Òkè Tí Ń “Rìn”
NÍ ÌWỌ̀-OÒRÙN Ireland, ìrísí aláìlẹ́gbẹ́ ti Croagh Patrick tí ó dàbí òkòtó ta gbogbo àwọn òkè tí wọ́n yí i ká yọ. Lọ́dọọdún, ní Sunday tí ó bá gbẹ̀yìn July, ó máa ń dàbí ẹni pé orí-òkè náà ń rìn nígbà tí àwọn ènìyàn tí wọ́n tó nǹkan bí 30,000, lọ́mọdé àti lágbà, bá ń gun orí-òkè náà (765 mità) lọ fún ìrìn-àjò sí ibi ìjọsìn ọdọọdún.
Ní ọjọ́ yìí, àwọn arìnrìn-àjò sí ibi ìjọsìn yóò máa gòkè wọn yóò sì máa sọ̀kalẹ̀ gba ojú-ọ̀nà ẹsẹ̀-kò-gbèjì, tí ó rí gbágungbàgun, àti, ní àwọn ibòmíràn, tí ó léwu. Ní tòótọ́, òkè tí wọn yóò gùn gbẹ̀yìn (nǹkan bí 300 mítà) dagun púpọ̀ ó sì kún fún àwọn àpáta tí ń yẹ̀, tí ń tipa bẹ́ẹ̀ mú kí gígòkè náà nira tí ó sì ń tánni lókun.
Àwọn kan ń gòkè yìí láì wọ bàtà, àwọn díẹ̀ yóò sì parí rẹ̀ pẹ̀lú fífi orúnkún wọn rìn. Nígbà àtijọ́, òru dúdú ni ìrìn-àjò sí ibi ìjọsìn náà máa ń bẹ̀rẹ̀.
Èéṣe tí Croagh Patrick fi jẹ́ ìrírí tí ó ṣe pàtàkì tóbẹ́ẹ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀?
Ó Pẹ́ Tí Ó Ti Wà Gẹ́gẹ́ Bí Ibi Ìrìn-Àjò Sí Ibi Ìjọsìn
Ní apá ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún karùn-ún C.E., Ṣọ́ọ̀ṣì Roman Katoliki rán Patrick gẹ́gẹ́ bíi bíṣọ́ọ̀bù míṣọ́nnárì sí Ireland. Olórí ète rẹ̀ ni láti yí àwọn ará Ireland sí ìsìn Kristian, láàárín àwọn ọdún rẹ̀ tí ó fi wàásù tí ó sì fi ṣiṣẹ́ láàárín àwọn ènìyàn, a gbóṣùbà fún Patrick fún fífi ìpìlẹ̀ lélẹ̀ fún Ṣọ́ọ̀ṣì Katoliki níbẹ̀.
Iṣẹ́ rẹ̀ gbé e dé ibi púpọ̀ jákèjádò orílẹ̀-èdè náà. Gẹ́gẹ́ bí àwọn ìsọfúnni kan ti sọ, ọ̀kan ni ìwọ̀-oòrùn Ireland níbi tí, ó ti lo 40 ọ̀sán àti òru lórí òkè-ńlá tí a wá sọ ní orúkọ rẹ̀ yìí—Croagh Patrick (tí ó túmọ̀ sí “Òkè Patrick”). Níbẹ̀ ni ó ti gbààwẹ̀ tí ó sì gbàdúrà fún àṣeyọrí iṣẹ́-àpèrán rẹ̀.
Jálẹ̀ àwọn ọdún ọ̀pọ̀ ìtàn àròfọ̀ nípa ìrìn-àjò rẹ̀ ti rúyọ. Ọ̀kan lára àwọn tí ó lókìkí jùlọ ni pé nígbà tí ó wà ní orí òkè-ńlá náà, Patrick le gbogbo ejò lọ kúrò ní Ireland.
Àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ tẹnumọ́ ọn pé ó kọ́ ṣọ́ọ̀ṣì kékeré kan sí orí-òkè náà. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti pẹ́ ti ilé yẹn kò ti sí níbẹ̀ mọ́, ìpìlẹ̀ rẹ̀ ti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ṣì wà níbẹ̀, ọ̀gangan náà àti òkè-ńlá náà sì ti di ibi ìrìn-àjò sí ibi ìjọsìn láti ọ̀pọ̀ ọdún.
Àwọn Apá-Ẹ̀ka Ìrìn-Àjò Sí Ibi Ìjọsìn Náà
Fún ẹnì kan tí ó ti dàgbà tàbí tí gígun òkè-ńlá kò mọ́ lára, láti lè gun òkè-ńlá oníkìlómítà márùn-ún kí ó sì sọ̀kalẹ̀ lálàáfíà jẹ́ àṣeyọrí kan nínú ara rẹ̀.
Ní àwọn ibi pàtàkì ni ọ̀nà ẹsẹ̀-kò-gbèjì náà, àwùjọ àwọn aṣètọ́jú pàjáwìrì ti wà ní sẹpẹ́ láti bójútó onírúurú ìfarapa.
Ibi mẹ́ta, tàbí ibùdó mẹ́ta, wà lójú ọ̀nà níbi tí àwọn arìnrìn-àjò sí ibi ìjọsìn náà ti máa ń tọrọ ìdáríjì fún ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Àwọn wọ̀nyí ni a ti ṣàlàyé ní kíkún lójú pátákó ìsọfúnni tí ó wà ní ibi tí gígun òkè náà ti bẹ̀rẹ̀.—Wo àpótí.
Èéṣe Tí Wọ́n Fi Ń Gòkè?
Èéṣe tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ fi ń rin ìrìn-àjò sí ibi ìjọsìn tí ó nira yìí? Èéṣe tí àwọn kan fi máa ń ṣe àṣerégèé tóbẹ́ẹ̀ nígbà tí wọ́n bá ń gòkè?
Ó dára, àwọn kan gbàgbọ́ pé nípa gbígbàdúrà nígbà ìrìn-àjò sí ibi ìjọsìn náà, àwọn ìrawọ́-ẹ̀bẹ̀ wọn fún àǹfààní ti ara wọn ni ó túbọ̀ ṣeé ṣe kí a gbọ́. Àwọn mìíràn ń ṣe é ní lílépa ìdáríjì fún àwọn àṣìṣe kan. Fún àwọn mìíràn, èyí ni ọ̀nà kan tí wọ́n lè gbà ṣọpẹ́. Ó dájú pé, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ń lọ nítorí àjọyọ̀ tí ó ní nínú. Aláṣẹ kan sọ pé ó jẹ́ ‘fífi ẹ̀mí ìfọwọ́sowọ́pọ̀ àti ìfẹ́ àjùmọ̀ṣe nǹkan papọ̀ hàn.’ Ó tún sọ pé gígun òkè Croagh Patrick “ni ọ̀nà tí wọ́n ń gbà tẹ̀lé ipasẹ̀ Patrick Mímọ́ tí wọ́n sì fi ń mọ gbèsè tí àwọn jẹ ẹ́ nínú ìgbàgbọ́.” Ó fikún un pé, èyí tí ó ṣe pàtàkì jùlọ ni pé, gígun òkè náà jẹ́ “ọ̀nà kan tí a ń gbà tọrọ ìdáríjì fún ẹ̀ṣẹ̀ nítorí pé àṣelàágùn tí ó ní nínú jẹ́ ààtò títọrọ ìdáríjì níti gidi. Rírọra gòkè pátápátá jẹ́ ìṣe ìrònúpìwàdà tí a mú gùn síi.”
Ọkùnrin kan sọ pẹ̀lú ìyangàn pé òun ti gùn ún ní ìgbà 25! Ó sọ pé, òun ṣe é, “láti lè ṣe ààtò títọrọ ìdáríjì!” Ọkùnrin mìíràn ṣàlàyé lọ́nà tí ó rọrùn pé, “O gbọ́dọ̀ jìyà, kí o tó jọrọ̀!”
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò pọndandan, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ń gun òkè náà láì wọ bàtà. Èéṣe tí wọ́n fi ń ṣe ìyẹn? Lákọ̀ọ́kọ́, wọ́n ka ilẹ̀ náà sí “mímọ́” nítorí náà ni wọ́n ṣe ń bọ́ bàtà wọn. Èkejì, ó jẹ́ híhùwà ní ìbámu pẹ̀lú ète wọn ti ‘ṣíṣe ààtò títọrọ ìdáríjì.’ Èyí pẹ̀lú ṣàlàyé ìdí rẹ̀ tí àwọn kan tilẹ̀ fi ń tọrọ ìdáríjì ní àwọn ibùdó lórí eékún wọn.
A Sún Wọn Láti Mọrírì Ẹlẹ́dàá
Ṣùgbọ́n bí ẹnì kan kò bá ṣàjọpín àwọn èrò-ìmọ̀lára ìsìn àwọn arìnrìn-àjò sí ibi ìjọsìn tí ń gòkè ní ọjọ́ àkànṣe ńkọ́? Bí ipò ojú-ọjọ́ bá dára tí ẹnì kan sì ní bàtà tí ara rẹ̀ gbàyà, a lè gun òkè-ńlá náà nígbàkigbà. A kò gun òkè náà ní ọjọ́ tí àwọn arìnrìn-àjò tí ń wọ́ tìì ń gòkè lọ. Ní àwọn ìgbà tí a sábà máa ń dúró láti sinmi, ó ṣeé ṣe fún wa láti ronú lórí gígòkè náà fúnra rẹ̀ àti ìyọrísí tí ó ní lórí ọ̀pọ̀lọpọ̀. Bí a ti ń finúwòye ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn arìnrìn-àjò sí ibi ìjọsìn tí wọ́n ń gun òkè tí ń jẹ́ kí àárẹ̀ tètè múni yìí tí wọ́n sì ń ṣe onírúurú ààtò ìtọrọ ìdáríjì, a sún wa láti ṣe kàyéfì pé, ‘Ohun tí Ọlọrun ha ń béèrè fún nìyí bí? Ààtò gígun òkè tàbí rírìn yíká ohun ìrántí kan nígbà tí a ń sọ àdúrà àsọtúnsọ ha túbọ̀ ń fa ẹnì kan súnmọ́ Ọlọrun níti gidi bí?’ Kí ni nípa ti ìmọ̀ràn Jesu lórí àwítúnwí àdúrà ní Matteu 6:6, 7?
Dájúdájú, a kò gòkè náà láti lè ní ìrírí ìsìn. Síbẹ̀, a nímọ̀lára títúbọ̀ súnmọ́ Ẹlẹ́dàá wa nítorí pé a lè mọrírì ìṣẹ̀dá rẹ̀, òkè níbikíbi jẹ́ apákan iṣẹ́-àgbàyanu tí ń bẹ nínú ayé. Láti orí-òkè náà ó ṣeé ṣe fun wa láti gbádùn ìrísí ojú-ilẹ̀ tí ó rẹwà láì sí ohunkóhun tí ó dí wa lójú, àní a rí etí bèbè Òkun Ńlá Atlantic. Ìyàtọ̀ tí ó hàn gbangba wà láàárín erékùṣù kékeré tí ń dán yinrinyinrin nísàlẹ̀ wa lápákan ní ibi tí omi òkun ti ya wọnú ilẹ̀ àti ẹkùn olókè gbágungbàgun tí ó jẹ́ aṣálẹ̀ ní òdìkejì.
A ronú nípa àwọn ibùdó mẹ́ta náà. Àwọn ọ̀rọ̀ Jesu fúnra rẹ̀ wá sí wa lọ́kàn, nígbà tí ó sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ tòótọ́ pé: “Nígbà tí iwọ bá ń gbàdúrà, máṣe wí ohun kan naa ní àwítúnwí, gan-an gẹ́gẹ́ bí awọn ènìyàn awọn orílẹ̀-èdè ti ń ṣe, nitori wọ́n lérò pé a óò gbọ́ tiwọn nitori lílò tí wọ́n ń lo ọ̀rọ̀ púpọ̀.”—Matteu 6:7.
A rí i pé òkè náà ti di apákan àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ tí ó ti di ẹgbẹẹgbẹ̀rún ènìyàn ní ìgbèkùn ààtò tí ń tánni lókun. A ronú nípa bí ìyẹn ṣe yàtọ̀ gédégédé sí òmìnira tí aposteli Johannu sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ nígbà tí ó wí pé: “Kí a pa awọn àṣẹ rẹ̀ [Ọlọrun] mọ́; síbẹ̀ awọn àṣẹ rẹ̀ kì í sì í ṣe ẹrù-ìnira.”—1 Johannu 5:3.
A gbádùn ìgbafẹ́ wa, títíkan gígun òkè Croagh Patrick. Ó sún wa láti máa fojúsọ́nà fún àkókò náà nígbà tí gbogbo aráyé yóò dòmìnira kúrò lọ́wọ́ àwọn àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ tí kò bá Bibeli mu tí yóò sì ṣeé ṣe fún wọn láti lè jọ́sìn Ẹlẹ́dàá onífẹ̀ẹ́ tí ó dá ayé “ní ẹ̀mí ati òtítọ́.”—Johannu 4:24.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 27]
Àwọn Apá Pàtàkì Nínú Ìrìn-àjò sí Ibi Ìjọsìn
Gbogbo arìnrìn-àjò sí ibi ìjọsìn tí ó bá gun òkè-ńlá náà ní Ọjọ́ Patrick Mímọ́ tàbí láàárín ọjọ́ mẹ́jọ àjọ̀dún náà, tàbí nígbàkigbà láàárín oṣù June, July, August àti September, tí ó bá sì GBÀDÚRÀ NÍNÚ TÀBÍ NÍTÒSÍ ṢỌ́Ọ̀ṢÌ KÉKERÉ NÁÀ fún Póòpù lè jèrè ìgbójúfòdá àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ lórí ìpìlẹ̀ lílọ ṣe Ìjẹ́wọ́ Ẹ̀ṣẹ̀ àti Gbígba Ara Oluwa ní Orí-Òkè tàbí láàárín ọ̀sẹ̀ náà.
ÀWỌN IBÙDÓ ÀṢÀ ÀTỌWỌ́DỌ́WỌ́
Àwọn “ibùdó” mẹ́ta ni ó wà níbẹ̀ (1) Nísàlẹ̀ òkòtó náà tàbí Leacht Benain, (2) Ní orí-òkè náà, (3) Roilig Muire, kò jìnnà púpọ̀ sí Lecanvey [ìlú kan] lẹ́gbẹ̀ẹ́ orí òkè náà.
Ibùdó Àkọ́kọ́ - LEACHT BENAIN
Arìnrìn-àjò sí ibi ìjọsìn yóò yípo ìtòjọ òkúta tí a ṣọgbà yíká ní kíka Bàbá Wa Tí Ń Bẹ Ní Ọ̀run 7, Ẹ Kókìkí Maria 7 àti Ìjẹ́wọ́ Ìgbàgbọ́ lẹ́ẹ̀kan.
Ibùdó Kejì - ORÍ-ÒKÈ NÁÀ
(a) Arìnrìn-àjò sí ibi ìjọsìn yóò kúnlẹ̀ yóò sì ka Bàbá Wa Tí Ń Bẹ Ní Ọ̀run 7, Ẹ Kókìkí Maria 7 àti Ìjẹ́wọ́ Ìgbàgbọ́ lẹ́ẹ̀kan.
(b) Arìnrìn-àjò sí ibi ìjọsìn náà yóò gbàdúrà nítòsí Ṣọ́ọ̀ṣì Kékeré tí ó wà fún àwọn ète Póòpù
(d) Arìnrìn-àjò sí ibi ìjọsìn yóò yí Ṣọ́ọ̀ṣì Kékeré náà ká nígbà 15 ní kíka Bàbá Wa Tí Ń Bẹ Ní Ọ̀run 15, Ẹ Kókìkí Maria 15 àti Ìjẹ́wọ́ Ìgbàgbọ́ lẹ́ẹ̀kan.
(e) Arìnrìn-àjò sí ibi ìjọsìn yóò rìn yíká Leaba Phadraig [ibùsùn Patrick] nígbà 7 tí yóò sì ka Bàbá Wa Tí Ń Bẹ Ní Ọ̀run 7, Ẹ Kókìkí Maria 7 àti Ìjẹ́wọ́ Ìgbàgbọ́ lẹ́ẹ̀kan.
Ibùdó Kẹta - ROILIG MUIRE
Arìnrìn-àjò sí ibi ìjọsìn yóò rìn yíká ìtòjọ àwọn òkúta nígbà 7 yóò sì máa ka Bàbá Wa Tí Ń Bẹ Ní Ọ̀run 7, Ẹ Kókìkí Maria 7 àti Ìjẹ́wọ́ Ìgbàgbọ́ lẹ́ẹ̀kan nídìí ọ̀kọ̀ọ̀kan [ìtòjọ mẹ́ta ni ó wà] wọ́n yóò sì rìn yíká ọgbà Roilig Muire látòkèdélẹ̀ nígbà 7 tí wọ́n yóò sì máa gbàdúrà.