Borí Àwọn Ohun Tó Lè Dènà Ìtẹ̀síwájú Rẹ!
KÁ SỌ pé o fi ọkọ̀ rẹ sí jíà, ẹ́ńjìnnì sì ń ṣiṣẹ́, ṣùgbọ́n ọkọ̀ takú, kò kúrò lójú kan. Ṣé kì í ṣe pé nǹkan kan ti bà jẹ́ lára ọkọ̀ náà? Rárá, òkúta ńlá kan ló wà níwájú ọ̀kan lára àwọn táyà iwájú. Kí o kàn gbé e kúrò ni, ọkọ̀ á ṣí.
Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, àwọn nǹkan kan wà tó lè dènà ìtẹ̀síwájú tẹ̀mí àwọn kan táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Fún àpẹẹrẹ, Jésù kìlọ̀ pé irú àwọn nǹkan bí “àníyàn ètò àwọn nǹkan yìí àti agbára ìtannijẹ ọrọ̀” lè ‘fún ọ̀rọ̀ òtítọ́ pa,’ kí ó sì dènà ìdàgbàsókè.—Mátíù 13:22.
Ní ti àwọn ẹlòmíràn, àwọn ìwà kan tó ti di mọ́líkì tàbí àwọn àléébù kan ló ń dènà ìtẹ̀síwájú wọn. Ọkùnrin ará Japan kan tó ń jẹ́ Yutaka fẹ́ràn ìhìn inú Bíbélì, àmọ́ tẹ́tẹ́ títa nìṣòro rẹ̀. Àìmọye ìgbà ló ti gbìyànjú láti borí àṣàkaṣà yìí, àmọ́ kò rí i ṣe. Àṣà bárakú yìí ti dá a ní gbèsè tó kúrò ní kékeré, ó ti pàdánù ilé mẹ́ta, ìdílé rẹ̀ kò bọ̀wọ̀ fún un mọ́, kò níyì lójú ara rẹ̀ mọ́. Ǹjẹ́ ó lè mú ohun ìdènà yìí kúrò, kí ó sì di Kristẹni?
Tàbí kẹ̀, gbé ọ̀rọ̀ obìnrin kan tó ń jẹ́ Keiko yẹ̀ wò. Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Bíbélì, ó ti gba ara rẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ohun búburú bí ìbọ̀rìṣà, ìṣekúṣe, àti iṣẹ́ wíwò. Ṣùgbọ́n o, Keiko jẹ́wọ́ pé: “Ohun ìdènà tó ga jù lọ fún mi ni sìgá mímu. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni mo gbìyànjú láti jáwọ́ nínú rẹ̀, ṣùgbọ́n kò ṣeé ṣe fún mi.”
Ìwọ náà lè ní ohun tó dà bí òkè ìṣòro tó ń dènà ìtẹ̀síwájú rẹ. Ohun yòówù kó jẹ́, mọ̀ dájú pé lágbára Ọlọ́run, wàá borí rẹ̀.
Rántí ohun tí Jésù sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ nígbà tí wọn ò lè lé ẹ̀mí èṣù jáde lára ọkùnrin oníwárápá kan. Lẹ́yìn tí Jésù ṣe ohun tí wọ́n ṣe tì láṣeyọrí, ó sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Bí ẹ bá ní ìgbàgbọ́ ìwọ̀n hóró músítádì, ẹ ó sọ fún òkè ńlá yìí pé, ‘Ṣípò kúrò ní ìhín lọ sí ọ̀hún,’ yóò sì ṣípò, kò sì sí ohunkóhun tí kì yóò ṣeé ṣe fún yín.” (Mátíù 17:14-20; Máàkù 9:17-29) Bẹ́ẹ̀ ni o, ìṣòro tó dà bí òkè ńlá lójú wa kò ju nǹkan bín-ń-tín lójú Ẹlẹ́dàá wa alágbára gbogbo.—Jẹ́nẹ́sísì 18:14; Máàkù 10:27.
Mímọ Àwọn Ohun Tí Ń Dènà Ìtẹ̀síwájú
Kóo tó lè borí ohun ìdènà, o gbọ́dọ̀ mọ ohun tí ohun ìdènà náà jẹ́. Báwo lo ṣe lè mọ̀ ọ́n? Nígbà míì, ẹnì kan nínú ìjọ, bóyá alàgbà tàbí ẹni tó ń kọ́ ẹ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, lè pe àfiyèsí rẹ sí nǹkan kan. Dípò bíbínú sí irú ìmọ̀ràn onífẹ̀ẹ́ bẹ́ẹ̀, á dáa kóo fi tìrẹ̀lẹ̀-tìrẹ̀lẹ̀ “fetí sí ìbáwí kí [o] sì di ọlọ́gbọ́n.” (Òwe 8:33) Nígbà míì sì rèé, ó lè jẹ́ ìgbà tóo ń dá kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ni àléébù rẹ hàn sí ọ. Dájúdájú, ọ̀rọ̀ Ọlọ́run “yè, ó sì ń sa agbára.” (Hébérù 4:12) Kíka Bíbélì àtàwọn ìtẹ̀jáde táa gbé ka Bíbélì lè fi ohun tóo ń rò lọ́kàn rẹ, ìmọ̀lára rẹ, àti ète rẹ hàn. Yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti fi àwọn ìlànà gíga Jèhófà díwọ̀n ara rẹ. Yóò jẹ́ kóo mọ àwọn nǹkan tó lè dènà ìtẹ̀síwájú rẹ nípa tẹ̀mí.—Jákọ́bù 1:23-25.
Bí àpẹẹrẹ, ká sọ pé akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan ní àṣà fífọkàn ro ọ̀ràn ìṣekúṣe. Ó lè má kà á sóhun tó lè ṣàkóbá fóun, kí ó máa ronú pé òun ò kúkú ṣe ohunkóhun tó lòdì. Bó ṣe ń bá ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ lọ, ó lè rí ọ̀rọ̀ inú Jákọ́bù 1:14, 15, tó sọ pé: “Olúkúlùkù ni a ń dán wò nípa fífà á jáde àti ríré e lọ nípasẹ̀ ìfẹ́-ọkàn òun fúnra rẹ̀. Lẹ́yìn náà, ìfẹ́-ọkàn náà, nígbà tí ó bá lóyún, a bí ẹ̀ṣẹ̀; ẹ̀wẹ̀, ẹ̀ṣẹ̀, nígbà tí a bá ti ṣàṣeparí rẹ̀, a mú ikú wá.” Nísinsìnyí ló wá rí i bí títọ ipa ọ̀nà yìí yóò ṣe dènà ìtẹ̀síwájú òun! Báwo ló ṣe lè mú ìdènà yìí kúrò?—Máàkù 7:21-23.
Bíborí Àwọn Ohun Ìdènà
Bóyá pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Kristẹni tó dàgbà dénú, akẹ́kọ̀ọ́ náà lè ṣe ìwádìí síwájú sí i nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, nípa lílo Watch Tower Publications Index.a Fún àpẹẹrẹ, àkòrí náà “Thoughts” [Èrò], tọ́ka òǹkàwé sí àpilẹ̀kọ mélòó kan táa ti tẹ̀ jáde tó dá lórí bíborí ríro ìròkurò. Àpilẹ̀kọ wọ̀nyí tọ́ka sí àwọn ẹsẹ Bíbélì tó lè ranni lọ́wọ́, bíi Fílípì 4:8, tó sọ pé: “Ohun yòówù tí ó jẹ́ òótọ́, ohun yòówù tí ó jẹ́ ti ìdàníyàn ṣíṣe pàtàkì, ohun yòówù tí ó jẹ́ òdodo, ohun yòówù tí ó jẹ́ mímọ́ níwà, ohun yòówù tí ó dára ní fífẹ́, ohun yòówù tí a ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ dáadáa, ìwà funfun yòówù tí ó bá wà, ohun yòówù tí ó bá sì wà tí ó yẹ fún ìyìn, ẹ máa bá a lọ ní gbígba nǹkan wọ̀nyí rò.” Àní sẹ́, a gbọ́dọ̀ fi èrò mímọ́, tí ń gbéni ró, rọ́pò èrò ìṣekúṣe!
Bí akẹ́kọ̀ọ́ náà ṣe ń bá ìwádìí nìṣó, ó dájú pé yóò tún rí àwọn ìlànà mìíràn nínú Bíbélì tí yóò ràn án lọ́wọ́ láti yẹra fún dídákún ìṣòro rẹ̀. Fún àpẹẹrẹ, Òwe 6:27 àti Mátíù 5:28 kìlọ̀ pé ká yẹra fún fífi àwọn ohun tí ń ru ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ takọtabo sókè bọ́ ọkàn wa. Onísáàmù náà gbàdúrà pé: “Mú kí ojú mi kọjá lọ láìrí ohun tí kò ní láárí.” (Sáàmù 119:37) Àmọ́ o, wíwulẹ̀ ka ẹsẹ Bíbélì wọ̀nyí kò tó. Ọkùnrin ọlọgbọ́n náà sọ pé: “Ọkàn-àyà olódodo máa ń ṣe àṣàrò.” (Òwe 15:28) Bí akẹ́kọ̀ọ́ náà bá ronú jinlẹ̀, kì í ṣe lórí kìkì ohun tí Ọlọ́run pa láṣẹ, ṣùgbọ́n pẹ̀lúpẹ̀lù lórí ìdí tí ó fi pa á láṣẹ, ó lè wá túbọ̀ lóye ìdí tí àwọn ọ̀nà Jèhófà fi bá ọgbọ́n àti òye mu.
Lékè gbogbo rẹ̀, ẹni tí ń làkàkà láti borí ohun tí ń dènà ìtẹ̀síwájú rẹ̀ gbọ́dọ̀ máa wá ìrànlọ́wọ́ Jèhófà déédéé. Ó ṣe tán, Ọlọ́run mọ ẹ̀dá wa, ó mọ̀ pé aláìpé ni wá, ekuru ló fi ṣẹ̀dá wa. (Sáàmù 103:14) Gbígbàdúrà láìdabọ̀ fún ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run, pa pọ̀ pẹ̀lú ìsapá ńláǹlà láti yẹra fún fífọkàn ro ọ̀ràn ìṣekúṣe, yóò so èso rere nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín—yóò jẹ́ ká ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́, tí kò ní máa dààmú wa.—Hébérù 9:14.
Má Juwọ́ Sílẹ̀
Ìṣòro yòówù kí o máa bá yí, mọ̀ pé ó lè padà wáyé lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Nígbà tíyẹn bá ṣẹlẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ìwà ẹ̀dá, ìrẹ̀wẹ̀sì lè dé, kí gbogbo rẹ̀ sì tojú sú ọ. Àmọ́ o, rántí ọ̀rọ̀ tí ń bẹ nínú Gálátíà 6:9, pé: “Ẹ má ṣe jẹ́ kí a juwọ́ sílẹ̀ ní ṣíṣe ohun tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀, nítorí ní àsìkò yíyẹ àwa yóò kárúgbìn bí a kò bá ṣàárẹ̀.” Àwọn èèyàn bíi Dáfídì àti Pétérù, tí wọ́n jẹ́ olùfọkànsìn ìránṣẹ́ Ọlọ́run kùnà bámúbámú ní àwọn ìgbà kan. Ṣùgbọ́n wọn ò jáwọ́. Wọ́n fi tìrẹ̀lẹ̀-tìrẹ̀lẹ̀ gba ìmọ̀ràn, wọ́n ṣe àwọn ìyípadà yíyẹ, wọ́n sì ń bá a lọ láti fi ara wọn hàn pé àwọn jẹ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run tó dáńgájíá. (Òwe 24:16) Láìka àwọn àṣìṣe Dáfídì sí, Jèhófà pè é ní “ọkùnrin kan tí ó tẹ́ ọkàn-àyà mi lọ́rùn, ẹni tí yóò ṣe gbogbo ohun tí mo fẹ́.” (Ìṣe 13:22) Pétérù pẹ̀lú borí àwọn àṣìṣe rẹ̀, ó sì di ọwọ̀n nínú ìjọ Kristẹni.
Ọ̀pọ̀ èèyàn lónìí ló ti kẹ́sẹ járí bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ nínú bíborí àwọn ohun ìdènà. Yutaka, táa mẹ́nu kàn níṣàájú, tẹ́wọ́ gba ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ó sọ pé: “Ìtìlẹyìn àti ìbùkún Jèhófà lórí gbogbo ìtẹ̀síwájú mi ràn mí lọ́wọ́ láti borí ìṣòro tẹ́tẹ́ títa tí mo ń bá yí. Inú mi dùn gan-an nítorí pé ọ̀rọ̀ Jésù ṣẹ sí mi lára—pé báa bá ní ìgbàgbọ́, a lè ṣí ‘àwọn òkè ńláńlá’ pàápàá nídìí.” Nígbà tó ṣe, Yutaka di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ nínú ìjọ.
Keiko tí tábà di bárakú fún ńkọ́? Arábìnrin tó ń bá obìnrin yìí kẹ́kọ̀ọ́ dá a lábàá pé kí ó ka onírúurú àpilẹ̀kọ nínú Jí! tó sọ̀rọ̀ nípa àṣà tábà mímu. Keiko tiẹ̀ kọ ọ̀rọ̀ tó wà nínú 2 Kọ́ríńtì 7:1 sínú ọkọ̀ rẹ̀, kí ó lè máa rán an létí lójoojúmọ́ láti wà ní mímọ́ lójú Jèhófà. Síbẹ̀síbẹ̀, kò lè jáwọ́. Keiko sọ pé: “Ọ̀ràn ara mi wá tojú sú mi. Fún ìdí yìí, mo bẹ̀rẹ̀ sí bi ara mi nípa ohun tí mo fẹ́ gan-an—ṣé Jèhófà ni mo fẹ́ sìn ni, tàbí Sátánì?” Gbàrà tó pinnu pé Jèhófà lòun fẹ́ sìn, ó fi taratara gbàdúrà fún ìrànlọ́wọ́. Ó wá sọ pé: “Ó yà mí lẹ́nu pé mo lè jáwọ́ sìgá mímu wẹ́rẹ́ báyẹn. Ó kàn dùn mí pé mi ò tètè jáwọ́ ni.”
Ìwọ náà lè ṣe àṣeyọrí sí rere nínú bíborí àwọn ohun tó lè dènà ìtẹ̀síwájú rẹ. Bóo bá ṣe túbọ̀ ń mú kí èrò, ìfẹ́ ọkàn, ọ̀rọ̀, àti ìṣesí rẹ bá àwọn ìlànà Bíbélì mu tó, bẹ́ẹ̀ náà ni wàá túbọ̀ máa ní iyì ara ẹni àti ìfọ̀kànbalẹ̀. Ara á tu àwọn arákùnrin àti arábìnrin rẹ nípa tẹ̀mí, àtàwọn mẹ́ńbà ìdílé rẹ, tí wọ́n yí ọ ká, wàá sì jẹ́ ìṣírí fún wọn. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, àjọṣe àárín ìwọ àti Jèhófà Ọlọ́run yóò túbọ̀ gún régé. Ó ṣèlérí pé òun yóò “mú ohun ìdìgbòlù èyíkéyìí kúrò ní ọ̀nà àwọn ènìyàn” òun, kí wọ́n má bàa bọ́ sí akóló Sátánì. (Aísáyà 57:14) Ìdánilójú sì wà pé bóo bá sapá láti mú àwọn ohun tó lè dènà ìtẹ̀síwájú tẹ̀mí rẹ kúrò, tóo sì borí wọn, Jèhófà yóò bù kún ọ ní jìngbìnnì.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti tẹ ìwé yìí jáde ní èdè mélòó kan.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]
Jésù ṣèlérí pé báa bá ní ìgbàgbọ́, a lè borí àwọn ohun ìdènà tó rí bí òkè ìṣòro
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30]
Kíka Bíbélì ń fún wa lókun láti borí àwọn àléébù tẹ̀mí