Ǹjẹ́ Ò Ń Ronú Nípa Ìgbéyàwó?
Báa bá fi ìṣòro ìkọ̀sílẹ̀ tó gba gbogbo àgbáyé kan wé ìsẹ̀lẹ̀, Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà ni yóò jẹ́ ibi tí jàǹbá yìí yóò ti kọ́kọ́ wáyé. Lọ́dún àìpẹ́ yìí, ìgbéyàwó tó lé ní àádọ́ta ọ̀kẹ́ ni wọ́n tú ká níbẹ̀—ìpíndọ́gba ìgbéyàwó méjì-méjì ní ìṣẹ́jú kọ̀ọ̀kan. Ṣùgbọ́n, ó ṣeé ṣe kí o mọ̀ pé kì í ṣe Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà nìkan ni wàhálà ọ̀ràn ìgbéyàwó bá.
GẸ́GẸ́ bí ìwádìí kan ti sọ, láti ọdún 1970, iye ìkọ̀sílẹ̀ tó ń wáyé ní Kánádà, ilẹ̀ England àti Wales, Faransé, Gíríìsì, àti Netherlands ti lé ní ìlọ́po méjì ohun tí ń ṣẹlẹ̀ níbẹ̀ tẹ́lẹ̀.
A kò kọminú rárá pé, ọ̀pọ̀ jù lọ tọkọtaya ń wọnú ìdè ìgbéyàwó nítorí pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ ara wọn, tí wọ́n sì fẹ́ láti lo ìyókù ìgbésí ayé wọn papọ̀. Ṣùgbọ́n, ó ṣeni láàánú pé, ìdílé aláyọ̀ tí ọ̀pọ̀ ń retí kí wọ́n tó ṣègbéyàwó kì í sábà rí bẹ́ẹ̀—àlá lásán ló sábà máa ń jẹ́. Nígbà tí ọ̀pọ̀ wá mọ bó ṣe ń rí gan-an, wọ́n ní kò yẹ káwọn ti tètè ṣègbéyàwó báyẹn, àwọn mìíràn sọ pé kì í ṣe irú ẹni tó yẹ kí àwọn fẹ́ làwọn lọ fẹ́, ohun méjèèjì yìí tilẹ̀ ni àwọn mìíràn sọ.
Èé ṣe tí ọ̀pọ̀ ìgbéyàwó fi ń forí ṣánpọ́n? Òǹkọ̀wé kan lórí ìfẹ́rasọ́nà sọ pé: “Ìdí pàtàkì ni àìmúrasílẹ̀.” Obìnrin náà tún fi kún un pé: “Nínú ìbálò mi pẹ̀lú àwọn tọkọtaya tó wà nínú ìrora gógó tí ìdààmú ìgbéyàwó fà, ìmọ̀lára méjì ló máa ń dà bò mí—àánú àti ìbínú. Àánú wọn máa ń ṣe mí nítorí pé, ipò ìbátan aláyọ̀ tí wọ́n rò pé yóò wà láàárín àwọn méjèèjì kò rí bẹ́ẹ̀ mọ́. Inú máa ń bí mi nítorí wọn kò lóye bí iṣẹ́ náà ti díjú tó.”
Lóòótọ́, ọ̀pọ̀ ló ń kù gìrì wọnú ìgbéyàwó láìní òye kankan nípa bí wọ́n ṣe lè ṣàṣeyọrí. Síbẹ̀, èyí kò fi bẹ́ẹ̀ yani lẹ́nu. Olùkọ́ni kan sọ pé: “Ẹ ò mọye àwọn ọ̀dọ́ wa tó jẹ́ pé ìṣesí èkúté àti aláǹgbá ni wọ́n ń lọ kọ́ ní kọ́lẹ́ẹ̀jì, ṣùgbọ́n tí wọn ò kọ́ nípa ìṣesí àwọn ẹni méjì táà ń pè ní tọkọtaya?”
Ǹjẹ́ ò ń ronú nípa ìgbéyàwó—bóyá ò ń ronú àtiṣègbéyàwó ní ọjọ́ ọ̀la tàbí ìgbéyàwó tóo ti wà nínú rẹ̀ lò ń rò? Bóo bá ń ronú nípa ìgbéyàwó, ó yẹ kí o mọ̀ pé ipò lọ́kọláya gidi yàtọ̀ pátápátá sí èyí táà ń rí nínú sinimá, táà ń wò lórí tẹlifíṣọ̀n, àti èyí táà ń kà nínú ìwé ìtàn eléré ìfẹ́. Síbẹ̀síbẹ̀, a lè sọ pé ìgbéyàwó àwọn ẹni méjì tí wọ́n dàgbà dénú, tí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ ara wọn dénú jẹ́ ìbùkún láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run. (Òwe 18:22; 19:14) Bó bá rí bẹ́ẹ̀, báwo ló ṣe lè dá ọ lójú pé o ti gbára dì láti kojú àwọn ohun tí ìgbéyàwó ń béèrè? Kí ni àwọn kókó tó yẹ kí o gbé yẹ̀ wò tóo bá fẹ́ yan ẹni tóo fẹ́ẹ́ fẹ́? Bó bá sì jẹ́ pé o ti ṣègbéyàwó, báwo ló ṣe lè mú kí rírí ayọ̀ pípẹ́ títí nínú ìgbéyàwó rẹ ṣeé ṣe?