Àwọn Olùpòkìkí Ìjọba Ròyìn
Ìfaradà Yọrí sí Ìbùkún Ọlọ́run ní Màláwì
JÓSẸ́FÙ jẹ́ olùṣòtítọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà. (Hébérù 11:22) Ó sì tún jẹ́ ọkùnrin onífaradà tí ó tayọ. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ẹ̀gbọ́n tirẹ̀ fúnra rẹ̀ dà á, a tà á sí oko ẹrú ní ìgbà méjì, a sì jù ú sí ọgbà ẹ̀wọ̀n nítorí ẹ̀sùn èké lẹ́yìn náà, Jósẹ́fù kò rẹ̀wẹ̀sì. Dípò èyí, ó fi sùúrù fara da ìpọ́njú ọlọ́pọ̀ ọdún, ní fífi ìrẹ̀lẹ̀ dúró de ìbùkún Jèhófà.—Jẹ́nẹ́sísì 37:23-28, 36; 39:11-20.
Bákan náà ni lónìí, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Màláwì ti fi sùúrù dúró de ìbùkún Ọlọ́run. Fún ọdún 26, àwọn Kristẹni Ẹlẹ́rìí yìí ti fara da ìfòfindè lábẹ́ ìjọba, àtakò líle koko, àti ọ̀pọ̀ ìwà ìkà bíburú jáì. Ṣùgbọ́n ìfaradà wọ́n ti mérè wá!
Nígbà tí inúnibíni bẹ́ sílẹ̀ ní Màláwì ní òpin ọdún 1967, akéde Ìjọba tí ó wà níbẹ̀ tó nǹkan bí 18,000. Finú wòye bí ayọ̀ Àwọn Ẹlẹ́rìí náà ti pọ̀ tó nígbà tí wọ́n gbọ́ pé ọdún iṣẹ́ ìsìn 1997 bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú góńgó tuntun akéde 38,393—tí ó ju ìlọ́po méjì àwọn tí ó wà ní ìbẹ̀rẹ̀ ìfòfindè náà! Ní àfikún sí i, iye àwọn tí wọ́n wá sí àwọn Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Àwọn Ońṣẹ́ Àlàáfíà Ọlọ́run” 13 tí a ṣe ní Màláwì lọ sókè sí iye tí ó ju 117,000 lọ. Ní tòótọ́, Jèhófà ti bù kún ìgbàgbọ́ àti ìfaradà wọn.
Àpẹẹrẹ ìbùkún yìí kan ni ìrírí ọ̀dọ́mọkùnrin kan tí ń jẹ́ Machaka. Nígbà tí Machaka tẹ́wọ́ gba ìfilọni kan láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, àwọn òbí rẹ̀ bínú gan an. Wọ́n sọ pé: “Bí o bá fẹ́ di Ẹlẹ́rìí, o gbọ́dọ̀ jáde kúrò ní ilé.” Ṣùgbọ́n, ìhàlẹ̀ yí kò kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá a láti máa bá ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ lọ. Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn òbí Machaka gba gbogbo aṣọ rẹ̀. Àwọn arákùnrin dáhùn pa dà nípa ríra aṣọ bíi mélòó kan fún un. Nígbà tí àwọn òbí Machaka gbọ́ nípa èyí, wọ́n sọ fún un pé: “Bí Àwọn Ẹlẹ́rìí yóò bá máa tì ọ́ lẹ́yìn, o gbọ́dọ̀ jáde kí o sì lọ gbé ọ̀dọ̀ wọn.” Lẹ́yìn gbígbé ọ̀ràn náà yẹ̀ wò dáradára, Machaka fi ilé sílẹ̀, ìdílé Ẹlẹ́rìí kan ní ìjọ àdúgbò sì gbà á sílé.
Inú bí àwọn òbí Machaka débi pé wọ́n pinnu láti kó kúrò ní àgbègbè náà kí wọ́n lè yàgò fún gbogbo àjọṣe pẹ̀lú Àwọn Ẹlẹ́rìí. Dájúdájú, èyí ba Machaka nínú jẹ́, ṣùgbọ́n ó rí ìtùnú púpọ̀ nígbà tí àwọn arákùnrin bá a jíròrò Orin Dáfídì 27:10, tí ó sọ pé: “Nígbà tí bàbá àti ìyá mi kọ̀ mí sílẹ̀, nígbà náà ni Olúwa yóò tẹ́wọ́ gbà mí.”
Láìpẹ́, inú àwọn òbí Machaka rọ̀, ó sì pinnu láti pa dà sílé. Ní tòótọ́, ìpinnu ọmọkùnrin wọn láti sin Jèhófà ní ipa lílágbára lórí wọn, nítorí pé àwọn náà fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà! Wọ́n tún wá sí Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Àwọn Ońṣẹ́ Àlàáfíà Ọlọ́run,” fún ọjọ́ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta, lẹ́yìn èyí tí ó sún wọn láti sọ pé: “Ní tòótọ́, ètò àjọ Ọlọ́run nìyí.”
Dájúdájú, àtakò lè jẹ́ àdánwò, ṣùgbọ́n àwọn adúróṣinṣin ìránṣẹ́ Ọlọ́run kìí juwọ́ sílẹ̀. Wọ́n ń fi ìgboyà tẹ̀ síwájú, ní mímọ̀ pé, “ìpọ́njú ń mú ìfaradà wá; ìfaradà, ní tirẹ̀, ipò ojú rere ìtẹ́wọ́gbà.” (Róòmù 5:3, 4) Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Màláwì lè jẹ́rìí sí i pé lóòótọ́ ìfaradà ń yọrí sí ìbùkún Ọlọ́run.