ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w95 3/1 ojú ìwé 24
  • Àwọn Ènìyàn Ọlọrun Yọ̀ọ̀da Ara Wọn Tìfẹ́-Inú Tìfẹ́-Inú

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ènìyàn Ọlọrun Yọ̀ọ̀da Ara Wọn Tìfẹ́-Inú Tìfẹ́-Inú
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Bá A Ṣe Ṣètò Àwọn Ibi Ìjọsìn Wa
    A Ṣètò Wa Láti Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà
  • Fífi Ìdùnnú Kúnjú Àìní Ìkórè Náà
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1998
  • Ètò Kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba—Ọ̀kan Pàtàkì Lára Iṣẹ́ Ìsìn Mímọ́
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2006
  • Ìmúgbòòrò Tí Ń Bá A Nìṣó Ń Mú Àìní fún Àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba Pọ̀ Sí I
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1997
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
w95 3/1 ojú ìwé 24

Àwọn Olùpòkìkí Ìjọba Ròyìn

Àwọn Ènìyàn Ọlọrun Yọ̀ọ̀da Ara Wọn Tìfẹ́-Inú Tìfẹ́-Inú

JOSEFU ni orúkọ rẹ̀, ó sì jẹ́ ọmọ ìbílẹ̀ erékùṣù Kipru. Ó wà lára àwọn Kristian ọ̀rúndún kìn-ín-ní tí wọn ta pápá àti ilé wọn kí wọ́n baà lè ṣètọrẹ owó fún ìtẹ̀síwájú ìsìn Kristian. Nítorí ọ̀yàyà ọkàn àti ìwà ọ̀làwọ́ rẹ̀, ó di ẹni tí a mọ̀ sí Barnaba, tí ó túmọ̀ sí “Ọmọkùnrin Ìtùnú.”—Ìṣe 4:34-37, NW.

Irúfẹ́ ojúlówó ọkàn-ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ nínú àwọn ẹlòmíràn tí sábà máa ń jẹ́ àmì ìdánimọ̀ fún àwọn olùjọ́sìn tòótọ́ ti Jehofa. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa lónìí kò yàtọ̀, gẹ́gẹ́ bí ìrírí tí ó tẹ̀lé e yìí láti Solomon Islands ti fi hàn.

Àwùjọ àwọn Ẹlẹ́rìí tí wọ́n ju 60 lọ láti Australia àti New Zealand rìnrìn-àjò lọ sí Honiara, olú-ìlú Solomon Islands lórí Guadalcanal. Wọ́n wá láti ṣèrànlọ́wọ́ pẹ̀lú kíkọ́ Gbọ̀ngàn Àpèjọ kan fún àwọn àpéjọ Kristian ńlá. Ó gbà wọ́n ní nǹkan bí ọ̀sẹ̀ méjì péré láti kọ́ gbọ̀ngàn kan tí ó ní àyè ìjókòó tí ó lè gba 1,200 ènìyàn!

Ní ọwọ́ àkókò kan náà, àwọn aláṣẹ àdúgbò ní ìlú kékeré Munda, lórí erékùṣù New Georgia, fún ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ní sarè ilẹ̀ kan ní àárín gbùngbùn ìlú. Wọ́n fẹ́ láti kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba kan, ibi ìjọsìn. Wọ́n sì nílò ọ̀kan nítòótọ́. Wọ́n ti ń pàdé nínú iyàrá àlejò nínú ilé ewé kékeré kan, ṣùgbọ́n wọn kò ní ohun tí wọ́n lè fi kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba.a Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé àwọn àgbàlagbà àti àwọn aláìlera àti àwọn ọmọdé ni wọ́n kún inú ìjọ náà, kò sì sí ẹni tí ó ní ìrírí nípa iṣẹ́ ilé kíkọ́.

Ní nǹkan bíi 380 kìlómítà síbẹ̀, lórí erékùṣù Guadalcanal, àwọn Ẹlẹ́rìí tí ń bẹ ní ìlú-ńlá Honiara yọ̀ọ̀da ara wọn tìfẹ́-inú tìfẹ́-inú. (Orin Dafidi 110:3) Wọ́n ronú pé: “Bí àwọn arákùnrin wa ní àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn bá nífẹ̀ẹ́ ìmúratán láti kọ́ Gbọ̀ngàn Àpéjọpọ̀ ní ọ̀sẹ̀ méjì, nígbà náà ó dájú pé a lè ran àwọn arákùnrin wa ní Munda lọ́wọ́ kí a sì kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba kan fún wọn ní ọ̀sẹ̀ méjì.”

Ohun tí ó ṣẹlẹ̀ nìyẹn. Ní ọjọ́ kan ọkọ̀-ojú-omi kan tí ó kún fún àwọn Ẹlẹ́rìí olùyọ̀ọ̀da ara-ẹni tí wọ́n láyọ̀ tí wọ́n sì ní ìháragàgà gúnlẹ̀ sí Munda. Tọkùnrin tobìnrin, tọmọdé tàgbà, ni ọwọ́ gbogbo wọn dí fún jíjá ẹrù wọn sílẹ̀ láti inú ọkọ̀ ẹrù náà wọ́n sì wà ní ìmúrasílẹ̀ láti bẹ̀rẹ̀ síí fi igi gẹdú, sìmẹ́ńtì, àti páànù ìbolé, àti àwọn ohun èèlò mìíràn tí ó ti ṣáájú wọn dé Munda kọ́lé.

Kété lẹ́yìn ti iṣẹ́ náà bẹ̀rẹ̀, ìjì ààrá lílágbára ba orísun ìpèsè omi ìlú náà jẹ́. Bí ó ti wù kí ó rí, èyí kò jásí ìṣòro tí kò ṣeé borí. Àwọn Ẹlẹ́rìí náà gbẹ́ kànga kan tí ó pèsè omi títí tí wọ́n fi parí iṣẹ́ ilé kíkọ́ náà. Ti oúnjẹ fún gbogbo àwọn òṣìṣẹ́ ńkọ́? Ìyẹn pẹ̀lú kì í ṣe ìṣòro. Àwọn olùyọ̀ọ̀da ara-ẹni tí wọ́n wá láti Honiara ni a ti rán wá pẹ̀lú oúnjẹ rẹpẹtẹ tí àwọn ìjọ Honiara pèsè fún wọn. Wọ́n tilẹ̀ mú àwọn ọlọ́wọ́-ṣíbí tiwọn dání!

Àwọn aládùúgbò ń wo ìwéwèédáwọ́lé yìí pẹ̀lú ìyanu. Ọ̀kan nínú wọn sọ pé: “Àwọn ìdáwọ́lé pàtàkì kì í parí láààrín ọjọ́ díẹ̀ níhìn-ín yìí. Ọ̀pọ̀ ọdún ni wọ́n máa ń gbà.” Aládùúgbò mìíràn, tí ó jẹ́ aṣáájú ìsìn, gbà pé a ti ń kọ́ ṣọ́ọ̀ṣì òun láti 20 ọdún sẹ́yìn àti pé a kò tí ì parí rẹ̀ síbẹ̀. Ní ìyàtọ̀ sí èyí, Gbọ̀ngàn Ìjọba titun ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ní Munda ni a parí láàárín ọjọ́ mẹ́wàá péré!

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àwọn ohun èèlò tí a gé láti inú ìgbẹ́ tàbí igbó ẹgàn ni a fi ń kọ́ ilé ewé. Igi àti òpó ni a fi ṣe férémù, òrùlé àti ara ògiri ní a sì bò pẹ̀lú ohun èèlò tí a fi ń bo ògiri tí a fi imọ̀-ọ̀pẹ ṣe tí a sì fi ìtàkùn hun papọ̀ mọ́ ara igi.

[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 24]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

Agbami Òkun South Pacific

SOLOMON ISLANDS

Munda

GUADALCANAL

Honiara

[Àwòrán ilẹ̀]

AUSTRALIA

NEW ZEALAND

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́