ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w03 8/15 ojú ìwé 3-4
  • Irú Orúkọ Wo Lò Ń Ṣe fún Ara Rẹ?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Irú Orúkọ Wo Lò Ń Ṣe fún Ara Rẹ?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ohun Tá A Fi Ń Rántí Àwọn Kan
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
  • Àwọn Ìpinnu Tó Ń Mú Kéèyàn Láyọ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Ohun Tó Dára Jù Lọ Tó O Lè Fayé Rẹ Ṣe!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • ‘Ìbùkún Wà Fún Olódodo’
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
w03 8/15 ojú ìwé 3-4

Irú Orúkọ Wo Lò Ń Ṣe fún Ara Rẹ?

ǸJẸ́ o ti ka ìkéde òkú rí nínú ìwé ìròyìn tàbí o ti rí àkọsílẹ̀ tó gùn jàn-ànràn-jan-anran tí wọ́n kọ nípa ìgbésí ayé ẹnì kan tó ti dolóògbé àtàwọn ohun tó gbé ṣe láyé? Ǹjẹ́ o béèrè lọ́wọ́ ara rẹ pé, ‘Kí làwọn èèyàn á sọ nípa èmi náà?’ Èèyàn mélòó ló ti ronú rí nípa nǹkan táwọn èèyàn á máa fi rántí wọn lẹ́yìn tí wọ́n bá kú? Nítorí náà, gbé àwọn ìbéèrè tó ṣe pàtàkì wọ̀nyí yẹ̀ wò: Kí làwọn èèyàn ì bá máa sọ nípa rẹ lónìí ká ní o ti kú lánàá? Irú orúkọ wo lò ń ṣe fún ara rẹ? Kí lò ǹ fẹ́ káwọn tó mọ̀ ẹ́ àti Ọlọ́run máa fi rántí rẹ?

Ọkùnrin ọlọ́gbọ́n tó kọ ìwé Oníwàásù sọ pé: “Orúkọ sàn ju òróró dáradára, ọjọ́ ikú sì sàn ju ọjọ́ tí a bíni lọ.” (Oníwàásù 7:1) Kí nìdí tí ọjọ́ téèyàn kú fi sàn ju ọjọ́ tá a bí èèyàn lọ? Ìdí ni pé èèyàn ò tíì lákọsílẹ̀ kankan nígbà tá a bí i. Kò tíì gbé ohunkóhun ṣe. Ọ̀nà tó gbà gbé ìgbésí ayé rẹ̀ ló máa mú káwọn èèyàn sọ̀rọ̀ rẹ̀ ní rere tàbí ní búburú. Ní ti àwọn tó ti ṣe orúkọ rere fún ara wọn fún ọ̀pọ̀ ọdún, ọjọ́ ikú wọn á sàn ju ọjọ́ ìbí wọn lọ.

Nítorí náà, gbogbo èèyàn ló láǹfààní láti yan ohun tó bá wù ú. Kódà, ojoojúmọ́ la ń yan àwọn ohun kan tó máa nípa lórí irú orúkọ tá a ti máa ṣe fún ara wa nígbà tá a bá dolóògbé, pàápàá jù lọ nípa ohun tí Ọlọ́run máa fi rántí wa. Ìdí rèé tí ọkùnrin ọlọ́gbọ́n náà tó jẹ́ Hébérù fi tún kọ ọ́ pé: “Ìrántí olódodo ni a ó bù kún, ṣùgbọ́n orúkọ àwọn ẹni burúkú yóò jẹrà.” (Òwe 10:7) Ẹ ò rí i pé àǹfààní ńlá ni kí Ọlọ́run rántí ẹni láti bù kúnni!

Tá a bá gbọ́n, ohun tó yẹ kó jẹ wá lọ́kàn jù lọ ni ṣíṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́, ká máa gbé níbàámu pẹ̀lú àwọn ìlànà rẹ̀. Ìyẹn túmọ̀ sí títẹ̀lé àwọn ìlànà pàtàkì tí Kristi sọ pé: “‘Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà rẹ àti pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ àti pẹ̀lú gbogbo èrò inú rẹ.’ Èyí ni àṣẹ títóbi jù lọ àti èkíní. Èkejì, tí ó dà bí rẹ̀, nìyí, ‘Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.’ Lórí àwọn àṣẹ méjì wọ̀nyí ni gbogbo Òfin so kọ́, àti àwọn Wòlíì.”—Mátíù 22:37-40.

À ń rántí àwọn kan gẹ́gẹ́ bí aláàánú, afẹ́dàáfẹ́re, ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn, tàbí ká tún rántí wọn fún ipa tí wọ́n ti kó nínú ọ̀ràn okòwò, ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì, ìmọ̀ ìṣègùn tàbí àwọn ìgbòkègbodò mìíràn. Kí ni ìwọ náà fẹ́ kí àwọn èèyàn máa fi rántí rẹ?

Akéwì ọmọ ilẹ̀ Scotland náà Robert Burns (1759 sí 1796) sọ pé ì bá wu òun ká ní Ọlọ́run lè fún wa lágbára láti lè máa wo ara wa lọ́nà táwọn èèyàn gbà ń wò wá. Ǹjẹ́ o lè wo ara rẹ láwòfín kó o sì sọ pé ó ní orúkọ rere lọ́dọ̀ èèyàn àti lọ́dọ̀ Ọlọ́run? Bópẹ́ bóyá, àjọṣe wa pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn ṣe pàtàkì púpọ̀ ju àṣeyọrí èyíkéyìí tá a lè ṣe láyé nídìí eré ìdárayá tàbí nínú ọ̀ràn okòwò. Ìbéèrè tó wá dìde ni pé: Báwo ni àjọṣe wa pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn, ìyẹn ìjíròrò wa, ìwà wa àti ọ̀nà tá a ń gbà fara ṣàpèjúwe ṣe ń nípa lórí wọn? Ṣé ẹni tó ṣe é sún mọ́ ni wá àbí ẹni tó ń ya ara rẹ̀ láṣo? Ṣé aláàánú ni wá tàbí oníkanra? Ṣé ẹni tó máa ń gba tàwọn ẹlòmíràn rò ni wá àbí ẹni tó jẹ́ pé ohun tó bá sọ labẹ gé? Ṣé ọlọ́yàyà tó ń kóni mọ́ra ni wá àbí ẹni tí kì í túra ká tí kò sì ṣeé sún mọ́? Ṣé ẹni tó mọ bá a ṣe ń fúnni nímọ̀ràn ni wá àbí ẹni tó máa ń fẹnu ba nǹkan jẹ́? Ẹ jẹ́ ká gbé àpẹẹrẹ bíi mélòó kan yẹ̀ wò tó jẹ́ ti ìgbà àtijọ́ àti ti òde òní ká wá rí bá a ṣe lè ṣe orúkọ rere fún ara wa.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 3]

Ó wu Robert Burns pé kí Ọlọ́run fún wa lágbára láti lè máa wo ara wa lọ́nà táwọn èèyàn gbà ń wò wá.

[Credit Line]

Látinú ìwé A History of England

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́