Ìtàn Ìgbésí Ayé
A Pinnu Láti Sin Jèhófà
GẸ́GẸ́ BÍ RAIMO KUOKKANEN ṢE SỌ Ọ́
Ogun Àgbáyé Kejì bẹ́ sílẹ̀ nílẹ̀ Yúróòpù lọ́dún 1939, àwọn orílẹ̀-èdè tó para pọ̀ jẹ́ ilẹ̀ Soviet sì gbógun ti ilẹ̀ Finland tó jẹ́ orílẹ̀-èdè mi. Bàbá mi lọ wọ ẹgbẹ́ ogun ilẹ̀ Finland. Kò pẹ́ tí ọkọ̀ òfuurufú àwọn ọmọ ogun Rọ́ṣíà fi bẹ̀rẹ̀ sí í ju bọ́ǹbù síbi tá à ń gbé, èyí sì mú kí màmá mi sọ pé kí n lọ sọ́dọ̀ ìyá mi àgbà níbi tí ààbò wà díẹ̀.
LỌ́DÚN 1971, mò ń sìn gẹ́gẹ́ bíi míṣọ́nnárì lórílẹ̀-èdè Uganda ní Ìlà Oòrùn Áfíríkà. Lọ́jọ́ kan, nígbà tí mò ń wàásù láti ilé dé ilé, ọ̀pọ̀ èèyàn tí jìnnìjìnnì bá sáré kọjá lẹ́gbẹ̀ẹ́ mi. Mò ń gbúròó ìbọn, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í sáré lọ sílé. Bí ìró ọta ìbọn náà ti ń sún mọ́ tòsí ọ̀dọ̀ mi, mo bẹ́ sínú gọ́tà tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀nà. Báwọn ọta ìbọn ti ń fò kọjá lórí mi ni mò ń rá kòrò lọ sílé.
Mo mọ̀ pé kò sóhun tí mo lè ṣe láti bọ́ lọ́wọ́ àwọn wàhálà tí Ogun Àgbáyé Kejì fà, kí wá nìdí témi àti ìyàwó mi tún fi lọ ń fẹ̀mí ara wa wewu nínú rògbòdìyàn Ìlà Oòrùn Áfíríkà? Ohun tó fà á ni ìpinnu tá a ṣe láti sin Jèhófà.
Ohun Tó Fún Mi Níṣìírí Láti Fẹ́ Sin Ọlọ́run
Ìlú Helsinki lórílẹ̀-èdè Finland ni wọ́n ti bí mi lọ́dún 1934. Iṣẹ́ kunlékunlé ni Bàbá mi ń ṣe. Lọ́jọ́ kan, ó lọ kun ilé tí wọ́n ń lò fún ẹ̀ka ọ́fíìsì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nílẹ̀ Finland. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà náà sọ fún un nípa àwọn ìpàdé tí wọ́n máa ń ṣe. Nígbà tó délé, ó sọ fún màmá mi nípa àwọn ìpàdé wọ̀nyẹn. Màmá mi kò lọ sáwọn ìpàdé náà lákòókò yẹn, àmọ́ nígbà tó yá, òun àti Ẹlẹ́rìí kan tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí í jíròrò ọ̀rọ̀ Bíbélì pa pọ̀. Láìpẹ́, màmá mi bẹ̀rẹ̀ sí í fi àwọn ohun tó ń kọ́ sílò, ó sì ṣèrìbọmi gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ́dún 1940.
Ṣáájú ìgbà yẹn, ìyá mi àgbà ti mú mi lọ sí abúlé lákòókò Ogun Àgbáyé Kejì. Màmá mi sì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ̀wé láti ìlú Helsinki sí màmá rẹ̀ àti àbúrò rẹ̀, ó ń sọ ohun táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà gbọ́ fún wọn. Àwọn méjèèjì nífẹ̀ẹ́ sí ohun tí wọ́n gbọ́, wọ́n sì ń sọ ohun tí wọ́n ń kọ́ fún èmi náà. Àwọn arìnrìn-àjò tó ń ṣojú fáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń wá sọ́dọ̀ ìyá mi àgbà, wọ́n sì máa ń fún wa níṣìírí, àmọ́ mi ò tíì pinnu láti sin Ọlọ́run lákòókò yẹn.
Mo Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Kọ́ Ẹ̀kọ́ Tó Wá Mú Kí N Sin Ọlọ́run
Nígbà tí ogun parí lọ́dún 1945, mo padà sílùú Helsinki, màmá mi sì bẹ̀rẹ̀ sí í mú mi lọ sípàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Nígbà mìíràn, ilé fíìmù ni màá lọ dípò kí n lọ sípàdé. Ṣùgbọ́n màmá mi máa ń sọ àwọn nǹkan tó gbọ́ nípàdé fún mi, ó sì máa ń tẹnu mọ́ ọn fún mi pé Amágẹ́dọ́nì ti sún mọ́lé. Mo gbà pé òótọ́ ni, mi ò sì pa ìpàdé jẹ mọ́. Bí mo ṣe túbọ̀ ń mọyì òtítọ́ tí mò ń kọ́ látinú Bíbélì, bẹ́ẹ̀ ló túbọ̀ ń wù mí kí n máa lọ́wọ́ nínú àwọn ìgbòkègbodò inú ìjọ.
Mo máa ń gbádùn àwọn ìpàdé àyíká àtàwọn ìpàdé àgbègbè. Lọ́dún 1948, mo lọ sí ìpàdé àgbègbè tó wáyé ní tòsí ilé ìyá mi àgbà níbi tí mo ti lọ lo ìsinmi ìgbà ẹ̀rùn. Ọ̀rẹ́ mi kan fẹ́ ṣèrìbọmi ní àpéjọ àgbègbè náà, ó sì sọ pé kí èmi náà ṣèrìbọmi. Mo sọ fún un pé mi ò mú aṣọ tí màá fi wọnú omi wá, àmọ́ ó sọ pé lẹ́yìn tóun bá ti ṣèrìbọmi tán, mo lè lo aṣọ tòun. Mo gbà láti ṣe bẹ́ẹ̀, mo sì ṣèrìbọmi lọ́jọ́ kẹtàdínlọ́gbọ̀n oṣù June ọdún 1948, nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún mẹ́tàlá.
Lẹ́yìn tí ìpàdé àgbègbè náà parí, àwọn ọ̀rẹ́ màmá mi kan sọ fún un pé mo ti ṣèrìbọmi. Nígbà tó rí mi lẹ́yìn náà, ó fẹ́ mọ ìdí tí mo fi ṣe irú nǹkan pàtàkì bẹ́ẹ̀ láìkọ́kọ́ sọ fóun. Mo ṣàlàyé pé mo ti lóye àwọn ẹ̀kọ́ téèyàn kọ́kọ́ ń kọ́ nínú Bíbélì mo sì mọ̀ pé èmi ni màá jíhìn ohunkóhun tí mo bá ṣe fún Jèhófà.
Ìpinnu Tí Mo Ṣe Láti Sin Ọlọ́run Túbọ̀ Ń Lágbára Sí I
Àwọn ará nínú ìjọ ràn mí lọ́wọ́ láti jẹ́ kí ìpinnu mi láti sin Jèhófà lágbára sí i. A jọ máa ń lọ wàásù láti ilé dé ilé, ó sì fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ ni wọ́n máa ń fún mi níṣẹ́ nípàdé. (Ìṣe 20:20) Ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún ni mí nígbà tí mo kọ́kọ́ sọ àsọyé fún gbogbo èèyàn. Láìpẹ́ lẹ́yìn náà ni wọ́n yàn mí ṣe ìránṣẹ́ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nínú ìjọ wa. Gbogbo àwọn iṣẹ́ ìsìn wọ̀nyí ló mú kí n dàgbà nípa tẹ̀mí, àmọ́ mo ṣì ní láti borí ìbẹ̀rù èèyàn.
Láyé ìgbà yẹn, àwọn àkọlé gàdàgbà la fi máa ń kéde àsọyé ìpàdé àgbègbè fáwọn èèyàn. Àkọlé náà jẹ́ páálí fífẹ̀ méjì tá a kọ nǹkan sí, tá a sì fi okun tẹ́ẹ́rẹ́ so wọ́n pọ̀ létí, èyí téèyàn máa ń gbé kọ́rùn tí ọ̀kan á kọjú síwájú tí èkejì á sì kọjú sẹ́yìn onítọ̀hún. Nítorí bẹ́ẹ̀, àwọn kan máa ń pè wá láwọn tó ń gbé páálí kọ́rùn kiri.
Nígbà kan, mo wà ní igun òpópónà kan tó pa rọ́rọ́ mo sì gbé àkọlé kọ́rùn, ni mo bá rí àwọn ọmọ kíláàsì mi tí wọ́n ń bọ̀ lọ́nà ọ̀dọ̀ mi tààrà. Bí wọ́n ti ń kọjá lọ́dọ̀ mi, ojú tí wọ́n fi wò mí mú kí ẹ̀rù bà mí gan-an. Mo gbàdúrà pé kí Jèhófà fún mi nígboyà kí n lè dúró síbi tí mo wà pẹ̀lú àkọlé tí mo gbé kọ́rùn. Ọ̀nà tí mo gbà borí ìbẹ̀rù èèyàn lákòókò yẹn ràn mí lọ́wọ́ láti gbára dì fún àdánwò ńlá tó máa wáyé lórí ọ̀ràn àìlọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ológún.
Nígbà tó yá, ìjọba pàṣẹ fún èmi àtàwọn ọ̀dọ́kùnrin kan tá a jọ jẹ́ Ẹlẹ́rìí pé ká lọ forúkọ sílẹ̀ fún iṣẹ́ ológun. A lọ síbi tí wọ́n ti ń wọṣẹ́ ológun lóòótọ́, àmọ́ a sọ fún wọn tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ pé a ò lè wọ aṣọ ológun. Àwọn aláṣẹ náà sọ wá sí àtìmọ́lé, lẹ́yìn náà, ilé ẹjọ́ ní ká lọ ṣẹ̀wọ̀n oṣù mẹ́fà. Wọ́n tún ní ká ṣẹ̀wọ̀n oṣù mẹ́jọ mìíràn kún un, ìyẹn iye oṣù tá à bá fi ṣiṣẹ́ ológun. Nítorí náà, a lo àròpọ̀ ọdún kan àti oṣù méjì lọ́gbà ẹ̀wọ̀n nítorí pé a ò lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ológun.
A máa ń pàdé pọ̀ nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n lójoojúmọ́ láti jíròrò Bíbélì. Láwọn oṣù tá a lò níbẹ̀, ọ̀pọ̀ lára wa ka Bíbélì tán lẹ́ẹ̀mejì. Nígbà tá a ṣẹ̀wọ̀n wa tán, ìpinnu ọ̀pọ̀ jù lọ lára wa túbọ̀ lágbára ju ti tẹ́lẹ̀ lọ pé Jèhófà la óò máa sìn. Títí dòní olónìí, ọ̀pọ̀ lára àwọn ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí wọ̀nyẹn ṣì ń sin Jèhófà tọkàntọkàn.
Lẹ́yìn tí mo kúrò lẹ́wọ̀n, mo padà sọ́dọ̀ àwọn òbí mi. Kété lẹ́yìn náà ni mo mọ Veera. Ẹlẹ́rìí tó nítara tó sì ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣèrìbọmi ni. A ṣègbéyàwó lọ́dún 1957.
Ohun Tó Ṣẹlẹ̀ Lálẹ́ Ọjọ́ Kan Yí Ìgbésí Ayé Wa Padà
Lálẹ́ ọjọ́ kan, àwọn arákùnrin tó ń bójú tó iṣẹ́ ní ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà wá sọ́dọ̀ wa, ọ̀kan lára wọn sì bi wá bá a bá fẹ́ láti ṣe iṣẹ́ alábòójútó àyíká. Lẹ́yìn tá a gbàdúrà ní gbogbo òru ọjọ́ náà, mo tẹ ẹ̀ka ilé iṣẹ́ wa láago mo sì sọ pé a óò ṣe é. Gbígbà tá a gbà láti ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò-kíkún túmọ̀ sí pé màá fi iṣẹ́ mi tó ń mówó gọbọi wọlé sílẹ̀, àmọ́ a pinnu láti fi Ìjọba Ọlọ́run sípò àkọ́kọ́ nínú ìgbésí ayé wa. Nígbà tá a bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ arìnrìn-àjò lóṣù December ọdún 1957, ẹni ọdún mẹ́tàlélógún ni mí, Veera sì jẹ́ ẹni ọdún mọ́kàndínlógún. Ọdún mẹ́ta la fi gbádùn ìbẹ̀wò tá à sì ń ṣe sáwọn ìjọ àwọn èèyàn Jèhófà nílẹ̀ Finland, tá à ń fún wọn níṣìírí.
Nígbà tí ọdún 1960 ń parí lọ, wọ́n pè mí sí ilé ẹ̀kọ́ Watchtower Bible School of Gilead ní Brooklyn, New York. Àwa mẹ́ta tá a wá láti ilẹ̀ Finland máa gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ àkànṣe olóṣù mẹ́wàá nípa iṣẹ́ àbójútó ẹ̀ka. Àwọn ìyàwó wa kò bá wa lọ, wọn ń ṣiṣẹ́ ní ẹ̀ka ọ́fíìsì wa nílẹ̀ Finland.
Kí ìdálẹ́kọ̀ọ́ náà tó parí, wọ́n sọ fún mi pé kí n lọ sí ọ́fíìsì arákùnrin Nathan H. Knorr, ẹni tó ń bójú tó iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé nígbà yẹn. Arákùnrin Knorr yan èmi àti ìyàwó mi sí iṣẹ́ míṣọ́nnárì lórílẹ̀-èdè Malagasy, tá a mọ̀ sí Madagascar nísinsìnyí. Mo kọ̀wé sí Veera, mo sì béèrè èrò rẹ̀ nípa iṣẹ́ tí wọ́n yàn fún wa yẹn. Kíá ló dáhùn pé, “Ó ti yá.” Nígbà tí mo padà sílẹ̀ Finland, a bẹ̀rẹ̀ sí í palẹ̀ mọ́ kíákíá láti lọ máa gbé ní orílẹ̀-èdè Madagascar.
Ayọ̀ àti Ìjákulẹ̀
Lóṣù January ọdún 1962, a wọkọ̀ òfuurufú lọ́ sí Antananarivo tó jẹ́ olú ìlú orílẹ̀-èdè Madagascar. Kóòtù tó nípọn la wọ̀ a sì dé fìlà onírun nítorí pé ìgbà òtútù la kúrò nílẹ̀ Finland. Nítorí pé ilẹ̀ olóoru ni orílẹ̀-èdè Madagascar, kíákíá la yí ọ̀nà tá à ń gbà wọṣọ padà. Ilé míṣọ́nnárì tá a kọ́kọ́ gbé jẹ́ ilé kékeré kan tí kò ní ju yàrá ibùsùn kan ṣoṣo lọ. Àwọn tọkọtaya míṣọ́nnárì mìíràn ti wà níbẹ̀ ṣáájú wa, nítorí náà ọ̀dẹ̀dẹ̀ lèmi àti Veera máa ń sùn.
A bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ èdè Faransé tó jẹ́ èdè àjùmọ̀lò lórílẹ̀-èdè Madagascar. Èyí ò rọrùn fún wa rárá nítorí pé àwa méjèèjì kì í sọ èdè tí Arábìnrin Carbonneau tó ń kọ́ wa ní èdè Faransé ń sọ. Èdè Gẹ̀ẹ́sì ló ń lò láti fi kọ wá lédè Faransé, àmọ́ Veera kò gbọ́ èdè Gẹ̀ẹ́sì. Nítorí bẹ́ẹ̀, mo máa ń fi èdè Finland sọ ohun tí Arábìnrin Carbonneau ń kọ́ wa fún Veera. Lẹ́yìn ìyẹn la wá mọ̀ pé ìgbà tá a bá fi èdè Swedish ṣàlàyé àwọn ọ̀rọ̀ tó díjú fún Veera ló máa ń lóye wọn, ni mo wá bẹ̀rẹ̀ sí í fi èdè Swedish ṣàlàyé gírámà èdè Faransé fún un. Láìpẹ́ láìjìnnà, a tẹ̀ síwájú nínú èdè Faransé, a sì tún bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ èdè Malagasy, ìyẹn èdè táwọn èèyàn ibẹ̀ ń sọ.
Ọkùnrin kan tó ń sọ èdè Malagasy lẹni àkọ́kọ́ tí mo kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nílẹ̀ Madagascar. Màá wo àwọn ẹsẹ Bíbélì nínú Bíbélì èdè Finnish, a óò sì wá àwọn ẹsẹ wọ̀nyẹn nínú Bíbélì èdè Malagasy tirẹ̀. Ìwọ̀nba àlàyé Ìwé Mímọ́ díẹ̀ ni mo lè ṣe fún un, àmọ́ láìpẹ́ òtítọ́ látinú Bíbélì bẹ̀rẹ̀ sí í gbilẹ̀ lọ́kàn rẹ̀, ó sì tẹ̀ síwájú débi pé ó ṣèrìbọmi.
Arákùnrin Milton Henschel láti orílé-iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Brooklyn ṣèbẹ̀wò sí orílẹ̀-èdè Madagascar lọ́dún 1963. Kété lẹ́yìn náà, wọ́n ṣí ẹ̀ka ọ́fíìsì tuntun sí Madagascar, wọ́n sì yàn mí láti máa ṣe alábòójútó ẹ̀ka láfikún sí iṣẹ́ alábòójútó àyíká àti àgbègbè tí mò ń ṣe. Ní gbogbo àkókò yìí, Jèhófà bù kún wa gan-an. Láti ọdún 1962 sí ọdún 1970, iye àwọn akéde Ìjọba Ọlọ́run tó wà nílẹ̀ Madagascar pọ̀ sí i látorí èèyàn márùnlélọ́gọ́rin [85] sí irínwó ó lé mọ́kàndínláàádọ́rin [469] èèyàn.
Lọ́jọ́ kan lọ́dún 1970, bá a ti dé láti òde ẹ̀rí, a rí ìwé kan lẹ́nu ọnà wa tó sọ pé kí gbogbo àwọn míṣọ́nnárì tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà fara hàn ní ọ́fíìsì mínísítà fún ọ̀rọ̀ abẹ́lé. Òṣìṣẹ́ ìjọba kan sọ fún wa níbẹ̀ pé ìjọba ní ká fi orílẹ̀-èdè náà sílẹ̀ lójú ẹsẹ̀. Nígbà tí mo béèrè pé ẹ̀ṣẹ̀ wo la ṣẹ̀ tí wọ́n fi ní ká kúrò nílùú, aláṣẹ náà sọ fún wa pé: “Ọ̀gbẹ́ni Kuokkanen, o kò dá ẹ̀ṣẹ̀ kankan.”
Mo sọ fún un pé: “Ọdún kẹjọ rèé tá a ti wà níbi. Ibí yìí ti di ilé wa. A ò kàn lè fi ibi yìí sílẹ̀ bẹ́ẹ̀ yẹn.” Láìka gbogbo akitiyan wa sí, gbogbo míṣọ́nnárì pátá ló kúrò níbẹ̀ láàárín ọ̀sẹ̀ kan. Ìjọba ti ẹ̀ka ilé iṣẹ́ wa pa, ọ̀kan lára àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà níbẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí í bójú tó iṣẹ́ ìwàásù. Ká tó fi àwọn ará wa ọ̀wọ́n ní Madagascar sílẹ̀ ni wọ́n ti fún wa ní ibòmíràn tá a ó ti lọ ṣiṣẹ́, ìyẹn ilẹ̀ Uganda.
A Tún Bẹ̀rẹ̀ Iṣẹ́ Ìsìn Níbòmíràn
Lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀ tá a kúrò ní Madagascar, a dé Kampala tó jẹ́ olú ìlú ilẹ̀ Uganda. Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ la bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ èdè Luganda tó jẹ́ èdè tó máa ń dún bí orin, àmọ́ ó ṣòro kọ́. Àwọn míṣọ́nnárì yòókù tá a jọ wà níbẹ̀ kọ́kọ́ kọ́ Veera ní èdè Gẹ̀ẹ́sì, ó sì wá ṣeé ṣe fún wa láti fi èdè Gẹ̀ẹ́sì wàásù fáwọn èèyàn lọ́nà tó múná dóko.
Ìlú Kampala máa ń gbóná, kò sì bá Veera lára mu rárá. Nítorí náà, wọ́n ní ká lọ máa sìn nílùú Mbarara tí kò fi bẹ́ẹ̀ gbóná. Àwa ni Ẹlẹ́rìí tó kọ́kọ́ wá síbẹ̀, lọ́jọ́ àkọ́kọ́ tá a sì lọ wàásù, ohun kan ṣẹlẹ̀ tó fún wa láyọ̀ gan-an. Mò ń bá ọkùnrin kan sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, ni ìyàwó rẹ̀ bá jáde láti ilé ìgbọ́únjẹ. Orúkọ obìnrin náà ni Margaret, ó sì ti ń fetí sí gbogbo ohun tí mò ń sọ. Veera bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ Margaret lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó sì tẹ̀ síwájú nínú ẹ̀kọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ó ṣèrìbọmi, ó sì di akéde tó ń fìtara wàásù Ìjọba Ọlọ́run.
Ìjà Láwọn Ojú Pópó
Lọ́dún 1971, ogun abẹ́lé tó ṣẹlẹ̀ kò jẹ́ ká ní ìfọ̀kànbalẹ̀ mọ́ ní Uganda. Lọ́jọ́ kan, ìjà ṣẹlẹ̀ láyìíká ilé míṣọ́nnárì tá à ń gbé nílùú Mbarara. Ìgbà yẹn lohun tí mo sọ níbẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ mi yẹn ṣẹlẹ̀ sí mi.
Veera ti ṣáájú mi dé sí ilé míṣọ́nnárì tá à ń gbé, ẹ̀yìn ìyẹn ni mo wá rá kòrò gba inú gọ́tà láti ọ̀nà jíjìn títí ti mo fi délé káwọn sójà má bàa rí mi. A rọra fi fóòmù àtàwọn àga wa ṣe ibi ààbò sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan nínú ilé wa. Ọ̀sẹ̀ kan gbáko la fi wà nínú ilé láì jáde, tá à ń gbọ́ ìròyìn lórí rédíò. Nígbà mìíràn, ọta ìbọn máa ń ta ba ògiri bá a ṣe ba síbi ààbò tá a ṣe sí ẹ̀gbẹ́ kan yàrá wa. A kì í tanná lálẹ́, kí wọ́n má bàa mọ̀ pé a wà nínú ilé. Nígbà kan, àwọn sójà kan wá síwájú ilé wa, wọ́n sì ń pariwo. A ò gbin pínkín, ńṣe là ń fi ohun jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ gbàdúrà sí Jèhófà. Lẹ́yìn tí ìjà náà parí, àwọn aládùúgbò wa wá sọ́dọ̀ wa, wọ́n sì dúpẹ́ lọ́wọ́ wa fún ààbò tí wọ́n rí. Wọ́n gbà pé Jèhófà ló pa gbogbo wa mọ́, àwa náà sì gbà pẹ̀lú wọn.
Gbogbo nǹkan ń lọ déédéé títí di àárọ̀ ọjọ́ kan tá a gbọ́ lórí rédíò pé ìjọba ilẹ̀ Uganda ti fòfin de àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ẹni tó kéde náà sọ pé kí gbogbo àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà padà sínú ẹ̀sìn tí wọ́n ti ń ṣe tẹ́lẹ̀. Mo lọ pàrọwà sáwọn aláṣẹ ìjọba nítorí ọ̀rọ̀ yìí, àmọ́ pàbó ló já sí. Lẹ́yìn náà, mo lọ sí ọ́fíìsì Ààrẹ Idi Amin, mo sì ni kí wọ́n fún mi láyè láti bá a sọ̀rọ̀. Olùgbàlejò tó ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀ sọ fún mi pé ọwọ́ ààrẹ dí. Mo padà lọ síbẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà àmọ́ kò ṣeé ṣe fún mi láti rí ààrẹ bá sọ̀rọ̀. Níkẹyìn, a ní láti kúrò ní Uganda lóṣù July ọdún 1973.
Ọdún Kan Di Ọdún Mẹ́wàá
Bí ọkàn wa ṣe bà jẹ́ nígbà tí wọ́n lé wa kúrò lórílẹ̀-èdè Madagascar lọkàn wa tún ṣe bà jẹ́ nígbà tá a fẹ́ fi àwọn ará wa ọ̀wọ́n nílẹ̀ Uganda sílẹ̀. Ká tó lọ síbi tuntun tí wọ́n yàn wá sí lórílẹ̀-èdè Senegal, a kọ́kọ́ lọ sílẹ̀ Finland. Ibẹ̀ ni wọ́n ti sọ fún wa pé ká má lọ sílẹ̀ Áfíríkà mọ́, pé ká dúró sí orílẹ̀-èdè Finland. Ó jọ pé iṣẹ́ míṣọ́nnárì wa ti parí nìyẹn. A wá ń ṣe aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe nílẹ̀ Finland, lẹ́yìn ìyẹn, a tún ṣe iṣẹ́ alábòójútó àyíká.
Nígbà tó fi máa di ọdún 1990, àtakò tí wọ́n ń ṣe sí iṣẹ́ wa lórílẹ̀-èdè Madagascar ti rọlẹ̀, orílé-iṣẹ́ wa ní Brooklyn sì ṣe ohun kan tó yà wá lẹ́nu, wọ́n sọ pé ṣé a lè lọ lo ọdún kan ní Madagascar? Ó wù wá láti lọ àmọ́ ìṣòro ńlá méjì kan dojú kọ wá. Bàbá mi tó ti dàgbà ń fẹ́ àbójútó, ara Veera kò sì le. Inú mi bà jẹ́ gan-an nígbà tí bàbá mi kú lóṣù November ọdún 1990, àmọ́ ara Veera tó ti ń yá sí i fún wa nírètí àtipadà sẹ́nu iṣẹ́ míṣọ́nnárì. A padà lọ sórílẹ̀-èdè Madagascar lóṣù September ọdún 1991.
Ọdún kan péré ni wọ́n ní ká lọ lò ní Madagascar, àmọ́ a lo ọdún mẹ́wàá gbáko. Láàárín àkókò yẹn, iye àwọn akéde Ìjọba Ọlọ́run pọ̀ sí i láti ẹgbẹ̀rún mẹ́rin [4,000] sí ẹgbẹ̀rún mọ́kànlá àti ẹgbẹ̀ta [11,600] èèyàn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mò ń gbádùn iṣẹ́ míṣọ́nnárì gan-an, síbẹ̀ ìrẹ̀wẹ̀sì máa ń bá mi nígbà míì, táá máa ṣe mí bíi pé mi ò bójú tó ìlera ìyàwó mi ọ̀wọ́n bó ti tọ́ àti bó ti yẹ, àti pé mi ò ráyè gbọ́ tiẹ̀. Àmọ́ Jèhófà fún àwa méjèèjì lókun láti máa bá iṣẹ́ wa lọ. Níkẹyìn, lọ́dún 2001, a padà sílẹ̀ Finland a sì wá ń ṣiṣẹ́ ní ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà níbẹ̀. Ìtara tá a ní fún Ìjọba Ọlọ́run ṣì pọ̀ gan-an. Bẹ́ẹ̀ la tún máa ń rántí ilẹ̀ Áfíríkà nígbà gbogbo. A ti pinnu láti máa ṣe ohun tó wu Jèhófà níbikíbi tó bá yàn wá sí.—Aísáyà 6:8.
[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 12]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
ILẸ̀ FINLAND
YÚRÓÓPÙ
[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 14]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
ÁFÍRÍKÀ
MADAGASCAR
[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 15]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
ÁFÍRÍKÀ
UGANDA
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]
Ọjọ́ ìgbéyàwó wa
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14, 15]
A ti ẹnu iṣẹ́ alábòójútó àyíká nílẹ̀ Finland, lọ́dún 1960 . . .
. . . bọ́ sẹ́nu iṣẹ́ míṣọ́nnárì nílẹ̀ Madagascar, lọ́dún 1962
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Èmi àti Veera lónìí