ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g 7/07 ojú ìwé 8-9
  • Jẹ́ Kí Ọlọ́run Ṣamọ̀nà Rẹ Kó O Lè Jogún “Ìyè Tòótọ́”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Jẹ́ Kí Ọlọ́run Ṣamọ̀nà Rẹ Kó O Lè Jogún “Ìyè Tòótọ́”
  • Jí!—2007
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ṣé Wàá Fẹ́ Láti Jàǹfààní Látinú Ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run?
  • Ọ̀nà Pa Dà Sí Párádísè
    Jí!—1997
  • ‘Àwọn Ọlọ́kàn Tútù Ni Yóò Jogún Ayé’—Lọ́nà Wo?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Ayé Yóò Rí Bí Ọlọ́run Ṣe Fẹ́ Kó Rí Láìpẹ́ Sígbà Tá A Wà Yìí
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Ohun Tí Ìjọba Ọlọ́run Yóò Ṣe
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
Àwọn Míì
Jí!—2007
g 7/07 ojú ìwé 8-9

Jẹ́ Kí Ọlọ́run Ṣamọ̀nà Rẹ Kó O Lè Jogún “Ìyè Tòótọ́”

BÍ ẸNIKẸ́NI bá máa jẹ́ afinimọ̀nà, irú ẹni bẹ́ẹ̀ gbọ́dọ̀ ṣeé gbára lé. Ó dá àwọn tó mọ Jèhófà, Ẹni tó ni Bíbélì, lójú pé òun lẹni tó ṣeé gbára lé jù lọ láyé àti lọ́run. “Kò lè purọ́.” (Títù 1:2; 2 Tímótì 3:16) Jóṣúà tó jẹ́ olùbẹ̀rù Ọlọ́run, tó kó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ sí Ilẹ̀ Ìlérí, jẹ́rìí sí i pé Jèhófà ṣeé gbára lé. Nígbà kan tó ń bá wọn sọ̀rọ̀, ó ní: “Ẹ̀yin sì mọ̀ dáadáa ní gbogbo ọkàn-àyà yín àti ní gbogbo ọkàn yín pé kò sí ọ̀rọ̀ kan tí ó kùnà nínú gbogbo ọ̀rọ̀ rere tí Jèhófà Ọlọ́run yín sọ fún yín. Gbogbo wọn ti ṣẹ fún yín. Kò sí ọ̀rọ̀ kan lára wọn tí ó kùnà.”—Jóṣúà 23:14.

Látìgbà tí Jóṣúà ti sọ̀rọ̀ yìí, ọ̀pọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì mìíràn ló ti nímùúṣẹ. Àkọsílẹ̀ tí ò lábààwọ́n yìí jẹ́ ká rí ìdí gbòógì tá a fi gbọ́dọ̀ ní ìgbàgbọ́ tó jinlẹ̀ nínú àwọn asọtẹ́lẹ̀ tí kò tíì nímùúṣẹ. Ọ̀pọ̀ lára irú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ bẹ́ẹ̀ kan ohun tí Ọlọ́run fẹ́ láti ṣe nípa ilẹ̀ ayé àti fún gbogbo èèyàn tó bá ṣègbọràn sí i.

Ṣé Wàá Fẹ́ Láti Jàǹfààní Látinú Ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run?

Jèhófà, tó fi ìfẹ́ bora bí aṣọ, fẹ́ kí gbogbo wa máa láyọ̀ nísinsìnyí àti títí láé. (Jòhánù 17:3; 1 Jòhánù 4:8) Ó dájú hán-únhán-ún pé Ọlọ́run fẹ́ ká gbádùn “ìyè tòótọ́,” ìyẹn ìyè àìnípẹ̀kun. (1 Tímótì 6:12, 19) Nítorí èyí, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tá a lé ní àádọ́ta ọ̀kẹ́ lọ́nà mẹ́fà ń ṣègbọràn sí àṣẹ Ọlọ́run nípa fífi ayọ̀ wàásù “ìhìn rere ìjọba yìí” fáwọn aládùúgbò wa. (Mátíù 24:14) Ní báyìí ná, à ń ṣe iṣẹ́ náà ní òjìlénígba ó dín márùn-ún ilẹ̀ [235]. Tàbí ká ṣáà kúkú sọ pé ní gbogbo orílẹ̀-èdè tó wà láyé!

Ìjọba Ọlọ́run jẹ́ ìjọba tá a fìdí rẹ̀ kalẹ̀ lókè ọ̀run, níbi tí Jésù Kristi ti máa ṣàkóso. (Dáníẹ́lì 7:13, 14; Ìṣípayá 11:15) Lábẹ́ àkóso rẹ̀, gbogbo ẹni ibi pátá, tó fi mọ́ gbogbo àwọn tó kọ̀ láti máa gbé ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìlànà òdodo Jèhófà, ló máa pa run. (Sáàmù 37:10; 92:7) Lẹ́yìn náà, gbogbo ayé pátá “yóò kún fún ìmọ̀ Jèhófà bí omi ti bo òkun.”—Aísáyà 11:9.

Ronú nípa àlàáfíà àti ìṣọ̀kan tó máa gbilẹ̀ nígbà tí gbogbo èèyàn tó wà lórí ilẹ̀ ayé bá ń sin Ọlọ́run “ní ẹ̀mí àti òtítọ́” tí wọ́n sì ń fínnú fíndọ̀ tẹrí ba fún un bó ṣe ń fìfẹ́ tọ́ wọn sọ́nà, ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìlànà rẹ̀ pípé! (Jòhánù 4:24) Bẹ́ẹ̀ ni, nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín, ọwọ́ àwọn èèyàn á wá tẹ “ìyè tòótọ́” tí Ọlọ́run ṣèlérí!

Àmọ́, bí Bíbélì ṣe sọ tẹ́lẹ̀, ìwọ̀nba èèyàn kéréje ló máa tẹ́wọ́ gba ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run tí wọ́n á sì tipa bẹ́ẹ̀ jèrè ìyè. (Mátíù 7:13, 14) Ṣé wàá fẹ́ láti wà lára wọn? Bó o bá máa fẹ́ láti wà lára wọn, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń fi tọkàntọkàn rọ̀ ẹ́ pé kó o máa yẹ ìlànà Ọlọ́run tó wà nínú Ìwé Mímọ́ wò kó o sì jẹ́ kó máa ṣamọ̀nà rẹ. Bó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ìwọ náà á “tọ́” ọ wò, wàá sì rí i pé lóòótọ́ ni Jèhófà jẹ́ ẹni rere. (Sáàmù 34:8) Bí ọgbọ́n tí Ọlọ́run dá mọ́ àwọn ẹyẹ kì í ṣeé jẹ́ kí wọ́n ṣìnà ibi tí wọ́n ń lọ, bẹ́ẹ̀ náà ni Jèhófà ṣe máa darí àwọn èèyàn tó bá jẹ́ olóòótọ́ wọnú Párádísè láìkùnà.—Lúùkù 23:43.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8, 9]

“Aláyọ̀ ni àwọn onínú tútù, níwọ̀n bí wọn yóò ti jogún ilẹ̀ ayé.”—MÁTÍÙ 5:5

“Àwọn ọlọ́kàn tútù ni yóò ni ilẹ̀ ayé, ní tòótọ́, wọn yóò sì rí inú dídùn kíkọyọyọ nínú ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà.”—SÁÀMÙ 37:11

“Àgọ́ Ọlọ́run wà pẹ̀lú aráyé . . . Yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́.”—ÌṢÍPAYÁ 21:3, 4

“Àwọn adúróṣánṣán ni àwọn tí yóò máa gbé ilẹ̀ ayé, àwọn aláìlẹ́bi sì ni àwọn tí a óò jẹ́ kí ó ṣẹ́ kù sórí rẹ̀. Ní ti àwọn ẹni burúkú, a óò ké wọn kúrò lórí ilẹ̀ ayé gan-an; àti ní ti àwọn aládàkàdekè, a ó fà wọ́n tu kúrò lórí rẹ̀.”—ÒWE 2:21, 22

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́