Kí Ló Máa Ràn Ọ́ Lọ́wọ́ Láti Lóye Bíbélì?
“ÌWỌ ti rọra fi ohun wọ̀nyí pa mọ́ kúrò lọ́dọ̀ àwọn ọlọ́gbọ́n àti amòye, o sì ti ṣí wọn payá fún àwọn ìkókó.” (Lúùkù 10:21) Ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ fún Bàbá rẹ̀ yìí jẹ́ ká rí i pé ká tó lè lóye Bíbélì, a gbọ́dọ̀ ní èrò tó dáa. Ọgbọ́n Jèhófà fara hàn nínú bó ṣe pèsè ìwé kan fún aráyé tó sì jẹ́ pé kìkì àwọn onírẹ̀lẹ̀ èèyàn, tí wọ́n ṣeé kọ́ lẹ́kọ̀ọ́, nìkan ló lè lóye rẹ̀ dáadáa.
Ó máa ń ṣòro fún èyí tó pọ̀ jù lọ nínú wa láti fi ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ hàn. Ìdí ni pé ẹ̀mí ìgbéraga ti wà nínú ẹ̀jẹ̀ gbogbo wa. Yàtọ̀ síyẹn, “ọjọ́ ìkẹyìn” là ń gbé, láàárín àwọn èèyàn tó jẹ́ “olùfẹ́ ara wọn, . . . olùwarùnkì, awúfùkẹ̀ pẹ̀lú ìgbéraga.” (2 Tímótì 3:1-4) Àwọn ìwà wọ̀nyí sì máa ń ṣèdíwọ́ fún wa láti lóye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ó dunni pé, lọ́nà kan tàbí òmíràn, ẹ̀mí ìgbéraga àwọn tó yí wa ká máa ń mú káwa náà fẹ́ gbéra ga. Báwo lo ṣe máa wá ní ànímọ́ téèyàn gbọ́dọ̀ ní láti lóye Bíbélì?
Bá A Ṣe Lè Múra Ọkàn àti Èrò Inú Wa Sílẹ̀
Ẹ́sírà tó jẹ́ olórí àwọn èèyàn Ọlọ́run láyé ọjọ́un “múra ọkàn-àyà rẹ̀ sílẹ̀ láti ṣe ìwádìí nínú òfin Jèhófà.” (Ẹ́sírà 7:10) Ǹjẹ́ àwọn ọ̀nà kan wà táwa náà lè gbà múra ọkàn wa sílẹ̀? Bẹ́ẹ̀ ni. A lè bẹ̀rẹ̀ nípa kíkọ́kọ́ ní èrò tó tọ́ nípa Ìwé Mímọ́. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sáwọn Kristẹni bíi tirẹ̀ pé: “Nígbà tí ẹ gba ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, èyí tí ẹ gbọ́ láti ọ̀dọ̀ wa, ẹ tẹ́wọ́ gbà á, kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ ènìyàn, ṣùgbọ́n, gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti jẹ́ lótìítọ́, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.” (1 Tẹsalóníkà 2:13) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn ló kọ Bíbélì, àtọ̀dọ̀ Jèhófà lohun tí wọ́n kọ ti wá. Mímọ kókó pàtàkì yìí á jẹ́ ká lè túbọ̀ fara mọ́ àwọn ohun tá a bá kà nínú Bíbélì.—2 Tímótì 3:16.
Ọ̀nà mìíràn tá a tún lè gbà múra ọkàn wa sílẹ̀ jẹ́ nípasẹ̀ àdúrà. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ẹ̀mí mímọ́ ni Ọlọ́run fi mú káwọn èèyàn kọ Bíbélì, ẹ̀mí mímọ́ yìí náà ni yóò ràn wá lọ́wọ́ láti lóye ohun tó wà nínú rẹ̀. A gbọ́dọ̀ gbàdúrà fún irú ìrànlọ́wọ́ bẹ́ẹ̀. Kíyè sí bí ọ̀kan lára àwọn tó kọ Sáàmù ṣe fi hàn pé kókó yìí jẹ òun lọ́kàn. Ó kọ̀wé pé: “Mú mi lóye, kí n lè máa pa òfin rẹ mọ́, kí n sì lè máa fi gbogbo ọkàn-àyà pa á mọ́.” (Sáàmù 119:34) Kì í ṣe ọgbọ́n tá a máa fi lóye ohun tó wà nínú Bíbélì nìkan ló yẹ ká gbàdúrà fún, ó tún yẹ ká gbàdúrà pé kí Ọlọ́run fún wa ní ọkàn tó máa jẹ́ ká lè gba ohun tí Bíbélì sọ. Ká tó lè lóye Bíbélì, ó pọn dandan ká múra tán láti tẹ́wọ́ gba ohun tó jẹ́ òótọ́.
Bó o ti ń ṣàṣàrò kó o lè mọrírì ohun tó ò ń kà, kíyè sí ọ̀nà tí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lè gbà ràn ọ́ lọ́wọ́. Ọ̀pọ̀ ìdí pàtàkì ló wà tó fi yẹ ká máa ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, àmọ́ èyí tó ṣe pàtàkì jù lọ lára àwọn ìdí náà ni pé yóò jẹ́ ká lè sún mọ́ Ọlọ́run. (Jákọ́bù 4:8) A óò lóye irú ẹni tí Jèhófà jẹ́ bá a ti ń kà nípa bó ṣe máa ń bójú tó onírúurú ipò, bí kò ṣe ń fọ̀rọ̀ àwọn tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ ṣeré, àti bó ṣe máa ń ṣe sáwọn tó bá kọ̀ ọ́ sílẹ̀. Olórí ìdí tó fi yẹ ká máa ka Bíbélì nígbà gbogbo ni pé ká lè túbọ̀ mọ Ọlọ́run dáadáa, èyí á sì mú kí àjọṣe wa pẹ̀lú rẹ̀ máa lágbára sí i.
Àwọn Ohun Tí Kì Í Jẹ́ Káwọn Kan Ní Èrò Tó Dáa
Kí ló lè ṣèdíwọ́ fún wa láti lóye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run? Ọ̀kan ni gbígba ohun kan gbọ́ nítorí pé àwọn tá a fẹ́ràn gba ohun náà gbọ́. Bí àpẹẹrẹ, o lè ka èrò àwọn kan àtohun tí wọ́n gbà gbọ́ sí pàtàkì gan-an. Àmọ́, ká láwọn èèyàn náà kò fara mọ́ ohun tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ńkọ́ tàbí tí wọn ò kà á sí pàtàkì? Nírú ipò báyìí, ó lè dìṣòro láti lóye ohun tí Bíbélì dìídì fi kọ́ni. Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi rọ̀ wá pé ká fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò àwọn ohun tí wọ́n ti fi kọ́ wa.—1 Tẹsalóníkà 5:21.
Màríà tó jẹ́ ìyá Jésù ní irú ìṣòro bẹ́ẹ̀. Ohun táwọn Júù gbà gbọ́ ni wọ́n fi kọ́ ọ láti kékeré. Ó máa ń pa Òfin Mósè mọ́ dáadáa, kò sì sí àní-àní pé ó máa ń lọ sí sínágọ́gù. Àmọ́ bó ti ń dàgbà, ó rí i pé Ọlọ́run kò fara mọ́ ọ̀nà ìjọsìn táwọn òbí òun fi kọ òun yẹn mọ́. Èyí mú kí Màríà tẹ́wọ́ gba ẹ̀kọ́ Jésù, ó sì wà lára àwọn tó kọ́kọ́ di ara ìjọ Kristẹni. (Ìṣe 1:13, 14) Èyí kò túmọ̀ sí pé Màríà kò bọ̀wọ̀ fáwọn òbí rẹ̀ tàbí pé kò ka ohun tí wọ́n gbà gbọ́ sí, kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe lóhun tó ṣe yẹn fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run. Bá a bá fẹ́ jàǹfààní látinú Bíbélì, àwa náà gbọ́dọ̀ ṣe bíi ti Màríà, ká fi ìgbọràn sí Ọlọ́run ṣáájú ìgbọràn sí ẹnikẹ́ni mìíràn.
Ó dunni pé, ọ̀pọ̀ èèyàn ni kò fi bẹ́ẹ̀ ka ohun tó wà nínú Bíbélì sí pàtàkì. Ó tẹ́ àwọn kan lọ́rùn kí wọ́n máa tẹ̀ lé àwọn ohun tí ìsìn wọn sọ àmọ́ tó jẹ́ pé irọ́ làwọn ohun náà dá lé. Ọ̀nà táwọn mìíràn sì ń gbà sọ̀rọ̀ àti bí wọ́n ṣe ń gbé ìgbésí ayé wọn fi hàn pé wọn ò ka òtítọ́ sí pàtàkì. Nípa bẹ́ẹ̀, títẹ́wọ́ gba ohun tí Bíbélì sọ máa ń gba pé kéèyàn yááfì àwọn ohun kan. Ó lè mú kí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ, àwọn aládùúgbò rẹ, tàbí àwọn tẹ́ ẹ jọ ń ṣiṣẹ́ kọ̀yìn sí ọ, kódà èyí lè ṣẹlẹ̀ nínú ìdílé rẹ pàápàá. (Jòhánù 17:14) Síbẹ̀, Sólómọ́nì, ọkùnrin ọlọ́gbọ́n náà, kọ̀wé pé: “Ra òtítọ́, má sì tà á.” (Òwe 23:23) Bó o bá mọyì òtítọ́ gan-an, Jèhófà á ràn ọ́ lọ́wọ́ láti lóye Bíbélì.
Ohun mìíràn tí kì í jẹ́ kéèyàn lóye ohun tí Bíbélì sọ ni kíkọ̀ láti fi ohun tó wà nínú rẹ̀ sílò. Jésù sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ẹ̀yin ni a yọ̀ǹda fún láti lóye àwọn àṣírí ọlọ́wọ̀ ti ìjọba ọ̀run, ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn wọnnì ni a kò yọ̀ǹda fún. Nítorí ọkàn-àyà àwọn ènìyàn yìí ti sébọ́, wọ́n sì ti fi etí wọn gbọ́ láìsí ìdáhùnpadà.” (Mátíù 13:11, 15) Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn tí Jésù wàásù fún ni kò ṣe nǹkan kan nípa ohun tí wọ́n gbọ́, tí wọn ò múra tán láti yí padà. Ọ̀rọ̀ wọn yàtọ̀ pátápátá sí ti ọkùnrin oníṣòwò arìnrìn-àjò tí Jésù mẹ́nu kàn nínú àkàwé kan! Bí oníṣòwò náà ti rí péálì kan tó níye lórí gan-an, kíá ló lọ ta gbogbo ohun tó ní kó lè ra péálì náà. Bó ṣe yẹ kí lílóye ohun tó wà nínú Bíbélì ṣeyebíye lójú tiwa náà nìyẹn.—Mátíù 13:45, 46.
Jíjẹ́ Ẹni Tó Ṣeé Kọ́ Lẹ́kọ̀ọ́
Ìṣòro tó burú jù lọ tí kì í jẹ́ kéèyàn lóye Bíbélì ni kéèyàn jẹ́ ẹni tí kì í fẹ́ kí ẹlòmíràn kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́. Ó lè ṣòro fún ẹnì kan láti fara mọ́ àwọn ohun tí kò mọ̀ tẹ́lẹ̀ tó bá dà bíi pé ẹni tó ń kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ náà rẹlẹ̀ sí i. Síbẹ̀, àwọn “tí kò mọ̀wé àti gbáàtúù” èèyàn ni àwọn àpọ́sítélì Jésù Kristi. (Ìṣe 4:13) Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń ṣàlàyé ohun tó mú wọn jẹ́ bẹ́ẹ̀, ó kọ̀wé pé: “Ẹ̀yin rí pípè tí òun pè yín, ẹ̀yin ará, pé kì í ṣe ọ̀pọ̀ ọlọ́gbọ́n nípa ti ara ni a pè, kì í ṣe ọ̀pọ̀ alágbára, kì í ṣe ọ̀pọ̀ àwọn tí a bí ní ilé ọlá; ṣùgbọ́n Ọlọ́run yan àwọn ohun òmùgọ̀ ayé, kí ó bàa lè kó ìtìjú bá àwọn ọlọ́gbọ́n ènìyàn.” (1 Kọ́ríńtì 1:26, 27) Bó o bá rí i pé ó máa ń ṣòro fún ọ láti ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ tí ẹnì kan tó rẹlẹ̀ sí ọ bá ń kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́, máa rántí pé Ọlọ́run ló ń lo ẹni yẹn láti kọ ọ́. Iyì wo ló tún ju kí Jèhófà, ‘Olùkọ́ni wa Atóbilọ́lá’ máa kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́?—Aísáyà 30:20; 54:13.
Ó ṣòro fún Náámánì, olórí ogun kan tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Síríà, láti gba ìtọ́ni látọ̀dọ̀ ẹnì kan tó rẹlẹ̀ sí i. Nígbà tó ń wá ìwòsàn sí àrùn ẹ̀tẹ̀ rẹ̀, ó lọ rí Èlíṣà tó jẹ́ wòlíì Jèhófà. Àmọ́ ìránṣẹ́ kan ló wá sọ fún Náámánì nípa ohun tí Ọlọ́run sọ pé yóò ṣe kó lè rí ìwòsàn. Ohun tí wọ́n ní kí Náámánì ṣe àti ọ̀nà tí wọ́n gbà sọ ọ́ mú kó ṣòro fún un láti gba ìtọ́ni náà pẹ̀lú ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀, débi pé ó kọ́kọ́ kọ̀ láti ṣe ohun tí wòlíì Ọlọ́run ní kó ṣe. Kò pẹ́ sígbà náà ni Náámánì wá yí èrò rẹ̀ padà tó sì rí ìwòsàn. (2 Àwọn Ọba 5:9-14) Irú nǹkan bẹ́ẹ̀ lè ṣẹlẹ̀ sáwa náà nígbà tá a bá bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. A lè kẹ́kọ̀ọ́ pé kí Ọlọ́run tó lè tẹ́wọ́ gbà wá kí ìwà wa sì máa múnú rẹ̀ dùn, ó di dandan ká yí bá a ṣe ń gbé ìgbésí ayé wa padà. Ǹjẹ́ a óò ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ láti jẹ́ kí ẹnì kan kọ́ wa lóhun tá a gbọ́dọ̀ ṣe? Kìkì àwọn tó bá lè gbà kí ẹlòmíràn kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ nìkan ló lè lóye Bíbélì.
Ọkùnrin kan tó wà nípò gíga lábẹ́ Káńdésì, ọbabìnrin àwọn ará Etiópíà, fi ànímọ́ kan tó dára hàn. Nígbà tó ń padà sílẹ̀ Áfíríkà nínú kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ̀, Fílípì sáré lọ bá a ó sì bá a sọ̀rọ̀. Fílípì wá béèrè lọ́wọ́ ọkùnrin náà bóyá ó lóye ohun tó ń kà. Ọkùnrin yìí jẹ́ ẹni tó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ ó sì fèsì pé: “Báwo ni mo ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀, láìjẹ́ pé ẹnì kan fi mí mọ̀nà?” Nígbà tí ọkùnrin náà wá lóye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ó ṣèrìbọmi. Lẹ́yìn ìgbà náà, “ó ń bá ọ̀nà rẹ̀ lọ, ó ń yọ̀.”—Ìṣe 8:27-39.
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lápapọ̀ kì í ṣe èèyàn jàǹkànjàǹkàn láwùjọ. Àwọn èèyàn tí wọ́n lọ ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nínú ilé wọn lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ lé ní mílíọ̀nù mẹ́fà. Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn ti rí i pé ayọ̀ tí kò lẹ́gbẹ́ ni ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àti níní òye ohun tó wà nínú rẹ̀ ń fúnni. Ìdí ni pé Bíbélì ń kọ́ni ní ọ̀nà tó dára jù lọ láti gbé ìgbésí ayé ẹni, ó ń ṣàlàyé ìrètí kan ṣoṣo tó dájú fún aráyé, ó sì ń fi ọ̀nà tá a lè gbà mọ Ọlọ́run hàn wá. Ayọ̀ yìí lè jẹ́ tìrẹ náà.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Ó ṣòro fún Náámánì láti gba ìtọ́ni tí ìránṣẹ́ kan tó rẹlẹ̀ sí i fún un
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Níní òye Bíbélì máa ń múnú wa dùn