Ìtàn Ìgbesí Ayé
Okun Jèhófà La Gbára Lé
GẸ́GẸ́ BÍ ERZSÉBET HAFFNER ṢE SỌ Ọ́
“Mi ò ní jẹ́ kí wọ́n lé ẹ jáde lórílẹ̀-èdè yìí.” Tibor Haffner ló sọ bẹ́ẹ̀ nígbà tó gbọ́ pé wọ́n ti pàṣẹ fún mi pé kí n fi orílẹ̀-èdè Czechoslovakia sílẹ̀. Ó wá sọ síwájú sí i pé: “Bó o bá gbà, màá fẹ́ ẹ, wàá sì wà lọ́dọ̀ mi títí ayé.”
NÍ January 29, 1938, ọ̀sẹ̀ díẹ̀ péré lẹ́yìn tí mo gbọ́ gbólóhùn tí mi ò retí yẹn, èmi àti Tibor, ìyẹn Kristẹni arákùnrin tó kọ́kọ́ wàásù fún ìdílé mi, fẹ́ra wa. Ìpinnu náà kò rọrùn rárá. Mo ṣẹ̀ṣẹ̀ pé ọmọ ọdún méjìdínlógún ni, níwọ̀n bí mo sì ti jẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run ni mo fẹ́ fi àárọ̀ ayé mi ṣe. Mo sunkún. Mo gbàdúrà. Ìgbà tára mi wálẹ̀ ni mo ṣẹ̀ṣẹ̀ wá rí i pé fífẹ́ tí Tibor ní kí n fẹ́ òun ju pé ó fẹ́ fi ṣàánú mi, mo wá rí i pé ó wu èmi pàápàá láti bá ẹni tó nífẹ̀ẹ́ mi tinútinú yìí gbé.
Àmọ́ báwo lọ̀rọ̀ ṣe jẹ́ ti mo fi dẹni tí wọ́n ń lé jáde nílùú? Ó ṣe tán, orílẹ̀-èdè tó ń fi ìjọba tiwa-n-tiwa yangàn tó sì sọ pé èèyàn lómìnira àtiṣe ìsìn tó bá wù ú ni mò ń gbé. Ó dáa, mo rò pé níbi tí mo dé yìí, ó yẹ kí n túbọ̀ sọ fún un yín nípa ìgbésí ayé mi látẹ̀yìnwá.
December 26, 1919 ni wọ́n bí mi lábúlé kan tó ń jẹ́ Sajószentpéter lórílẹ̀-èdè Hungary, tó wà ní nǹkan bí ọgọ́jọ kìlómítà lápá ìlà oòrùn Budapest, ọmọ ìjọ Kátólíìkì ti Ilẹ̀ Gíríìkì sì làwọn òbí mi. Ó dùn mí pé bàbá mi kú kí wọ́n tó bí mi. Kò pẹ́ lẹ́yìn náà ni màmá mi fẹ́ ọkùnrin kan tí ìyàwó tiẹ̀ náà ti kú tó sì lọ́mọ mẹ́rin, bá a ṣe kó lọ sí Lučenec nìyẹn, ìlú rírẹwà kan ní orílẹ̀-èdè tá a mọ̀ sí Czechoslovakia nígbà yẹn. Lákòókò yẹn, kì í ṣe ohun tó rọrùn rárá láti wà nínú irú ìdílé bẹ́ẹ̀. Nítorí pé èmi ni mo kéré jù nínú àwa ọmọ márààrún, ńṣe ló dà bíi pé mi ò kì í ṣara wọn. Àtijẹ-àtimu nira gan-an, ìyà ohun tara nìkan kọ́ ló sì ń jẹ mi, àmọ́ mi ò tún rí ìfẹ́ àti àmójútó tó yẹ kí ọmọ rí gbà lọ́dọ̀ òbí.
Ǹjẹ́ A Rẹni Tó Mọ Ìdáhùn Náà?
Nígbà tí mo dọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún, àwọn ìbéèrè kàǹkàkàǹkà bẹ̀rẹ̀ sí jà gùdù lọ́kàn mi. Tọkàntara ni mo fi máa ń ka ìtàn Ogun Àgbáyé Kìíní, ìyàlẹ́nu ló sì máa ń jẹ́ fún mi láti rí báwọn orílẹ̀-èdè tó lajú tó sì pera wọn ní Kristẹni ṣe para wọn lọ rẹpẹtẹ. Yàtọ̀ síyẹn, mo rí i pé ńṣe lẹ̀mí ogun túbọ̀ ń gba àwọn èèyàn lọ́kàn níbi gbogbo. Èyí kò fibì kankan bá ohun tí mo kọ́ ní ṣọ́ọ̀ṣì pé ká nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò wa mu.
Nípa bẹ́ẹ̀, mo gba ọ̀dọ̀ àlùfáà ìjọ Kátólíìkì kan lọ mo sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Òfin wo gan-an ló yẹ kó máa darí àwa Kristẹni, ṣé ká máa lọ sógun ká sì máa pa àwọn aládùúgbò wa ni àbí ká nífẹ̀ẹ́ wọn?” Ìbéèrè yìí bí i nínú, ló bá sọ pé nǹkan táwọn ọ̀gá pátápátá sọ pé kóun máa kọ́ àwọn èèyàn lòún ń kọ́ wọn. Ohun kan náà ló ṣẹlẹ̀ nígbà tí mo lọ sọ́dọ̀ àlùfáà kan tó jẹ́ ọmọlẹ́yìn Calvin àti nígbà tí mo lọ sọ́dọ̀ olùkọ́ kan nínú ẹ̀sìn Júù. Mi ò rí ìdáhùn kankan gbà ju pé ńṣe ni ìbéèrè mi ṣàjèjì sí wọn ó sì ń yà wọ́n lẹ́nu. Níkẹyìn, mo lọ rí àlùfáà kan tó jẹ́ ọmọlẹ́yìn Luther. Inú bí i, àmọ́ kí n tó kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀ ó sọ pé: “Bó bá jẹ́ lóòótọ́ lo fẹ́ mọ nǹkan kan nípa rẹ̀, lọ bi àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.”
Mo gbìyànjú kí n rí àwọn Ẹlẹ́rìí, àmọ́ mi ò rí wọn. Bí mo ṣe ń bọ̀ láti ibi iṣẹ́ lọ́jọ̀ díẹ̀ lẹ́yìn náà, mo rí i tí ilẹ̀kùn wa rọra ṣí sílẹ̀. Ọ̀dọ́kùnrin kan báyìí tó rẹwà ló ń ka nǹkan kan fún màmá mi látinú Bíbélì. Èrò tó yára wá sí mi lọ́kàn ni pé, ‘Ẹni yẹn gbọ́dọ̀ jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà!’ La bá sọ pé kí ọkùnrin yìí, Tibor Haffner wọlé, mo sì tún àwọn ìbéèrè mi béèrè. Dípò tí ì bá fi máa sọ èrò tara ẹ̀, ńṣe ló fi ohun tí Bíbélì sọ nípa àmì tá a fi ń dá àwọn Kristẹni tòótọ́ mọ̀ hàn mí àti irú àkókò tí à ń gbé.—Jòhánù 13:34, 35; 2 Tímótì 3:1-5.
Láàárín oṣù díẹ̀ péré, kí n tó pé ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún, mo ṣèrìbọmi. Mo ronú pé gbogbo èèyàn ló yẹ kó gbọ́ nípa òtítọ́ ṣíṣeyebíye tí mo wá rí lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ wàhálà yìí. Bi mo ṣe fi iṣẹ́ ìwàásù ṣeṣẹ́ ṣe nìyẹn, èyí sì nira gan-an ní Czechoslovakia láwọn ọdún 1930. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ti fìdí iṣẹ́ wa múlẹ̀ lábẹ́ òfin, síbẹ̀ àtakò gbígbóná jan-jan látọ̀dọ̀ àwọn àlùfáà kò jẹ́ kó rọrùn fún wa rárá.
Ìgbà Àkọ́kọ́ Tí Mo Fojú Winá Inúnibíni
Lọ́jọ́ kan, nígbà tó ku díẹ̀ kí ọdún 1937 parí, èmi àti arábìnrin kan jọ ń wàásù ní abúlé kan tí kò jìnnà sí Lučenec. Ká tó pajú pẹ́, wọ́n ti mú wa wọ́n sì kó wa lọ sẹ́wọ̀n. Ẹ̀ṣọ́ tó wà níbẹ̀ sọ pé: “Ibi tẹ́ ẹ máa kú sí lẹ dé yìí,” àfi gbà-à, ló tilẹ̀kùn yàrá tí wọ́n há wa mọ́ lọ́gbà ẹ̀wọ̀n náà.
Nígbà tó fi máa di ìrọ̀lẹ́, àwọn ẹlẹ́wọ̀n mẹ́rin mìíràn ti kún wa. A bẹ̀rẹ̀ sí tù wọ́n nínú a sì ń wáàsù fún wọn. Ara wọn wá balẹ̀, gbogbo oru la sì fi sọ ọ̀rọ̀ òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì fún wọn.
Nígbà tó di aago mẹ́fà ìdájí, bẹ́ẹ̀ lẹ̀ṣọ́ yẹn pè mí jáde látinú yàrá ọgbà ẹ̀wọ̀n náà. Mo bá sọ fún ẹnì kejì mi pé: “A ó tún máa pàdé nínú Ìjọba Ọlọ́run.” Mo ni kó bá mi sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ fún ìdílé mi bí òun náà ò bá kú. Mo gbàdúrà ìdákẹ́jẹ́ mo sì tẹ̀ lé ẹ̀ṣọ́ náà lọ. Ó mú mi lọ síbi tó ń gbé láyìíká ọgbà ẹ̀wọ̀n náà. Ó sì sọ pé: “Ọmọbìnrin, àwọn ìbéèrè kan wà tí mo fẹ́ bi ẹ́.” Lálẹ́ àná, o sọ pé Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run. Ṣé o lè fi ibi tó wà hàn mí nínú Bíbélì?” Ìyàlẹ́nu gbáà lèyí jẹ́ fún mi, ara sì tù mí pẹ̀sẹ̀! Ó mú Bíbélì rẹ̀ jáde, mo sì fi orúkọ Jèhófà han òun àti ìyàwó rẹ̀. Ó tún béèrè àwọn ìbéèrè mìíràn lórí àwọn kókó tá a jíròrò pẹ̀lú àwọn obinrin mẹ́rin yẹn lóru. Àwọn ìdáhùn náà dùn mọ́ ọn nínú, ló bá ní kí ìyàwó òun ṣe oúnjẹ àárọ́ fún èmi àti ẹnì kejì mi.
Ọjọ́ díẹ̀ lẹ́yìn náà, wọ́n fi wá sílẹ̀, àmọ́ adájọ́ kan sọ pé níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ọmọ orílẹ̀-èdè Hungary ni mí, mo ní láti fi orílẹ̀-èdè Czechoslovakia sílẹ̀. Ẹ̀yìn ìṣèlẹ̀ yìí ni Tibor Haffner ní kí n wá ṣe aya òun. A ṣègbéyàwó, mo sì kó lọ sílé àwọn òbí rẹ̀.
Inúnibíni Le Sí I
À ń bá iṣẹ́ ìwáàsù nìṣó lẹ́yìn tá a di tọkọtaya, bó tilẹ̀ jẹ́ pé Tibor tún ní àwọn iṣẹ́ mìíràn tó ń bójú tó nínú ètò àjọ wa. O kú ọjọ́ díẹ̀ péré káwọn ọmọ ogun Hungary wọnú ìlú wa ní oṣù November 1938, la bí ọmọkùnrin wa, Tibor Kékeré. Ní Yúróòpù, Ogun Àgbáyé Kejì ti ń rọ̀dẹ̀dẹ̀. Àwọn ará Hungary ti gba èyí tó pọ̀ jù lára Czechoslovakia, èyí sì mú kí inúnibíni tí wọ́n ń ṣe sáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ń gbé láwọn àgbègbè tí wọ́n ti gbà náà túbọ̀ le sí i.
Ní October 10, 1942, Tibor lọ sí ìlú Debrecen láti lọ pàdé àwọn arákùnrin kan. Àmọ́ lílọ tó lọ yìí, kò padà wálé. Ó sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ fún mi lẹ́yìn náà. Àwọn ọlọ́pàá kan tó wọ aṣọ àwọn òṣìṣẹ́ ló wà lórí afárá níbi tí wọ́n ti fẹ́ ṣèpàdé ọ̀hún dípò àwọn arákùnrin náà. Wọ́n ń dúró de ọkọ mi àti Pál Nagypál tí wọ́n dé kẹ́yìn. Làwọn ọlọ́pàá yìí bá kó wọn lọ sí àgọ́ ọlọ́pàá tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí fi kùmọ̀ lù wọ́n ní àtẹ́lẹsẹ̀ títí wọ́n fi dákú nítorí ìrora.
Lẹ́yìn náà, wọ́n pàṣẹ fún wọn pé kí wọ́n wọ bàtà wọn kí wọ́n sì dìde dúró. Pẹ̀lú ìrora yìí náà ni wọ́n fipá mú wọn lọ sídìí ọkọ̀ ojú irin. Àwọn ọlọ́pàá tún mú ọkùnrin mìíràn dé tí wọ́n fi báńdéèjì di orí rẹ̀ débi pé, ekukáká ló fi ń ríran. Arákùnrin András Pilling lẹni yìí, tóun náà wá sí ìpàdé yẹn. Wọ́n fi ọkọ̀ ojú irin gbé ọkọ̀ mi lọ sí ibi tí wọ́n ń kó àwọn Ẹlẹ́rìí jọ sí ní Alag, ní tòsí Budapest. Ọ̀kan lára àwọn ẹ̀ṣọ́ tó rí ẹsẹ̀ Tibor bó ṣe bó yánnayànna sọ tẹ̀gàntẹ̀gàn pé: “Háà, àwọn èèyàn kan mà kúkú níkà o! Má ṣèyọnu, àá tọ́jú ẹ.” Báwọn ẹ̀sọ́ méjì mìíràn ṣe tún bẹ̀rẹ̀ sí na Tibor lẹ́sẹ̀ nìyẹn, tí ẹ̀jẹ̀ sì ń fọ́n sílẹ̀ káàkiri. Lẹ́yìn ìṣẹ́jú díẹ̀, ó dákú lọ gbọnrangandan.
Ní oṣù tó tẹ̀ lé e, wọ́n ṣẹjọ́ Tibor àtàwọn ọgọ́ta arákùnrin àti arábìnrin mìíràn. Wọ́n dájọ́ ikú fún arákùnrin András Bartha, Dénes Faluvégi àti János Konrád, wọ́n ní kí wọ́n yẹgi fún wọn. Wọ́n dá ẹ̀wọ̀n gbére fún arákùnrin András Pilling, wọ́n sì ní kí ọkọ mi lọ fi ẹ̀wọ̀n ọdún méjìlá jura. Ẹ̀ṣẹ̀ wo ni wọ́n ṣẹ̀? Olùpẹ̀jọ́ fẹ̀sùn ìdìtẹ̀-gbàjọba, kíkọ̀ láti wọṣẹ́ ológun, ṣíṣe amí àti sísọ ọ̀rọ̀ ṣọ́ọ̀ṣì mímọ́ jù lọ láìdáa kàn wọ́n. Nígbà tó yá, wọ́n yí ìdájọ́ àwọn tí wọ́n ti dájọ́ ikú fún padà sí ẹ̀wọ̀n gbére.
Mo Tẹ̀ Lé Ọkọ Mi
Lọ́jọ́ kẹta tí Tibor lọ fún ìpàdé ilú Debrecen yẹn, aago mẹ́fà ò tíì lù tí mo ti jí, mo sì ń lọ àwọn aṣọ wa. Ẹ̀ẹ̀kan náà ni mo déédéé gbọ́ gbà-gbà-gbà, lára ilẹ̀kùn. Mo sọ lọ́kàn mi pé, ‘Wọ́n ti dé.’ Ọlọ́pàá mẹ́fà wọlé wá wọ́n sì sọ fún mi pé wọ́n ti fún àwọn láṣẹ láti yẹ inú ilé wa wò. Wọ́n mú gbogbo àwa tá a wà nínú ilé, wọ́n sì kó wa lọ sí àgọ́ ọlọ́pàá, títí kan ọmọ mi tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́ta. Lọ́jọ́ yẹn kan náà, wọ́n kó wa lọ sí ọgbà ẹ̀wọ̀n kan nílùú Pétervására, ní orílẹ̀-èdè Hungary.
Lẹ́yìn tá a débẹ̀, ibà kọ lù mí wọ́n sì mú mi kúrò láàárín àwọn ẹlẹ́wọ̀n yòókù. Nígbà tí mo gbádùn, àwọn sójà méjì wá sínú yàrá tí wọ́n há mi mọ́, wọ́n ń jiyàn lórí mi. Ọ̀kan sọ pé, “A gbọ́dọ̀ yìnbọn pa á. Màá yìnbọn fún un!” Àmọ́ èkèjì rẹ̀ fẹ́ mọ bí ìlera mi ṣe rí kí wọ́n tó yìnbọn fún mi. Mo bẹ̀ wọ́n pé kí wọ́n má pa mí. Níkẹyìn wọ́n jáde, mo sì dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé ó ràn mí lọ́wọ́.
Ọ̀nà táwọn ẹ̀ṣọ́ wọ̀nyẹn gbà ń wádìí ọ̀rọ̀ lẹ́nu èèyàn le kú. Wọ́n dá mi dọ̀bálẹ̀ wọ́n sì ní kí n dojú bolẹ̀, wọ́n ki ìbọ̀sẹ̀ bọ̀ mí lẹ́nu, wọ́n dè mí tọwọ́-tẹsẹ̀, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí nà mí títí ẹ̀jẹ̀ fi ń jáde lára mi. Àfìgbà tí ọ̀kan lára àwọn sójà náà sọ pé ó rẹ òun ni wọ́n tó dáwọ́ dúró. Wọ́n wá bi mí pé ta ni ọkọ mi fẹ́ lọ pàdé lọ́jọ́ tí wọ́n mú un. Mi ò sọ fún wọn, bí wọ́n ṣe tún bẹ̀rẹ̀ sí nà mí nìyẹn fún odindi ọjọ́ mẹ́ta gbáko. Nígbà tó di ọjọ́ kẹrin, wọ́n fún mi láyè láti gbé ọmọ mi lọ fún màmá mi. Nínú òtútù tó ń mú burúkúburúkú, mo gbé ọmọ mi kékéré pọ̀n sẹ́yìn mi tó ti dégbò, mo sì fẹsẹ̀ rin nǹkan bíi kìlómità mẹ́tàlá lọ sídìí ọkọ̀ ojú irin. Látibẹ̀, mo wọkọ̀ ojú irin délé, àmọ́ mo ní láti padà sí àgọ́ ọlọ́pàá lọ́jọ́ yẹn kan náà.
Wọ́n dájọ́ fún mi pé kí n lọ ṣẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́fà ní ọgbà ẹ̀wọ̀n kan ní Budapest. Nígbà tí mo débẹ̀, mo gbọ́ pé Tibor náà wà níbẹ̀. Inu wa dùn gan-an nígbà tí wọ́n fún wa láyè láti bára wa sọ̀rọ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé gbogbo ọ̀rọ̀ ọ̀hún ò ju ìṣẹ́jú díẹ̀ lọ láti ẹ̀yìn irin! Àwa méjèèjì rí i pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa, ìwọnba àkókò ṣíṣeyebíye tá a sì fi jọ sọ̀rọ̀ yìí fún wa lókun. Ká tó tún padà fojú kanra, àdánwò bíburú jáì ń dúró de àwa méjèèjì, léraléra ló sì jẹ́ pé díẹ̀ báyìí ló máa ń kù kí ẹ̀mí wa bọ́.
Láti Ọgbà Ẹ̀wọ̀n Kan Dé Òmíràn
Àwa arábìnrin bí ọgọ́rin ni wọ́n kó pa pọ̀ sinú yàrá ọgbà ẹ̀wọ̀n kan ṣoṣo. Ó ń ṣe wá bíi pé ká rí oúnjẹ tẹ̀mí díẹ̀ jẹ, àmọ́ ó dá bí ẹni pé kò sọ́nà kankan tí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ lè gbà dénú ọgbà ẹ̀wọ̀n náà. Ǹjẹ́ a lè rí nǹkan kan nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n níbẹ̀? Jẹ́ kí n sọ ohun tá a ṣe fún ẹ. Mo yọ̀ọ̀da ara mi láti máa bá àwọn òṣìṣẹ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n náà rán àwọn ìbọ̀sẹ̀ wọn tó ya. Nínú ọ̀kan lára àwọn ìbọ̀sẹ̀ náà, mo fi bébà pélébé kan sínú rẹ̀ tí mo fi béèrè pé a fẹ́ mọ nọ́ǹbà tá a ti lè rí Bíbélì láàárín àwọn ìwé tó wà níbi ìkówèésí nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n náà. Kí wọ́n má bàa fura rárá, mó fi orúkọ ìwé méjì mìíràn kún un.
Lọ́jọ́ kejì, mo tún gba ìbọ̀sẹ̀ rẹpẹtẹ látọ̀dọ̀ àwọn òṣìṣẹ́ náà. Ìdáhùn wà nínú ọ̀kan lára wọn. Mo wá fún ọ̀kan lára àwọn ẹ̀ṣọ́ náà láwọn nọ́ńbà yìí mo sì ní kí wọ́n fún mi láwọn ìwé náà. Inu wa dùn gan-an nígbà tá a gba àwọn ìwé náà, tí Bíbélì sì wà lára wọn! A máa ń pààrọ̀ àwọn ìwé yóòkù lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, àmọ́ a mú Bíbélì dání. Nígbà tí ẹ̀sọ́ náà bá béèrè nípa rẹ̀, ohun tá a máa ń sọ fún un ni pé: “Ìwé tó tóbi ni, gbogbo èèyàn ló sì fẹ́ kà á.” Nípa bẹ́ẹ̀, ó ṣeé ṣe fún wa láti máa ka Bíbélì.
Lọ́jọ́ kan, ọ̀gá kan pè mí sínú ọ́fíìsì rẹ̀. Ó ṣe dáadáa sí mi lọ́nà tó yà mí lẹ́nu.
Ó wá sọ pé: “Ìyáàfin Haffner, mo ní ìròyìn rere fún ẹ. O lè lọ sílé. Bóyá lọ́la. Bí ọkọ̀ ojú irin bá wà, o tiẹ̀ lè lọ lónìí pàápàá.”
Mo bá dáhùn pé: “Ìyẹn á ti lọ wà jù.”
Ó wá sọ pé: “Lóòótọ́ ni, á ti lọ wà jù. O lọ́mọ kékeré lọ́wọ́, mo sì mọ̀ pé wàá fẹ́ láti tọ́ ọ.” Lẹ́yìn náà ló fi kún un pé, “Kàn buwọ́ lu ìwé yìí.”
Mo béèrè pé: “Kí ló wà nínú ẹ̀?”
Bẹ́ẹ̀ ló ṣáà ń sọ pé, “Má ṣèyọnu nípa ohun tó wà nínú rẹ̀. Sáà buwọ́ lù ú, kó o sì máa lọ.” Lẹ́yìn náà ló sọ fún mi pé: “Ṣé o rí i, tó o bá ti délé báyìí, ohunkóhun tó bá wù ẹ́ lo lè ṣe. Àmọ́ nísinsìnyí, o gbọ́dọ̀ fọwọ́ síwèé pé o kì í ṣe ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ́.”
Mo rìn sẹ́yìn, mo sì kọ̀ jálẹ̀.
Ló bá fìbínú pariwo mọ́ mi pé: “A jẹ́ pé ibi tí wàá kú sí rèé!” ó sì lé mi jáde.
Ní May 1943, wọ́n gbé mi lọ sí ọgbà ẹ̀wọ̀n mìíràn nílùú Budapest, lẹ́yìn náà wọ́n tún gbé mi lọ si abúlé kan tó ń jẹ́ Márianosztra, níbi tá a ti ń gbé nílé àwọn ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé pẹ̀lú nǹkan bí àádọ́rin àwọn obìnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé. Láìka ebi àtàwọn ìnira mìíràn sí, ńṣe là ń hára gàgà láti sọ fún wọn nípa ìrètí wa. Ọ̀kan lára àwọn obìnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé náà nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ wa gan-an ó sì sọ pé: “Àwọn ẹ̀kọ́ wọ̀nyí dára gan-an ni. Mi ò tíì gbọ́ irú nǹkan báyìí rí. Ẹ jọ̀ọ́, ẹ túbọ̀ sọ ọ́ fún mi.” A sọ fún un nípa ayé tuntun tó ń bọ̀ àti bí ìgbésí ayé ṣe máa dùn mọ̀ràn-ìn mọran-in tó níbẹ̀. Bá a ṣe ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, bẹ́ẹ̀ ni ìyá ìjọ dé. Kíá ni wọ́n wá mú obìnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé náà lọ, wọ́n bọ́ aṣọ rẹ̀, wọ́n sì nà á bí ẹni máa kú. Nígbà tá a tún padà fojú kàn án, ó bẹ̀ wá pé: “Ẹ jọwọ́, ẹ bá mi gbàdúrà sí Jèhófà pé kó gbà mí, kó sì yọ mí kúrò níbí yìí. Mo fẹ́ di ọ̀kan lára yín.”
Ibòmíràn tí wọ́n tún kó wa lọ ni ọgbà ẹ̀wọ̀n ògbólógbó kan ní Komárom, ìlú kan ní bèbè Odò Danube, tó jẹ́ nǹkan bí ọgọ́rin kìlómítà lápá ìwọ̀ oòrùn Budapest. Ìgbésí ayé ibẹ̀ kò yẹ ọmọ èèyàn rárá. Bíi tàwọn arábìnrin kan, àìsàn ibà kọ lù mí ó sì fẹ́rẹ̀ẹ́ pa mí, mò ń pọ ẹ̀jẹ̀ kò sì sí ìmí nínú mi mọ́. A ò ní oògùn kankan, mo sì gbà pé ikú ti yá nìyẹn. Àmọ́ àkókò yìí làwọn ọ̀gá ibẹ̀ ń wá ẹnì kan tó lè ṣiṣẹ́ ọ́fíìsì. Àwọn arábìnrin tó wà níbẹ̀ dárúkọ mi fún un. Nípa bẹ́ẹ̀, wọ́n fún mi láwọn oògùn díẹ̀, mo sì gbádùn.
Èmi àti Ìdílé Mi Tún Wa Papọ̀
Báwọn ọmọ ogun Soviet ti ń sún mọ́ tòsí láti apá ìlà oòrùn, wọ́n fipá mú wa ṣí lọ sí apá ìwọ̀ oòrùn. Tí n bá ní kí n máa sọ gbogbo aburú tá a là kọjá, àkókò ò lè tó láti sọ wọ́n. Ọ̀pọ̀ ìgbà ló jẹ́ pé díẹ̀ báyìí ló máa ń kù kí ẹ̀mí mi bọ́, àmọ́ mo dúpẹ́ pé Jèhófà dáàbò rẹ̀ bò mí, mo là á já. Nígbà tí ogun yẹn parí, ìlú Tábor lórílẹ̀-èdè Czech la wà, ní nǹkan bí ọgọ́rin kìlómítà sí ìlú Prague. Ó gba èmi àti Magdalena àbúrò ọkọ mi ní ọ̀sẹ̀ mẹ́ta gbáko sí i ká tó lè dé ilé wa ní Lučenec, ní May 30, 1945.
Láti ọ̀ọ́kán, mo rí ìyá ọkọ mi àti ọmọ mi ọ̀wọ́n Tibor, nínú àgbàlá. Omi lé ròrò sójú mi, mo sì kígbe pè é látọ̀ọ́kán pé, “Tibike!” Ó sáré ó sì fò mọ́ mí. Gbólóhùn tó kọ́kọ́ jáde lẹ́nu ẹ̀ ni, “Mọ́mì, ẹ ò lọ mọ́ o, àbí ẹ tún máa lọ?” Mi ò lè gbàgbé gbólóhùn yẹn láéláé.
Jèhófà fi àánú hàn sí Tibor ọkọ mi pẹ̀lú. Láti ọgbà ẹ̀wọ̀n ní Budapest, wọ́n gbé e lọ sí agọ́ iṣẹ́ àṣekú ní Bor, òun àti nǹkan bí ọgọ́jọ àwọn arákùnrin mìíràn ni wọ́n gbé lọ síbẹ̀. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọ́n bára wọn ní bèbè ikú, àmọ́ Jèhófà kò jẹ́ kí wọ́n pa gbogbo wọn run. Tibor padà délé ní April 8, 1945, nǹkan bí oṣù kan kí n tó dé.
Lẹ́yìn tí ogun yẹn parí, a ṣì tún nílò okun látọ̀dọ̀ Jèhófà láti lè la gbogbo àdánwò ogójì ọdún tó tẹ̀ lé e lábẹ́ ìjọba Kọ́múníìsì ní Czechoslovakia já. Wọ́n tún dá ẹ̀wọ̀n ọlọ́jọ́ gbọọrọ fún Tibor, mo wá ní láti máa dá nìkan tọ́jú ọmọ wa. Lẹ́yìn tí wọ́n fi Tibor sílẹ̀, ó sìn gẹ́gẹ́ bí alábòójútó arìnrìn-àjò. Láàárín ogójì ọdún ètò ìjọba Kọ́múníìsì náà, gbogbo àǹfààní tá a ní la fi ń sọ ohun tá a gbà gbọ́ fáwọn èèyàn. Ó ṣeé ṣe fun wa láti ran ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Wọ́n sì wá di àwọn ọmọ wa nípa tẹ̀mí.
Ìdùnnú ṣubú layọ̀ nígbà tá a ní òminira ìsìn lọ́dún 1989. Lọ́dún tó tẹ̀ lé e, a lọ sí ìpàdé àgbègbè wa àkọ́kọ́ ní orílẹ̀-èdè wa lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún. Nígbà tá a rí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa tí wọ́n ti pa ìwàtítọ́ wọn mọ́ fún ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún, a mọ̀ lóòótọ́ pé Jèhófà ni orísun okun gbogbo wọn pátá.
Tibor ọkọ mi ọ̀wọ́n ṣe olóòótọ́ sí Ọlọ́run títí tó fi kú ní October 14, 1993, èmí sì ń gbé nítòsí ọmọ mi ní Žilina tó wà nítòsí Slovakia. Mi ò fi bẹ́ẹ̀ lókun mọ́, àmọ́ okun mi nípa tẹ̀mí ṣì wà digbí pẹ̀lú agbára Jèhófà. Mo gbà gbọ́ láìsí iyèméjì kankan pé, pẹ̀lú agbára rẹ̀, kò sí àdánwò náà tí mi ò lè fara dà nínú ètò àwọn nǹkan tó ti di ògbólógbòó yìí. Láfikún sí i, mò ń retí àkókò náà, nígbà tí màá lè wà láàyè títí láé nípasẹ̀ inú rere àílẹ́tọ̀ọ́sí Jèhófà.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]
Ọmọ mi, Tibor Kékeré rèé, (nígbà tó wà lọ́mọ ọdún mẹ́rin) ti mo ní láti fi sílẹ̀
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]
Tibor Àgbà, àtàwọn arákùnrin mìíràn ní Bor
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]
Èmi àti Tibor àti Magdalena, àbúrò ọkọ mi, lọ́dún 1947, nílùú Brno
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Ọ̀pọ̀ ìgbà ló jẹ́ pé díẹ̀ báyìí ló máa ń kù kí ẹ̀mí mi bọ́, àmọ́ mo dúpẹ́ pé Jèhófà dáàbò rẹ̀ bò mí, mo là á já