ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w06 8/15 ojú ìwé 12-15
  • “Ẹ Jẹ́ Ká Fi Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ Wé Ara Wọn”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Ẹ Jẹ́ Ká Fi Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ Wé Ara Wọn”
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ǹjẹ́ Bíbélì Kọ́ Wa Pé Ọkàn Ò Lè Kú?
  • Àwọn Ìwádìí Tí Russell Ṣe Nínú Ìwé Mímọ́
  • Àṣà Fífi Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ Wé Ara Wọn Bá Bíbélì Mu
  • Wo Àwọn Ọ̀rọ̀ Tó Yí Ẹsẹ Bíbélì Náà Ká
  • Ṣé Ò Ń Jẹ́ Kí Bíbélì Ṣàlàyé Ara Rẹ̀?
  • Ṣíṣiṣẹ́ Nínú “Pápá” Ṣáájú Ìkórè
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
  • Ábúráhámù—Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
  • A Bí Ìjọba Ọlọ́run ní Ọ̀run
    Ìjọba Ọlọ́run Ti Ń Ṣàkóso!
  • “Baba Gbogbo Àwọn Tí Wọ́n Ní Ìgbàgbọ́”
    Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
w06 8/15 ojú ìwé 12-15

“Ẹ Jẹ́ Ká Fi Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ Wé Ara Wọn”

ÀLÙFÁÀ ṣọ́ọ̀ṣì kan rí ìwé pélébé kan nínú ọkọ̀ rélùwéè kan tó ń lọ sí ìlú New York City. Ìwé náà sọ pé ọkàn máa ń kú. Ìyàlẹ́nu lèyí jẹ́ fún un, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í ka ìwé náà. Ìdí tí ẹnu fi yà á ni pé kò fìgbà kan ṣiyèméjì rárá pé ọkàn ò lè kú. Nígbà yẹn, kò mọ ẹni tó kọ̀wé náà. Síbẹ̀, ó rí i pé òótọ́ ni àlàyé inú rẹ̀, ó bá Ìwé Mímọ́ mu, ìwé tó yẹ kéèyàn fara balẹ̀ kà sì ni.

Orúkọ àlùfáà náà ni George Storrs. Ọdún 1837 ni ohun tá à ń sọ yìí ṣẹlẹ̀, ọdún kan náà tí Charles Darwin kọ́kọ́ ṣe àkọsílẹ̀ àwọn ohun kan tó ń rò lọ́kàn, èyí tó wá sọ di ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n nígbà tó yá. Ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn lọ̀rọ̀ ẹ̀sìn ṣì jẹ lọ́kàn láyé ìgbà yẹn, wọ́n sì gba Ọlọ́run gbọ́ gan-an. Àwọn èèyàn púpọ̀ ló ń ka Bíbélì, wọn ò sì kóyán rẹ̀ kéré.

Ìgbà tó yá ni Storrs wá rí i pé ọ̀gbẹ́ni Henry Grew tó ń gbé nílùú Philadelphia, ní ìpínlẹ̀ Pennsylvania lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ló kọ̀wé ọ̀hún. Ohun tí Grew gbà gbọ́ ni pé, “Ìwé Mímọ́ . . . ló lè ṣàlàyé ara rẹ̀.” Grew àtàwọn tí wọ́n jọ gba ohun kan náà gbọ́ ti ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kí ìgbé ayé wọn àti gbogbo ohun tí wọ́n ń ṣe lè bá Bíbélì mu. Ìwádìí tí wọ́n ṣe sì ti jẹ́ kí wọ́n rí àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì kan nínú Bíbélì.

Nítorí pé ohun tí Grew kọ wú Storrs lórí, ó fara balẹ̀ yẹ ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ nípa ọkàn wò, ó sì jíròrò ọ̀rọ̀ náà pẹ̀lú àwọn àlùfáà bíi tirẹ̀. Lẹ́yìn ọdún márùn-ún tí Storrs ti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jinlẹ̀-jinlẹ̀, ó tẹ ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó ṣeyebíye tó ṣẹ̀ṣẹ̀ rí nínú Bíbélì jáde. Lákọ̀ọ́kọ́, ó múra ọ̀rọ̀ ìwàásù kan sílẹ̀, èyí tó sọ lọ́jọ́ Sunday kan lọ́dún 1842. Àmọ́ ó wò ó pé ó yẹ kí òun tún ṣe àwọn ìwàásù mìíràn sí i láfikún kí òun bàa lè ṣàlàyé ẹ̀kọ́ náà dáadáa. Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, gbogbo ìwàásù rẹ̀ lórí ẹ̀kọ́ pé ọkàn ń kú jẹ́ mẹ́fà, ó sì tẹ̀ wọ́n sínú ìwé tó pe àkọlé rẹ̀ ní Six Sermons (Ìwàasù Mẹ́fà). Storrs fi ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan wé òmíràn káwọn èèyàn lè rí àwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́ pàtàkì táwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ti fi ẹ̀kọ́ èké bò mọ́lẹ̀.

Ǹjẹ́ Bíbélì Kọ́ Wa Pé Ọkàn Ò Lè Kú?

Bíbélì sọ pé àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù tí wọ́n jẹ́ ẹni àmì òróró yóò dẹni tí kò lè kú, ìyẹn ni èrè tí wọ́n á gbà nítorí ìṣòtítọ́ wọn. (1 Kọ́ríńtì 15:50-56) Storrs wá sọ pé, tó bá jẹ́ pé èrè àwọn olóòótọ́ ni pé wọ́n á dẹni tí kò lè kú, á jẹ́ pé kò ní tọ̀nà láti sọ pé ọkàn àwọn èèyàn búburú kò lè kú nìyẹn. Dípò tí ì bá fi máa méfò, inú Ìwé Mímọ́ gan-an ni Storrs lọ. Ó ṣàyẹ̀wò Mátíù 10:28 (Bíbélì Mímọ́), èyí tó sọ pé: “Ẹ kuku fòiya ẹniti o le pa ara ati ọkàn run li ọrun apadi.” Ohun tí ẹsẹ yìí sọ jẹ́ kó gbà pé ọkàn lè pa run. Ó tún ṣàyẹ̀wò Ìsíkíẹ́lì 18:4 (Bíbélì Mímọ́), èyí tó sọ pé: “Ọkàn ti o bá ṣẹ̀, on o kú.” Nígbà tó fi ọ̀rọ̀ yìí wé ohun tí Bíbélì sọ látòkèdélẹ̀, ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó ṣeyebíye náà túbọ̀ ṣe kedere. Storrs kọ̀wé pé: “Bí ohun tí mo gbà gbọ́ pé ọkàn lè kú bá tọ̀nà, á jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí kò yé àwọn èèyàn nítorí ìgbàgbọ́ tí wọ́n ní pé ọkàn kì í kú, máa yéni yékéyéké, á tẹ́ni lọ́rùn, á nítumọ̀ síni, á sì wọni lọ́kàn dáadáa.”

Àmọ́, ẹsẹ Ìwé Mímọ́ bíi Júúdà ẹsẹ keje ńkọ́? Ẹsẹ náà sọ pé: “Ani bi Sodomu ati Gomorra, ati awọn ilu agbegbe wọn, ti fi ara wọn fun àgbere iṣe bakanna, ti nwọn si ntẹle ara ajeji lẹhin, awọn li a fi lelẹ bi apẹrẹ, nwọn njiya iná ainipẹkun.” (Bíbélì Mímọ́) Táwọn kan bá ka ẹsẹ Bíbélì yìí, wọ́n lè rò pé ńṣe ni ọkàn àwọn tí Ọlọ́run pa run ní Sódómù àti Gòmórà yóò máa joró nínú iná títí ayé. Storrs kọ̀wé pé: “Ẹ jẹ́ ká fi ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wé ara wọn.” Ó wá fa ọ̀rọ̀ 2 Pétérù 2:5, 6 yọ, èyí tó sọ pé: “Kò si dá aiye igbãni si, ṣugbọn o pa Noa . . . , mọ́, . . . , nigbati o mu kikun omi wá sori aiye awọn alaiwà-bi-Ọlọrun; ti o sọ awọn ilu Sodomu on Gomorra di ẽru, nigbati o fi ifọ́ afọbajẹ dá wọn lẹbi, ti o fi wọn ṣe apẹrẹ fun awọn ti yio jẹ alaiwà-bi-Ọlọrun.” (Bíbélì Mímọ́) Bẹ́ẹ̀ ni o, Ọlọ́run sọ Sódómù àti Gòmórà di eérú, ó sì pa àwọn tó ń gbébẹ̀ run ráúráú.

Storrs wá ṣàlàyé pé: “Ìwé Pétérù jẹ́ ká túbọ̀ lóye ọ̀rọ̀ inú ìwé Júúdà yìí. Kedere kèdèrè làwọn ìwé Bíbélì méjèèjì jẹ́ ká rí ìdájọ́ tí Ọlọ́run ṣe fáwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ wọ̀nyẹn. . . . Ńṣe ni Ọlọ́run fi ìdájọ́ tó ṣe fún ayé ìgbàanì, Sódómù àti Gòmórà ṣe ẹ̀kọ́ àríkọ́gbọ́n, ìkìlọ̀ tàbí ‘àpẹẹrẹ’ tó wà títí ayé, tàbí ‘ayérayé’ fún gbogbo èèyàn títí dìgbà ìkẹyìn ayé.” Nítorí náà, ohun tí Júúdà ń sọ ni pé ńṣe ni iná pa Sódómù àti Gòmórà run ráúráú, wọn ò sì ní sí mọ́ títí ayé. Ìyẹn ò fi hàn rárá pé ọkàn ò lè kú.

Kì í ṣe pé Storrs kàn ń ṣa àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó bá èrò rẹ̀ mu jọ tó wá ń fi àwọn tí kò bá èrò rẹ̀ mu sílẹ̀ o. Ó máa ń wo ọ̀rọ̀ tó yí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kọ̀ọ̀kan ká, á sì tún wo bí ẹsẹ náà ṣe bá Bíbélì mu látòkèdélẹ̀. Bó bá rí i pé ó dà bíi pé ẹsẹ Bíbélì kan ń ta ko àwọn mìíràn, yóò wo gbogbo Bíbélì kó lè mọ ohun tó yẹ kó jẹ́ ìtumọ̀ ẹsẹ Bíbélì yẹn gan-an.

Àwọn Ìwádìí Tí Russell Ṣe Nínú Ìwé Mímọ́

Lára àwọn tó rìn mọ́ George Storrs ni ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń pe àwọn èèyàn mọ́ra kí wọ́n lè jọ máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nílùú Pittsburgh ní ìpínlẹ̀ Pennsylvania. Orúkọ rẹ̀ ni Charles Taze Russell. Ọdún 1876 ni ọ̀kan lára àwọn àpilẹ̀kọ tó kọ́kọ́ kọ láti fi ṣàlàyé àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì jáde nínú ìwé ìròyìn Bible Examiner tí Storrs jẹ́ olóòtú rẹ̀. Russell sọ pé ìwádìí tí àwọn tó ti ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣáájú òun ti ṣe ran òun lọ́wọ́ gan-an. Nígbà tó yá, tí Russell di olóòtú ìwé ìròyìn Zion’s Watch Tower, ó sọ pé òun mọrírì ìrànlọ́wọ́ tí Storrs ṣe fún òun, ní ti ohun tó sọ fún òun àtohun tó tẹ̀ sínú ìwé.

Nígbà tí C. T. Russell wà lọ́mọ ọdún méjìdínlógún, ó kó àwọn kan tí wọ́n á jọ máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mọ́ra, ó sì gbé ìlànà kan kalẹ̀ nípa bí wọ́n á ṣe máa kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀. Ọ̀kan lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí wọ́n jọ ń kẹ́kọ̀ọ́ ni A. H. Macmillan. Nígbà tó ń ṣàlàyé ọ̀nà tí wọ́n ń gbà kẹ́kọ̀ọ́, ó ní: “Ẹnì kan á béèrè ìbéèrè, wọ́n á sì jọ jíròrò ìbéèrè náà. Wọ́n á wo gbogbo ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó sọ̀rọ̀ nípa ìbéèrè yẹn. Tí wọ́n bá ti wá rí bí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wọ̀nyí ṣe bára wọn mu tó sì tẹ́ wọn lọ́rùn, wọ́n á sọ ohun tí wọ́n fohùn ṣọ̀kan lé lórí, wọ́n á sì kọ ọ́ sílẹ̀.”

Russell gbà pé téèyàn bá yẹ Bíbélì wò látòkèdélẹ̀, èèyàn ní láti rí bí àwọn ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ ṣe bára wọn mu tí wọn kò sì takora, ọ̀rọ̀ náà sì ní láti bá ìwà Ọlọ́run tó ni Bíbélì mu. Nígbàkigbà tó bá dà bíi pé ibì kan nínú Bíbélì ṣòro láti lóye, Russell máa ń wò ó pé àwọn ibòmíràn nínú Bíbélì ní láti ṣe àlàyé rẹ̀ tàbí kí wọ́n sì mú kó ṣe kedere sí i.

Àṣà Fífi Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ Wé Ara Wọn Bá Bíbélì Mu

Àmọ́ o, kì í ṣe Russell tàbí Storrs tàbí Grew ló kọ́kọ́ fi ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan wé òmíràn kí wọ́n lè ṣàlàyé ara wọn. Àtọ̀dọ̀ Jésù Kristi tó dá ẹ̀sìn Kristẹni sílẹ̀ ni àṣà yìí ti bẹ̀rẹ̀. Ó máa ń lo onírúurú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ láti fi ṣàlàyé ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan. Bí àpẹẹrẹ, nígbà táwọn Farisí ń ṣàròyé torí pé àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ń ya erín ọkà jẹ lọ́jọ́ Sábáàtì, Jésù fa ọ̀rọ̀ yọ látinú 1 Sámúẹ́lì 21:6 láti fi jẹ́ kí wọ́n mọ bó ṣe yẹ kí wọ́n tẹ̀ lé òfin Sábáàtì. Àwọn aṣáájú ìsìn mọ ìtàn yẹn dáadáa, wọ́n mọ̀ pé Dáfídì àtàwọn ọkùnrin tó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ jẹ búrẹ́dì àfihàn. Jésù wá mẹ́nu kan apá ibi tí Òfin Mósè ti sọ pé kìkì àwọn àlùfáà tí wọ́n jẹ́ àtọmọdọ́mọ Áárónì nìkan ló lẹ́tọ̀ọ́ láti jẹ búrẹ́dì àfihàn náà. (Ẹ́kísódù 29:32, 33; Léfítíkù 24:9) Síbẹ̀síbẹ̀, àlùfáà tí Dáfídì bá sọ̀rọ̀ sọ pé kó jẹ búrẹ́dì náà. Nígbà tí Jésù wá fẹ́ parí àlàyé tó múná dóko tó ń ṣe fún wọn, ó fa ọ̀rọ̀ yọ látinú ìwé Hóséà, ó ní: “Bí ẹ bá ti lóye ohun tí èyí túmọ̀ sí pé, ‘Àánú ni èmi ń fẹ́, kì í sì í ṣe ẹbọ,’ ẹ kì bá ti dá àwọn aláìjẹ̀bi lẹ́bi.” (Mátíù 12:1-8) Ẹ ò rí i pé àpẹẹrẹ tó dára gan-an lèyí jẹ́ tó bá di ọ̀rọ̀ fífi ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan wé òmíràn kéèyàn lè lóye Ìwé Mímọ́ lọ́nà tó pé pérépéré!

Àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù náà tẹ̀ lé àṣà ká máa fi ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan ṣàlàyé òmíràn. Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń kọ́ àwọn èèyàn ní Tẹsalóníkà, ó “bá wọn fèrò-wérò láti inú Ìwé Mímọ́, ó ń ṣàlàyé, ó sì ń fi ẹ̀rí ìdánilójú hàn nípasẹ̀ àwọn ìtọ́ka pé ó pọndandan kí Kristi jìyà, kí ó sì dìde kúrò nínú òkú.” (Ìṣe 17:2, 3) Pọ́ọ̀lù tún fi ẹsẹ Bíbélì kan ṣàlàyé òmíràn nínú àwọn lẹ́tà tí Ọlọ́run mí sí i láti kọ. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tó ń kọ lẹ́tà sáwọn Hébérù, ó fa ọ̀pọ̀ ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yọ láti fi hàn dájú pé Òfin Mósè jẹ́ òjìji àwọn ohun rere tó ń bọ̀.—Hébérù 10:1-18.

Láìsí àní-àní, ńṣe làwọn tó ń fi tọkàntọkàn kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní ọ̀rúndún kọkàndínlógún àti ọ̀rúndún ogún wulẹ̀ ń tẹ̀ lé àṣà tó ti wà tipẹ́ láàárín àwọn Kristẹni yìí. Àṣà fífi ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan wé òmíràn la ṣì ń lò nínú ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ títí di báyìí. (2 Tẹsalóníkà 2:15) Ohun táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń ṣe nìyẹn tá a bá fẹ́ ṣe ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé lórí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan.

Wo Àwọn Ọ̀rọ̀ Tó Yí Ẹsẹ Bíbélì Náà Ká

Báwo la ṣe lè tẹ̀ lé apẹẹrẹ Jésù àtàwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ olóòótọ́ nígbà tá a bá ń ka Bíbélì? Lákọ̀ọ́kọ́ ná, a lè wo àwọn ọ̀rọ̀ tó yí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá à ń gbé yẹ̀ wò ká. Báwo lèyí ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti lóye ohun tí à ń kà? Bí àpẹẹrẹ, ẹ jẹ́ ká wo ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ nínú Mátíù 16:28. Jésù ní: “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín pé àwọn kan wà lára àwọn tí wọ́n dúró níhìn-ín tí kì yóò tọ́ ikú wò rárá títí wọn yóò fi kọ́kọ́ rí Ọmọ ènìyàn tí ń bọ̀ nínú ìjọba rẹ̀.” Àwọn kan lè máa wò ó pé ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ yìí ò rí bẹ́ẹ̀ nítorí pé gbogbo àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù tó wà níbẹ̀ nígbà tó sọ ọ̀rọ̀ yẹn ti kú kó tó di pé a gbé Ìjọba Ọlọ́run kalẹ̀ lọ́run. Àní, ìwé kan tó ń ṣàlàyé Bíbélì tí wọ́n pe àkọlé rẹ̀ ní The Interpreter’s Bible sọ nípa ẹsẹ Bíbélì yìí pé: “Àsọtẹ́lẹ̀ yìí ò ṣẹ, ìdí nìyí táwọn tó di Kristẹni lẹ́yìn ìyẹn fi ń sọ pé àfiwé lásán ni ọ̀rọ̀ yìí.”

Àmọ́ o, àwọn ọ̀rọ̀ tó yí ẹsẹ Bíbélì yìí ká àtàwọn ohun tí Máàkù àti Lúùkù kọ sílẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ yìí jẹ́ ká mọ ohun tí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí ń sọ gan-an. Kí ni Mátíù sọ kété lẹ́yìn tó sọ ọ̀rọ̀ tó wà lókè yìí? Ó kọ̀wé pé: “Ọjọ́ mẹ́fà lẹ́yìn náà, Jésù mú Pétérù àti Jákọ́bù àti Jòhánù arákùnrin rẹ̀ lọ́wọ́, ó sì mú wọn wá sí orí òkè ńlá kan tí ó ga fíofío ní àwọn nìkan. A sì yí i padà di ológo níwájú wọn.” (Mátíù 17:1, 2) Máàkù àti Lúùkù náà fi hàn pé ohun tí Jésù sọ nípa Ìjọba náà kan ìyípadà ológo yẹn. (Máàkù 9:1-8; Lúùkù 9:27-36) Bí Jésù ṣe yí padà di ológo níṣojú àwọn àpọ́sítélì mẹ́ta náà jẹ́ àpẹẹrẹ ògo tí Jésù máa ní nígbà tó bá di Ọba. Pétérù fi hàn pé bí ọ̀rọ̀ ṣe rí gan-an nìyí nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa “agbára àti wíwàníhìn-ín Olúwa wa Jésù Kristi” tó wá mẹ́nu kan ìyípadà ológo Jésù tó ṣojú rẹ̀.—2 Pétérù 1:16-18.

Ṣé Ò Ń Jẹ́ Kí Bíbélì Ṣàlàyé Ara Rẹ̀?

Kí lo lè ṣe tó ò bá lóye ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan lẹ́yìn tó o ti wo àwọn ọ̀rọ̀ tó yí i ká pàápàá? Fi ẹsẹ Ìwé Mímọ́ náà wé àwọn mìíràn, ṣùgbọ́n má gbà gbé pé ìtumọ̀ rẹ̀ ní láti bá ohun táwọn ẹsẹ Bíbélì yòókù ń sọ mu. Ohun kan tó lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti lè ṣe èyí dáadáa wà nínú Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun, tó ti wà lódindi tàbí lápá kan ní èdè mẹ́tàdínlọ́gọ́ta [57]. Ohun tó wà nínú rẹ̀ ni àwọn atọ́ka tó wà nínú òpó tó wà láàárín ojú ewé kọ̀ọ̀kan, ọ̀pọ̀ lára ẹ̀dà Bíbélì yìí tá a ti tẹ̀ jáde ló sì ní èyí nínú. Àwọn atọ́ka tó lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́fà ó lé márùn-ún [125,000] ló wà nínú Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun. “Ọ̀rọ̀ Ìṣáájú” nínú Bíbélì atọ́ka New World Translation of the Holy Scriptures—With References sọ pé: “Tá a bá fara balẹ̀ fi àwọn atọ́ka tó wà nínú òpó tó wà láàárín ojú ewé kọ̀ọ̀kan Bíbélì yìí wéra tá a sì tún ṣàyẹ̀wò àwọn àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé inú rẹ̀, a óò rí i bí àwọn ìwé Bíbélì mẹ́rìndínláàádọ́rin náà ṣe bára wọn mú láìsí ìtakora rárá. Èyí sì fi hàn pé ìwé kan ṣoṣo tí Ọlọ́run mí sí ni gbogbo wọn.”

Ẹ jẹ́ ká wo bí àwọn atọ́ka náà ṣe lè jẹ́ ká lóye ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan. Ìtàn Ábúrámù tàbí Ábúráhámù la máa fi ṣe àpẹẹrẹ. Ronú nípa ìbéèrè yìí ná: Ta ló jẹ́ aṣáájú nígbà tí Ábúrámù àti ìdílé rẹ̀ kúrò nílùú Úrì? Jẹ́nẹ́sísì 11:31 kà pé: “Térà mú Ábúrámù ọmọkùnrin rẹ̀ àti Lọ́ọ̀tì, . . . àti Sáráì aya ọmọ rẹ̀, . . . wọ́n sì bá a jáde kúrò ní Úrì ti àwọn ará Kálídíà, láti lọ sí ilẹ̀ Kénáánì. Nígbà tí ó ṣe, wọ́n dé Háránì, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí gbé níbẹ̀.” Béèyàn bá kàn ka ìtàn yìí, ńṣe lèèyàn á rò pé Térà baba Ábúrámù ló kó wọn jáde kúrò níbẹ̀. Àmọ́, nínú Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun, atọ́ka mọ́kànlá ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló wà fún ẹsẹ yìí nìkan ṣoṣo. Atọ́ka tó kẹ́yìn tọ́ka sí Ìṣe 7:2, níbi tí ìkìlọ̀ tí Sítéfánù fún àwọn Júù ọ̀rúndún kìíní wà. Ẹsẹ náà kà pé: “Ọlọ́run ògo fara han Ábúráhámù baba ńlá wa nígbà tí ó wà ní Mesopotámíà, [ṣáájú] kí ó tó bẹ̀rẹ̀ sí gbé ní Háránì, ó sì wí fún un pé, ‘Jáde kúrò ní ilẹ̀ rẹ àti kúrò lọ́dọ̀ àwọn ìbátan rẹ, kí o sì wá sí ilẹ̀ tí èmi yóò fi hàn ọ́.’” (Ìṣe 7:2, 3) Ṣé kì í ṣe ọ̀rọ̀ bí Ábúrámù ṣe kúrò ní Háránì ni Sítéfánù fẹ́ sọ níbí? Kò lè rí bẹ́ẹ̀ rárá, torí pé ara Ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run mí sí ni ọ̀rọ̀ yìí wà.—Jẹ́nẹ́sísì 12:1-3.

Kí wá nìdí tí Jẹ́nẹ́sísì 11:31 fi sọ pé “Térà mú Ábúrámù ọmọkùnrin rẹ̀” àtàwọn yòókù nínú ìdílé rẹ̀ jáde kúrò nílùú Úrì? Térà ṣì ni baba ńlá tó jẹ́ olórí ìdílé wọn. Gbígbà tó gbà pé òun á bá Ábúrámù lọ ni Bíbélì fi sọ pé òun ló mú ìdílé náà lọ sí Háránì. Tá a bá fi ẹsẹ Ìwé Mímọ́ méjì wọ̀nyí wéra, tá a sì wo bí wọ́n ṣe bára mu, a óò lè fojú inú rí ohun tó ṣẹlẹ̀ gan-an. Ńṣe ni Ábúrámù fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ rọ baba rẹ̀ pé kó bá òun jáde kúrò ní Úrì gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti pa á láṣẹ.

Nígbà tá a bá ń ka Ìwé Mímọ́, ó yẹ ká máa wo àwọn ọ̀rọ̀ tó yí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan ká ká sì tún wo bó ṣe bá Bíbélì mu látòkèdélẹ̀. Bíbélì gba àwa Kristẹni níyànjú pé: “Kì í ṣe ẹ̀mí ayé ni àwa gbà, bí kò ṣe ẹ̀mí tí ó ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá, kí àwa bàa lè mọ àwọn nǹkan tí Ọlọ́run ti fi fún wa pẹ̀lú inú rere. Nǹkan wọ̀nyí ni àwa pẹ̀lú ń sọ, kì í ṣe pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ tí a fi kọ́ni nípasẹ̀ ọgbọ́n ẹ̀dá ènìyàn, bí kò ṣe pẹ̀lú àwọn tí a fi kọ́ni nípasẹ̀ ẹ̀mí, bí àwa ti ń mú àwọn nǹkan ti ẹ̀mí pa pọ̀ mọ́ àwọn ọ̀rọ̀ ti ẹ̀mí.” (1 Kọ́ríńtì 2:11-13) Láìsí àní-àní, ó yẹ ká máa bẹ Jèhófà pé kó ràn wá lọ́wọ́ ká lè lóye Ọ̀rọ̀ rẹ̀, ká sì gbìyànjú láti máa “mú àwọn nǹkan ti ẹ̀mí pa pọ̀ mọ́ àwọn ọ̀rọ̀ ti ẹ̀mí” nípa rírí i pé a wo àwọn ọ̀rọ̀ tó yí ẹsẹ Bíbélì kan ká, a sì tún wá àwọn ẹsẹ Bíbélì tó jẹ mọ́ ọn. Ẹ jẹ́ ká máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nìṣó ká lè rí àwọn ẹ̀kọ́ tó ṣeyebíye tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]

Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní ọ̀rúndún kọkàndínlógún tí wọ́n fi ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wé ara wọn: George Storrs, Henry Grew, Charles Taze Russell àti A. H. Macmillan

[Àwọn Credit Line]

Òkè: Ìwé SIX SERMONS tí George Storrs kọ (1855); àwòrán kejì láti apá òkè: Collection of The New-York Historical Society/69288

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi ẹ̀rí ti ẹ̀kọ́ rẹ̀ lẹ́yìn nípa títọ́ka sí Ìwé Mímọ́

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́