Ǹjẹ́ Bíbélì Lè Ràn Wá Lọ́wọ́ Lóde Òní?
“BÁA bá wo Bíbélì lódindi, èyí tó yẹ ní kíkà nínú rẹ̀ kò ju ìpín kan ṣoṣo nínú ọgọ́rùn-ún, ṣùgbọ́n gbogbo ìyókù, òkú ọ̀rọ̀ ni, kò sì bóde òní mu.” Ọ̀dọ́mọkùnrin kan ló sọ bẹ́ẹ̀. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa gbà pẹ̀lú ẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé títí di báa ti ń wí yìí, kò síwèé tó tà tó Bíbélì láyé, síbẹ̀ àìmọye èèyàn ni kò fi bẹ́ẹ̀ kọbi ara sí i, tí wọn ò sì mọ àwọn ohun tó fi ń kọ́ni.
Nínú ẹ̀dà tí ìwé ìròyìn èdè Jámánì náà Süddeutsche Zeitung gbé jáde nígbà Kérésìmesì ọdún 1996, ó sọ pé Bíbélì “ti di ìwé táwọn èèyàn ò fi bẹ́ẹ̀ kà mọ́ o. Nísinsìnyí táyé ti dayé ìmọ̀ ìjìnlẹ̀, táwọn èèyàn ò sì ka ẹ̀sìn kún mọ́, ṣe làwọn èèyàn ń wo àwọn ìtàn Bíbélì bí abàmì ìtàn tí kò lórí tí kò nídìí.” Onírúurú ìwádìí ti kín ọ̀rọ̀ yìí lẹ́yìn. Àwọn ìwádìí kan fi hàn pé ọ̀pọ̀ ọmọdé ni kò tiẹ̀ mọ ẹni tí wọ́n ń pè ní Jésù. Nínú ìwádìí kan, lára àwọn tí wọ́n fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò, àwọn tó lè sọ ìtàn Bíbélì nípa ọmọ onínàákúnàá àti ìtàn aláàánú ará Samáríà kò tó ìdajì.
Ìwé Reformierte Presse tí Ìjọ Ajíhìnrere ilẹ̀ Switzerland tẹ̀ jáde sọ pé ní ilẹ̀ yẹn, àwọn èèyàn ò fi bẹ́ẹ̀ ra Bíbélì bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́. Àwọn tó tilẹ̀ ní Bíbélì nílé pàápàá, eruku ló bò ó níbi tí wọ́n gbé e sí. Bẹ́ẹ̀ náà ló rí ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì. Ìwádìí kan sọ pé, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo èèyàn ló ní Bíbélì lọ́wọ́, ṣàṣà làwọn tó ń kà á.
Àmọ́ o, nínú ayé yìí kan náà, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ tún wà o, tó jẹ́ pé ojú ọ̀tọ̀ gbáà ni wọ́n fi ń wo Bíbélì. Wọ́n kà á sí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, wọ́n gbà pé ó wúlò, ó sì ṣàǹfààní. Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé, wọn ò lè ṣe kí wọ́n má kà á. Ọ̀dọ́mọbìnrin kan tilẹ̀ kọ̀wé pé: “Lójoojúmọ́, mo máa ń sapá láti rí i pé mo ka orí kan tàbí méjì nínú Bíbélì. Àkàgbádùn ni.” Irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ ń fara balẹ̀ ronú lórí ohun tí Bíbélì fi ń kọ́ni, wọ́n sì ń gbìyànjú láti fi ìmọ̀ràn rẹ̀ sílò nínú ìgbésí ayé wọn. Wọ́n gbà pé Bíbélì lè ràn wọ́n lọ́wọ́ nínú ayé oníwàhálà táa wà yìí.
Kí lèrò rẹ? Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ Bíbélì ò ti kùtà lóde òní? Àbí ó ṣì wúlò, tó sì ṣàǹfààní? Ǹjẹ́ Bíbélì lè ràn wá lọ́wọ́ lóde òní?