Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Ṣe Ohun Tó Tọ́?
NÍGBÀ kan báyìí, ọkùnrin kan tó ka jẹ̀jẹ̀rẹ̀ nínú ìwé sọ pé: “Agbára àti-fẹ́-ṣe wà pẹ̀lú mi, ṣùgbọ́n agbára àtiṣe ohun tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀ kò sí. Nítorí rere tí mo fẹ́ ni èmi kò ṣe, ṣùgbọ́n búburú tí èmi kò fẹ́ ni èmi fi ń ṣe ìwà hù.” Kí ló mú kó ṣòro fún ọkùnrin yìí láti ṣe rere tó wù ú kó máa ṣe? Ó ṣàlàyé ìdí ẹ̀, ó ní: “Mo wá rí òfin yìí nínú ọ̀ràn tèmi: pé nígbà tí mo bá fẹ́ láti ṣe ohun tí ó tọ́, ohun tí ó burú a máa wà pẹ̀lú mi. Ní ti gidi, mo ní inú dídùn sí òfin Ọlọ́run ní ìbámu pẹ̀lú ẹni tí mo jẹ́ ní inú, ṣùgbọ́n mo rí òfin mìíràn nínú àwọn ẹ̀yà ara mi tí ń bá òfin èrò inú mi jagun, tí ó sì ń mú mi lọ ní òǹdè fún òfin ẹ̀ṣẹ̀ tí ó wà nínú àwọn ẹ̀yà ara mi.”—Róòmù 7:18, 19, 21-23.
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù lọkùnrin tó sọ̀rọ̀ yìí, nǹkan bí ẹgbàá [2,000] ọdún sẹ́yìn lọ̀rọ̀ ọ̀hún sì ti wà lákọọ́lẹ̀. Ó fi ọ̀rọ̀ náà ṣàlàyé ìdí tó fi ṣòro fáwa èèyàn aláìpé láti ṣohun tó tọ́. Kéèyàn tó lè máa tẹ̀ lé ìlànà tó tọ́ ní gbogbo ìgbà, pàápàá nígbà tí nǹkan bá ṣòro, ó gba kéèyàn jẹ́ ẹni tó ń dúró lórí òtítọ́. Torí náà ó yẹ ká bi ara wa ní ìbéèrè yìí, Kí nìdí tó ṣe pàtàkì jù lọ tó fi yẹ ká máa ṣe ohun tó tọ́?
Ronú lórí ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ nípa bí ọjọ́ iwájú ẹni tó bá ń hùwà tó tọ́ ṣe máa rí. Nínú Sáàmù 37:37, 38, a kà pé: “Máa ṣọ́ aláìlẹ́bi, kí o sì máa wo adúróṣánṣán, nítorí pé ọjọ́ ọ̀la ẹni yẹn yóò kún fún àlàáfíà. Ṣùgbọ́n ó dájú pé a ó pa àwọn olùrélànàkọjá rẹ́ ráúráú lápapọ̀; ọjọ́ ọ̀la àwọn ènìyàn burúkú ni a óò ké kúrò ní tòótọ́.” Bákan náà, Òwe 2:21, 22 sọ fún wa pé: “Nítorí àwọn adúróṣánṣán ni àwọn tí yóò máa gbé ilẹ̀ ayé, àwọn aláìlẹ́bi sì ni àwọn tí a óò jẹ́ kí ó ṣẹ́ kù sórí rẹ̀. Ní ti àwọn ẹni burúkú, a óò ké wọn kúrò lórí ilẹ̀ ayé gan-an; àti ní ti àwọn aládàkàdekè, a ó fà wọ́n tu kúrò lórí rẹ̀.”
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ìlérí yìí àtàwọn míì tá a rí nínú Bíbélì fún wa ní ìwúrí láti máa ṣe nǹkan tó dùn mọ́ Ọlọ́run nínú, síbẹ̀ àwọn nǹkan wọ̀nyí gan-an kọ́ ni olórí ohun tó fà á tá a fi fẹ́ máa ṣohun tó máa múnú Ọlọ́run dùn. Olórí ohun tó mú ká fẹ́ máa ṣe ohun tó tọ́ ni ọ̀ràn kan tó kan gbogbo ẹ̀dá tó lè dánú rò. Àpilẹ̀kọ tó kàn yìí á ṣàlàyé ọ̀ràn náà, á sì sọ bó ṣe kàn wá.