì òkun, níbi tí wọ́n gbàgbọ́ pé àwọn ènìyàn ń gbé pẹ̀lú ayọ̀ pípé. Gẹ́gẹ́ bí ìtàn àròsọ kan ti wí, Ọba Arthur, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó farapa yánnayànna, ó ń bá a lọ láti wàláàyè lẹ́yìn tí ó ti rí erékùṣù yíyanilẹ́nu kan tí a ń pè ní Avalon.

Ní àkókò ìgbàanì àti ní Sànmánì Agbedeméjì, ọ̀pọ̀lọpọ̀ rò pé ọgbà ìdùnnú gidi kan, ọgbà Edeni, ṣì wà níbìkan, “lórí òkè kan tí kò ṣeédé tàbí lódìkejì òkun kan tí kò ṣeérékọjá,” ni òpìtàn náà Jean Delumeau ṣàlàyé. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé akéwì ọmọ ilẹ̀ Italy náà Dante gbàgbọ́ nínú paradise ti ọ̀run kan, ó ronúwòye pe paradise ilẹ̀-ayé kan ṣì wà lórí òkè Purgatory rẹ̀, ní òdìkejì ìlú-ńlá Jerusalemu. Àwọn kan gbàgbọ́ pé Asia ni a ti lè rí i, ní Mesopotamia, tàbí lórí àwọn òkè Himalaya. Àwọn ìtàn àròsọ Sànmánì Agbedeméjì nípa paradise Edeni pọ̀ jaburata. Ọ̀pọ̀ gbàgbọ́ pé nítòsí paradise náà, ìjọba àgbàyanu kan wà tí Prester John ẹlẹ́mìí-ìsìn náà ń ṣàkóso. Ọpẹ́ ní fún ìsúnmọ́tòsí paradise ilẹ̀-ayé náà, ìgbésí-ayé nínú ìjọba Prester John ní wọ́n sọ pé ó pẹ́ tí ó sì kùn fún ayọ̀ pípé pérépéré, orísun ànító àti ọrọ̀ tí kìí tán. Àwọn mìíràn tí wọ́n fi àwọn ìtàn àròsọ Griki ìgbàanì sọ́kan, ronú pé àwọn erékùṣù paradise ní a níláti rí ní Atlantic. Àwọn àwòrán ojú-ilẹ̀ ti Sànmánì Agbedeméjì fi ìdálójú ìgbàgbọ́ bẹ́ẹ̀ hàn nínú wíwà ọgbà Edeni, kódà ni fífi ojú ibi tí a rò pé ó wà hàn.

Ní ọ̀rúndún kẹẹ̀ẹ́dógún àti ìkẹrìndínlógún, àwọn awakọ̀ ojú omi tí wọ́n sọdá Atlantic ń wá ayé tí ó ti fìgbàkan wà rí, lẹ́ẹ̀kan àti nígbà kan náà, tí ó jẹ́ titun àti ti àtijọ́. Wọ́n ronú pé lódìkejì agbami òkun náà, wọn yóò rí ọgbà Edeni náà kìí ṣe kìkì àwọn ará Indies. Christopher Columbus, fún àpẹẹrẹ, wá a kiri láàárín àwọn òkè olótùútù àti àwọn ilẹ̀ olóoru ní Gúúsù àti Àárín Gbùgbùn America. Àwọn ọmọ ilẹ̀ Europe olùṣèwádìí tí wọ́n dé sí Brazil ní ó dá lójú pé paradise tí ó sọnù náà gbọ́dọ̀ wà níbẹ̀ nítorí ipò ojú ọjọ́ wíwà déédéé àti oúnjẹ àti ewéko púpọ̀ jaburata. Bí ó ti wù kí ó rí láìpẹ́ láìjìnnà, wọ́n fi tipátipá mọ òtítọ́ kíkorò náà.

Àwọn Ibi Aláìlálèébù​—⁠Wọ́n Ha Jẹ́ Ibi Dídárawẹ́kú Bí?

Dípò wíwá ayé dídárawẹ́kú ní àwọn apá ibi jíjìnnà réré ilẹ̀-ayé, àwọn mìíràn ti gbìyànjú láti wéwèé rẹ̀. Nípa bẹ́ẹ̀ ní 1516, afẹ́nifẹ́re ọmọ ilẹ̀ England náà Thomas More ṣàpèjúwe erékùṣù Ibi Aláìlálèébù gẹ́gẹ́ bí ibi yíyanilẹ́nu, alálàááfíà tí ó sì rí ara gba nǹkan sí, tí ó yàtọ̀ pátápátá sí ayé oníbàjẹ́ tí òun mọ̀. Àwọn mìíràn ti gbìyànjú pẹ̀lú láti wéwèé àwọn ayé dídára jù, àwọn ayé sísàn jù: ní ọ̀rúndún kẹfà B.C.E., Plato àti Orílẹ̀-èdè Aláààrẹ rẹ̀; ní 1602, Tommason Campanella ọmọ Italy tí ó jẹ́ mẹ́ḿbà ẹgbẹ́ ìsìn àti Ìlú-Ńlá Oòrùn rẹ̀ tí a ṣètò dáradára; lẹ́yìn àwọn ọdún díẹ̀, ọmọ ilẹ̀ England ọlọ́gbọ́n-èrò-orí náà Francis Bacon ṣàpèjúwe “dúkìá ìní aláyọ̀ tí ń gbáyìn-⁠ìn” ti Atlantis Titun rẹ̀. Bí àwọn ọ̀rúndún ti ń kọjá lọ, àwọn onírònú lónírúurú (bóyá onígbàgbọ́ tàbí bẹ́ẹ̀kọ́) ti ṣàpèjúwe ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ Ibi Aláìlálèébù. Bí ó ti wù kí ó rí, ìwọ̀nba, bí ó bá wà rárá, ni a gbàgbọ́.

Àwọn kan tilẹ̀ ti gbìyànjú láti kọ́ àwọn Ibi Aláìlálèébù tiwọn. Fún àpẹẹrẹ, ní 1824 ọkùnrin ọmọ ilẹ̀ England Robert Owen, pinnu láti ṣílọ sí Indiana, U.S.A., kí ó baà lè mú àwọn èrò rẹ̀ nípa Ibi Aláìlálèébù ṣẹ ní abúlé tí òun pè ni Harmony Titun. Ní gbígbàgbọ́ dájú pé lábẹ́ àwọn ipò títọ́, àwọn ènìyàn yóò sunwọ̀n síi, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ lo gbogbo ohun àmúṣọrọ̀ rẹ̀ tán ní lílàkàkà láti fìdí ohun tí ó fọkànrò gẹ́gẹ́ bí ayé oníwàrere titun múlẹ̀. Ṣùgbọ́n àwọn àbájáde fihàn pé gbígbé lábẹ́ àwọn ipò titun kò tó láti mú àwọn ènìyàn titun jáde.

Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo àbá èrò orí ti òṣèlú ní ó gbà pé ènìyàn níláti wéwèé ayé ní ìbámu pẹ̀lú ìmọ̀ rẹ̀ àti ọgbọ́n orí rẹ̀ nípa ohun tí ó jẹ́ òtítọ́ kí wọ́n baà lè mú paradise tí a ti ń lálàá rẹ̀ wá sí ilẹ̀-ayé. Síbẹ̀, ní òdìkejì, ìgbìyànjú láti lé ìdàníyàn bẹ́ẹ̀ bá ti yọrísí ogun àti ìṣọ̀tẹ̀, iru bí Ìṣọ̀tẹ̀ Ilẹ̀ France ní 1789 àti Ìṣọ̀tẹ̀ Bolshevik ní 1917. Dípò mímú àwọn ipò paradise wá, àwọn ìsapá wọ̀nyí sábà máa ń ṣamọ̀nà sí ìrora àti ìjìyà púpọ̀ síi.

Àwọn ìdàníyàn, ìwéwèé, Ibi Aláìlálèébù, àti ìgbìdánwò láti rí wọn​—⁠jẹ́ ìtàn ìjákulẹ̀ kan tẹ̀lé òmíràn. Ní ọjọ́ wa àwọn kan ń sọ̀rọ̀ nípa “àlá ti a fọ́yángá” àti “òpin sànmánì ibi aláìlálèébù,” ní kíké sí wa láti kọ́ “láti gbé láìsí ibi aláìlálèébù.” Ìrètí rírí ayé dídára jù kan ha wà bí, tàbí a ha ti kádàrá rẹ̀ láti jẹ́ àlá kan lásán bí?

Àwọn Kristian àti Ayé Dídára Jù Kan

Ayé titun kan kìí ṣe àlá rárá​—⁠ìrètí dídájú kan ni! Jesu Kristi, Olùpilẹ̀ṣẹ̀ ìsìn Kristian, mọ̀ pé ayé ìsinsìnyí kìí ṣe èyí tí ó dára jùlọ nínú àwọn ayé tí ọwọ́ lè tẹ̀. O kọ́ni pé ilẹ̀-ayé ni àwọn ọlọ́kàn tútù yóò jogún àti pé ìfẹ́ Ọlọrun yóò di ṣíṣe níbẹ̀. (Matteu 5:5; 6:9, 10) Òun àti àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ mọ̀ pé ọ̀tá Ọlọrun, Satani Eṣu, ni ó ń darí ayé yìí, àti pé èyí ni lájorí ìdí fún àwọn àjálù tí ń dé bá aráyé. (Johannu 12:31; 2 Korinti 4:4; 1 Johannu 5:19; Ìfihàn 12:12) Àwọn Ju olùṣòtítọ́ dúró de ọjọ́ náà nígbà tí Ọlọrun yóò mu ogun, ìrora, àti àìsàn kúrò ní ilẹ̀-ayé nígbẹ̀yìn gbẹ́yín kí ó baà lè fí àwọn olùfẹ́ àlàáfíà àti ìdájọ́-òdodo kún inú rẹ̀. Ní ọ̀nà kan náà, àwọn Kristian ọ̀rúndún kìn-⁠ín-⁠ní fi pẹ̀lú ìgbẹ́kẹ̀lé dúró de fífi ètò àwọn nǹkan titun, “ọ̀run titun àti ayé titun” rọ́pò ayé ìsinsìnyí.​—⁠2 Peteru 3:13; Orin Dafidi 37:11; 46:8, 9; Isaiah 25:8; 33:24; 45:18; Ìfihàn 21:⁠1.

Nígbà tí a gbé Jesu Kristi kọ́ òpó igi ìdálóró, ó tún ìlérí ayé dídára jù kan ṣe fún olubi tí ó fi ìgbàgbọ́ díẹ̀ hàn nínú Rẹ̀. “[Jesu] wí fún un pé: ‘Ní òótọ́ ni mo sọ fún ọ lónìí, Ìwọ yóò wà pẹ̀lú mi ní paradise.’” (Luku 23:​40-⁠43, NW) Kí ni olubi yẹn lóye àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn sí? Jesu ha dábàá pé olubi náà yóò ‘wà pẹ̀lú òun’ ní ọ̀run ní ọjọ́ yẹn gan-⁠an, gẹ́gẹ́ bí àwọn ìtumọ̀ Bibeli Katoliki àti Protẹstanti kan ti dọ́gbọ́n fihàn bí? Bẹ́ẹ̀kọ́, kìí ṣe ohun tí Jesu nílọ́kan nìyẹn, níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé lẹ́yìn àjíǹde rẹ̀, Jesu sọ fún Maria Magdalene pé Òun “kò tíì gòkè lọ sọ́dọ̀ Baba.” (Johannu 20:​11-⁠18) Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Jesu kọ́ wọn fún ọdún mẹ́ta àti ààbọ̀, ṣáájú Pentikosti 33 C.E. àní àwọn aposteli rẹ̀ kò tilẹ̀ ronú nípa paradise kan ní ọ̀run. (Iṣe 1:​6-⁠11) Olubi yẹn lóye ohun tí ọ̀pọ̀ jùlọ àwọn Ju tí wọn ń gbé ní àkókò yẹn lóye: Jesu ń ṣèlérí ayé dídára jù kan tí yóò wá sórí paradise ilẹ̀-ayé kan. Ọ̀mọ̀wé ọmọ ilẹ̀ Germany kan gbà pé: “Ẹ̀kọ́ gbígba èrè iṣẹ́ lẹ́yìn ikú kò tilẹ̀ farahàn nínú Májẹ̀mú Láéláé.”

Pé paradise kan yóò wà lórí ilẹ̀-ayé wa ni aposteli Paulu jẹ́rìí sí nínú lẹ́tà rẹ̀ sí àwọn ara Heberu. Nígbà tí ó ń fún àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ níṣìírí láti máṣe ‘ṣàìnání irú ìgbàlà ńlá bí èyí; tí a tètèkọ́ bẹ̀rẹ̀ síí sọ láti ọ̀dọ̀ Jesu Kristi,’ Paulu fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé Jehofa Ọlọrun fún Jesu ní ọlá-àṣẹ lórí ‘ilẹ̀-ayé tí a ń gbé [Griki, oi·kou·meʹne] tí ń bọ̀.’ (Heberu 2:​3, 5) Nínú Ìwé Mímọ́ Kristian Lédè Griki, gbólóhùn ọ̀rọ̀ náà oi·kou·meʹne nígbà gbogbo máa ń tọ́kasí ilẹ̀-ayé wa tí ènìyàn ń gbé kìí ṣe sí ayé kan ní ọ̀run. (Fiwé Matteu 24:14; Luku 2:1; 21:26; Iṣe 17:31.) Nítorí náà Ìjọba Ọlọrun tí Kristi Jesu yóò ṣàkóso yóò lo àṣẹ ìṣàkóso lórí ilẹ̀-ayé tí a ń gbé. Ìyẹn níti gidi yóò jẹ́ ibi gbígbámúṣé kan láti gbé!

Àní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Ìjọba náà fúnraarẹ̀ wà ní ọ̀run, kì yóò ṣaláìlọ́wọ́ sí àwọn ọ̀ràn ilẹ̀-ayé. Pẹ̀lú ìyọrísí wo? Àìlera, àwọn ìwà búburú, òṣì, àti ikú yóò di ìrántí àtijọ́. Àní ìjákulẹ̀ àti àìnítẹ̀ẹ́lọ́rùn yóò pòórá. (Ìfihàn 21:​3-⁠5) Bibeli sọ pé ‘Ọlọrun ṣí ọwọ́ rẹ̀, ó sì tẹ́ ìfẹ́ gbogbo ohun alààyè lọ́rùn.’ (Orin Dafidi 145:16) Àwọn ìṣòro bí àìríṣẹ́ṣe àti ìbàyíkájẹ́ yóò rí ojútùú gbígbéṣẹ́ tí ó sì tọ́jọ́. (Isaiah 65:​21-⁠23; Ìfihàn 11:18) Ṣùgbọ́n ju gbogbo rẹ̀ lọ, ọpẹ́ ni fún ìbùkún Ọlọrun, ìjagunmólú òtítọ́, ìdájọ́-òdodo, àti àlàáfíà yóò wà​—⁠àwọn ànímọ́ tí ó jọ pé wọn ti fẹ́rẹ̀ẹ́ pòórá!​—⁠Orin Dafidi 85:​7-⁠13; Galatia 5:​22, 23.

Gbogbo èyí ha jẹ́ àlá, Ibi Aláìlálèébù kan bí? Bẹ́ẹ̀kọ́, àkókò lílekoko jùlọ lára gbogbo àwọn àkókò nínú èyí tí a ń gbé fihàn pé a wà ní “ìkẹyìn ọjọ́” ayé yìí àti pé nítorí èyí ayé titun náà ti súnmọ́lé. (2 Timoteu 3:​1-⁠5) Ìwọ yóò ha fẹ́ láti gbé níbẹ̀ bí? Kẹ́kọ̀ọ́ bí yóò ti ṣeéṣe nípa kíkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Ayé dídára jù kan ti kù sí dẹ̀dẹ̀, ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀ ju bí a ti lè lálàá rẹ̀ rí lọ. Kìí ṣe Ibi Aláìlálèébù kan tí a finú rò​—⁠òtítọ́ gidi ni!

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Ayé dídára jù kan​—⁠yóò di òtítọ́ gidi láìpẹ́

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́