ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w96 1/15 ojú ìwé 31
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àṣírí Kan Ha Wà fún Ayọ̀ Ìdílé Bí?
    Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé
  • Gbádùn Ìgbésí Ayé Ìdílé
    Gbádùn Ìgbésí Ayé Ìdílé
  • Ìdílé—Ohun Kòṣeémánìí fún Ẹ̀dá Ènìyàn!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Mọyì Àǹfààní Tó O Ní Pé O Wà Nínú Ìdílé Jèhófà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2021
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
w96 1/15 ojú ìwé 31

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Efesu 3:14, 15 sọ pé Ọlọrun ni “olúkúlùkù ìdílé ní ọ̀run ati lórí ilẹ̀-ayé jẹ ní gbèsè fún orúkọ rẹ̀.” Ìdílé ha wà ní ọ̀run bí, ìdílé ẹ̀dá ènìyàn kọ̀ọ̀kan ha ń gba orúkọ rẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Jehofa lọ́nà kan ṣáá bí?

Kò sí ìdílé kankan ní ọ̀run tí ó ní bàbá kan, ìyá kan, àti àwọn ọmọ, bí ó ti wà lórí ilẹ̀ ayé—tí wọ́n bá ara wọn tan nípa ti ara. (Luku 24:39; 1 Korinti 15:50) Jesu tọ́ka sí i kedere pé àwọn áńgẹ́lì kì í gbéyàwó, kò sì sí ohunkóhun tí ó tọ́ka sí i ní ọ̀nàkọnà pé wọ́n ń mú irú ọmọ jáde.—Matteu 22:30.

Ṣùgbọ́n, Bibeli sọ̀rọ̀ lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ nípa Jehofa Ọlọrun gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó gbé ètò àjọ rẹ̀ ti ọ̀run níyàwó; ó gbéyàwó, tí a bá sọ ọ́ ní ọ̀nà tẹ̀mí. (Isaiah 54:5) Ètò àjọ ti ọ̀run náà mú irú ọmọ jáde, irú bí i àwọn áńgẹ́lì. (Jobu 1:6; 2:1; 38:4-7) Nígbà náà, ní ọ̀nà yìí, àgbàyanu ìdílé tẹ̀mí ń bẹ ní ọ̀run.

Ní àfikún sí i, ìdílé ìṣàpẹẹrẹ tuntun ń dìde ní ọ̀run, tí ó ní Jesu Kristi àti ìyàwó tí ó jẹ́ ìjọ rẹ̀ ti 144,000 nínú. (2 Korinti 11:2) Ọ̀pọ̀ lára àwọn ẹni àmì òróró wọ̀nyí ti kú, pẹ̀lú ìwàláàyè ti ọ̀run ní iwájú wọn. Àwọn kan ṣì wà láàyè lórí ilẹ̀ ayé. Gbogbo wọn ń hára gàgà fojú sọ́nà fún “ìgbéyàwó Ọ̀dọ́ Àgùtàn” ní ọ̀run. Bibeli so ìgbéyàwó náà pọ̀ pẹ̀lú àkókò ìpọ́njú ńlá tí ń sún mọ́lé—ìparun Babiloni Ńlá, àti ìkékúrò ìyókù ètò ìgbékalẹ̀ Satani.—Ìṣípayá 18:2-5; 19:2, 7, 11-21; Matteu 24:21.

Nípa àwọn ìdílé orí ilẹ̀ ayé, aposteli Paulu kò tọ́ka sí i nínú Efesu 3:15 pé gbogbo àwùjọ ìdílé kọ̀ọ̀kan ń gba orúkọ wọn ní tààràtà láti ọ̀dọ̀ Jehofa. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó dájú pé ohun tí Paulu ní lọ́kàn ni ìlà ìdílé ńlá kan tí ń pa orúkọ mọ́. Joṣua 7:16-19 fúnni ní àpẹẹrẹ kan. Níbẹ̀ ni Jehofa ti túdìí àṣírí ẹ̀ṣẹ̀ Akani. Lákọ̀ọ́kọ́ ná, ẹ̀bi náà ni a dojú rẹ̀ kọ tàbí tí a fi mọ sórí ẹ̀yà Juda. Lẹ́yìn náà ni a túbọ̀ mú un ṣe pàtó sórí ìdílé Sera. Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, a túdìí àṣírí agboolé Akani. A fojú wo, tàbí sọ̀rọ̀ Akani pa pọ̀ pẹ̀lú ìyàwó rẹ̀ àti àwọn ọmọ rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí apá kan agboolé (tàbí, ìdílé) Sabdi, bàbá àgbà Akani. Ìdílé yẹn, lẹ́yìn náà, ni àwùjọ ńlá tí ń pa orúkọ baba ńlá wọ́n, Sera, mọ́.

Láàárín àwọn Heberu, irú ìlà ìdílé bẹ́ẹ̀ jẹ́ ohun pàtàkì, ọ̀pọ̀ ni a tò lẹ́sẹẹsẹ nínú Bibeli. Ọlọrun ti ìpamọ́ náà lẹ́yìn nípa ṣíṣètò, níbi tí ó bá ti yẹ, fún àwọn ajogún láti ta orúkọ ìdílé náà látaré nípasẹ̀ ṣíṣú aya arákùnrin ẹni lópó.—Genesisi 38:8‚ 9; Deuteronomi 25:5‚ 6.

Gbé àpẹẹrẹ Jesu gẹ́gẹ́ bí ọmọkùnrin Dafidi yẹ̀ wò, gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ irú ìdílé ńlá, tàbí ìdílé amẹ́bímúbàátan. Ó hàn kedere pé kì í ṣe ọmọ Ọba Dafidi ní tààràtà, a kò bí i títí di ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún lẹ́yìn ikú Dafidi. Síbẹ̀, ohun kan tí a fi dá Messia mọ̀ ni pé, ó ní láti jẹ́ láti ìdílé Dafidi, gẹ́gẹ́ bí àwọn Júù ní gbogbogbòò ti mọ̀. (Matteu 22:42) Jesu wá láti ìlà Dafidi nípasẹ̀ ìyá rẹ̀ àti bàbá tí ó gbà á tọ́.—Matteu 1:1; Luku 2:4.

Ṣùgbọ́n báwo ni irú àwọn ìdílé bẹ́ẹ̀ ṣe gba orúkọ wọn láti ọ̀dọ̀ Jehofa? Òkodoro òtítọ́ ni pé àwọn ìgbà díẹ̀ wà—irú bí i ìgbà ti Abrahamu àti Isaaki—nígbà tí Jehofa ní tààràtà fún olórí ìdílé ní orúkọ. (Genesisi 17:5‚ 19) Àyàfi àwọn wọ̀nyẹn. Ní ti èyí tí ó pọ̀ jù, Jehofa kì í fún ìdílé kọ̀ọ̀kan ni orúkọ tí wọ́n ń ta látaré sí àwọn ọmọ.

Bí ó ti wù kí ó rí, Jehofa pilẹ̀ ìdílé ẹ̀dá ènìyàn kan nígbà tí ó pàṣẹ fún Adamu àti Efa láti ‘máa bí sí i, kí wọ́n sì máa rẹ̀, kí wọ́n sì gbilẹ̀.’ (Genesisi 1:28) Jehofa sì fàyè gba Adamu àti Efa aláìpé láti mú irú ọmọ jáde, ní títipa báyìí ṣe ìpìlẹ̀ fún gbogbo ìdílé ẹ̀dá ènìyàn. (Genesisi 5:3) Nítorí náà, ní èyí tí ó ju ọ̀nà kan lọ, a lè pe Ọlọrun ní Olùpilẹ̀ṣẹ̀ àwọn orúkọ ìdílé.

Ọ̀pọ̀ àṣà ìbílẹ̀ lónìí kò rò pé ó di dandan láti pa orúkọ ìdílé mọ́ fún àwọn ìran tí ń bọ̀. Bí ó ti wù kí ó rí, ní gbogbo ilẹ̀, àwọn Kristian ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Jehofa fún ìṣètò ìdílé, wọ́n sì ń bọlá fún un nípa ṣíṣiṣẹ́ kára láti mú kí ìdílé wọn kọ̀ọ̀kan ṣàṣeyọrí.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́