Wọ́n Ṣọ̀kan Ní Ọ̀nà Ìgbésí Ayé Tó Dára Jù Lọ
Bí iye olùgbé ayé bá túbọ̀ ń ga sí i, láìpẹ́ láìjìnnà, àwọn tó ń gbé ilẹ̀ ayé yóò máa lọ sí bílíọ̀nù mẹ́fà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀dọ̀ baba ńlá kan náà ni gbogbo wọn ti ṣẹ̀ wá, ọ̀pọ̀ jù lọ ni kò gbà pé àwọn jẹ́ mẹ́ńbà ìdílé àgbáyé kan náà tí yóò jíhìn fún Ẹlẹ́dàá tó jẹ́ ọlọ́gbọ́n àti onífẹ̀ẹ́. Ìyapa àti gbọ́nmisi-omi-ò-to tí ó wà láàárín àwọn orílẹ̀-èdè, ìran, àti àwùjọ ń fúnni ní ẹ̀rí tí ń múni sorí kọ́ nípa ipò ìbànújẹ́ tí ayé wà.
PẸ̀LÚ ipò tí ayé wà báyìí, ó jọ pé ìṣọ̀kan àgbáyé ti di góńgó àléèbá. Ìwé náà, The Columbia History of the World, sọ pé: “Bó bá jẹ́ ti ìbéèrè tó ṣe pàtàkì jù lọ náà nípa bí a ṣe lè gbé papọ̀ ni, ayé tiwa yìí kò ní èrò tuntun kankan nípa rẹ̀, bó ti wù kó mọ.”
Àmọ́ ṣá o, mímú ìṣọ̀kan wà láàárín gbogbo àwọn olùgbé ayé kò nílò èrò tuntun. Ìwé Mímọ́ ti lànà ohun tó lè mú ìṣọ̀kan wá. Ó dá lórí ìjọsìn Ẹni náà tó dá ilẹ̀ ayé àti gbogbo ẹ̀mí tí ń bẹ lórí rẹ̀. Ní báyìí, ojúlówó ìṣọ̀kan ní ti ọ̀nà ìrònú, ète, àti ọ̀nà ìgbésí ayé ti wà láàárín àwọn ènìyàn Ọlọ́run. Wọ́n lé ní mílíọ̀nù márùn-ún ààbọ̀ ní igba ilẹ̀ ó lé mẹ́tàlélọ́gbọ̀n [233], ìgbàgbọ́ wọn sì ṣọ̀kan pé, ọ̀nà ìgbésí ayé tí Ọlọ́run fẹ́ ni ọ̀nà dídára jù lọ. Gẹ́gẹ́ bí ti onísáàmù, àdúrà wọn ni pé: “Jèhófà, fún mi ní ìtọ́ni nípa ọ̀nà rẹ. Èmi yóò máa rìn nínú òtítọ́ rẹ. Mú ọkàn-àyà mi ṣọ̀kan láti máa bẹ̀rù orúkọ rẹ.”—Sáàmù 86:11.
Wòlíì Aísáyà ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa mímú àwọn ènìyàn ṣọ̀kan nínú ìjọsìn mímọ́ gaara yìí tipẹ́tipẹ́ sẹ́yìn. Ó kọ̀wé pé: “Yóò sì ṣẹlẹ̀ ní apá ìgbẹ̀yìn àwọn ọjọ́ pé òkè ńlá ilé Jèhófà yóò di èyí tí a fìdí rẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in sí orí àwọn òkè ńláńlá, dájúdájú, a óò gbé e lékè àwọn òkè kéékèèké; gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè yóò sì máa wọ́ tìrítìrí lọ sórí rẹ̀. Dájúdájú, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn yóò lọ, wọn yóò sì wí pé: ‘Ẹ wá, ẹ sì jẹ́ kí a gòkè lọ sí òkè ńlá Jèhófà, sí ilé Ọlọ́run Jékọ́bù; òun yóò sì fún wa ní ìtọ́ni nípa àwọn ọ̀nà rẹ̀, àwa yóò sì máa rìn ní àwọn ipa ọ̀nà rẹ̀.’”—Aísáyà 2:2, 3.
Ìṣọ̀kan Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kò mà láfiwé o. Nínú àwọn ìjọ tó ju ọ̀kẹ́ mẹ́rin ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbàarin [87,000] yíká ayé, oúnjẹ tẹ̀mí kan náà ni wọ́n ń jẹ nínú àwọn ìpàdé wọn lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. (Mátíù 24:45-47) Ṣùgbọ́n, láti àárín ọdún 1998 títí di ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1999, Àwọn Ẹlẹ́rìí ti fi ìṣọ̀kan wọn hàn lọ́nà mìíràn—nípa pípàdé fún ọjọ́ mẹ́ta níbi àwọn Àpéjọpọ̀ “Ọ̀nà Ìgbésí Ayé Tí Ọlọ́run Fẹ́” jákèjádò ayé. Ní orílẹ̀-èdè mẹ́tàlá, ọ̀pọ̀ àwọn aṣojú láti onírúurú ilẹ̀ wá sí àwọn ìpàdé wọ̀nyí, irú àwọn ìpàdé bẹ́ẹ̀ la pè ní àpéjọpọ̀ àgbáyé. A pe àwọn mìíràn ni àpéjọpọ̀ àgbègbè. Èyí ó wù kó jẹ́, ìtòlẹ́sẹẹsẹ àwọn ohun rere tẹ̀mí kan náà ni a gbé kalẹ̀ ní gbogbo àpéjọpọ̀ wọ̀nyí.
Ó mà lárinrin o, láti rí àwọn tí wọ́n wá ṣèpàdé, tí wọn ń yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀, tí wọ́n múra dáadáa, tí wọ́n ń wọ́ lọ tìrítìrí sínú àwọn gbọ̀ngàn ńlá àti pápá ìṣeré nítorí kí Jèhófà lè kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́! Àpẹẹrẹ kan ni ti aṣojú tó wá sí àpéjọpọ̀ àgbáyé tí ó wáyé ní Michigan, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Arábìnrin náà sọ pé: “Ayọ̀ ńlá ló jẹ́ láti rí àwọn ará tó wá láti ibi gbogbo lágbàáyé—láti ilẹ̀ Olómìnira Czech, Barbados, Nàìjíríà, Hungary, ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, Holland, Etiópíà, Kẹ́ńyà, àti ọ̀pọ̀ ilẹ̀ mìíràn—tí wọ́n ń dì mọ́ra gbàgìgbàgì! Ó mà dára láti rí àwọn ará tí ń gbé ní ìrẹ́pọ̀ o, tí omijé ayọ̀ ń ṣàn lójú wọn nítorí ìfẹ́ tí wọ́n ní fún ẹnì kìíní kejì àti fún Jèhófà, Ọlọ́run wọn atóbilọ́lá.” Àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e yóò ṣàtúpalẹ̀ ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọpọ̀ náà tí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ jákèjádò ayé gbádùn.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 3]
Mountain High Maps® Copyright © 1997 Digital Wisdom, Inc.