Ẹ̀KỌ́ 11
Bó O Ṣe Lè Jàǹfààní Púpọ̀ Látinú Bíbélì
Ṣé o ti gba iṣẹ́ ńlá kan rí àmọ́ tó ṣòro fún ẹ láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ náà? Kí iṣẹ́ náà lè rọrùn fún ẹ, ó lè jẹ́ pé ńṣe lo pín in sọ́nà mélòó kan, tó o sì ń ṣe é díẹ̀díẹ̀. Ohun kan náà lo máa ṣe tó o bá fẹ́ ka Bíbélì. O lè bi ara ẹ pé, ‘Ibo ni mo ti máa bẹ̀rẹ̀?’ Nínú ẹ̀kọ́ yìí, a máa wo àwọn nǹkan tó o lè ṣe tó máa jẹ́ kó o gbádùn kíka Bíbélì àti kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
1. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa ka Bíbélì déédéé?
Tẹ́nì kan bá ń ka Bíbélì tàbí “òfin Jèhófà” déédéé, ó máa láyọ̀, gbogbo ohun tó bá ń ṣe á sì máa yọrí sí rere. (Ka Sáàmù 1:1-3.) Ohun tó o máa fi bẹ̀rẹ̀ ni pé kó o máa fi ìṣẹ́jú díẹ̀ ka Bíbélì lójoojúmọ́. Bí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run bá ṣe ń yé ẹ sí i, bẹ́ẹ̀ ni wàá túbọ̀ máa gbádùn kíka Bíbélì.
2. Kí ló máa jẹ́ kó o jàǹfààní látinú kíka Bíbélì?
Tá a bá fẹ́ jàǹfààní púpọ̀ látinú Bíbélì, ó yẹ ká dúró díẹ̀, ká sì ronú lórí ohun tá à ń kà. A gbọ́dọ̀ kà á, ká sì “ṣàṣàrò lórí rẹ̀.” (Jóṣúà 1:8, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé) Bó o ṣe ń ka Bíbélì, bi ara rẹ láwọn ìbéèrè bíi: ‘Kí lohun tí mò ń kà yìí kọ́ mi nípa Jèhófà Ọlọ́run? Báwo ni mo ṣe lè lò ó nígbèésí ayé mi? Báwo ni mo ṣe lè fi àwọn ẹsẹ Bíbélì yìí ran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́?’
3. Ìgbà wo lo lè rí àyè láti máa ka Bíbélì?
Ṣé ó máa ń nira fún ẹ láti ráyè ka Bíbélì? Ká sòótọ́, kì í rọrùn fún ọ̀pọ̀ lára wa. Rí i pé ò ń ‘lo àkókò rẹ lọ́nà tó dára jù lọ.’ (Éfésù 5:16) Bó o ṣe máa ṣe é ni pé wàá ya àkókò kan sọ́tọ̀ tí wàá fi máa ka Bíbélì lójoojúmọ́. Àárọ̀ kùtù làwọn kan máa ń ka Bíbélì. Ọwọ́ ọ̀sán làwọn míì máa ń kà á, bóyá nígbà oúnjẹ ọ̀sán. Àwọn kan sì máa ń ka Bíbélì ní alẹ́ kí wọ́n tó sùn. Ìgbà wo lo rò pé ó máa rọrùn fún ẹ?
KẸ́KỌ̀Ọ́ JINLẸ̀
Kọ́ bó o ṣe lè túbọ̀ gbádùn kíka Bíbélì. Wo bó o ṣe lè múra sílẹ̀ dáadáa kó o lè jàǹfààní púpọ̀ tó o bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
Bí èèyàn ṣe lè kọ́ bí wọ́n ṣe ń jẹ oríṣiríṣi oúnjẹ, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe yẹ ká kọ́ bá a ṣe lè gbádùn kíka Bíbélì
4. Kọ́ bó o ṣe lè gbádùn kíka Bíbélì
Ó lè má kọ́kọ́ rọrùn tó o bá bẹ̀rẹ̀ sí í ka Bíbélì. Àmọ́, tó bá yá, wàá rí i pé ńṣe lá máa ‘wù ẹ́ gan-an’ láti ka Bíbélì, bíi ti ẹnì kan tó lè má kọ́kọ́ fẹ́ràn oúnjẹ tuntun kan níbẹ̀rẹ̀, àmọ́ tó wá ń gbádùn oúnjẹ náà gan-an nígbà tó yá. Ka 1 Pétérù 2:2, kó o sì dáhùn ìbéèrè yìí:
Ṣé o rò pé tó o bá ń ka Bíbélì lójoojúmọ́, kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ wàá máa gbádùn ẹ̀, á sì máa wù ẹ́ kà?
Wo FÍDÍÒ yìí kó o lè mọ bí àwọn kan ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í gbádùn kíka Bíbélì. Lẹ́yìn náà, kó o dáhùn àwọn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e.
Nínú fídíò yẹn, àwọn ìṣòro wo làwọn ọ̀dọ́ yẹn borí?
Kí ló ràn wọ́n lọ́wọ́ tí wọ́n fi ń ka Bíbélì déédéé?
Kí ni wọ́n ṣe tó mú kí wọ́n túbọ̀ gbádùn kíka Bíbélì?
Ohun tó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́:
Lo Bíbélì tí èdè inú rẹ̀ bóde mu, tí ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ sì péye. A rọ̀ ẹ́ pé kó o ka Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun.
Kọ́kọ́ ka ibi tó o rò pé wàá fẹ́ràn jù lọ. Kó o lè mọ ohun tí wàá ṣe, lọ wo àtẹ náà “Máa Ka Bíbélì Lójoojúmọ́.”
Sàmì sí ibi tó o kà á dé. Lo àtẹ náà “Sàmì sí Ibi Tó O Ka Bíbélì Dé,” tó wà nínú ìwé yìí.
Lo JW Library®. Ní ibikíbi tó o bá wà, o lè ka Bíbélì, kó o sì tún gbọ́ Bíbélì tá a ti gbohùn ẹ̀ sílẹ̀ lórí JW Library tó wà lórí fóònù rẹ tàbí lórí ẹ̀rọ míì.
Wo Àfikún tó wà nínú Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun. Ó ní àwòrán ilẹ̀, àtẹ ìsọfúnni àti àlàyé ọ̀rọ̀ tó lè mú kó o túbọ̀ gbádùn ohun tó ò ń kà nínú Bíbélì.
5. Múra ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ sílẹ̀
Ka Sáàmù 119:34, kó o sì dáhùn ìbéèrè yìí:
Kí nìdí tó fi yẹ kó o gbàdúrà kó o tó ka Bíbélì tàbí tó o bá fẹ́ múra ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ sílẹ̀?
Báwo lo ṣe lè jàǹfààní tó pọ̀ gan-an látinú ìkẹ́kọ̀ọ́ kọ̀ọ̀kan? Bó o ṣe ń múra ẹ̀kọ́ kọ̀ọ̀kan inú ìwé yìí sílẹ̀, ohun tó o máa ṣe rèé:
A. Ka àwọn ìpínrọ̀ tó wà ṣáájú apá “Kẹ́kọ̀ọ́ Jinlẹ̀” nínú ẹ̀kọ́ kọ̀ọ̀kan.
B. Ka àwọn ẹsẹ Bíbélì tó wà níbẹ̀, kó o sì wo bí ohun tó wà nínú àwọn ẹsẹ Bíbélì náà ṣe kan ẹ̀kọ́ tó ò ń kọ́.
D. Sàmì sí àwọn ọ̀rọ̀ tàbí gbólóhùn pàtàkì tó dáhùn ìbéèrè kọ̀ọ̀kan; ìyẹn á ràn ẹ́ lọ́wọ́ nígbà tí ìwọ àti olùkọ́ rẹ bá ń jíròrò ẹ̀kọ́ náà.
Ǹjẹ́ o mọ̀?
Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti lo oríṣiríṣi Bíbélì. Àmọ́, èyí tá a nífẹ̀ẹ́ sí jù ni Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun nítorí pé ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ péye, ó tètè ń yéni, ó sì lo orúkọ Ọlọ́run—Wo àpilẹ̀kọ orí ìkànnì náà, “Ṣé Bíbélì Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Yàtọ̀?”
ÀWỌN KAN SỌ PÉ: “Kò rọrùn rárá láti máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Mi ò ráyè, agbára mi ò sì gbé e.”
Kí lèrò tìẹ?
KÓKÓ PÀTÀKÌ
Tó o bá fẹ́ jàǹfààní púpọ̀ látinú Bíbélì, wá àyè láti máa kà á, gbàdúrà kí ohun tó ò ń kà lè yé ẹ, kó o sì máa múra ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ sílẹ̀.
Kí lo rí kọ́?
Kí ló máa jẹ́ kó o jàǹfààní púpọ̀ látinú Bíbélì?
Ìgbà wo lo lè rí àyè ka Bíbélì kó o sì máa kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀?
Kí nìdí tó fi yẹ kó o máa múra ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ sílẹ̀?
ṢÈWÁDÌÍ
Wo àwọn nǹkan tó máa jẹ́ kó o lè jàǹfààní púpọ̀ látinú kíka Bíbélì.
“Bó O Ṣe Lè Rí Ẹ̀kọ́ Kọ́ Látinú Kíka Bíbélì” (Ilé Ìṣọ́ No. 1 2017)
Wo ohun mẹ́ta tó yẹ kó o ṣe kó o lè máa gbádùn kíka Bíbélì.
“Báwo Ni Bíbélì Ṣe Lè Ràn Mí Lọ́wọ́?—Apá Kìíní: Wo Ohun Tó Wà Nínú Bíbélì” (Àpilẹ̀kọ orí ìkànnì)
Wo bó o ṣe lè gbádùn kíka Bíbélì.
“Báwo Ni Bíbélì Ṣe Lè Ràn Mí Lọ́wọ́?—Apá Kejì: Jẹ́ Kí Bíbélì Gbádùn Mọ́ Ẹ” (Àpilẹ̀kọ orí ìkànnì)
Gbọ́ ohun táwọn tó ti ń ka Bíbélì tipẹ́ sọ nípa bó o ṣe lè kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́nà tó máa ṣe ẹ́ láǹfààní.