Ìgbàgbọ́ Lè Yí Ìgbésí Ayé Rẹ Padà
“BÉÈYÀN ò tiẹ̀ gba Ọlọ́run gbọ́, ìyẹn ò ní kó máà níwà rere.” Èrò ẹnì kan tó gbà pé Ọlọ́run ò ṣeé mọ̀ nìyẹn o. Obìnrin náà wí pé, ìwà tó dáa lòun fi tọ́ àwọn ọmọ òun dàgbà, àwọn pẹ̀lú sì ti fi irú ọ̀pá ìdiwọ̀n gíga bẹ́ẹ̀ kọ́ àwọn ọmọ tiwọn pẹ̀lú—wọ́n ṣe gbogbo èyí láìjẹ́ pé wọ́n gba Ọlọ́run gbọ́.
Ǹjẹ́ èyí túmọ̀ sí pé níní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run kò pọndandan? Dájúdájú, ẹni tí à ń wí yìí rò bẹ́ẹ̀. Òótọ́ sì ni pé kì í ṣe gbogbo ẹni tí kò gba Ọlọ́run gbọ́ lèèyàn burúkú. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣáà sọ nípa “àwọn ènìyàn orílẹ̀-èdè,” àwọn tí kò mọ Ọlọ́run, ṣùgbọ́n, ‘tí wọ́n ń ṣe àwọn ohun tí ó jẹ́ ti òfin lọ́nà ti ẹ̀dá.’ (Róòmù 2:14) Gbogbo wa pátá—títí dórí àwọn tó gbà gbọ́ pé Ọlọ́run kò ṣeé mọ̀—la bí ẹ̀rí-ọkàn mọ́. Ọ̀pọ̀ ṣe tán láti tẹ̀ lé ohun tí ẹ̀rí-ọkàn wọ́n bá sọ fún wọn bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kò gba Ọlọ́run gbọ́, ẹni tó fún wọn ní òye yẹn láti mọ ohun tó tọ́ yàtọ̀ sí ohun tí kò tọ́.
Àmọ́ ṣá o, ìgbàgbọ́ tó fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin táa ní nínú Ọlọ́run—ìyẹn ni ìgbàgbọ́ táa gbé ka Bíbélì—lágbára púpọ̀púpọ̀ láti lè sún wa hùwà rere ju bí ẹ̀rí-ọkàn tí a kì í tọ́ sọ́nà ti lè ṣe lọ. Ìgbàgbọ́ táa gbé ka Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ń dá ẹ̀rí-ọkàn lẹ́kọ̀ọ́, ó ń jẹ́ kó túbọ̀ lè mọ ohun tó tọ́ yàtọ̀ sí ohun tí kò tọ́. (Hébérù 5:14) Ìyẹn nìkan kọ́, ìgbàgbọ́ tún ń fún àwọn ènìyàn lókun láti di ọ̀pá ìdiwọ̀n gíga mú láìka wàhálà ńlá tó lè dé báni sí. Fún àpẹẹrẹ, ní ọ̀rúndún ogún yìí, ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè ni àwọn ọ̀jẹ̀lú ṣàkóso lé lórí, èyí tó mú kí àwọn ọmọlúwàbí bẹ̀rẹ̀ sí hùwà tó burú jáì, tétí ò gbọ́dọ̀ gbọ́. Àmọ́ ṣá o, àwọn tó ní ìgbàgbọ́ tòótọ́ nínú Ọlọ́run kọ̀ láti fi ìlànà tiwọn báni dọ́rẹ̀ẹ́, àní wọ́n gbà láti kúkú fẹ̀mí wọn lélẹ̀. Ní àfikún sí i, ìgbàgbọ́ táa gbé ka Bíbélì lè yí ènìyàn padà. Ó lè ra ìgbésí ayé tó dà bíi pé ó ti polúkúrúmuṣu padà, ó sì lè ranni lọ́wọ́ láti yẹra fún àwọn àṣìṣe ńlá. Gbé àwọn àpẹẹrẹ díẹ̀ yẹ̀ wò.
Ìgbàgbọ́ Lè Yí Ìgbésí Ayé Ìdílé Padà
“Ìgbàgbọ́ rẹ ti mú ọ ṣe ohun tí èèyàn rò pé kò lè ṣeé ṣe.” Ohun tí adájọ́ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì kan sọ nìyẹn nígbà tó sọ ìpinnu rẹ̀ lórí ọ̀nà tí a ó máa gbà tọ́jú àwọn ọmọ John àti Tania. Nígbà tí ọ̀ràn John àti Tania wá síwájú àwọn aláṣẹ, wọn ò tíì ṣègbéyàwó, ìgbésí ayé tí wọ́n ń gbé ní ìyẹ̀wù wọn sì bani lẹ́rù. John, tó jẹ́ ajoògùnyó, tí tẹ́tẹ́ títa sì ti wọ̀ lẹ́wù, ti di ọ̀daràn kó lè máa rówó ná sórí àwọn ìwà játijàti tó ti mọ́ ọn lára. Yálà àwọn ọmọ rẹ̀ àti màmá wọn jẹun tàbí wọn ò jẹun, ìyẹn ò kàn án. Kí wá ni “iṣẹ́ ìyanu” tó ṣẹlẹ̀?
Lọ́jọ́ kan John gbọ́ tí ọmọ ẹ̀gbọ́n rẹ̀ kan ń sọ̀rọ̀ nípa Párádísè. Ọ̀rọ̀ ọ̀hún wọ̀ ọ́ lọ́kàn, ló bá da ìbéèrè bo àwọn òbí ọmọ náà. Ẹlẹ́rìí Jèhófà làwọn òbí ọmọ ọ̀hún, ni wọ́n bá ran John lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa rẹ̀ látinú Bíbélì. Bí eré bí àwàdà, John àti Tania nígbàgbọ́ táa gbé ka Bíbélì, èyí sì yí ìgbésí ayé wọn padà. Wọ́n lọ ṣe ìgbéyàwó wọn lábẹ́ òfin, wọ́n sì borí gbogbo ìkùdíẹ̀-káàtó wọn. Àwọn aláṣẹ tó wá fimú fínlẹ̀ láti mọ kí ló ń ṣẹlẹ̀ lágboolé wọn rí ohun tó dà bíi pé kò lè ṣeé ṣe rárá lákòókò díẹ̀ ṣáájú ìgbà yẹn—ìyẹn ni ìdílé aláyọ̀ tó ń gbé nínú ilé tó mọ́ tónítóní, ilé tó dáa láti tọ́ ọ́mọ dàgbà. Abájọ tí adájọ́ náà fi sọ pé ìgbàgbọ́ tuntun tí John àti Tania ṣẹ̀ṣẹ̀ gbà ló ṣe “iṣẹ́ ìyanu” yìí.
Ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún kìlómítà sí England, ọ̀ṣọ́ọ́rọ́ adélébọ̀ kan tó ń gbé ọ̀kan nínú àwọn Orílẹ̀-Èdè Ìtòsí Ìlà Oòrùn ayé ti fẹ́rẹ̀ẹ́ di ọ̀kan lára àwọn tí ìbànújẹ́ ti dorí wọn kodò. Ó ti ń ṣètò bí yóò ṣe di ọ̀kan lára àwọn àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn tí ìgbéyàwó wọn ń yọrí sí ìkọ̀sílẹ̀ lọ́dọọdún. Ọmọ kan ṣoṣo ló bí, ṣùgbọ́n, ọkọ rẹ̀ jù ú lọ dáadáa. Èyí làwọn ẹbí rẹ̀ rinkinkin mọ́, ní wọ́n bá ń rọ̀ ọ́ pé kó lọ jáwèé fọ́kọ ẹ̀, òun náà sì ti ń ṣètò àtiṣe bẹ́ẹ̀. Ṣùgbọ́n, ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń bá a ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Nígbà tí Ẹlẹ́rìí náà gbọ́ nípa ohun tó ń ṣẹlẹ̀, ó ṣàlàyé ohun tí Bíbélì sọ nípa ìgbéyàwó fún un—fún àpẹẹrẹ, ó ní ìgbéyàwó jẹ́ ẹ̀bùn láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, kì í ṣe ohun kan táa kàn lè gbé jù nù bẹ́ẹ̀. (Mátíù 19:4-6, 9) Obìnrin náà wá ronú pé, ‘Ó yà mí lẹ́nu pé, obìnrin yìí, tí kò bá mi tan rárá, ló fẹ́ yọ ìdílé wa nínú ewu, nígbà tí àwọn ìbátan mi gan-an ń fẹ́ kí gbogbo nǹkan dàrú.’ Ìgbàgbọ́ tuntun tó ṣẹ̀ṣẹ̀ gbà ló ràn án lọ́wọ́ tí kò jẹ́ kí ìgbéyàwó rẹ̀ forí ṣánpọ́n.
Ohun mìíràn tó ti jẹ́ kí ìbànújẹ́ dorí ọ̀pọ̀ kodò ni oyún ṣíṣẹ́. Ìsọfúnni látọ̀dọ̀ àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè fojú bù ú pé lọ́dọọdún, ó kéré tán, mílíọ̀nù márùn-ún lé lógójì àwọn ọmọ tí a kò bí ni à ń mọ̀ọ́mọ̀ ṣẹ́ oyún wọn dà nù. Irú ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn máa ń bani nínú jẹ́ gan-an. Ìmọ̀ Bíbélì ran obìnrin kan tó ń gbé ní ilẹ̀ Philippines lọ́wọ́, kò jẹ́ kó wà lára àwọn tí ìbànújẹ́ dorí wọn kodò.
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà dé ọ̀dọ̀ obìnrin náà, ó gba ìwé pẹlẹbẹ kan táa fi ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, orúkọ ìwé náà ni, Kí Ni Ọlọrun Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa?a ó sì bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Oṣù díẹ̀ lẹ́yìn náà, ó ṣàlàyé ohun tó fà á tí òun fi gbà láti kẹ́kọ̀ọ́. Obìnrin náà ti lóyún nígbà tí àwọn Ẹlẹ́rìí kọ́kọ́ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, ṣùgbọ́n òun àti ọkọ rẹ̀ ti gbà láti ṣẹ́ oyún yìí. Ṣùgbọ́n, àwòrán ọmọ tí a kò tíì bí tó wà lójú ewé kẹrìnlélógún ìwé pẹlẹbẹ náà gún ọkàn obìnrin náà ní kẹ́ṣẹ́. Àlàyé táa gbé ka Bíbélì tó wà lójú ewé náà pé ìwàláàyè jẹ́ ohun tó yẹ ká bọ̀wọ̀ fún nítorí pé ‘ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni orísun ìyè wà,’ sún un láti máà ṣẹ́ oyún náà. (Sáàmù 36:9) Ní báyìí, ó ti di ìyá ọmọ làǹtì-lanti kan, ọmọ tó rẹwà.
Ìgbàgbọ́ Ń Ṣèrànwọ́ fún Àwọn Táwọn Kan Ò Kà Sí
Ni Etiópíà, ìpàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń lọ lọ́wọ́, làwọn ọkùnrin méjì kan tí wọn ò múra dáadáa bá wọlé. Nígbà tí ìpàdé náà parí, ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí lọ bá wọn, ó sì kí wọn tọ̀yàyàtọ̀yàyà. Àwọn ọkùnrin náà ní kí wọ́n bá wọn wá nǹkan. Ẹlẹ́rìí náà kò fún wọn lówó, ohun mìíràn tó ju owó lọ ló fún wọn. Ó rọ̀ wọ́n láti nígbàgbọ́ nínú Ọlọ́run, èyí tó jẹ́ pé “ó níye lórí púpọ̀púpọ̀ ju wúrà.” (1 Pétérù 1:7) Ọ̀kan lára wọn fara balẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Èyí ló yí ìgbésí ayé rẹ̀ padà. Bí ìgbàgbọ́ rẹ̀ ti ń pọ̀ sí i, ló bá jáwọ́ nínú sìgá mímu, kò mu ọtí àmujù mọ́, ó pa ìṣekúṣe tì, kò sì fín tábà mọ́. Ó wá kọ́ bó ṣe lè máa gbọ́ bùkátà ara rẹ̀, ó ti wá ń gbé ìgbésí ayé mímọ́, tó nítumọ̀ báyìí.
Ní Ítálì, ọkùnrin ẹni ọdún mẹ́tàdínláàádọ́ta kan wà níbẹ̀ tí wọ́n ti rán lẹ́wọ̀n ọdún mẹ́wàá, tó sì wà ní àhámọ́ ilé ìwòsàn àrùn ọpọlọ tó jẹ́ ti àwọn ẹlẹ́wọ̀n. Ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó láṣẹ láti wọnú ọgbà ẹ̀wọ̀n, kó sì ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ nípa tẹ̀mí, bá a ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ọkùnrin yìí tẹ̀ síwájú kíákíá. Ìgbàgbọ́ yí ìgbésí ayé rẹ̀ padà tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn ẹlẹ́wọ̀n yòókù fi máa ń wá gbàmọ̀ràn lọ́dọ̀ rẹ̀ lórí bí wọ́n ṣe lè yanjú ìṣòro wọn. Ìgbàgbọ́ rẹ̀ tó gbé ka Bíbélì ti sọ ọ́ di ẹni tí àwọn aláṣẹ ọgbà ẹ̀wọ̀n náà bọ̀wọ̀ fún, tí wọ́n ń buyì fún, tí wọ́n sì fọkàn tán.
Láwọn ọdún àìpẹ́ yìí, ọ̀pọ̀ ìròyìn làwọn ìwé ìròyìn ti gbé jáde nípa ogun abẹ́lé tó ń jà ní Áfíríkà. Èyí tó kó jìnnìjìnnì báni jù lọ ni ìròyìn nípa àwọn ọ̀dọ́mọdé tí wọ́n ń kọ́ níṣẹ́ sójà. Wọ́n á rọ àwọn ọmọdé wọ̀nyí lóògùn yó, wọ́n á sọ wọ́n di ẹni tí ẹ̀mí èèyàn ò jọ lójú mọ́, wọ́n á wá fipá mú wọn láti máa hùwà ìkà tó burú jáì sáwọn mọ̀lẹ́bí wọn, kí wọ́n lè fi hàn pé àwọn wà lẹ́yìn ẹgbẹ́ tí wọ́n ń jà fún. Ǹjẹ́ ìgbàgbọ́ táa gbé ka Bíbélì lágbára láti yí ìgbésí ayé irú àwọn ògowẹẹrẹ bẹ́ẹ̀ padà? Ó kéré tán, nínú ọ̀ràn ẹni méjì, ó rí bẹ́ẹ̀.
Ní Liberia, Alex ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ọmọ àlùfáà ní Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì. Àmọ́, ọmọ ọdún mẹ́tàlá ni nígbà tó di ọmọ ẹgbẹ́ ajàjàgbara kan, tó sì di sójà kékeré, tó burú jèpè lọ. Kí àyà rẹ̀ lè ki lójú ogun, ló bá wọnú ẹgbẹ́ àjẹ́. Alex fojú ara rẹ̀ rí bí wọ́n ṣe pa ọ̀pọ̀ lára ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, àmọ́ mìmì kan ò mì í. Lọ́dún 1997, ó pàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó sì ṣàkíyèsí pé wọn o tàbùkù òun. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni wọ́n ràn án lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ ohun tí Bíbélì sọ nípa ìwà ipá. Ní Alex bá fiṣẹ́ sójà sílẹ̀. Bí ìgbàgbọ́ rẹ̀ ti ń pọ̀ sí i, ó pa àṣẹ Bíbélì mọ́, èyí tó sọ pé: “Kí ó yí padà kúrò nínú ohun búburú, kí ó sì máa ṣe ohun rere; kí ó máa wá àlàáfíà, kí ó sì máa lépa rẹ̀.”—1 Pétérù 3:11.
Láàárín àkókò yẹn, sójà kékeré nígbà kan rí tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Samson wá sí ìlú tí Alex ń gbé. Òun pẹ̀lú wà nínú ẹgbẹ́ akọrin ṣọ́ọ̀ṣì tẹ́lẹ̀ rí, àmọ́ ọdún 1993 ló di sójà, ló bá tibẹ̀ di ajoògùnyó, ó di abẹ́mìílò, ó sì di oníṣekúṣe. Lọ́dún 1997, wọ́n dá a dúró lẹ́nu iṣẹ́ ológun. Monrovia ni Samson ń lọ, níbi tó ti fẹ́ lọ wọṣẹ́ àwọn àkànṣe ẹ̀ṣọ́ nígbà tí ọ̀rẹ́ rẹ̀ kan rọ̀ ọ́ pé kó kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, kí la máa rí, ló bá di ẹni tó nígbàgbọ́ táa gbé ka Bíbélì. Èyí ló ki í láyà láti pa gbogbo ìgbésí ayé arógunyọ̀ tó ti ń gbé tì. Alex àti Samson ń gbé ìgbésí ayé alálàáfíà báyìí, wọn ò sì lọ́wọ́ nínú ìwà játijàti mọ́. Ǹjẹ́ ohun mìíràn tún wà tó lè yí ìgbésí ayé tó ti bà jẹ́ bẹ́ẹ̀ padà yàtọ̀ sí ìgbàgbọ́ táa gbé ka Bíbélì?
Irú Ìgbàgbọ́ Tí À Ń Fẹ́
Ìwọ̀nba díẹ̀ nìwọ̀nyí nínú ọ̀pọ̀ lára àwọn àpẹẹrẹ tó fi hàn pé agbára tí ojúlówó ìgbàgbọ́ táa gbé ka Bíbélì ní pọ̀ gidigidi. Àmọ́ ṣá o, kì í ṣe gbogbo ẹni tó bá ṣáà ti sọ pé òun gba Ọlọ́run gbọ́ ló ń tẹ̀ lé ìlànà gíga tó wà nínú Bíbélì. Ká sòótọ́, àwọn kan tí ò gbà pé Ọlọ́run ń bẹ tiẹ̀ ń gbé ìgbésí ayé tó dáa ju tí àwọn míì tí wọ́n pera wọn ní Kristẹni. Ìdí ni pé ohun tó wà nínú ìgbàgbọ́ táa gbé ka Bíbélì ju pé kí èèyàn ṣáà gbà pé Ọlọ́run ń bẹ.
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù pe ìgbàgbọ́ ní “ìfojúsọ́nà tí ó dáni lójú nípa àwọn ohun tí a ń retí, ìfihàn gbangba-gbàǹgbà àwọn ohun gidi bí a kò tilẹ̀ rí wọn.” (Hébérù 11:1) Nítorí náà, ohun tó tún wé mọ́ ìgbàgbọ́ ni pé kí nǹkan tí èèyàn ò fojú rí dáni lójú dáadáa nítorí ẹ̀rí tí kò ṣeé já ní koro tó wà lọ́wọ́ ẹni. Pàápàá jù lọ irú ìgbàgbọ́ yìí wé mọ́ gbígbà láìṣiyèméjì kankan pé Ọlọ́run ń bẹ, pé ó fẹ́ràn wa, àti pé yóò bù kún gbogbo àwọn tó bá ṣe ìfẹ́ rẹ̀. Àpọ́sítélì náà wí pé: “Ẹni tí ó bá ń tọ Ọlọ́run wá gbọ́dọ̀ gbà gbọ́ pé ó ń bẹ àti pé òun ni olùsẹ̀san fún àwọn tí ń fi taratara wá a.”—Hébérù 11:6.
Irú ìgbàgbọ́ yìí ló yí ìgbésí ayé John, Tania, àti àwọn mìíràn táa sọ̀rọ̀ wọn nínú àpilẹ̀kọ yìí padà. Ó sún wọn láti ní ìgbọ́kànlé kíkún nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, Bíbélì, ó jẹ́ kó máa darí wọn láti ṣe ìpinnu. Ó ràn wọ́n lọ́wọ́ láti fi àwọn nǹkan kan rúbọ fúngbà díẹ̀, kí wọ́n má bàá lọ máa ṣe ohun tó rọ̀ wọ́n lọ́rùn, ṣùgbọ́n tó jẹ́ pé kò tọ́. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ìrírí wọ̀nyí yàtọ̀ síra, bákan náà ni gbogbo wọn ṣe bẹ̀rẹ̀. Ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló bá gbogbo wọn ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, wọ́n sì wà rí i pé òótọ́ ni ohun tí Bíbélì sọ pé: “Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yè, ó sì ń sa agbára.” (Hébérù 4:12) Agbára Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ló ran ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn lọ́wọ́ láti ní ìgbàgbọ́ tó lágbára tó yí ìgbésí ayé wọn padà sí rere.
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń báṣẹ́ wọn lọ ní ilẹ̀ tó ju igba ó lé ọgbọ̀n àti àwọn erékùṣù òkun. Wọ́n rọ̀ ọ́ láti wá kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Nítorí kí ni? Nítorí tó dá wọn lójú gbangba-gbàǹgbà pé, ìgbàgbọ́ táa gbé ka Bíbélì lè mú ìyípadà tó kàmàmà wá sínú ìgbésí ayé ìwọ náà.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., ló tẹ̀ ẹ́ jáde.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 3]
Ìgbàgbọ́ táa gbé ka Bíbélì ń yí ìgbésí ayé ẹni padà sí rere
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 2]
Ẹ̀yìn ìwé náà, Biblia nieświeska láti ọwọ́ Szymon Budny, 1572