Ohun Tó Dára Jù Lọ Tó O Lè Fayé Rẹ Ṣe!
OWÓ làwọn kan ń fi ìgbésí ayé wọn wá kiri, kò sì sóhun tówó lè rà tí kò wù wọ́n láti ní. Ńṣe làwọn míì ń wá bí wọ́n ṣe máa dolókìkí, nígbà tó sì jẹ́ pé báwọn kan ṣe máa di ayàwòrán tó mọṣẹ́ dunjú ni wọ́n ń bá kiri. Tàwọn kan ni pé kí wọ́n máa ṣàánú àwọn èèyàn. Ṣùgbọ́n àwọn kan wà tí wọn ò mọbi tí ìgbésí ayé wọn dorí kọ, wọn ò sì mọ̀dí tí wọ́n fi wà láàyè.
Ìwọ ńkọ́? Ṣó o ti ronú jinlẹ̀ lórí ìdí tó o fi wà láàyè? O ò ṣe ṣàyẹ̀wò díẹ̀ lára àwọn nǹkan táwọn èèyàn ń lépa kó o wá wò ó bóyá wọ́n ń rí nǹkan gidi gbé ṣe tàbí bóyá wọ́n ń ní ìtẹ́lọ́rùn nígbèésí ayé wọn? Kí ni nǹkan tó dára jù lọ téèyàn lè fìgbésí ayé rẹ̀ ṣe?
Owó àti Ìgbádùn Ní Àyè Tiwọn
Nínú Oníwàásù 7:12, Bíbélì sọ pé: “Ọgbọ́n jẹ́ fún ìdáàbòbò, gẹ́gẹ́ bí owó ti jẹ́ fún ìdáàbòbò; ṣùgbọ́n àǹfààní ìmọ̀ ni pé ọgbọ́n máa ń pa àwọn tí ó ni ín mọ́ láàyè.” Ká sòótọ́, owó wúlò láyè tiẹ̀. Owó la fi ń ṣayé, pàápàá téèyàn bá níyàwó àtọmọ tó ń bọ́.—1 Tímótì 5:8.
Àwọn adùn kan wà nígbèésí ayé tí kò yẹ kéèyàn má ṣaláì tọ́ wò, àmọ́ béèyàn ò bá lówó lọ́wọ́ ńkọ́? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jésù Kristi tó jẹ́ Olùdásílẹ̀ ìsìn Kristẹni gbà pé òun ò ní ibi tóun máa gbé orí òun lé, síbẹ̀ àwọn ìgbà míì wà tó máa ń gbádùn oúnjẹ tó dọ́ṣọ̀ àti wáìnì gidi. Yàtọ̀ síyẹn, kì í ṣe èèwọ̀ fún Jésù láti wọ aṣọ olówó ńlá.—Mátíù 8:20; Jòhánù 2:1-11; 19:23, 24.
Àmọ́ kì í ṣe fàájì ni Jésù fi gbogbo ọjọ́ tó lò láyé ṣe. Ó mọ ohun pàtàkì tó tìtorí ẹ̀ wá sáyé. Jésù sọ pé: “Tí ẹnì kan bá tilẹ̀ ní ọ̀pọ̀ yanturu pàápàá, ìwàláàyè rẹ̀ kò wá láti inú àwọn ohun tí ó ní.” Ó wá sọ àpèjúwe kan tó dá lórí ọkùnrin ọlọ́rọ̀ kan tó kó irè tó pọ̀ lóko rẹ̀ tó wá lọ ń ronú pé: “Kí ni èmi yóò ṣe, nísinsìnyí tí èmi kò ní ibì kankan láti kó àwọn irè oko mi jọ sí? . . . Ṣe ni èmi yóò ya àwọn ilé ìtọ́jú nǹkan pa mọ́ mi lulẹ̀, èmi yóò sì kọ́ àwọn tí ó tóbi, ibẹ̀ ni èmi yóò sì kó gbogbo ọkà mi jọ sí àti gbogbo àwọn ohun rere mi; ṣe ni èmi yóò sọ fún ọkàn mi pé: ‘Ọkàn, ìwọ ní ọ̀pọ̀ ohun rere tí a tò jọ pa mọ́ fún ọ̀pọ̀ ọdún; fara balẹ̀ pẹ̀sẹ̀, máa jẹ, máa mu, máa gbádùn.’” Kí ló burú nínú ohun tí ọkùnrin yìí ń rò? Àpèjúwe náà ń tẹ̀ síwájú pé: “Ọlọ́run wí fún [ọkùnrin ọlọ́rọ̀ náà] pé, ‘Aláìlọ́gbọ́n-nínú, òru òní ni wọn yóò fi dandan béèrè ọkàn rẹ lọ́wọ́ rẹ. Ta ni yóò wá ni àwọn ohun tí ìwọ tò jọ pa mọ́?’” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọkùnrin yẹn lè tọ́jú irè oko rẹ̀, àmọ́ nígbà tó kú tán, kò lè jẹ̀gbádùn àwọn ohun tó ti kó jọ mọ́. Jésù wá fi ẹ̀kọ́ yìí parí àpèjúwe náà pé: “Bẹ́ẹ̀ ni ó máa ń rí fún ẹni tí ó bá ń to ìṣúra jọ pa mọ́ fún ara rẹ̀ ṣùgbọ́n tí kò ní ọrọ̀ síhà ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.”—Lúùkù 12:13-21.
Lóòótọ́ la nílò owó níwọ̀nba, ó sì yẹ ká máa jẹ̀gbádùn díẹ̀díẹ̀. Àmọ́ kì í ṣe owó tàbí fàájì ló yẹ ká kà sí pàtàkì jù nínú ìgbésí ayé wa. Kéèyàn ní ọrọ̀ lọ́dọ̀ Ọlọ́run, ìyẹn ni pé kó fi ìgbésí ayé rẹ̀ ṣe ohun tó máa mú kó rí ojúure Ọlọ́run, ló ṣe pàtàkì jù lọ láti máa lépa.
Téèyàn Bá Ń Ṣe Nǹkan Tórúkọ Rẹ̀ Ò Fi Ní Pa Rẹ́ Ńkọ́?
Ọ̀pọ̀ èèyàn ló fẹ́ ṣe ohun tórúkọ wọn ò fi ní pa rẹ́ lẹ́yìn ikú wọn. Kò kúkú fi gbogbo ara burú téèyàn bá fẹ́ ṣe nǹkan táwọn èèyàn á fi máa rántí rẹ̀. Bíbélì ṣáà sọ pé: “Orúkọ sàn ju òróró dáradára, ọjọ́ ikú sì sàn ju ọjọ́ tí a bíni lọ.”—Oníwàásù 7:1.
Lọ́jọ́ téèyàn bá kú, gbogbo ohun tónítọ̀hún gbélé ayé ṣe ti dọ̀rọ̀ ìtàn. Tó bá rí ohun gidi gbé ṣe, ọjọ́ ikú rẹ̀ sàn ju ọjọ́ tí wọ́n bí i lọ fíìfíì nìyẹn, nítorí pé lọ́jọ́ tí wọ́n bí i, ẹnì kankan ò tíì mọ ohun tó máa gbélé ayé ṣe.
Sólómọ́nì Ọba ló kọ ìwé Bíbélì tó ń jẹ́ Oníwàásù. Ábúsálómù, ẹ̀gbọ́n Sólómọ́nì tó jẹ́ ọbàkan rẹ̀, fẹ́ ṣe nǹkan tí kò ní jẹ́ kí orúkọ rẹ̀ pa rẹ́. Àmọ́, ó dà bíi pé àwọn ọmọkùnrin mẹ́ta tó bí ti kú ní kékeré, ipasẹ̀ àwọn ọmọ wọ̀nyí ló sì yẹ káwọn èèyàn fi máa rántí Ábúsálómù látìrandíran. Kí wá ni Ábúsálómù ṣe? Ìwé Mímọ́ sọ pé: “Ábúsálómù . . . gbé ọwọ̀n kan, ó sì tẹ̀ síwájú láti gbé e nà ró fún ara rẹ̀, èyí tí ó wà ní Pẹ̀tẹ́lẹ̀ Rírẹlẹ̀ Ọba, nítorí ó sọ pé: ‘Èmi kò ní ọmọkùnrin láti lè pa orúkọ mi mọ́ ní ìrántí.’ Nítorí náà, ó fi orúkọ ara rẹ̀ pe ọwọ̀n náà.” (2 Sámúẹ́lì 14:27; 18:18) Kò sẹ́ni tó mọbi tí àwókù ọwọ̀n náà wà báyìí. Ohun táwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì fi ń rántí Ábúsálómù ni bó ṣe jẹ́ ọlọ̀tẹ̀ paraku tó fẹ́ gbàjọba lọ́wọ́ Dáfídì bàbá rẹ̀.
Lónìí, ọ̀pọ̀ èèyàn ló fẹ́ kí wọ́n máa fi ohun táwọn gbé ṣe láyé rántí àwọn. Wọ́n ń fẹ́ gbayì lọ́dọ̀ àwọn èèyàn tó jẹ́ pé ẹnu tí wọ́n fi sọ pé adé gún lónìí ni wọ́n á tún fi sọ pé adé ò gún lọ́la. Kí ló máa wá ṣẹlẹ̀ sí iyì tí wọ́n ti gbà? Nínú ìwé kan tí Ọ̀gbẹ́ni Christopher Lasch kọ, tó pe orúkọ rẹ̀ ní The Culture of Narcissism, ó sọ pé: “Lákòókò wa yìí, ògo àwọn èèyàn kì í pẹ́ wọmi, torí pé àwọn táyé gbà pé wọ́n ṣàṣeyọrí làwọn tó ṣì ní ẹ̀jẹ̀ ọ̀dọ́ lára, àwọn arẹwà, àtàwọn tó bá ń ṣohun mérìíyìírí. Ìdí nìyẹn táwọn táyé ń gbé gẹ̀gẹ̀ fi máa ń bẹ̀rù kí wọ́n má dẹni táyé á gbàgbé.” Ìyẹn ló fà á tí ọ̀pọ̀ gbajúmọ̀ fi ń lo oògùn olóró àti ọtí líle tí wọ́n sì ń tipa bẹ́ẹ̀ dá ẹ̀mí ara wọn légbodò. Ṣẹ́ ẹ wá rí i pé òfo ni kéèyàn máa lépa òkìkí.
Tó bá jẹ́ bọ́ràn ṣe rí nìyẹn, ọ̀dọ̀ ta ló yẹ ká ti lórúkọ rere? Nígbà tí Jèhófà ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn kan tó pa Òfin rẹ̀ mọ́, ó tipasẹ̀ Aísáyà wòlíì rẹ̀ sọ pé: “Àní èmi yóò fún wọn ní ohun ìránnilétí àti orúkọ ní ilé mi àti nínú àwọn ògiri mi . . . Orúkọ tí yóò wà fún àkókò tí ó lọ kánrin ni èmi yóò fún wọn, ọ̀kan tí a kì yóò ké kúrò.” (Aísáyà 56:4, 5) Àwọn ẹni tí Ọlọ́run tẹ́wọ́ gbà yóò ní “ohun ìránnilétí àti orúkọ,” torí pé wọ́n ṣègbọràn sí i. Ọlọ́run á máa rántí orúkọ wọn “fún àkókò tí ó lọ kánrin” táá fi jẹ́ pé orúkọ wọn ò ní pa rẹ́. Irú orúkọ tí Bíbélì rọ̀ wá pé ká ní nìyẹn, ìyẹn orúkọ rere lọ́dọ̀ Jèhófà Ẹlẹ́dàá wa.
Ohun tó máa ṣẹlẹ̀ ní àkókò táwọn tó jẹ́ olóòótọ́ máa rí ìyè àìnípẹ̀kun gbà nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé ni Aísáyà ń sọ. “Ìyè àìnípẹ̀kun” nínú Párádísè yẹn ni “ìyè tòótọ́,” ìyẹn irú ìgbésí ayé tí Ọlọ́run fẹ́ káwọn èèyàn máa gbé nígbà tó dá wọn. (1 Tímótì 6:12, 19) Dípò tá ó fi máa fìgbésí ayé wa lé ohun tí ò ní tọ́jọ́ tí kì í sì í fúnni ní ìtẹ́lọ́rùn, ńṣe là bá kúkú máa wá ìyè àìnípẹ̀kun.
Dídi Ayàwòrán Tàbí Olówó Tí Ń Fowó Ṣàánú Kò Ní Kí Ìgbésí Ayé Tẹ́ni Lọ́rùn
Ọ̀pọ̀ ayàwòrán ló wù pé káwọn mọ àwòrán yà débi táwọn á fi gbà pé kò kù síbì kan. Àmọ́, ìwọ̀nba ọdún táwa èèyàn ń lò láyé báyìí kò tó fún èèyàn láti báṣẹ́ débẹ̀ yẹn. Nígbà tí Hideo, ayàwòrán tá a mẹ́nu bà nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, pé ẹni àádọ́rùn-ún ọdún, ó sa gbogbo ipá rẹ̀ láti lè mọ nǹkan yà ju bó ṣe mọ̀ ọ́n yà tẹ́lẹ̀ lọ. Ká tiẹ̀ sọ pé ayàwòrán kan mọ̀ ọ́n yà débi tóhun tó bá yà yóò fi máa dá a lọ́rùn, tó bá fi máa dìgbà táá mọ̀ ọ́n débi tó fẹ́ yẹn, ó lè máà lágbára láti ṣiṣẹ́ púpọ̀ bíi tìgbà tí eegun ṣì wà lára rẹ̀. Àmọ́ ká ló lè ní ìyè àìnípẹ̀kun ńkọ́? Ronú lórí adúrú àǹfààní tó máa ní láti mọṣẹ́ ọnà rẹ̀ lámọ̀dunjú!
Béèyàn bá ń lé bóun ṣe máa dolówó tó ń fowó ṣàánú ńkọ́? Ẹni tó bá sọ pé àwọn tálákà àtàwọn aláìní lòun á máa fi ohun ìní òun ta lọ́rẹ, ó yẹ ká kí i ká yìn ín. Bíbélì sọ pé: “Ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tí ó wà nínú rírígbà lọ.” (Ìṣe 20:35) Lóòótọ́, téèyàn bá ń gba tàwọn aláìní rò, ó lè mú kí onítọ̀hún nítẹ̀ẹ́lọ́rùn. Àmọ́, ká tiẹ̀ sọ pé ẹnì kan fi gbogbo ayé rẹ̀ wá bó ṣe máa dáa fáwọn ẹlòmíì, ẹni mélòó ló lè ràn lọ́wọ́? Ohun táwa èèyàn lè ṣe láti gbọn ìyà àwọn èèyàn nù kò tó nǹkan. Ohun yòówù tá a lè fi ta àwọn èèyàn lọ́rẹ, kò lè mú kí wọ́n ní ohun pàtàkì kan tí gbogbo èèyàn nílò, àmọ́ tí ọ̀pọ̀ èèyàn kì í fiyè sí tí wọn kì í sì í bójú tó. Kí lohun náà?
Ohun Pàtàkì Tó Gbọ́dọ̀ Wà Nínú Ìgbésí Ayé Wa
Nínú ìwàásù tí Jésù ṣe lórí òkè, ó sọ ohun kan tó pọn dandan kó wà nígbèésí ayé gbogbo wa, bó ṣe sọ ọ́ ni pé: “Aláyọ̀ ni àwọn tí àìní wọn nípa ti ẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn, níwọ̀n bí ìjọba ọ̀run ti jẹ́ tiwọn.” (Mátíù 5:3) Gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ṣe sọ, kì í ṣe ọrọ̀, òkìkí, ibi téèyàn mọ iṣẹ́ ọnà dé tàbí béèyàn ṣe ń fowó ṣàánú tó ló máa fún èèyàn láyọ̀ tó máa wà títí lọ. Kàkà bẹ́ẹ̀, téèyàn bá ń sin Ọlọ́run lèèyàn tó lè ní ayọ̀ gidi.
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rọ àwọn tí kò mọ Ẹlẹ́dàá pé kí wọ́n wá a. Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Láti ara ọkùnrin kan ni [Ọlọ́run] . . . ti dá gbogbo orílẹ̀-èdè àwọn ènìyàn, láti máa gbé ní ojú gbogbo ilẹ̀ ayé pátá, ó sì gbé àṣẹ kalẹ̀ nípa àwọn àkókò tí a yàn kalẹ̀ àti àwọn ààlà ibùgbé tí a gbé kalẹ̀ fún àwọn ènìyàn, fún wọn láti máa wá Ọlọ́run, bí wọ́n bá lè táràrà fún un, kí wọ́n sì rí i ní ti gidi, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, ní ti tòótọ́, kò jìnnà sí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa. Nítorí nípasẹ̀ rẹ̀ ni àwa ní ìwàláàyè, tí a ń rìn, tí a sì wà.”—Ìṣe 17:26-28.
Ó dìgbà tá a bá ń sin Ọlọ́run, bó ṣe yẹ ká sìn ín ká tó lè ní ayọ̀ tòótọ́ nígbèésí ayé wa. Ìyẹn á sì mú ká láǹfààní láti jogún “ìyè tòótọ́.” Gbé àpẹẹrẹ Teresa tó di olókìkí nínú eré orí tẹlifíṣọ̀n lórílẹ̀-èdè rẹ̀ yẹ̀ wò. Òun ni Adúláwọ̀ ọmọ ilẹ̀ Amẹ́ríkà àkọ́kọ́ tó kópa tó jọjú nínú eré tí wọ́n ń fi wákàtí kan ṣe lórí tẹlifíṣọ̀n. Àmọ́ nígbà tó yá, ó pa gbogbo ìwọ̀nyẹn tì. Kí ló fà á? Ó sọ pé: “Ó dá mi lójú pé títẹ̀lé ìlànà tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni ọ̀nà tó dáa jù lọ láti gbé ìgbé ayé.” Teresa mọ̀ pé kíkópa nínú eré orí tẹlifíṣọ̀n táá máa jẹ́ káwọn èèyàn wo ìbálòpọ̀ àti ìwà ipá bí ohun tó dára lè ba àjọṣe òun pẹ̀lú Ọlọ́run jẹ́, kò sì fẹ́ kíyẹn ṣẹlẹ̀. Nítorí náà kò ṣeré lórí tẹlifíṣọ̀n mọ́. Ó wá bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ìgbésí ayé tó ń fúnni láyọ̀, ó di aṣáájú-ọ̀nà tó ń wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run déédéé láti lè ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run.
Nígbà tí ọ̀gbẹ́ni kan tó jẹ́ ọ̀rẹ́ Teresa nígbà kan rí ń sọ̀rọ̀ lórí bí Teresa ṣe fi eré orí ìtàgé sílẹ̀, wọ́n ní ó sọ pé: “Ó dùn mí wọra torí pé mi ò fẹ́ kí àṣeyọrí tó ṣe yẹn bọ́ mọ́ ọn lọ́wọ́. Àmọ́ ó ṣe kedere pé ohun tó rí kó tó fi eré orí ìtàgé sílẹ̀ ṣe pàtàkì, ó sì tẹ́ ẹ lọ́rùn.” Ó ṣẹlẹ̀ pé Teresa kú lẹ́yìn ìgbà yẹn. Àmọ́ lẹ́yìn ikú rẹ̀, ọ̀rẹ́ rẹ̀ tá a mẹ́nu bà lẹ́ẹ̀kan yẹn sọ pé: “Ó láyọ̀, kí lèèyàn tún ń wá nígbèésí ayé tó jùyẹn lọ? Mélòó nínú wa ló lè sọ pé òun láyọ̀ bíi tirẹ̀?” Ìrètí tó dájú wà lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run pé àjíǹde yóò wà fáwọn tó fi àjọṣe wọn pẹ̀lú Ọlọ́run ṣáájú nígbèésí ayé wọn bó tilẹ̀ jẹ́ pé ikú pa wọ́n.—Jòhánù 5:28, 29.
Ẹlẹ́dàá fẹ́ ṣe ohun kan fún ilẹ̀ ayé àtàwọn èèyàn tó ń gbé lórí rẹ̀. Ó fẹ́ kó o lóye ohun tóun fẹ́ ṣe yìí kó o bàa lè gbádùn Párádísè lórí ilẹ̀ ayé. (Sáàmù 37:10, 11, 29) Ìsinsìnyí ló yẹ kó o túbọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà, Ẹlẹ́dàá ọ̀run àtayé, kó o sì kọ́ nípa ohun tó fẹ́ ṣe fún ọ. Tayọ̀tayọ̀ làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò rẹ á fi ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti ní ìmọ̀ yẹn. Jọ̀wọ́ kàn sí wọn tàbí kó o kọ̀wé sáwa tá a ṣe ìwé ìròyìn yìí.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]
Kí ló burú nínú èrò ọkùnrin ọlọ́rọ̀ inú àkàwé Jésù?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Ṣé wàá fẹ́ gbádùn ìyè àìnípẹ̀kun nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé?