ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w95 11/15 ojú ìwé 8-9
  • Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa Káàkiri Ayé—New Zealand

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa Káàkiri Ayé—New Zealand
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa Káàkiri Ayé—Bahamas
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Jehofa Ti Bojuto Mi Daradara
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
w95 11/15 ojú ìwé 8-9

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa Káàkiri Ayé—New Zealand

ERÉKÙṢÙ ha lè yin Jehofa bí? Bẹ́ẹ̀ ni, ní ìbámu pẹ̀lú Isaiah 42:10: “Ẹ kọ orin tuntun sí Oluwa, ìyìn rẹ̀ láti òpin ayé, ẹ̀yin . . . erékùṣù, àti àwọn tí ń gbé inú wọn.” Dájúdájú, àwọn erékùṣù tí ó para pọ̀ di New Zealand ń yin Jehofa. A mọ̀ ọ́n káàkiri àgbáyé nítorí àwọn adágún, àwọn ẹsẹ̀ odò tẹ́ẹ́rẹ́, àwọn òkè ńlá gíga gogoro, àwọn ìṣàn òkìtì yìnyín, àwọn etíkun, àwọn igi eléwé wẹ́rẹ́wẹ́rẹ́ nínú igbó títutù yọ̀yọ̀, àti igbó títẹ́jú rẹrẹ, New Zealand ń sọ̀rọ̀ nípa ọlá ńlá àti ìtóbilọ́lá Ẹlẹ́dàá ọ̀run òun ayé.

Láti ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún ogún wá, púpọ̀ sí i àwọn olùgbé New Zealand ti pa ohùn wọn pọ̀ láti yin Jehofa, nípa yíyíjú sí i nínú ìjọsìn mímọ́ gaara àti ṣíṣàjọpín ìhìn rere Ìjọba Ọlọrun pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn. Láìpẹ́ yìí, Ẹlẹ́rìí kan tí ó ti ní ìrírí tí ó dára nípa jíjẹ́rìí fún àwọn ìbátan rẹ̀, pinnu láti jẹ́rìí fún ìdílé rẹ̀. Ó pèsè àwọn ẹ̀dà ìwé náà Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye fún mẹ́ḿbà ìdílé rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn. Kí ni ìyọrísí náà títí di báyìí? Ó ròyìn pé arábìnrin kan àti arákùnrin kan ti ń kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli nísinsìnyí, ọmọkùnrin ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ti ṣe batisí gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, àwọn yòókù sì ti túbọ̀ ń fetí sílẹ̀ sí òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọrun nísinsìnyí. Ó ṣì ní agbègbè púpọ̀ láti ṣiṣẹ́; yàtọ̀ sí àwọn òbí rẹ̀, ó ní arákùnrin mẹ́fà àti arábìnrin mẹ́sàn-án!

Nígbà tí àwọn Ẹlẹ́rìí bá pawọ́ pọ̀ láti kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba, èyí máa ń yọrí sí ìyìn sí Jehofa. Fún àpẹẹrẹ, Roy Perkins tí ó jẹ́ akọ̀ròyìn fún ìwé agbéròyìnjáde, kọ nínú Opotiki News ti May 17, 1994, pé: “Ní ti pé mo jẹ́ aláìgbàgbọ́, iṣẹ́ àti ìsapá gbogbo àwọn òṣìṣẹ́ tí wọ́n ń fi gbogbo ara ṣiṣẹ́, tí wọ́n sì ń lo àkókò àti ìsapá tí ó tó báyẹn nínú iṣẹ́ ìdáwọ́lé náà, nítorí ìfẹ́ wọn fún Ọlọrun wọn, wú mi lórí púpọ̀.

“Ní gbogbo wákàtí tí wọ́n fi ṣiṣẹ́ ní òpin ọ̀sẹ̀ náà, èmi kò rí tàbí gbọ́ èdèkòyedè ẹgbẹ́ kankan . . . Àwọn obìnrin wà lórí pẹpẹ títẹ́ náà, wọ́n sí ń ṣiṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn ọkùnrin, wọ́n ń dán ara bíríkì, wọ́n ń gbé àwọn ohun ìkọ́lé náà, pẹ̀lú ayọ̀ àti ìfọ̀kànbalẹ̀.

“Wọn kò sì fi ìṣẹ́jú kankan ṣòfò níbi kí lágbájá, tàmẹ̀dò, tàbí làkáṣègbè máa lọ wé sìgá. Ní gbogbo ibi tí àwọn ènìyàn ti ń ṣiṣẹ́, afẹ́fẹ́ ibẹ̀ mọ́ gaara, àyàfi òórùn ọ̀dà àti eruku bíríkì ni o lè gbọ́.”

Ẹgbẹ́ àwọn alàgbà Ìjọ Opotiki kọ̀wé pé: “Iṣẹ́ ìdáwọ́lé náà lápapọ̀ wú àwọn ènìyàn ìlú náà lórí. Ó dà bíi pé gbogbo ènìyàn ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. A ti bẹ̀rẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli. Ọ̀kan pàtàkì tí ó mú ọkàn wa yọ gidigidi ni ti tọkọtaya kan, ti wọ́n ti jingíri sínú ìsìn, tí wọ́n ti fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sọ pé, a kò gbọdọ̀ bẹ̀ wọ́n wò. Wọ́n ń wá sí ibi ìkọ́lé náà lójoojúmọ́, wọ́n sì ń wá sí ìpàdé. Lẹ́yìn náà, ọkọ náà sọ pé, ‘Mo rí i dájú pé ènìyàn Ọlọrun ni yín. Nínú lọ́hùn-ún, mo ti ń yán hànhàn ní gbogbo ọjọ́ ayé mi láti dara pọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn tí wọ́n rí báyìí.’”

Ní ọdún tí ó ṣáájú, akọ̀ròyìn kan fún Otago Daily Times sọ ọ̀rọ̀ tí ó tẹ̀ lé e yìí nípa Gbọ̀ngàn Ìjọba àsárékọ́ kan ní Dunedin pé: “Ó jẹ́ àgbéṣe kan tí ó kàmàmà, àpẹẹrẹ ìsúnniṣe àti ìranra-ẹni-lọ́wọ́ kíkàmàmà.” Ìwé agbéròyìnjáde kan náà sọ pé: “Tìyanutìyanu ni àwọn ará ìlú náà fi ń wo bí a ti ń kọ́ ilé ńlá kan níṣojú wọn, ó sì dájú pé púpọ̀ yóò máa ronú nípa àwọn ìyípadà mìíràn àti àwọn iṣẹ́ ìdáwọ́lé tí a lè ṣàṣeyọrí rẹ̀, bí àkójọpọ̀ àwọn olùyọ̀ọ̀da ara ẹni àti ọ̀pọ̀ ẹ̀mí ìfọwọ́sowọ́pọ̀ tí ó rí bẹ́ẹ̀ bá wà lárọ̀ọ́wọ́tó. Gbọ̀ngàn Ìjọba jẹ àmì tí ó ṣeé mú yangàn tí àṣeyọrí ìsapá iṣẹ́ ìkọ́lé ní.”

Lára ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn tí wọ́n wá síbi ìkọ́lé náà, ọkùnrin kan ṣàkíyèsí pé àwọn Ẹlẹ́rìí ń kọ́ “ṣọ́ọ̀ṣì,” nígbà tí ẹ̀yà ìsìn tòun ń ta ṣọ́ọ̀ṣì wọn nítorí àwọn mẹ́ḿbà wọn ń joro sí i. Ó dábàá pé: “Ì bá ṣe pé ẹ dúró fún oṣù méjìlá mìíràn sí i ni, ẹ̀ bá ti ra ọ̀kan lára tiwa. A ní láti ta ọ̀kan nítorí agbára wa kò ká sísan owó rẹ̀ mọ́. Ṣùgbọ́n, òótọ́ ni pé, ẹ̀yin ènìyàn yìí kò ní àwùjọ àlùfáà tí ẹ ń san owó fún. . . . Àti pé àwọn ilé yín ṣe é fi owó tí ó mọníwọ̀n tún ṣe, kì í ṣe ilé gogoro aborí ṣóńṣó, tí ó ṣoro láti tọ́jú.”

Dájúdájú, àwọn erékùṣù lè yin Ọlọrun. Ǹjẹ́ kí ìyìn Jehofa máa bá a nìṣó láti máa lọ sókè sí i ní ilẹ̀ Pacific rírẹwà yìí—àti káàkiri ayé!

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 9]

ÌSỌFÚNNI ṢÓKÍ NÍPA ORÍLẸ̀-ÈDÈ:

Ọdún Iṣẹ́ Ìsìn 1994

GÓŃGÓ IYE ÀWỌN TÍ Ń JẸ́RÌÍ: 12,867

ÌṢIRÒ ÌFIWÉRA: Ẹlẹ́rìí 1 sí 271

ÀWỌN TÍ WỌ́N PÉSẸ̀ SÍBI ÌṢE ÌRÁNTÍ: 24,436

ÌPÍNDỌ́GBA ÀWỌN AKÉDE TÍ WỌ́N JẸ́ AṢÁÁJÚ Ọ̀NÀ: 1,386

ÌPÍNDỌ́GBA ÀWỌN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ BIBELI: 7,519

IYE TÍ A BATISÍ: 568

IYE ÀWỌN ÌJỌ: 158

Ọ́FÍÌSÌ Ẹ̀KA: MANUREWA

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]

Àwọn aṣáájú ọ̀nà lẹ́nu iṣẹ́ pápá ní nǹkan bíi 1930

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]

Ilé lílò ti ẹ̀ka ní Manurewa

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]

Wíwàásù ìhìn iṣẹ́ Ìjọba náà ní Devonport, Auckland

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́