ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w06 8/15 ojú ìwé 8-11
  • Ìtẹ̀síwájú Tó Dùn Mọ́ni ní Erékùṣù Ẹlẹ́wà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìtẹ̀síwájú Tó Dùn Mọ́ni ní Erékùṣù Ẹlẹ́wà
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Ìsọ̀rí
  • Ìtẹ̀síwájú Àrà Ọ̀tọ̀ Kan
  • Àwọn Ọmọdé Tó Ń Kópa Nínú Iṣẹ́ Ọlọ́run Ń Pọ̀ Sí I
  • Báwọn Ọmọ Náà Ṣe Ń Dàgbà Sí I
  • Wọ́n Borí Ìdíwọ́ Kí Wọ́n Lè Tẹ̀ Síwájú
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
w06 8/15 ojú ìwé 8-11

Ìtẹ̀síwájú Tó Dùn Mọ́ni ní Erékùṣù Ẹlẹ́wà

TÉÈYÀN bá dé ilẹ̀ Taiwan tó jẹ́ erékùṣù tó sì rí bí ewéko tútù yọ̀yọ̀ ṣe bolẹ̀ níbẹ̀, ó máa ń wuni gan-an. Ní ilẹ̀ olóoru yìí, èèhù ìrẹsì tó máa ń tutù yọ̀yọ̀ máa ń di aláwọ̀ góòlù tí èso rẹ̀ bá ti gbẹ nígbà ìkórè. Igbó kìjikìji tó tutù yọ̀yọ̀ ló bo àwọn gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè ibẹ̀. Àwọn ewéko igbó àti ewéko ara òkè yìí dùn-ún wò, wọ́n sì tuni lára ju àárín àwọn ìlú ńlá tí èrò kún fọ́fọ́ lọ. Ohun tí ará ilẹ̀ Potogí tó kọ́kọ́ dé erékùṣù náà rí nìyẹn tó fi sọ ibẹ̀ ní Ilha Formosa, tó túmọ̀ sí “Erékùṣù Ẹlẹ́wà.”

Láìsí àní-àní, erékùṣù ẹlẹ́wà ni Taiwan, bó tilẹ̀ jẹ́ pé erékùṣù kékeré ni. Kò gùn ju irínwó kìlómítà ó dín mẹ́wàá [390] lọ, kò sì fẹ̀ ju ọgọ́jọ [160] kìlómítà lọ níbi tó ti fẹ̀ jù. Òkè ńláńlá ló gba erékùṣù náà. Òkè Yü Shan (ìyẹn Òkè Morrison) tó wà níbẹ̀ ga ju Òkè Fuji ilẹ̀ Japan àti Òkè Cook ilẹ̀ New Zealand lọ. Pẹ̀tẹ́lẹ̀ etíkun tí kò fẹ̀, tó yí àwọn òkè ibẹ̀ ká, làwọn ìlú táwọn èèyàn ilẹ̀ Taiwan kún fọ́fọ́ wà. Àwọn èèyàn ibẹ̀ sì ti lé ní mílíọ̀nù méjìlélógún báyìí.

Ìtẹ̀síwájú Àrà Ọ̀tọ̀ Kan

Àmọ́, ìtẹ̀síwájú kan tún ń bá a lọ lọ́nà tó túbọ̀ ń hàn kedere ní Taiwan, ìyẹn ni ìtẹ̀síwájú nínú ìgbòkègbodò àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ohun tó ń fa ìtẹ̀síwájú yìí ni ìtara tí àwọn ará lọ́mọdé lágbà fi ń ṣiṣẹ́ ìwàásù látìgbà tí wọ́n bá ti mọ Jèhófà Ọlọ́run tòótọ́. Bí iye àwọn tó ń ṣakitiyan lójú méjèèjì láti ran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́ kí wọ́n lè mọ Jèhófà àtàwọn ohun tó fẹ́ ṣe lọ́jọ́ iwájú ṣe ń pọ̀ sí i wúni lórí gan-an ni.

Bí àwọn ará ṣe ń pọ̀ sí i, ó di dandan kí ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní Taiwan wá ibi tó fẹ̀ ju ibi tí wọ́n ń lò nílùú Taipei lọ. Ìdí ni pé ibẹ̀ ò gbà wọ́n mọ́ bí wọ́n ṣe ń bójú tó àwọn akéde ilẹ̀ Taiwan tó ti di ẹgbẹ̀sán ó dín mẹ́tàlélógún [1, 777] nígbà yẹn. Ní December 1990, wọ́n ra ilẹ̀ kan sílùú Hsinwu tí wọn yóò kọ ẹ̀ka ọ́fíìsì tó fẹ̀ ju ti tẹ́lẹ̀ sí. Àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn lọ́mọdé lágbà ní Taiwan pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn tó wá láti ilẹ̀ òkèèrè ṣiṣẹ́ kára níbi ilẹ̀ náà fún ọdún mélòó kan. Nígbà tó sì fi máa di August 1994, wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí í lo ẹ̀ka ọ́fíìsì tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ kọ́ yìí. Àwọn akéde tó ń wàásù ìhìn rere inú Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run níbẹ̀ nígbà náà jẹ́ ẹgbẹ̀tàlá ó dín márùnlélọ́gọ́rin [2,515]. Lónìí, ní ọdún mẹ́wàá lẹ́yìn náà, àwọn akéde náà ti ju ìlọ́po méjì iye yẹn. Wọ́n ti lé ní ẹgbẹ̀rún márùn-ún àti ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [5,500] báyìí, nǹkan bí ìdámẹ́rin wọn ló sì ń ṣe iṣẹ́ ajíhìnrere tá a máa ń fi àkókò tó pọ̀ gan-an ṣe lóṣooṣù. Ipa tó wúni lórí gan-an làwọn ọ̀dọ́ lọ́kùnrin lóbìnrin tí wọ́n dà bí “ìrì” òwúrọ̀ tí ń tuni lára ń kó nínú iṣẹ́ Ọlọ́run.—Sáàmù 110:3.

Àwọn Ọmọdé Tó Ń Kópa Nínú Iṣẹ́ Ọlọ́run Ń Pọ̀ Sí I

Ọmọdé ni púpọ̀ nínú àwọn akéde ìhìn rere onítara yìí. Ọmọ ilé ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ tiẹ̀ làwọn kan. Bí àpẹẹrẹ, nílùú kan ní àríwá Taiwan, àwọn ará pe tọkọtaya kan wá sípàdé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run fúngbà àkọ́kọ́, ìyẹn ilé ẹ̀kọ́ táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa bí a ṣe lè kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ẹnu ya tọkọtaya náà nígbà tí wọ́n rí i pé ọmọdékùnrin kan tó ń jẹ́ Weijun tó ka Bíbélì lórí pèpéle mọ̀ ọ́n kà ju ọ̀pọ̀ àgbàlagbà míì lọ. Wọ́n sì tún rí bí àwọn ọmọ tí ò tiẹ̀ tíì bẹ̀rẹ̀ ilé ìwé ṣe ń dáhùn ìbéèrè dáadáa láwọn ìpàdé míì. Tọkọtaya yìí wá sọ pé ìwà àwọn ọmọ wa kéékèèké ní Gbọ̀ngàn Ìjọba dára gan-an ni.

Kí ló jẹ́ káwọn ọmọdé wọ̀nyí fọkàn sí ẹ̀kọ́ Bíbélì ní orílẹ̀-èdè tí ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn ti jẹ́ ẹlẹ́sìn Búdà àti ti Táò yìí? Ohun tó jẹ́ kó rí bẹ́ẹ̀ ni pé àwọn òbí wọn tó jẹ́ Kristẹni ń fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò, wọ́n sì ń rí i dájú pé àjọṣe tó dán mọ́rán wà láàárín ìdílé wọn àti Jèhófà, èyí tó ń jẹ́ kí ilé wọn tòrò. Nítorí pé àwọn òbí Weijun máa ń gbìyànjú láti jẹ́ kí ìgbà ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé àti òde ẹ̀rí jẹ́ àkókò alárinrin, ẹ̀gbọ́n Weijun méjì, ọkùnrin kan àti obìnrin kan, ló ti ṣèrìbọmi. Nígbà tí Weijun tó ṣì jẹ́ ọmọ kékeré sọ pé òun fẹ́ máa bá ìjọ jáde òde ìwàásù lẹ́nu àìpẹ́ yìí, ìyá rẹ̀ sọ pé ìwé ìròyìn tó tiẹ̀ ti fi síta lóṣù yẹn náà ti ju àpapọ̀ èyí tí gbogbo àwọn yòókù nínú ìdílé náà fi síta lọ. Ó fẹ́ràn àtimáa sọ̀rọ̀ nípa òtítọ́, kó máa dáhùn nípàdé, kó sì máa sọ àwọn ohun tó ti kọ́ fáwọn èèyàn.

Báwọn Ọmọ Náà Ṣe Ń Dàgbà Sí I

Báwo làwọn ọmọ tó ń ṣe dáadáa yìí ṣe ń ṣe sí bí wọ́n ṣe ń dàgbà? Ọ̀pọ̀ jù lọ wọn ló ṣì ń bá a nìṣó láti fẹ́ràn Jèhófà àti iṣẹ́ ìsìn wọn tọkàntọkàn. Àpẹẹrẹ kan ni ti arábìnrin Huiping tó jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́. Lọ́jọ́ kan, olùkọ́ wọn sọ pé àwọn ẹlẹ́sìn kan kì í gba ẹ̀jẹ̀ sára ṣùgbọ́n òun ò mọ àwọn ẹlẹ́sìn náà. Nígbà tí wọ́n ṣe tán ní kíláàsì, ọ̀dọ́mọbìnrin yìí sọ fún olùkọ́ rẹ̀ pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni àwọn ẹlẹ́sìn tí kì í gba ẹ̀jẹ̀ yẹn, ó sì ṣàlàyé ìdí rẹ̀ fún un.

Olùkọ́ wọn míì fi fídíò nípa àwọn àrùn téèyàn ń kó látinú ìṣekúṣe hàn wọ́n. Wọ́n mẹ́nu kan ọ̀rọ̀ inú 1 Kọ́ríńtì 6:9 nínú fídíò náà, ṣùgbọ́n obìnrin olùkọ́ yìí sọ pé Bíbélì ò lòdì sí ìbẹ́yà-kan-náà-lòpọ̀. Ni arábìnrin Huiping bá tún ṣàlàyé irú ojú tí Ọlọ́run fi ń wo ìbẹ́yà-kan-náà-lòpọ̀ fún olùkọ́ yìí.

Nígbà tí ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Shuxia tí wọ́n jọ wà nílé ẹ̀kọ́ fẹ́ kọ ọ̀rọ̀ lórí ìwà ipá nínú ìdílé, Huiping fún un ní ìwé ìròyìn Jí! ti November 8, 2001 tí àkòrí rẹ̀ jẹ́ “Ìrànwọ́ fún Àwọn Obìnrin Tọ́kọ Wọn Ń Lù,” ó sì sọ fún un pé ìwé ìròyìn náà sọ̀rọ̀ púpọ̀ nípa ohun tí Bíbélì wí lórí kókó náà. Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, Shuxia di akéde tí kò tíì ṣèrìbọmi. Ní báyìí, ńṣe lòun àti Huiping jọ ń wàásù fáwọn mìíràn.

Púpọ̀ nínú àwọn Kristẹni tó wà nílé ẹ̀kọ́ rí i pé kì í rọrùn fáwọn táwọn èèyàn bá mọ̀ pé àwọn ń tẹ̀ lé ìlànà Bíbélì, pàápàá láwọn ìlú tó wà ní ìgbèríko. Àwọn ọmọ ilé ìwé Zhihao fojú rẹ̀ rí màbo nítorí ìgbàgbọ́ rẹ̀ àti iṣẹ́ ìwàásù tó ń ṣe. Ó ní: “Wọ́n dà mí láàmù débi pé, ńṣe làyà mi máa ń já tí mo bá rí ọmọ iléèwé mi nígbà tá a bá wà lóde ẹ̀rí. Nígbà míì, àwọn mẹ́wàá lè pé lé mi lórí tí wọ́n á máa fi mí ṣe yẹ̀yẹ́!” Lọ́jọ́ kan, olùkọ́ wọn ní kí Zhihao wá sọ̀rọ̀ nípa ohun tó gbà gbọ́ fún kíláàsì wọn. Zhihao ní: “Mo bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ mi látorí Jẹ́nẹ́sísì orí kìíní, mo sì sọ̀rọ̀ lórí àwọn ìbéèrè bíi: Ta ló dá ayé àti gbogbo ohun tó wà nínú rẹ̀? Àti, báwo lọmọ èèyàn ṣe dé ilẹ̀ ayé? Gbàrà tí mo ṣí Bíbélì láti kà á làwọn kan ti ń fi mí rẹ́rìn-ín pé ìtàn irọ́ ni mò ń kà. Àmọ́ mí ò dákẹ́, mo sọ̀rọ̀ mi parí. Nígbà tó yá, mo wá bá àwọn kan lára àwọn ọmọ kíláàsì mi yẹn sọ̀rọ̀ nípa iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà àti ìgbàgbọ́ wa. Nísinsìnyí, tí wọ́n bá rí mi lóde ẹ̀rí, wọn ò jẹ́ fi mí ṣe yẹ̀yẹ́ mọ́!”

Zhihao tún sọ pé: “Àràárọ̀ la máa ń ka ẹ̀kọ́ ojoojúmọ́ nítorí Ẹlẹ́rìí làwọn òbí mi. A tún máa ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì a sì máa ń lọ sípàdé déédéé. Ìyẹn ni kì í jẹ́ kí ẹ̀rù àwọn tó bá ṣì fẹ́ máa fi mí ṣe yẹ̀yẹ́ bà mí mọ́ nígbà tí mo bá ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó ń tuni lára.”

Àpẹẹrẹ mìíràn ni ti arábìnrin Tingmei tó wà ní iléèwé ẹ̀kọ́ṣẹ́ tó wà fáwọn obìnrin. Nígbà kan, àwọn ọmọ kíláàsì rẹ̀ ní kó bá àwọn lọ sí ìrìn àjò afẹ́ ráńpẹ́ kan pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin kan láti iléèwé àwọn ọkùnrin. Tingmei rí i pé ìwàkiwà lè wáyé nígbà ìrìn àjò pẹ̀lú irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀, kò sì bá wọn lọ. Ọ̀pọ̀ ìgbà làwọn ọmọ kíláàsì ẹ̀ fi irú ìrìn bẹ́ẹ̀ lọ̀ ọ́, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti fi ìwé Awọn Ìbéèrè Tí Awọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Awọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́a ṣàlàyé ọ̀rọ̀ yẹn fún wọn. Ńṣe làwọn ọmọbìnrin náà fi ń ṣe yẹ̀yẹ́ pé kò lajú. Àmọ́ nígbà tó di pé ọ̀kan lára àwọn ọmọbìnrin náà gboyún, tó sì ṣẹ́ ẹ, wọ́n rí i pé ìlànà Bíbélì ló dáa kéèyàn máa tẹ̀ lé lóòótọ́. Tingmei sọ pé: “Ìtọ́ni Bíbélì tí mò ń tẹ̀ lé jẹ́ kí n ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́. Ìyẹn sì fún mi láyọ̀ àti ìfọ̀kànbalẹ̀.”

Wọ́n Borí Ìdíwọ́ Kí Wọ́n Lè Tẹ̀ Síwájú

Ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ ni Tingmei àti Ruiwen. Nígbà tí Ruiwen wà lọ́mọdé, ohun ìnira gbáà ló ka ìpàdé àti òde ẹ̀rí lílọ sí. Àmọ́ nígbà tó ṣàkíyèsí ìyàtọ̀ tó wà nínú ojúlówó ìfẹ́ táwọn ará ìjọ rẹ̀ ní àti ìfẹ́ oréfèé táwọn ọmọ kíláàsì rẹ̀ ní, ó rí i pé á dáa kí òun ṣe àwọn ìyípadà kan ní ìgbésí ayé òun. Ó wá bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù fáwọn ọmọ iléèwé rẹ̀. Èyí sì jẹ́ kó mọ ohun tó tún kàn láti ṣe. Bó ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ nìyẹn, tó ń fi ohun tó lé ní àádọ́ta wákàtí wàásù lóṣooṣù. Nígbà tó yá, ó di aṣáájú-ọ̀nà déédéé, ó sì ń lo ohun tó lé ní àádọ́rin wákàtí láti fi wàásù lóṣooṣù. Arábìnrin Ruiwen sọ pé: “Ẹnu mi ò gbọpẹ́ fún ohun tí Jèhófà ṣe fún mi. Kò pa mí tì rárá. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ṣe àwọn ohun tí kò fẹ́ láwọn ìgbà kan síbẹ̀ ó ṣì fẹ́ràn mi. Irú ìfẹ́ yẹn náà ni ìyá mi àtàwọn ará ìjọ ní sí mi. Ní báyìí tí mo ti wá ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì márùn-ún, ńṣe ni inú mi ń dùn pé mò ń kópa nínú iṣẹ́ tó ń fúnni láyọ̀ jù lọ.”

Ní iléèwé girama tó wà lábúlé kan, wọ́n yan àwọn ọmọdé kan tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí pé kí wọ́n lọ ṣojú iléèwé wọn níbi ìdíje ijó ìbílẹ̀ kan. Nígbà táwọn ọmọ yìí gbọ́ bí ìdíje náà ṣe máa rí, wọ́n rí i pé àwọn ò ní lè kópa nínú irú ìdíje bẹ́ẹ̀ nítorí pé ó lòdì sí ẹ̀rí ọkàn wọn tí wọ́n ti fi Bíbélì kọ́. Wọ́n gbìyànjú láti ṣàlàyé ara wọn, pé kí wọ́n jọ̀wọ́ yọ̀ǹda àwọn, ṣùgbọ́n àwọn olùkọ́ wọn ò gbà. Wọ́n ní nígbà tí wọ́n ti yàn wọ́n, ó di dandan kí wọ́n lọ. Níwọ̀n bí àwọn ọmọ yìí ò sì ti fẹ́ ṣe ohun tó lòdì sí ìgbàgbọ́ wọn, wọ́n kọ̀wé sí ẹ̀ka ilé iṣẹ́ ètò ẹ̀kọ́ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì láti fi ṣàlàyé ìṣòro wọn. Wọn kò dá àwọn ọmọ yìí lóhùn ní tààràtà, àmọ́ kò pẹ́ sígbà yẹn ni iléèwé wọn gba ìtọ́ni pé wọn ò gbọ́dọ̀ fipá mú ẹnikẹ́ni láti kópa nínú irú ìdíje bẹ́ẹ̀. Inú àwọn ọmọ yìí dùn gan-an pé ẹ̀kọ́ Bíbélì táwọn kọ́ ń mú kí ẹ̀rí ọkàn àwọn ṣiṣẹ́ dáadáa, àti pé ẹ̀kọ́ yẹn tún jẹ́ káwọn lè dúró gbọn-in lórí ohun tó tọ́!

Àní àwọn aláàbọ̀ ara pàápàá ń fi ìdùnnú sọ ìrètí tí ẹ̀kọ́ Bíbélì mú kí wọ́n ní fáwọn èèyàn. Látìgbà tí wọ́n ti bí arábìnrin Minyu ló ti láàrùn ẹ̀gbà. Torí pé kò lè lo ọwọ́ rẹ̀ rárá, ahọ́n ló fi ń ṣí ibi tó bá fẹ́ kà nínú Bíbélì. Tó bá níṣẹ́ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, ńṣe ló máa dùbúlẹ̀ sórí àga tìmùtìmù tí kò ga, táwọn onílé rẹ̀ á sì jókòó sórí ìjókòó tí kò ga láti lè bá a mú makirofóònù dání. Akitiyan tí Minyu ń ṣe láti lè ṣe iṣẹ́ rẹ̀ nílé ẹ̀kọ́ yìí wúni lórí gan-an ni!

Nígbà tí Minyu fẹ́ di akéde Ìjọba Ọlọ́run, àwọn arábìnrin inú ìjọ rẹ̀ lọ kọ́ bí wọ́n á ṣe máa fi tẹlifóònù wàásù láti lè ṣèrànlọ́wọ́ fún un. Ahọ́n ni Minyu máa fi ń tẹ nọ́ńbà tó bá fẹ́ pè lórí tẹlifóònù, arábìnrin tó bá ń ràn án lọ́wọ́ yóò sì máa bá a kọ iye àwọn tó bá pè sílẹ̀. Ó gbádùn iṣẹ́ ìwàásù náà débi pé ó di olùrànlọ́wọ́ aṣáájú-ọ̀nà, ó sì ń fi àádọ́ta sí ọgọ́ta wákàtí bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ Ìjọba Ọlọ́run lóṣooṣù lórí tẹlifóònù. Ó tiẹ̀ tipa bẹ́ẹ̀ rí àwọn kan tí wọ́n gba ìwé tó ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, tí wọ́n sì gbà kó ṣe ìpadàbẹ̀wò àwọn. Àwọn mẹ́ta bẹ́ẹ̀ ló ti ń bá ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì báyìí.

Láìsí àní-àní, ńṣe làwọn ọ̀dọ́ tó wà ní àwọn ìjọ Ẹlẹ́rìí Jèhófà méjìdínlọ́gọ́rin [78] tó wà ní Taiwan dà bí ìrì atura tí ń sẹ̀ bí wọ́n ṣe ń fi tinútinú àti tìtaratìtara wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run tó jẹ́ ọ̀rọ̀ tó ń gbéni ró fún ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ èèyàn tó kún erékùṣù náà. Apá kékeré lèyí sì jẹ́ nínú bí àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì kan ṣe ń ṣẹ kárí ayé, ìyẹn àsọtẹ́lẹ̀ tó sọ pé: “Àwọn ènìyàn rẹ yóò fi tinútinú yọ̀ǹda ara wọn ní ọjọ́ ẹgbẹ́ ológun rẹ. Nínú ọlá ńlá ìjẹ́mímọ́, láti inú ilé ọlẹ̀ ọ̀yẹ̀, ìwọ ní àwùjọ rẹ ti àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n rí bí ìrì tí ń sẹ̀.” (Sáàmù 110:3) Ìṣírí ńláǹlà làwọn ọ̀dọ́ yìí jẹ́ o fáwọn àgbàlagbà akéde inú ìjọ wọn gbogbo. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, wọ́n tún jẹ́ orísun ayọ̀ fún Bàbá wọn ọ̀run, Jèhófà Ọlọ́run!—Òwe 27:11.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

WỌ́N NÍLÒ GBỌ̀NGÀN ÌJỌBA PÚPỌ̀ SÍ I

Bí iye àwọn akéde ṣe ń pọ̀ sí i ní Taiwan, bẹ́ẹ̀ ló ṣe túbọ̀ ń ṣòro fún gbogbo wọn láti ní Gbọ̀ngàn Ìjọba káríkárí. Kí nìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé abúlé nìkan ni wọ́n ti lè rí ilẹ̀ tí wọ́n lè fi kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba. Yàtọ̀ síyẹn, owó gọbọi ni wọ́n ń ta ilẹ̀, òfin ilé kíkọ́ sì tún le gan-an. Ohun tí wọ́n tún lè ṣe láwọn ìlú ńlá ni pé kí wọ́n ra àwọn ibi tó jẹ́ ọ́fíìsì kí wọ́n wá sọ ọ́ di Gbọ̀ngàn Ìjọba. Àmọ́ ìṣòro ọ̀pọ̀ irú ọ́fíìsì bẹ́ẹ̀ ni pé àjà rẹ̀ máa ń sún mọ́lẹ̀ jù, àwọn onílé tún ń gba owó gọbọi lórí àtúnṣe rẹ̀ àtìgbàdégbà, àwọn èèyàn kì í sì í lè wọbẹ̀ nígbà tí wọ́n bá fẹ́, tàbí kí àwọn nǹkan míì bẹ́ẹ̀ tún wà tí kò ní jẹ́ kí irú ilé bẹ́ẹ̀ dára láti lò fún Gbọ̀ngàn Ìjọba.

Ṣùgbọ́n pẹ̀lú gbogbo èyí, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní Taiwan ṣì kọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba tuntun mélòó kan lẹ́nu ọdún àìpẹ́ yìí. Wọ́n sì ń bá a lọ láti máa wá ibi tí wọ́n á tún kọ́ àwọn míì sí, nítorí àwọn ará ti múra tán láti gbé gbogbo ìnáwó tó bá gbà, wọ́n sì tún múra tán láti kọ́ iṣẹ́ ilé kíkọ́ láti lè máa kọ́ àwọn Gbọ̀ngàn náà.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́