ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w94 5/1 ojú ìwé 4-7
  • Bí O Ṣe Ń Jọ́sìn Ha Ṣe Pàtàkì Bí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Bí O Ṣe Ń Jọ́sìn Ha Ṣe Pàtàkì Bí?
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìsìn Èyíkéyìí Ṣáá Ha Lè Wu Ọlọrun Bí?
  • Àwọn Ọ̀pá Ìdiwọ̀n Ẹlẹ́dàá fún Ìjọsìn
  • Ìrànlọ́wọ́ Wà Lárọ̀ọ́wọ́tó
  • Ìjọsìn Tó Ní Ìtẹ́wọ́gbà Ọlọ́run
    Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?
  • Ṣíṣe Isin Mimọgaara fun Lilaaja
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Ìwọ Ha Ti Rí Ìsì Tí Ó Tọ̀nà Bí?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Jija Àjàbọ́ Kuro Ninu Isin Èké
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
w94 5/1 ojú ìwé 4-7

Bí O Ṣe Ń Jọ́sìn Ha Ṣe Pàtàkì Bí?

ÌLÚ Africa kékeré náà ń gbóná fòò lábẹ́ oòrùn ọ̀sángangan. A lè gbọ́ ìró ìlù tí ń dún kíkankíkan, orin kíkọ, àti àtẹ́wọ́ onídùnnú ní erékùṣù kan tí ń bẹ nítòsí. Ṣùgbọ́n èyí kìí ṣe àlámọ̀rí ẹgbẹ́-òun-ọ̀gbà. Ìjọsìn ìbílẹ̀ àwọn ará Africa ni. Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn ìró náà wà ní ìforígbárí pẹ̀lú àwọn ìró ohùn lílekoko kan tí ń wá láti ibi ṣọ́ọ̀ṣì mẹ́mìímẹ́mìí kan tí ń bẹ nítòsí. Níbẹ̀ ni àwọn olùjọsìn tí ń yọ̀ ṣìnkìn náà ti ń ṣe àwọn “ìwòsàn” lọ́nà ìyanu wọ́n sì ń fèdèfọ̀. Ní ìhà kejì ìlú náà ni irú ìjọsìn mìíràn kan tí ó yàtọ̀ tún wà. Ohùn làdánì kan tí ń dún gooro ń késí àwọn Mùsùlùmí olùjọ́sìn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ láti wá kírun.

Bẹ́ẹ̀ni, ìfọkànsìn nínú ìsìn ní onírúurú ọ̀nà ni a lè rí ní ọ̀pọ̀ àwọn ìlú-ńlá àti ìlú ní Africa. Láti ìrandíran ni ó ti máa ń tẹ́ àwọn ará Africa lọ́rùn láti tẹ̀lé àwọn àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ ìsìn tiwọn. Ṣùgbọ́n nígbà tí ó ṣe àwọn míṣọ́nnárì Kristẹndọm dé, ní títẹ̀lé àwọn ọmọ-ogun orílẹ̀-èdè Europe ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, tí wọ́n sì gbìdánwò lọ́nà ìkà láti “sọ” olúkúlùkù “di Kristian”​—⁠àní títíkan orúkọ tí wọ́n ń jẹ́ pàápàá.

Kí ni ìyọrísí náà? Irú ẹ̀yà ìsìn kan tí ó da ìgbàgbọ́ àti àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ Africa pọ̀ mọ́ ìgbàgbọ́ àwọn ìsìn tí wọ́n ti òkèèrè wá. Títí di òní yìí ọ̀pọ̀ àwọn “Kristian” olùjọsìn ń lo àwọn oògùn ìṣọ́ra àti ońdè. Síbẹ̀, àwọn míṣọ́nnárì Kristẹndọm ti fi ìsìn Kristian tòótọ́ hàn lọ́nà òdì tí ó burú lékenkà, wọ́n sì fi ìrunú sílẹ̀ sẹ́yìn gẹ́gẹ́ bí ogún-ìní. Dé ìwọ̀n gíga, àwọn ni wọ́n fa ìṣarasíhùwà sísé ọkàn àwọn ènìyàn sí Bibeli èyí tí ó wà láàárín àwọn ará Africa kan lónìí.

Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ọ̀pọ̀ oríṣi àwọn “ìsìn Kristian” ni a ṣì ń ṣe káàkiri ibi gbogbo lónìí. Ní àwọn ọdún àìpẹ́ yìí àwọn àwùjọ ìsìn mẹ́mìímẹ́mìí ní pàtàkì ti gbajúmọ̀; àwọn ṣọ́ọ̀ṣì onígbàgbọ́ wò-⁠ó-sàn ti gbèrú di púpọ̀. Akọ̀ròyìn kan ṣàlàyé òòfà tí àwọn ṣọ́ọ̀ṣì wọ̀nyí ní nípa sísọ̀rọ̀ àkíyèsí pé ‘èrò àwọn ará Africa nípa ìsìn lọ́nà púpọ̀ jùlọ jẹ́ ti ṣíṣe ohun tí ó wúlò tí ó sì ṣàǹfààní jùlọ fún àwọn ènìyàn. Lọ́kàn àwọn ará Africa, ó gbọ́dọ̀ ṣeéṣe fún ìsìn láti fún ìwàláàyè ènìyàn ní ìtẹ́lọ́rùn tààràtà nípa ohun-ìní ti ara. Nítorí náà, fún ará Africa kan tí ó gbàgbọ́ pé àwọn alárinà tẹ̀mí jẹ́ kòṣeémánìí nínú èyí tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ ohun gbogbo, ọ̀nà ìgbàṣe nǹkan àwọn ṣọ́ọ̀ṣì ẹlẹ́mìí [tàbí onígbàgbọ́ wò-⁠ó-sàn] wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú àwọn ohun tí ọ̀nà ìgbà gbé ìgbésí-ayé rẹ̀ béèrè fún.’ Bí ó ti wù kí ó rí, ó baninínújẹ́ pé ọ̀pọ̀ àwọn ṣọ́ọ̀ṣì mẹ́mìímẹ́mìí ni ó ṣe kedere pé a ti fìdí wọn múlẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìdáwọ́lé tí ń mówó wọlé.

Lónìí, iye tí ó ju 6,000 ẹ̀ya ìsìn ní ń bẹ ní Africa. Bóyá o ti nímọ̀lára pé gbogbo àwọn ìsìn àti ẹ̀ya ìsìn wọ̀nyí ni wọ́n ní kọ́kọ́rọ́ ìgbàlà lọ́wọ́. Ṣùgbọ́n ìbéèrè gidi náà ni pé, Báwo ni ìmọ̀lára Ọlọrun ti rí?

Ìsìn Èyíkéyìí Ṣáá Ha Lè Wu Ọlọrun Bí?

Dájúdájú, Ẹlẹ́dàá àgbáyé kì yóò fi wá sílẹ̀ nínú ọ̀ràn yìí láìsí ìdarísọ́nà. (Amosi 3:7; Iṣe 17:​26, 27) Ẹ̀rí sì pọ̀ pelemọ pé ìtọ́sọ́nà àtọ̀runwá ni a lè rí nínú Bibeli. Bẹ́ẹ̀kọ́, Bibeli kìí ṣe ìwé àwọn aláwọ̀ funfun, gẹ́gẹ́ bí àwọn kan ti pè é. Níti tòótọ́, kò sí ẹnìkan​—⁠dúdú tàbí funfun​—⁠tí a lè fi ọlá fún nítorí rẹ̀. “Gbogbo ìwé-mímọ́ [ni] ó ní ìmísí Ọlọrun,” ni 2 Timoteu 3:16 sọ. Àwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́, gbígbéṣẹ́ ti Bibeli, ìlọ́jọ́lórí ńláǹlà rẹ̀, lílàájá rẹ̀ lójú àwọn àtakò rírorò, àwọn àsọtẹ́lẹ̀ pípéye rẹ̀ àti ìpínkiri yíká ayé lọ́nà tí kò ní alábàádọ́gba​—⁠gbogbo ìwọ̀nyí jẹ́ àwọn ẹ̀rí ṣíṣekedere nípa ìkọ̀wé rẹ̀ tí ó jẹ́ àtọ̀runwá.

Kí ni ìwé yẹn fi kọ́ wa? Ohun kan ni pé, ó sọ fún wa pé “Ọlọrun òtítọ́” kanṣoṣo ni ó wà. (Johannu 17:⁠3) Bí ọ̀ràn bá rí bẹ́ẹ̀, báwo ni òtítọ́ ṣe lè wà nínú gbogbo ìsìn? Àwọn àwùjọ ìsìn kìí ha forígbárí pẹ̀lú araawọn nígbà tí ó bá di ọ̀ràn ẹni tí Ọlọrun jẹ́ àti ànímọ́ rẹ̀ bí? Òǹkọ̀wé Bibeli náà Jakọbu kọ̀wé nípa “ìsìn mímọ́gaara àti ojúlówó.” (Jakọbu 1:27, Today’s English Version) Bí àìní bá wà láti dá ojúlówó ìsìn mọ̀ yàtọ̀, ìsìn èké tàbí ayédèrú tún níláti wà pẹ̀lú. Èyí yóò tako èròngbà náà pé gbogbo ìsìn wulẹ̀ jẹ́ àwọn ọ̀nà yíyàtọ̀síra tí a lè gbà tọ Ọlọrun lọ.

Àwọn Ọ̀pá Ìdiwọ̀n Ẹlẹ́dàá fún Ìjọsìn

Kí ni ọ̀nà yíyẹ fún jíjọ́sìn Ọlọrun? Bibeli kọ́ wa pé ìmọ̀ pípéye ni gbòǹgbò ojúlówó ìjọsìn. Wòlíì títóbilọ́lá náà Jesu Kristi sọ nígbà kan rí fún obìnrin ará Samaria kan pé: “Ẹ̀yin ń sin ohun tí ẹ̀yin kò mọ̀.” (Johannu 4:22) Èyí ha lè jẹ́ òtítọ́ nípa ìwọ náà pẹ̀lú bí? A ha ti kọ́ ọ pé Ọlọrun Olodumare ní orúkọ ara-ẹni kan, Jehofa? (Orin Dafidi 83:18) Ìwọ ha mọ ohun tí àwọn ète rẹ̀ jẹ́ nípa ènìyàn àti ilẹ̀-ayé bí? (Matteu 6:​9, 10; Efesu 1:9, 10; 3:11) Ìsìn rẹ ha nawọ́ ìrètí tòótọ́ gidi sí ọ nípa ọjọ́-ọ̀la kan tí ó dára jù bí? Bí ìwọ bá sì ka araàrẹ sí Kristian kan, ìwọ ha lè ṣàlàyé ìgbàgbọ́ rẹ láti inú Ìwé Mímọ́ bí, tàbí wọ́n ha wulẹ̀ jẹ́ ogún-ìní àfilénilọ́wọ́ kan ṣáá tí ìwọ kò wá àkókò láti ṣàyẹ̀wò rẹ̀ bí?

Bí o bá ríi pé o ṣaláìní ìmọ̀ pípéye, ìwọ lè ní in nípasẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọrun, Bibeli. Jehofa Ọlọrun retí pé kí àwọn olùjọ́sìn rẹ̀ tòótọ́ mọ ohun tí Ìwé Mímọ́-Ọlọ́wọ̀ yẹn fi kọ́ni dunjú. Jù ìyẹn lọ, ó retí pé kí wọ́n fi í sílò nínú ìgbésí-ayé wọn. Ìṣarasíhùwà wa gbọ́dọ̀ dàbí ti onípsalmu náà tí ó wí pé: “Ọ̀rọ̀ rẹ ni fìtílà fún ẹsẹ̀ mi, àti ìmọ́lẹ̀ sí ipa ọ̀nà mi.” (Orin Dafidi 119:105) Àyè ipò wo ni ìsìn rẹ ti ràn ọ́ lọ́wọ́ dé láti mọ Bibeli àti láti lóye rẹ̀?

Apá ẹ̀ka pàtàkì mìíràn ti ìjọsìn tòótọ́ ni ìgbàgbọ́ nínú Jesu Kristi, kìí wulẹ̀ ṣe gẹ́gẹ́ bíi wòlíì títóbi kan ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí Ọmọkùnrin bíbí kanṣoṣo ti Ọlọrun. Ìwé Mímọ́ polongo ní kedere pé Jesu ni “Olùpilẹ̀ṣẹ̀ ìyè.” (Iṣe 3:15; 4:12) Ọ̀pọ̀lọpọ̀ jẹ́wọ́ pé àwọn gbàgbọ́ nínú Jesu, ṣùgbọ́n báwo ni ìgbàgbọ́ wọn ti jẹ́ gidi tó? Ojúlówó ìgbàgbọ́ nínú Kristi béèrè fún ṣíṣègbọràn sí àwọn ìtọ́ni rẹ̀. Ọlọrun fúnraarẹ̀ fún wa ní ìṣírí láti ṣe èyí nígbà tí ó polongo pé: “Èyíyìí ni àyànfẹ́ Ọmọ mi: ẹ máa gbọ́ tirẹ̀.” (Marku 9:⁠7) Nípa báyìí àwọn olùjọ́sìn tòótọ́ ń sakun láti rìn ní ipasẹ̀ Jesu tímọ́tímọ́ bí ó bá ti lè ṣeéṣe tó. (1 Peteru 2:21) Ọ̀nà kan tí wọ́n ń gbà ṣe bẹ́ẹ̀ ni nípa kíkópa nínú iṣẹ́ ìwàásù fún gbogbo ènìyàn tí òun bẹ̀rẹ̀ rẹ̀. (Matteu 4:17; 10:5-⁠7) Ìsìn rẹ ha fún ọ ní ìṣírí láti nípìn-⁠ín ti ara-ẹni nínú iṣẹ́ yìí bí?

Ìfẹ́ tún jẹ́ ohun kan tí ìjọsìn tòótọ́ béèrè fún. A ṣàpèjúwe Jehofa Ọlọrun gẹ́gẹ́ bí ògidi àpẹẹrẹ ìfẹ́ gan-⁠an, Jesu sì sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé a óò dá wọn mọ̀yàtọ̀ nípa ìfẹ́ tí wọ́n ń fihàn láàárín araawọn. (Johannu 13:34, 35; 1 Johannu 4:⁠8) Ní ríronú lórí àràádọ́ta-ọ̀kẹ́ àwọn ènìyàn tí wọ́n sọ pé Kristian ni wọ́n lónìí, kò ha yẹ kí ayé kúnfọ́fọ́ fún ìfẹ́ bí? Ṣùgbọ́n, níti gidi, ayé wa ti jásí ibìkan tí kò ní ìfẹ́ rárá. Ogun ti fòpin sí àràádọ́ta-ọ̀kẹ́ ìwàláàyè nínú ọ̀rúndún yìí nìkanṣoṣo. Ìwà-ọ̀daràn àti ìwà-ipá ń báa lọ láti peléke síi. Nítorí náà bi araàrẹ léèrè, ‘Bí gbogbo ènìyàn bá ń ṣe ìsìn mi, ayé yóò ha túbọ̀ jẹ́ ibìkan tí ó ní ìfẹ́ bí?’

Ní àkótán, Bibeli fihàn pé àwọn olùjọsìn tòótọ́ gbọ́dọ̀ pa araawọn mọ́ kúrò nínú ayé tí kò mọ Ọlọrun. Nígbà tí Ọlọrun ya orílẹ̀-èdè Israeli ìgbàanì sọ́tọ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́mẹ̀ṣọ́ ìjọsìn mímọ́gaara, ó kìlọ̀ fún àwọn ènìyàn rẹ̀ láti yẹra fún ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ tímọ́tímọ́ pẹ̀lú àwọn orílẹ̀-èdè oníwà ìbàjẹ́ tí ó yí wọn ká. (Deuteronomi 7:​1-⁠6) Bákan náà ni Kristi Jesu sọ nípa àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ní Johannu 17:16, pé: “Wọn kìí ṣe ti ayé, gẹ́gẹ́ bí èmi kìí tií ṣe ti ayé.” Àwọn olùjọ́sìn tòótọ́ ti Ọlọrun kò ní ipa kankan nínú òṣèlú, ìwàpálapàla, iṣẹ́-òwò oníwọra, tàbí àwọn ọgbọ́n ìmọ̀ ọ̀ràn èyíkéyìí tí kò bọlá fún Ọlọrun. (Johannu 18:36; 1 Johannu 2:​15-⁠17) Wọ́n ṣègbọràn sí àṣẹ tí a kọ sínú Romu 12:2 pé: Ẹ má sì da ara yín pọ̀ mọ́ ayé yìí.” Ìyẹn ha ni ohun tí ìsìn rẹ ń fún ọ ní ìṣírí láti ṣe bí?

Ìrànlọ́wọ́ Wà Lárọ̀ọ́wọ́tó

Bẹ́ẹ̀ni, bí o ṣe ń jọ́sìn ṣe pàtàkì níti gidi lójú Ọlọrun. Ní tirẹ̀, ìsìn tòótọ́ kanṣoṣo ni ó wà. (Efesu 4:​4-⁠6) Ìjíròrò wa ṣókí ti mẹ́nukan díẹ̀ lára àwọn kókó pàtàkì inú ẹ̀kọ́ Bibeli. Èéṣe tí ìwọ kò fi sakun láti kọ́ púpọ̀ síi?

Láìka ọ̀nà tí a gbà tọ́ ọ dàgbà níti ìsìn sí, àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa lè ṣèrànwọ́ fún ọ nínú ọ̀ràn yìí. A mọ̀ wọ́n yíká ayé fún iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Bibeli lójú méjèèjì wọn. Wọ́n fi ara wọn fún ríran àwọn ènìyàn láti gbogbo ẹ̀yà ìran àti ipò àtilẹ̀wá níti ìsìn lọ́wọ́ láti jèrè òye tí ó túbọ̀ jinlẹ̀ nípa Bibeli. (Owe 2:​1-⁠6) Wọ́n ń tẹ àwọn ìwé-ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli tí a ṣe ìwádìí lé lórí dáradára jáde.a Níti tòótọ́, wọn yóò tilẹ̀ wá sí ilé rẹ lọ́fẹ̀ẹ́ láti kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Bibeli gẹ́gẹ́ bí ẹnìkan. Àràádọ́ta-ọ̀kẹ́ àwọn ènìyàn kárí-ayé ń jàǹfààní ní lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí láti inú ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Bibeli yìí. Èéṣe tí ìwọ fúnraàrẹ kò fi ṣe bẹ́ẹ̀? Nítòótọ́, ó ṣekókó pé kí o ṣe bẹ́ẹ̀ nítorí pé bí o ṣe ń jọ́sìn ṣe pàtàkì nítòótọ́.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Irú ìtẹ̀jáde kan bẹ́ẹ̀ ni Mankind’s Search for God, tí a tẹ̀jáde ní 1990 láti ọwọ́ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc. Ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn ti mọrírì ìjíròrò rẹ̀ tí ó fòye hàn tí ó sì jinlẹ̀ ní ẹ̀kọ́ nípa àwọn ìsìn pàtàkì nínú ayé.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]

Àwọn míṣọ́nnárì Kristẹndọm fi ìsìn Kristian hàn lọ́nà òdì tí ó burú lékenkà

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]

Ọ̀pọ̀ àwọn ṣọ́ọ̀ṣì mẹ́mìímẹ́mìí jẹ́ ìdáwọ́lé tí ń mówó wọlé

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]

Ìgbàgbọ́ nínú Jesu jẹ́ apá ṣíṣekókó nínú ìjọsìn tòótọ́

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ń ran àràádọ́ta-ọ̀kẹ́ lọ́wọ́ láti jèrè ìmọ̀ pípéye nípasẹ̀ àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́