Rírí Ààbò Nínú Ayé Eléwu
RÍRÌN nínú pápá tí wọ́n ri àwọn ohun abúgbàù sí kò yàtọ̀ sí rírìn ní bèbè ikú. Ṣùgbọ́n o, ǹjẹ́ kò ní sàn jù, ká ní o ní àwòrán kan lọ́wọ́ tó ń tọ́ka rẹ sí ibi táwọn ohun abúgbàù náà wà? Síwájú sí i, ká sọ pé o ti gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́ lórí dídá onírúurú ohun abúgbàù mọ̀. Dájúdájú, irú òye yẹn yóò dín ewu dídi abirùn kù gidigidi tàbí ewu kíkú.
A lè fi Bíbélì wé àwòrán yẹn àti ìdánilẹ́kọ̀ọ́ téèyàn gbà lórí dídá ohun abúgbàù mọ̀. Bíbélì ní ọgbọ́n tó tayọ nínú, tó bá dọ̀ràn yíyẹra fún ewu àti wíwá ojútùú sáwọn ìṣòro tí ń dìde nínú ìgbésí ayé.
Ẹ gbọ́ ìlérí tí ń fini lọ́kàn balẹ̀ yìí nínú ìwé Òwe 2:10, 11, tó kà pé: “Nígbà tí ọgbọ́n bá wọnú ọkàn-àyà rẹ, tí ìmọ̀ sì dùn mọ́ ọkàn rẹ pàápàá, agbára láti ronú yóò máa ṣọ́ ọ, ìfòyemọ̀ yóò máa fi ìṣọ́ ṣọ́ ọ.” Ọgbọ́n àti ìfòyemọ̀ táa ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí kò tọ̀dọ̀ ènìyàn wá bí kò ṣe látọ̀dọ̀ Ọlọ́run. “Ní ti ẹni tí ń fetí sí [ọgbọ́n látọ̀dọ̀ Ọlọ́run], yóò máa gbé nínú ààbò, yóò sì wà láìní ìyọlẹ́nu lọ́wọ́ ìbẹ̀rùbojo ìyọnu àjálù.” (Òwe 1:33) Ẹ jẹ́ ká wo bí Bíbélì ṣe lè fi kún ààbò wa, kí ó sì ràn wá lọ́wọ́ láti yẹra fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìṣòro.
Yíyẹra fún Àwọn Jàǹbá Gbẹ̀mígbẹ̀mí
Kúlẹ̀kúlẹ̀ àlàyé tí Àjọ Ìlera Àgbáyé (WHO) fi ìṣirò gbé jáde lẹ́nu àìpẹ́ yìí fi hàn pé iye àwọn tí jàǹbá ọkọ̀ ń pa lọ́dọọdún kárí ayé jẹ́ nǹkan bí ọ̀kẹ́ méjìdínlọ́gọ́ta ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbàáfà [1,171,000]. Iye tó sì fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ogójì mílíọ̀nù àwọn mìíràn ló ń fara pa, àwọn tí jàǹbá wọ̀nyí sì ń sọ di aláàbọ̀ ara lé díẹ̀ ní mílíọ̀nù mẹ́jọ.
Bó tiẹ̀ jẹ́ pé wíwà láìséwu rárá nígbà téèyàn bá ń wakọ̀ kò ṣeé ṣe, síbẹ̀ ọ̀pọ̀ ọ̀nà la lè gba fi kún ààbò tara wa nípa pípa àwọn òfin ìrìnnà mọ́. Nígbà tí Bíbélì ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn aláṣẹ tí ń ṣe òfin ìrìnnà, tí wọ́n sì ń mú un ṣẹ, ó sọ pé: “Kí olúkúlùkù ọkàn wà lábẹ́ àwọn aláṣẹ onípò gíga.” (Róòmù 13:1) Àwọn awakọ̀ tí ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn yìí ń dín jàǹbá ọkọ àti onírúurú àgbákò tó ń tìdí ẹ̀ yọ kù.
Nǹkan míì tó tún ń jẹ́ kéèyàn máa fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ wakọ̀ ni ọ̀wọ̀ fún ìwàláàyè. Bíbélì sọ nípa Jèhófà Ọlọ́run pé: “Nítorí pé ọ̀dọ̀ rẹ ni orísun ìyè wà.” (Sáàmù 36:9) Èyí fi hàn pé ìwàláàyè jẹ́ ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Nítorí náà, a ò lẹ́tọ̀ọ́ láti fi ẹ̀bùn yẹn du ẹnikẹ́ni tàbí láti fọwọ́ yẹpẹrẹ mú ẹ̀mí, títí kan tiwa fúnra wa.—Jẹ́nẹ́sísì 9:5, 6.
Láìṣẹ̀ṣẹ̀ máa sọ, ọ̀wọ̀ fún ẹ̀mí ènìyàn wé mọ́ rírí i dájú pé ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ àti ilé wa ní ètò ààbò tó jọjú. Ní Ísírẹ́lì ìgbàanì, ààbò ṣe kókó nínú gbogbo ọ̀ràn ìgbésí ayé. Fún àpẹẹrẹ, nígbà tí wọ́n bá kọ́lé, Òfin Ọlọ́run sọ pé kí òrùlé ní ìgbátí, nítorí pé ibẹ̀ ni ìdílé wọ́n ti ń ṣe ọ̀pọ̀ nǹkan. “Kí o ṣe ìgbátí sí òrùlé rẹ, kí ìwọ má bàa fi ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ sórí ilé rẹ nítorí pé ẹnì kan . . . lè já bọ́ láti orí rẹ̀.” (Diutarónómì 22:8) Bí ẹnì kan bá já bọ́ nítorí pé onílé ò pa òfin yìí mọ́, onílé ọ̀hún yóò jíhìn fún Ọlọ́run. Láìsí àní-àní, lílo ìlànà onífẹ̀ẹ́ tí ń bẹ nínú òfin yìí yóò dín jàǹbá kù níbi iṣẹ́ tàbí níbi eré ìnàjú pàápàá.
Gbígbógunti Àwọn Àṣà Aṣekúpani
Gẹ́gẹ́ bí Àjọ Ìlera Àgbáyé ti wí, àwọn tó ń mu sìgá lágbàáyé báyìí ti lé ní bílíọ̀nù kan, nǹkan bí mílíọ̀nù mẹ́rin èèyàn ni sìgá sì ń ṣekú pa lọ́dọọdún. Wọ́n ń retí pé iye yẹn á fẹ́rẹ̀ẹ́ tó mílíọ̀nù mẹ́wàá ní nǹkan bí ogún sí ọgbọ̀n ọdún sígbà táa wà yìí. Yàtọ̀ sáwọn tó ń kú yìí, ẹgbàágbèje àwọn amusìgá yòókù, àtàwọn tí ń fi àwọn oògùn líle “ṣe fàájì” yóò sọ ara wọn di olókùnrùn, wọn yóò sì bayé ara wọn jẹ́ nítorí àṣàkaṣà wọ̀nyí.
Òótọ́ ni pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kò dìídì mẹ́nu kan sìgá mímu àti ìjoògùnyó, ṣùgbọ́n àwọn ìlànà inú rẹ̀ lè dáàbò bò wá lọ́wọ́ àṣàkaṣà wọ̀nyí. Fún àpẹẹrẹ, Kọ́ríńtì Kejì orí keje, ẹsẹ kìíní, gbà wá nímọ̀ràn pé: “Ẹ jẹ́ kí a wẹ ara wa mọ́ kúrò nínú gbogbo ẹ̀gbin ti ẹran ara àti ti ẹ̀mí.” Kò sí tàbí-ṣùgbọ́n nípa bóyá sìgá àtàwọn oògùn líle ní ọ̀pọ̀ èròjà olóró tí ń ba ara jẹ́, tàbí tí ń sọ ara di ẹlẹ́gbin. Bẹ́ẹ̀, Ọlọ́run ń fẹ́ kí ara wa jẹ́ “mímọ́,” láìní èérí àti àbùkù. (Róòmù 12:1) Ǹjẹ́ o ò gbà pé títẹ̀lé ìlànà wọ̀nyí yóò dín ọ̀pọ̀ ohun tí ń fẹ̀mí ẹni wewu kù?
Ṣíṣẹ́pá Àwọn Àṣà Eléwu
Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti ya aláṣejù nínú ọ̀ràn jíjẹ àti mímu. Ara àwọn ohun tí àjẹjù sì ń fà ni àtọ̀gbẹ, àrùn jẹjẹrẹ, àti àrùn ọkàn. Ọtí àmujù tún ń fa àwọn ìṣòro míì, ó ń sọni di òkú ọ̀mùtí, ó ń fa ìsúnkì ẹ̀dọ̀, ó ń da ìdílé rú, ó sì ń fa jàǹbá ọkọ̀. Ní òdìkejì ẹ̀wẹ̀, àwọn tí ń yan oúnjẹ lódì lè ṣe ara wọn léṣe, kí wọ́n sì wá fẹ̀mí ara wọn sínú ewu àìjẹunkánú nítorí ìbẹ̀rù sísanra.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì kì í ṣe ìwé nípa ìṣègùn, síbẹ̀ ó ń fúnni ní ìmọ̀ràn tó sọjú abẹ níkòó nípa ìjẹ́pàtàkì jíjẹ àti mímu níwọ̀nba. “Ìwọ, ọmọ mi, gbọ́, kí o sì di ọlọ́gbọ́n, kí o sì máa ṣamọ̀nà ọkàn-àyà rẹ nìṣó ní ọ̀nà. Má ṣe wá wà lára àwọn tí ń mu wáìnì ní àmuyó kẹ́ri, lára àwọn tí ń jẹ ẹran ní àjẹkì. Nítorí ọ̀mùtípara àti alájẹkì yóò di òtòṣì.” (Òwe 23:19-21) Síbẹ̀, Bíbélì sọ pé ó yẹ kí ọ̀ràn jíjẹ àti mímu gbádùn mọ́ni. “Kí olúkúlùkù ènìyàn máa jẹ, kí ó sì máa mu ní tòótọ́, kí ó sì rí ohun rere nítorí gbogbo iṣẹ́ àṣekára rẹ̀. Ẹ̀bùn Ọlọ́run ni.”—Oníwàásù 3:13.
Bíbélì tún rọ̀ wá pé ká wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì nínú eré ìmárale, ó sọ pé “ara títọ́ ṣàǹfààní fún ohun díẹ̀.” Ṣùgbọ́n ó tún jẹ́ kó yé wa pé: “Fífọkànsin Ọlọ́run ṣàǹfààní fún ohun gbogbo, bí ó ti ní ìlérí ìyè ti ìsinsìnyí àti ti èyí tí ń bọ̀.” (1 Tímótì 4:8) O lè béèrè pé, ‘Báwo ni fífọkànsin Ọlọ́run ṣe ṣàǹfààní nísinsìnyí?’ Àǹfààní ẹ̀ pọ̀. Yàtọ̀ sí pé fífọkànsin Ọlọ́run ń fi ohun pàtàkì nípa tẹ̀mí kún ìgbésí ayé ẹni, ó tún ń mú kí àwọn ànímọ́ rere gbèrú, irú bí ìfẹ́, ìdùnnú, àlàáfíà, àti ìkóra-ẹni-níjàánu, gbogbo ànímọ́ wọ̀nyí ló sì ń jẹ́ kéèyàn ní ẹ̀mí rere àti ìlera.—Gálátíà 5:22, 23.
Àwọn Aburú Tí Ìṣekúṣe Ń Fà
Lónìí, ìwà rere ti ń kẹ́rù sọ́kọ̀. Ara ohun tó sì ń tìdí ẹ̀ yọ ni àjàkálẹ̀ àrùn éèdì. Gẹ́gẹ́ bí Àjọ Ìlera Àgbáyé ti wí, ó ti lé ní mílíọ̀nù mẹ́rìndínlógún èèyàn tó ti kú látìgbà tí àrùn éèdì ti bẹ̀rẹ̀ sí jà ràn-ìn. Níbi tó sì ti dé báyìí, nǹkan bíi mílíọ̀nù mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n èèyàn ni fáírọ́ọ̀sì tí ń fa àrùn éèdì ti ràn. Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn tí àrùn éèdì ń bá fínra ló kó o nítorí ìṣekúṣe tí wọ́n ń ṣe kiri, tàbí torí pé wọ́n lo abẹ́rẹ́ táwọn ajoògùnyó ti kó èèràn ràn, tàbí torí pé wọ́n gba ẹ̀jẹ̀ tó ní àrùn náà sára.
Àwọn aburú míì tí ìwà pálapàla ń fà ni àrùn ìléròrò ẹ̀yà ìbímọ, àtọ̀sí, àrùn mẹ́dọ̀wú, àti àrùn rẹ́kórẹ́kó. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn tí ń gbé ayé ní àkókò táa kọ Bíbélì kò lo irú orúkọ wọ̀nyẹn, síbẹ̀ láyé ìgbà yẹn, wọ́n mọ àwọn ẹ̀yà ara tí a sábà máa ń kó èèràn ràn nípasẹ̀ àwọn àrùn tí ìbálòpọ̀ ń kó ranni. Bí àpẹẹrẹ, ìwé Òwe 7:23 ṣàpèjúwe ohun búburú tó ń tìdí àgbèrè jáde, ó ní ó dà bí ìgbà tí ‘ọfà la ẹ̀dọ̀ sọ́tọ̀ọ̀tọ̀.’ Ẹ̀dọ̀ ni àrùn rẹ́kórẹ́kó àti àrùn mẹ́dọ̀wú sábà máa ń gbógun tì. Ẹ ò rí bí ìmọ̀ràn Bíbélì ti bọ́ sákòókò, tó sì jẹ́ ti onífẹ̀ẹ́ tó, pé kí Kristẹni ‘ta kété sí ẹ̀jẹ̀ àti sí àgbèrè’!—Ìṣe 15:28, 29.
Ìdẹkùn Ìfẹ́ Owó
Nítorí àtidolówó ọ̀sán gangan, ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń kó owó wọn dà sórí òwò tí kò láyọ̀lé. Ó mà ṣe o, ìfowóṣòfò tàbí ìfowójóná ló sábà máa ń yọrí sí. Àmọ́, Bíbélì sọ fún ìránṣẹ́ Ọlọ́run pé: “Kí ó máa ṣe iṣẹ́ àṣekára, kí ó máa fi ọwọ́ rẹ̀ ṣe ohun tí ó jẹ́ iṣẹ́ rere, kí ó lè ní nǹkan láti pín fún ẹni tí ó wà nínú àìní.” (Éfésù 4:28) Òótọ́ ni pé ẹni tí ń ṣiṣẹ́ kára kì í sábà di olówó rẹpẹtẹ. Ṣùgbọ́n, ó máa ń ní ìbàlẹ̀ ọkàn, iyì, bóyá kó tilẹ̀ tún ní owó tó lè fi ti iṣẹ́ rere lẹ́yìn.
Bíbélì kìlọ̀ pé: “Àwọn tí ó pinnu láti di ọlọ́rọ̀ máa ń ṣubú sínú ìdẹwò àti ìdẹkùn àti ọ̀pọ̀ ìfẹ́-ọkàn tí í ṣe ti òpònú, tí ó sì ń ṣeni lọ́ṣẹ́, èyí tí ń ri ènìyàn sínú ìparun àti ègbé. Nítorí ìfẹ́ owó ni gbòǹgbò onírúurú ohun aṣeniléṣe gbogbo, àti nípa nínàgà fún ìfẹ́ yìí, . . . àwọn kan . . . ti fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìrora gún ara wọn káàkiri.” (1 Tímótì 6:9, 10) Kò sírọ́ ńbẹ̀ pé ọ̀pọ̀ “àwọn tí ó pinnu láti di ọlọ́rọ̀” ló ń dọlọ́rọ̀ lóòótọ́. Àmọ́ kí wọ́n tó dà á ńkọ́? Ṣé kì í ṣe òótọ́ ni pé wọn kì í ráyè bójú tó ìlera wọn, ẹbí wọn, àti ipò tẹ̀mí wọn, tí wọn kì í sì í rí oorun sùn?—Oníwàásù 5:12.
Ẹni tó bá gbọ́n á mọ̀ pé ‘ìwàláàyè kò wá láti inú àwọn ohun téèyàn ní.’ (Lúùkù 12:15) Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo àwùjọ ni owó àtàwọn dúkìá kan ti jẹ́ ohun kòṣeémánìí. Òótọ́ sì ni Bíbélì sọ pé “owó . . . jẹ́ fún ìdáàbòbò,” ṣùgbọ́n ó fi kún un pé “àǹfààní ìmọ̀ ni pé ọgbọ́n máa ń pa àwọn tí ó ni ín mọ́ láàyè.” (Oníwàásù 7:12) Láìdàbí owó, ìmọ̀ títọ́ àti ọgbọ́n lè ràn wá lọ́wọ́ nínú gbogbo ipò táa bá wà, àgàgà nínú àwọn ọ̀ràn tó kan ìwàláàyè wa.—Òwe 4:5-9.
Ìgbà Tí Ọgbọ́n Nìkan Ṣoṣo Máa Dáàbò Bò Wá
Láìpẹ́, ọgbọ́n tòótọ́ yóò “pa àwọn tí ó ni ín mọ́ láàyè” lọ́nà tí a ò rírú ẹ̀ rí—yóò dáàbò bò wọ́n la “ìpọ́njú ńlá” tó kù sí dẹ̀dẹ̀ já, nígbà tí Ọlọ́run yóò pa àwọn olubi run. (Mátíù 24:21) Bíbélì sọ pé tó bá dìgbà yẹn, ńṣe làwọn èèyàn á kó owó wọn dà sójú pópó, á di “ohun ìkórìíra tẹ̀gàntẹ̀gàn.” Èé ṣe? Nítorí pé wọ́n á ti kan ìdin nínú iyọ̀ kí wọ́n tó mọ̀ pé wúrà àti fàdákà kò lè ra ẹ̀mí wọn padà “ní ọjọ́ ìbínú kíkan ti Jèhófà.” (Ìsíkíẹ́lì 7:19) Bẹ́ẹ̀ sì rèé, “ogunlọ́gọ̀ ńlá,” tó ti fọgbọ́n ‘to ìṣúra wọn pa mọ́ sí ọ̀run’ nípa fífi ire tẹ̀mí sí ipò kìíní nínú ìgbésí ayé wọn, yóò jàǹfààní nínú iṣẹ́ àṣejèrè tí wọ́n ṣe, wọn óò sì jèrè ìyè ayérayé nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé.—Ìṣípayá 7:9, 14; 21:3, 4; Mátíù 6:19, 20.
Báwo ni ọwọ́ wa ṣe lè tẹ ọjọ́ iwájú aláàbò yìí? Jésù dáhùn, ó ní: “Èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun, gbígbà tí wọ́n bá ń gba ìmọ̀ ìwọ, Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà sínú, àti ti ẹni tí ìwọ rán jáde, Jésù Kristi.” (Jòhánù 17:3) Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn ló ti rí ìmọ̀ yìí nínú Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Kì í ṣe kìkì pé àwọn wọ̀nyí ní ìrètí àgbàyanu tó wà lọ́jọ́ ọ̀la nìkan ni, àní wọ́n tún ní ìbàlẹ̀ ọkàn àti ààbò nísinsìnyí. Bí onísáàmù náà ṣe sọ ọ́ gẹ́lẹ́ ló rí, ó ní: “Àlàáfíà ni èmi yóò dùbúlẹ̀, tí èmi yóò sì sùn, nítorí pé ìwọ tìkára rẹ, Jèhófà, nìkan ṣoṣo ni ó mú kí n máa gbé nínú ààbò.”—Sáàmù 4:8.
Ǹjẹ́ o lè ronú kan orísun ìsọfúnni míì tó lè dáàbò bo ìlera àti ẹ̀mí rẹ, gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ti ṣe? Kò sí ìwé míì tó ní ọlá àṣẹ tí Bíbélì ní, kò sì sí ìwé míì tó lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti rí ààbò tòótọ́ nínú ayé eléwu yìí. O ò ṣe fara balẹ̀ yẹ̀ ẹ́ wò?
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]
Ara Líle àti Ààbò—Ọpẹ́lọpẹ́ Bíbélì
Ọ̀dọ́bìnrin kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Janea bẹ̀rẹ̀ sí mu igbó, sìgá, kokéènì, àwọn oògùn amóríyá náà, amphetamine àti LSD, àtàwọn oògùn líle mìíràn, kí ó lè bọ́ lọ́wọ́ gbogbo ìṣòro ìgbésí ayé. Ó tún ń mu àmupara ọtí. Gẹ́gẹ́ bí Jane ti wí, ọ̀kan-ùn-kan-ùn lòun àti ọkọ rẹ̀. Ayé wọn ò lójú rárá. Láìpẹ́ lẹ́yìn náà ni Jane wá pàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ó bẹ̀rẹ̀ sí wá sáwọn ìpàdé Kristẹni, ó sì ń ka Ilé Ìṣọ́ àti èkejì rẹ̀, ìwé ìròyìn Jí!, ó sì ń fún ọkọ rẹ̀ kà pẹ̀lú. Bí àwọn méjèèjì ṣe bẹ̀rẹ̀ sì kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí nìyẹn. Nígbà tí wọ́n wá mọyì ọ̀pá ìdiwọ̀n gíga Jèhófà, wọ́n jáwọ́ nínú gbogbo nǹkan tí wọ́n ti sọ di bárakú. Kí ni ìyọrísí rẹ̀? Jane kọ̀wé ní ọdún mélòó kan lẹ́yìn náà pé: “Ìgbésí ayé wa tuntun ti fún wa láyọ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀. Mo dúpẹ́ gan-an lọ́wọ́ Jèhófà fún agbára tí Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ní láti wẹ̀ wá mọ́, a sì dúpẹ́ fún ìgbésí ayé títura àti alálàáfíà tí à ń gbádùn báyìí.”
A lè rí ìjẹ́pàtàkì jíjẹ́ òṣìṣẹ́ olóòótọ́ nínú ọ̀ràn Kurt, ẹni tí iṣẹ́ rẹ̀ jẹ mọ́ bíbójú tó ètò ìṣiṣẹ́ kọ̀ǹpútà. Nígbà tí wọ́n nílò àwọn ohun ìṣiṣẹ́ tuntun, àwọn ọ̀gá Kurt sọ pé òun ni kó lọ ná nǹkan wọ̀nyẹn lọ́jà, kó sì rà wọ́n. Kurt rí ibi tó dáa láti rà á, wọ́n jọ dúnàádúrà, ìná sì wọ̀. Àmọ́ nígbà tí akọ̀wé àwọn òǹtajà fẹ́ kọ iye owó ọjà, ó ṣì í kọ, iye tó pè é fi ọ̀kẹ́ méjì [40,000] dọ́là (owó Amẹ́ríkà) dín sí iye tí wọ́n jọ sọ tẹ́lẹ̀. Kurt rí àṣìṣe yẹn, ó sì kàn sí àwọn ọlọ́jà náà. Máníjà wọn sọ pé látọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n tóun ti wà lẹ́nu iṣẹ́, òun ò tíì rírú ìwà ìṣòtítọ́ yẹn rí. Kurt ṣàlàyé pé Bíbélì ló ń ṣàkóso ẹ̀rí ọkàn òun. Ìyọrísí rẹ̀ ni pé máníjà yẹn béèrè fún ọ̀ọ́dúnrún ẹ̀dà Jí! tó sọ̀rọ̀ nípa ìṣòtítọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ajé, kí òun lè pín in fáwọn tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́. Ní ti Kurt, ó rí ìgbéga lẹ́nu iṣẹ́ nítorí ìṣòtítọ́ rẹ̀.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A ti yí orúkọ wọn padà.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
“Èmi, Jèhófà, ni Ọlọ́run rẹ, Ẹni tí ń kọ́ ọ kí o lè ṣe ara rẹ láǹfààní.”—AÍSÁYÀ 48:17