Ọkùnrin Tó Ṣiṣẹ́ Takuntakun Láti Ṣe Bíbélì Táwọn Èèyàn Lè Máa Kà
Akíkanjú ọkùnrin kan wà tó ń jẹ́ Seraphim. Wọ́n bà á lórúkọ jẹ́, wọ́n dojú tì í, wọ́n sì pa á tì. Ìlà oòrùn ilẹ̀ Siberia tó jẹ́ ilẹ̀ olótùútù ló kú sí. Ìwọ̀nba èèyàn díẹ̀ ló rántí pé ọ̀kan pàtàkì ni lára àwọn tó mú ìtẹ̀síwájú bá ìmọ̀ táwọn ọmọ ilẹ̀ Gíríìsì bíi tiẹ̀ ní nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Iṣẹ́ akọni tó ṣe láti rí i pé Bíbélì tẹ àwọn èèyàn lọ́wọ́ wà lára ohun tó ṣekú pa á.
ÌGBÀ tí ilẹ̀ Gíríìsì wà lára Ilẹ̀ Ọba Ottoman ni Seraphim gbé láyé. Ọmọ Ìjọ Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì Ilẹ̀ Gíríìsì kan tó kẹ́kọ̀ọ́ jinlẹ̀, tó ń jẹ́ George Metallinos sọ pé, “kò fi bẹ́ẹ̀ sí ilé ìwé gidi kan” lásìkò náà, àti pé “ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn ni kò kàwé,” títí kan àwọn àlùfáà.
Lásìkò náà, ẹ̀ka èdè Gíríìkì táwọn ọ̀mọ̀wé ń sọ, ìyẹn Kóínè, ti yàtọ̀ gan-an sí èdè Gíríìkì tó wà lẹ́nu àwọn aráàlú, èyí tó jẹ́ pé ó ní onírúurú ẹ̀ka èdè. Ìyàtọ̀ náà pọ̀ débi pé àwọn tí kò lọ sílé ìwé ò lóye Kóínè yìí mọ́, bẹ́ẹ̀ èdè yẹn ni wọ́n fi kọ Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì. Nítorí àríyànjiyàn tí ìyàtọ̀ yìí dá sílẹ̀, àwọn aláṣẹ ṣọ́ọ̀ṣì sọ pé ẹ̀ka èdè Gíríìkì tó ń jẹ́ Kóínè, tó jẹ́ pé kò yé àwọn aráàlú, làwọn fọwọ́ sí kí wọ́n máa lò nínú ìsìn.
Ipò tí orílẹ̀-èdè Gíríìsì wà nìyẹn ní nǹkan bí ọdún 1670 tí wọ́n bí Stephanos Ioannis Pogonatus. Ìdílé olókìkí kan ní erékùṣù Lesbos nílẹ̀ Gíríìsì ni wọ́n bí i sí. Àwọn tálákà àti púrúǹtù pọ̀ gan-an ní erékùṣù náà. Nítorí pé kò fi bẹ́ẹ̀ sí ilé ìwé, ilé àwọn ọkùnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé tó wà ní erékùṣù náà ni Stephanos ti lọ sílé ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀. Ọ̀dọ́mọdé ló jẹ́ nígbà tó ti gba oyè díákónì ní Ìjọ Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì Ilẹ̀ Gíríìsì, tí wọ́n sì sọ ọ́ ní Seraphim.
Ní nǹkan bí ọdún 1693, Seraphim lọ sí Kọnsitantinópù (tó ń jẹ́ Istanbul báyìí, nílẹ̀ Turkey) láti lọ gba ìmọ̀ kún ìmọ̀. Nígbà tó yá, ìmọ̀ àti òye tó ní mú káwọn ọ̀tọ̀kùlú ilẹ̀ Gíríìsì máa wò ó bí èèyàn pàtàkì. Láìpẹ́ sígbà náà, àwọn ẹgbẹ́ ajàjàgbara ilẹ̀ Gíríìsì kan tó ń ṣẹgbẹ́ wọn lábẹ́lẹ̀ rán an lọ sọ́dọ̀ Peter Ńlá tó jẹ́ ọba ilẹ̀ Rọ́ṣíà. Ìrìn-àjò Seraphim sílùú Moscow gbé e gba ọ̀pọ̀ ibi nílẹ̀ Yúróòpù nígbà tó ń lọ àti nígbà tó ń bọ̀, ó sì jẹ́ kó mọ̀ nípa àwọn àyípadà tó ń dé bá ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn àti ìmọ̀ àwọn èèyàn. Ó lọ sí ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì lọ́dún 1698, ó sì dojúlùmọ̀ àwọn ẹni ńláńlá ní ìlú London àti Oxford. Wọ́n wá fi òun àti Bíṣọ́ọ̀bù Àgbà ti ìlú Canterbury, tó jẹ́ olórí ìjọ Áńgílíkà mọ́ra wọn, èyí sì padà ṣe Seraphim láǹfààní gan-an.
Ó Tẹ Bíbélì Jáde
Nígbà tí Seraphim wà ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, ó rí i pé ó ṣe pàtàkì gan-an káwọn tó ń sọ èdè Gíríìkì ní Bíbélì “Májẹ̀mú Tuntun” (ìyẹn Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì) míì tó lè tètè yéni. Seraphim wá lo Bíbélì tí ọkùnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé kan tó tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Maximus ṣe ní ohun tó lé ní àádọ́ta ọdún ṣáájú ìgbà yẹn láti fi bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìtumọ̀ Bíbélì tuntun tirẹ̀ tó máa jẹ́ èyí tí kò láṣìṣe, tó sì máa tètè yéni. Ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ yẹn tìtara-tìtara, àmọ́ kò pẹ́ tówó fi tán lọ́wọ́ ẹ̀. Ó dà bíi pé ọ̀rọ̀ yẹn máa lójú nígbà tí Bíṣọ́ọ̀bù Àgbà ti ìlú Canterbury yẹn sọ pé òun máa fún un lówó tí yóò máa fi bá iṣẹ́ náà lọ. Ohun tí Bíṣọ́ọ̀bù Àgbà náà ṣe múnú Seraphim dùn gan-an. Ó wá lọ ra bébà táá fi tẹ Bíbélì náà, ó sì tún lọ ṣètò sílẹ̀ lọ́dọ̀ ẹni tó máa tẹ̀ ẹ́.
Ṣùgbọ́n ìdajì Ìhìn Rere Lúùkù ni wọ́n tẹ̀ ẹ́ dé tówó tó rí gbà fi tán. Àyípadà tó dé bá ọ̀rọ̀ ìṣèlú ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì kò jẹ́ kí Bíṣọ́ọ̀bù Àgbà náà tún lè fún un lówó sí i mọ́. Àmọ́ Seraphim ò jẹ́ kí ìyẹn dá òun dúró. Ó lọ bá àwọn ọlọ́rọ̀ kan fún ìrànlọ́wọ́, ó sì sa gbogbo ipá rẹ̀ láti tẹ Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì tó jẹ́ àtúnṣe lórí ti tẹ́lẹ̀ yìí jáde lọ́dún 1703. Ẹgbẹ́ Tó Ń Ṣètìlẹyìn fún Iṣẹ́ Ìjíhìnrere Nílẹ̀ Òkèèrè [Society for Propagating the Gospel in Foreign Parts] tiẹ̀ fún un lára owó tó fi ṣiṣẹ́ náà.
Nígbà tí Maximus ń ṣe ìtumọ̀ Bíbélì alápá méjì tó ṣe, ó fi Ìwé Mímọ́ ní èdè Gíríìkì tí wọ́n ṣe ní ìpilẹ̀ṣẹ̀ kún un. Bíbélì rẹ̀ yìí fẹ̀, ó sì wúwo. Ṣùgbọ́n ní ti àtúnṣe Bíbélì ti Seraphim ṣe, lẹ́tà ọ̀rọ̀ tó wẹ́rẹ́ ni wọ́n fi tẹ̀ ẹ́, ìtumọ̀ èdè Gíríìkì tó bóde mu nìkan sì ni. Ó fúyẹ́, kò sì tún wọ́n tó ti Maximus.
Ó Dá Kún Àríyànjiyàn Tó Wà Nílẹ̀
Ọ̀mọ̀wé George Metallinos sọ pé: “Láìsí àní-àní, Bíbélì tó bóde mu yìí jẹ́ ohun táwọn èèyàn ń fẹ́ gan-an. Àmọ́ Seraphim lo àǹfààní yẹn láti fọ̀rọ̀ gún àwọn àlùfáà kan tó lòdì sí ṣíṣe ìtumọ̀ Bíbélì lára.” Ohun tó sọ nínú ojú ewé ìṣáájú Bíbélì rẹ̀ bí àwọn àlùfáà nínú, ó ní ‘tìtorí àwọn àlùfáà àtàwọn aṣáájú ìjọ kan tí kò mọ èdè Gíríìkì tó ń jẹ́ Kóínè lòun ṣe ṣe Bíbélì náà, pé kí agbára Ẹ̀mí Tó Mọ́ Jù Lọ lè mú kó ṣeé ṣe fún wọn láti ka ohun tó wá látinú Bíbélì ìpilẹ̀ṣẹ̀ ní àkàyé, kí wọ́n wá sọ ìtumọ̀ rẹ̀ fáwọn ọmọ ìjọ.’ (Ìwé The Translation of the Bible Into Modern Greek—During the 19th Century) Bí Seraphim ṣe dá sí àríyànjiyàn lórí ọ̀rọ̀ ṣíṣe ìtumọ̀ Bíbélì tó ti ń jà ràn-ìn nínú Ìjọ Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì Ilẹ̀ Gíríìsì nìyẹn.
Àwọn tó sọ pé ó dára láti máa ṣe ìtumọ̀ Bíbélì sọ pé bí àwọn èèyàn bá ṣe mọ Bíbélì tó ni wọ́n ṣe máa tẹ̀ síwájú tó nínú ìjọsìn Ọlọ́run tí ìwà wọn á sì dára sí i. Wọ́n sì gbà pé ó yẹ káwọn àlùfáà mọ Ìwé Mímọ́ ju bí wọ́n ṣe mọ̀ ọ́n lọ. Wọ́n sì tún gbà gbọ́ pé kò sí èdè téèyàn ò lè fi ṣàlàyé ẹ̀kọ́ Bíbélì.—Ìṣípayá 7:9.
Ní tàwọn tó ta ko ṣíṣe ìtumọ̀ Bíbélì, ohun tí wọ́n fi ń bojú ni pé, báwọn èèyàn bá túmọ̀ Bíbélì, wọ́n á gbé èrò tara wọn wọ̀ ọ́, èyí ò sì ní jẹ́ kí Ìjọ Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì láṣẹ lórí ohun tó yẹ kó jẹ́ ìtumọ̀ àti àlàyé ẹ̀kọ́ inú Bíbélì. Bẹ́ẹ̀, ohun tó ń bà wọ́n lẹ́rù gan-an ni pé àwọn ìjọ Pùròtẹ́sítáǹtì ń fi ìtumọ̀ Bíbélì tí wọ́n ń ṣe dín agbára Ìjọ Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì Ilẹ̀ Gíríìsì kù. Ọ̀pọ̀ lára àwọn àlùfáà Ìjọ Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì gbà pé ojúṣe àwọn ni láti dènà ohunkóhun tó bá fẹ́ jẹ́ káwọn ìjọ Pùròtẹ́sítáǹtì rọ́wọ́ mú, àní títí kan gbogbo akitiyan láti mú kí Bíbélì túbọ̀ yé àwọn èèyàn. Bí ọ̀rọ̀ ṣíṣe ìtumọ̀ Bíbélì ṣe di ohun tó ń dá wàhálà sílẹ̀ láàárín àwọn ìjọ Pùròtẹ́sítáǹtì àti Ìjọ Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì nìyẹn.
Kì í ṣe pé Seraphim fẹ́ kúrò nínú Ìjọ Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì, àmọ́ ó ń táṣìírí àwọn àlùfáà tó jẹ́ alátakò rẹ̀ pé òpè àti ẹlẹ́tanú ni wọ́n. Ohun tó kọ sí ọ̀rọ̀ ìṣáájú inú Bíbélì “Májẹ̀mú Tuntun” tó ṣe ni pé: “Gbogbo Kristẹni tó bẹ̀rù Ọlọ́run ló yẹ kó máa ka Bíbélì Mímọ́” láti lè “di ẹni tó ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Kristi, kó sì máa tẹ̀ lé ohun tí [Kristi] kọ́ni.” Seraphim sọ ọ́ gbangba pé ọmọ Èṣù lẹni tó bá ní kéèyàn máa ka Ìwé Mímọ́.
Àwọn Alátakò Gbógun Ti Seraphim
Nígbà tí Bíbélì tí Seraphim túmọ̀ dé ilẹ̀ Gíríìsì, inú bí àwọn olórí Ìjọ Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì. Ni wọ́n bá ka Bíbélì tuntun náà léèwọ̀. Wọ́n dáná sun òmíràn lára rẹ̀, wọ́n sì sọ pé ńṣe làwọn yóò lé ẹnikẹ́ni tó bá ní Bíbélì yẹn lọ́wọ́ tàbí ẹni tó bá ń kà á kúrò nínú ìjọ. Bíṣọ́ọ̀bù Gabriel Kẹta fòfin de Bíbélì Seraphim yìí, ó ní wọn ò gbọ́dọ̀ tà á mọ́, pé kò yẹ kí Seraphim ṣe é, àti pé kò wúlò.
Gbogbo èyí kò kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá Seraphim o, àmọ́ ó rí i pé ó yẹ kóun túbọ̀ ṣọ́ra. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn olórí Ìjọ Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ka Bíbélì yìí léèwọ̀, àwọn àlùfáà àtàwọn ọmọ ìjọ kan fẹ́ràn rẹ̀. Ó sì rí i tà gan-an. Àmọ́, wàhálà òun àtàwọn alágbára tó jẹ́ alátakò rẹ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ni o.
Àwọn Ohun Tó Ṣekú Pa Seraphim
Yàtọ̀ sí pé Seraphim fẹ́ kí Bíbélì máa tẹ àwọn aráàlú lọ́wọ́, ó tún wà nínú ẹgbẹ́ olóṣèlú àti tàwọn ajàjàgbara. Torí kó lè ráyè ṣe nǹkan méjèèjì yìí dáadáa ló ṣe padà lọ sílùú Moscow nígbà ẹ̀ẹ̀rùn ọdún 1704. Ó di ọ̀rẹ́ Peter Ńlá tímọ́tímọ́, ó sì fìgbà kan jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n tó ń kọ́ni ní ilé ẹ̀kọ́ gíga Russian Royal Academy. Àmọ́ Seraphim padà sí ìlú Kọnsitantinópù lọ́dún 1705 nítorí pé ó ń ṣàníyàn nípa ohun tó lè ṣẹlẹ̀ sí Bíbélì tó túmọ̀.
Nígbà tí Seraphim wá tún Bíbélì yẹn tẹ̀ lọ́dún 1705 yìí, ó yọ ojú ewé ìṣáájú tó fi sọ̀rọ̀ gún àwọn àlùfáà lára nínú èyí tó kọ́kọ́ tẹ̀ kúrò. Ó wá fi ọ̀rọ̀ ìṣáájú ráńpẹ́ tó gba àwọn èèyàn níyànjú pé kí wọ́n máa ka Bíbélì dípò rẹ̀. Ó rí Bíbélì tó ṣe àtúntẹ̀ rẹ̀ yìí tà gan-an ju ti tẹ́lẹ̀ lọ, kò sì sí ẹ̀rí kankan tó fi hàn pé àwọn àlùfáà bínú rárá nípa Bíbélì náà.
Àmọ́ lọ́dún 1714, ọmọ ilẹ̀ Gíríìsì kan tó jẹ́ arìnrìn-àjò tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Alexander Helladius, ẹni tó ta ko ṣíṣe ìtumọ̀ Bíbélì, ṣe jàǹbá ńlá kan fún Seraphim. Nínú ìwé rẹ̀ tó pè ní Status Præsens Ecclesiæ Græcæ (Ipò tí Ṣọ́ọ̀ṣì Ilẹ̀ Gíríìsì Wà Báyìí), ó bẹnu àtẹ́ lu ìtumọ̀ Bíbélì Seraphim burúkú-burúkú, àtàwọn tó túmọ̀ rẹ̀. Helladius fi odindi orí kan nínú ìwé rẹ̀ sọ̀rọ̀ nípa Seraphim, ó ní olè, gbájúẹ̀, púrúǹtù àti afàwọ̀rajà tó jẹ́ oníwà ìbàjẹ́ ni. Ǹjẹ́ òótọ́ làwọn ẹ̀sùn tó fi kàn án yìí? Òǹkọ̀wé kan tó ń jẹ́ Stylianos Bairaktaris sọ irú ojú tí ọ̀pọ̀ ọ̀mọ̀wé fi ń wo Seraphim, ó ní ó jẹ́ ‘òṣìṣẹ́ gidi àti aṣáájú tó jẹ́ ọlọ́pọlọ pípé’ táwọn kan ń gbéjà kò tìtorí pé òye rẹ̀ ta tàwọn èèyàn ìgbà ayé rẹ̀ yọ. Síbẹ̀, ìwé tí Helladius kọ yìí wà lára ohun tó ṣekú pa Seraphim.
Wọ́n Ń Wo Seraphim Tìfura-Tìfura
Nígbà tí Seraphim fi máa padà sí ilẹ̀ Rọ́ṣíà lọ́dún 1731, Peter Ńlá ti kú. Ló bá di pé àwọn aláṣẹ ilẹ̀ Rọ́ṣíà ò kà á sí mọ́. Ọbabìnrin Anna Ivanovna tó ń ṣàkóso níbẹ̀ kò sì fẹ́ ohunkóhun tó bá lè dá wàhálà sílẹ̀ nínú ìjọba rẹ̀. Ní January 1732, àhesọ ọ̀rọ̀ kan ń lọ káàkiri ìlú St. Petersburg pé amí kan tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Gíríìsì ti wọ ilẹ̀ Rọ́ṣíà, ó sì ti ń ṣèpalára fún ilẹ̀ náà. Seraphim lẹ́ni tí wọ́n fúra sí yẹn o. Bí wọ́n ṣe fàṣẹ ọba mú un lọ sí ilé àwọn ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé tó wà ní àdúgbò Nevsky nìyẹn láti lọ wádìí ọ̀rọ̀ lẹ́nu rẹ̀. Àṣé ìwé tí Helladius kọ onírúurú ẹ̀ṣùn tó fi kan Seraphim sí ti wà nílẹ̀ dè é ní ilé àwọn ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé náà. Ẹ̀ẹ̀mẹ́ta ni Seraphim tó jẹ́ díákónì kọ̀wé láti fi ṣàlàyé ara rẹ̀ pé irọ́ ni gbogbo ẹ̀ṣùn náà. Nǹkan bí oṣù márùn-ún ni wọ́n fi wádìí ọ̀rọ̀ lẹ́nu rẹ̀, síbẹ̀ gbogbo àlàyé rẹ̀ kò tà létí wọn nítorí báwọn èèyàn ṣe fúra sí i tó.
Níwọ̀n bí wọn ò ti rí ẹ̀rí gidi kan tó fi hàn pé Seraphim jẹ̀bi, wọn kò dájọ́ ikú fún un. Síbẹ̀, àwọn aláṣẹ Rọ́ṣíà ò tú u sílẹ̀ nítorí àwọn ẹ̀sùn tí Helladius ti fi kàn án. Wọ́n wá rán díákónì tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Gíríìsì yìí lọ sí ẹ̀wọ̀n gbére nílẹ̀ Siberia. Wọ́n kọ ọ́ síwèé tí wọ́n fi ṣèdájọ́ rẹ̀ pé nítorí ẹ̀sùn tó wà nínú “ìwé àròkọ tí Helladius òǹkọ̀wé ọmọ ilẹ̀ Gíríìsì kọ” làwọn fi dá a lẹ́jọ́. Bí wọ́n ṣe fi ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ de Seraphim lọ sí ìlà oòrùn ilẹ̀ Siberia ní oṣù July ọdún 1732 nìyẹn, tí wọ́n sì sọ ọ́ sí ọgbà ẹ̀wọ̀n burúkú kan tó ń jẹ́ Okhotsk.
Nǹkan bí ọdún mẹ́ta lẹ́yìn náà ni Seraphim kú síbi tí wọ́n pa á tì sí, tó sì dẹni ìgbàgbé. Lóòótọ́, ọ̀pọ̀ nǹkan míì tó ṣe àti ọ̀nà tó gbà ṣe wọ́n kò tọ̀nà kò sì bọ́gbọ́n mu, síbẹ̀ Bíbélì tó túmọ̀ jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn Bíbélì tó ti wà lédè Gíríìkì òde òní báyìí táwọn èèyàn ń kà.a Lára irú àwọn Bíbélì tó wà ní èdè Gíríìkì òde òní bẹ́ẹ̀ ni Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun tó tètè yéni, tó sì tún wà ní onírúurú èdè. A dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà Ọlọ́run gan-an ni pé ó dáàbò bo Ọ̀rọ̀ rẹ̀ káwọn èèyàn níbi gbogbo bàa lè “wá sí ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́”!—1 Tímótì 2:3, 4.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo àpilẹ̀kọ náà “Akitiyan Láti Tẹ Bíbélì Jáde Lédè Gíríìkì Òde Òní” nínú Ilé Ìṣọ́ November 15, 2002, ojú ìwé 26 sí 29.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]
Peter Ńlá
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 10]
Fọ́tò: Nípasẹ̀ ìyọ̀ǹda American Bible Society