ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w06 12/15 ojú ìwé 12-14
  • Wọ́n Ṣàwárí Ẹ́bílà Ìlú Àtijọ́ Tó Ti Di Ìgbàgbé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Wọ́n Ṣàwárí Ẹ́bílà Ìlú Àtijọ́ Tó Ti Di Ìgbàgbé
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ọ̀pọ̀ Ìtàn Nípa Ìlú Ẹ́bílà
  • Ìsìn Tí Wọ́n Ń Ṣe ní Ẹ́bílà
  • Àwọn Wàláà Ayé Àtijọ́ àti Bíbélì
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • B2 Ìbẹ̀rẹ̀ àti Ìrìn Àjò Àwọn Baba Ńlá
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • Lati Ori Yèyé Ayé Si Awọn Abo-Ọlọrun Ọlọ́mọyọyọ
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Mari Ìlú Pàtàkì Kan Láyé Àtijọ́ Tó Wà Nínú Aṣálẹ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
w06 12/15 ojú ìwé 12-14

Wọ́n Ṣàwárí Ẹ́bílà Ìlú Àtijọ́ Tó Ti Di Ìgbàgbé

Nígbà ẹ̀ẹ̀rùn ọdún 1962, ọ̀dọ́kùnrin ọmọ ilẹ̀ Ítálì kan tó ń jẹ́ Paolo Matthiae tó sì jẹ́ awalẹ̀pìtàn, ṣàyẹ̀wò àwọn pẹ̀tẹ́lẹ̀ tó wà lápá àríwá ìwọ̀ oòrùn ilẹ̀ Síríà, ṣùgbọ́n kò dá a lójú pé òun máa rí nǹkan kan níbẹ̀. Àwọn kan gbà pé ibi mélòó kan làwọn awalẹ̀pìtàn ti lè rí nǹkan gidi lápá àárín ilẹ̀ Síríà. Àmọ́ nígbà tí Matthiae fi ọdún méjì péré walẹ̀ ní ìlú Tẹli Mádẹ́kì tó jẹ́ nǹkan bí ọgọ́ta kìlómítà sí gúúsù ìlú Alépò, ó rí ohun kan tí ‘ọ̀pọ̀ èèyàn kà sí àwárí tó ṣe pàtàkì jù lọ nínú àwárí táwọn awalẹ̀pìtàn ṣe ní ọ̀rúndún ogún.’

ÀWỌN àkọsílẹ̀ ayé ọjọ́un fi hàn pé ìlú kan ti wà rí tí wọ́n ń pè ní Ẹ́bílà. Àmọ́ kò sẹ́ni tó mọ èyí tí wọ́n ti lè walẹ̀ kan àwókù ìlú náà lára àwọn òkìtì àlàpà tó wà káàkiri Àárín Gbùngbùn Ìlà Oòrùn ayé. Ọ̀kan nínú àwọn àkọsílẹ̀ ayé àtijọ́ sọ pé Ságónì ọba Ákádì ṣẹ́gun “ìlú Márì, Yámútì àti Ẹ́bílà.” Nínú àkọsílẹ̀ míì, ọba àwọn ará Súmà tó ń jẹ́ Gúdíà sọ pé wọ́n gbé àwọn igi gẹdú tó dára gan-an wá fóun láti “àwọn òkè tó wà ní Íbílà [Ẹ́bílà].” Orúkọ ìlú Ẹ́bílà tún fara hàn nínú àkọsílẹ̀ kan nílùú Kánákì nílẹ̀ Íjíbítì gẹ́gẹ́ bí ọkàn lára àwọn ìlú ayé ọjọ́un tí Fáráò Tútímósà Kẹta pa run. Gbogbo èyí jẹ́ ká rí ìdí táwọn awalẹ̀pìtàn fi ń wá bí wọ́n ṣe máa mọ ọ̀gangan ibi tí ìlú tí wọ́n ń pè ní Ẹ́bílà wà.

Nígbà táwọn awalẹ̀pìtàn túbọ̀ walẹ̀ ní ìlú Tẹli Mádẹ́kì, wọ́n rí ohun tí wọ́n ń wá. Lọ́dún 1968, wọ́n rí àfọ́kù ère Ibiti-Límì ọba Ẹ́bílà. Èdè àwọn ará Ákádì ni wọ́n sì fi kọ ọ̀rọ̀ ẹ̀jẹ́ kan sára ère náà, tó fi hàn pé ńṣe ni wọ́n fi júbà abo-òrìṣà wọn tí wọ́n ń pè ní Íṣítà, èyí tó “gbayì ní Ẹ́bílà.” Bí ìwádìí àwọn awalẹ̀pìtàn yìí ṣe jẹ́ kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í mọ “èdè, ìtàn àti àṣà ìṣẹ̀ǹbáyé tí wọn ò mọ̀ tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ nìyẹn.”

Lọ́dún 1974 sí 1975, àwọn awalẹ̀pìtàn rí àwọn wàláà kan tí wọ́n kọ ọ̀rọ̀ sí lára. Àwọn wàláà náà sì jẹ́ kí wọ́n mọ̀ dájú pé ìlú Ẹ́bílà ayé ọjọ́un ni wọ́n ń pè ní Tẹli Mádẹ́kì báyìí nítorí pé àìmọye ìgbà ni orúkọ Ẹ́bílà fara hàn lára wọn. Àwọn ohun tí wọ́n wà jáde látinú ilẹ̀ nílùú Tẹli Mádẹ́kì tún jẹ́ kí wọ́n rí i pé ẹ̀ẹ̀mejì ni ìlú Ẹ́bílà ti wà rí. Nígbà tó kọ́kọ́ di ìlú alágbára, àwọn ọ̀tá pa á rún. Lẹ́yìn náà wọ́n tún un kọ́, àmọ́ àwọn ọ̀tá tún pa á run ó sì di ìgbàgbé fún ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún.

Ọ̀pọ̀ Ìtàn Nípa Ìlú Ẹ́bílà

Orí pẹ̀tẹ́lẹ̀ ọlọ́ràá ni ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ìlú ayé ọjọ́un wà, bí irú pẹ̀tẹ́lẹ̀ ọlọ́ràá tó wà láàárín odò Tígírísì àti odò Yúfírétì níbi tó ṣeé ṣe kí iṣẹ́ ọ̀gbìn ti búrẹ́kẹ́. Ilẹ̀ Mesopotámíà làwọn ìlú tí Bíbélì kọ́kọ́ mẹ́nu kàn wà. (Jẹ́nẹ́sísì 10:10) Ó dà bíi pé “Àpáta Funfun” ni orúkọ náà Ẹ́bílà túmọ̀ sí, èyí tó fi hàn pé òkúta ẹfun ni ilẹ̀ ibi tí wọ́n kọ́ ìlú náà sí. Ẹ̀rí fi hàn pé òkúta ẹfun tí wọ́n rí yìí ló mú kí wọ́n tẹ ìlú náà dó síbẹ̀, nítorí ìyẹn fi hàn pé omi wà lágbègbè náà, èyí tó ṣe pàtàkì ní àgbègbè tí odò ńlá jìn sí.

Nítorí pé òjò kì í fi bẹ́ẹ̀ rọ̀ ní àgbègbè ibi tí ìlú Ẹ́bílà wà, àwọn ará ibẹ̀ ò lè ṣiṣẹ́ àgbẹ̀ aládàá ńlá, àwọn ohun tí wọ́n sì ń gbìn ò kọjá oúnjẹ oníhóró, àjàrà àti igi ólífì. Àgbègbè náà tún dára fún iṣẹ́ ẹran sísìn, pàápàá àgùntàn. Bí ìlú Ẹ́bílà ṣe wà láàárín pẹ̀tẹ́lẹ̀ Mesopotámíà àti Etíkun Mẹditaréníà mú kí ibẹ̀ dára fún òwò igi gẹdú, òwò òkúta iyebíye àti irin. Ìlú Ẹ́bílà ń ṣàkóso àgbègbè táwọn èèyàn tó tó nǹkan bí ọ̀kẹ́ mẹ́wàá [200,000] ń gbé, nǹkan bí ìdá mẹ́wàá iye yìí, ìyẹn ọ̀kẹ́ kan [20,000], ló sì ń gbé ní Ẹ́bílà tí í ṣe olú ìlú.

Àwókù ààfin ńlá kan tí wọ́n walẹ̀ kàn fi bí ọ̀làjú àwọn ará Ẹ́bílà ṣe tó nígbà yẹn hàn. Ilẹ̀kùn ńlá téèyàn á gbà kọjá kó tó lè wọnú ààfin náà ga tó ogójì sí àádọ́ta ẹsẹ̀ bàtà. Nígbà yẹn, ńṣe ni wọ́n ń fẹ ààfin náà sí i bí àwọn tó wà nínú ètò ìjọba wọn alágbára ṣe ń pọ̀ sí i. Ètò ìjọba ìlú Ẹ́bílà pín sí oríṣiríṣi ẹ̀ka. Àwọn kan wà tí wọ́n ń pè ní olúwa àtàwọn kan tí wọ́n ń pè ní alàgbà, àwọn ló ń ran ọba àti ayaba lọ́wọ́.

Wọ́n ti rí ohun tó lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́tàdínlógún [17,000] wàláà amọ̀ tó ṣì wà lódindi àtèyí tó ti di àfọ́kù. Ó ṣeé ṣe káwọn odindi wàláà tí wọ́n kọ́kọ́ rí ju ẹgbẹ̀rún mẹ́rin lọ, orí ṣẹ́ẹ̀fù onípákó tí wọ́n rọra tò wọ́n sí ni wọ́n sì ti bá wọn. Ọ̀rọ̀ tí wọ́n kọ sára àwọn wàláà náà fi bí iṣẹ́ káràkátà ìlú Ẹ́bílà ṣe búrẹ́kẹ́ tó hàn. Bí àpẹẹrẹ, àwọn nǹkan tí wọ́n rí àmì ọba Fáráò méjì lára wọn fi hàn pé ìlú náà àti Íjíbítì ń bára wọn ṣòwò. Ọ̀nà ìgbàkọ̀wé àwọn ará Súmà ni wọ́n fi kọ ọ̀rọ̀ sára ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn wàláà náà. Àmọ́ èdè àwọn ará Ẹ́bílà tó jẹ́ ọ̀kan lára èdè tí àwọn ẹ̀yà tó jẹ́ ìran Ṣémù ń sọ láyé ọjọ́un ni wọ́n fi kọ àwọn kan lára wọn. Ọpẹ́lọpẹ́ àwọn wàláà tí wọ́n sì rí wọ̀nyí ni wọ́n fi lè lóye èdè àwọn ará Ẹ́bílà náà. Nígbà táwọn onímọ̀ nípa apá ìlà oòrùn ayé rí èdè ìran Ṣémù tó pẹ́ tó yẹn, orí wọn wú. Ohun míì nípa àwọn wàláà náà ni pé èdè méjì ni wọ́n fi kọ ọ̀rọ̀ sí àwọn kan lára wọn. Tí wọ́n bá ti fi èdè Súmà kọ nǹkan kan, wọ́n á wá kọ ohun tó túmọ̀ sí ní èdè àwọn ará Ẹ́bílà. Ìwé náà, Ebla—Alle origini della civiltà urbana (Ẹ́bílà Láyé Ìgbà Tí Ọ̀làjú Ṣẹ̀ṣẹ̀ Bẹ̀rẹ̀) sọ pé àwọn wàláà náà ni “ìwé atúmọ̀ èdè tó tíì pẹ́ jù lọ tá a mọ̀.”

Ó hàn gbangba pé alágbára ni wọ́n nílùú Ẹ́bílà tó bá dọ̀rọ̀ ogun jíjà, nítorí pé àwọn awalẹ̀pìtàn rí ère àwọn ọmọ ogun tó ń pa àwọn ọ̀tá wọn tàbí tí wọ́n gbé orí tí wọ́n bẹ́ dání. Bí ìlú Ẹ́bílà sì ṣe lágbára tó yẹn náà, nígbà tó forí gbárí pẹ̀lú Ásíríà àti Bábílónì báwọn yẹn ṣe ń di alágbára, ó pa run, ògo rẹ̀ sì wọmi. Kò tíì ṣeé ṣe fún àwọn awalẹ̀pìtàn láti ṣàwárí bí wọ́n ṣe gbógun jà á gẹ́lẹ́, àmọ́ ó dà bíi pé Ọba Ságónì Kìíní (tó yàtọ̀ sí Ságónì tí Aísáyà 20:1 mẹ́nu kàn) ló gbógun ja ìlú Ẹ́bílà, Naramu-Sínì tí í ṣe ọmọ ọmọ rẹ̀ sì tún gbógun jà á lẹ́yìn náà. Ohun táwọn awalẹ̀pìtàn rí fi hàn pé ńṣe ni wọ́n gbógun jà á lọ́nà tó burú jáì, wọ́n sì run ún nírun ìkà.

Àmọ́ bá a ṣe sọ lẹ́ẹ̀kan, wọ́n tún ìlú náà kọ́ ó sì tún di ìlú pàtàkì lágbègbè tó wà. Ńṣe ni wọ́n dìídì ṣètò bí wọ́n ṣe fẹ́ kí ìlú tuntun náà rí kí wọ́n tó kọ́ ọ, èyí tó mú kí ògo rẹ ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Ibì kan wà lápá ìsàlẹ̀ ìlú náà tí wọ́n yà sí mímọ́ fún abo-òrìṣà wọn tí wọ́n ń pè ní Íṣítà, èyí táwọn ará Bábílónì kà sí abo-òrìṣà afúnnilọ́mọ. Ó ṣeé ṣe kó o ti gbọ́ nípa Ẹnubodè Íṣítà tó gbajúmọ̀ tí wọ́n walẹ̀ kàn nínú àwókù ìlú Bábílónì. Wọ́n rí ilé gbàràmù-gbaramu kan ní Ẹ́bílà tó dà bíi pé wọ́n máa ń kó àwọn kìnnìún tí wọ́n gbà gbọ́ pé ó jẹ́ ohun mímọ́ fún abo-òrìṣà Íṣítà sí. Èyí ló mú wa dorí ohun tó kàn láti gbé yẹ̀ wò báyìí, ìyẹn irú ìsìn tí wọ́n ń ṣe ní Ẹ́bílà.

Ìsìn Tí Wọ́n Ń Ṣe ní Ẹ́bílà

Àìmọye òrìṣà ni wọ́n ń bọ ní ìlú Ẹ́bílà bíi tàwọn ìlú tí wọ́n jọ wà ní Ìlà Oòrùn ayé nígbà láéláé. Díẹ̀ lára àwọn òrìṣà náà ni Báálì, Hádádì (táwọn ọba Síríà kan máa ń jórúkọ mọ́), àti Dágánì. (1 Àwọn Ọba 11:23; 15:18; 2 Àwọn Ọba 17:16) Gbogbo àwọn òrìṣà wọ̀nyí sì làwọn ará ìlú Ẹ́bílà bẹ̀rù. Kódà wọ́n tún máa ń júbà àwọn òrìṣà táwọn ìlú míì ń bọ. Àwárí táwọn awalẹ̀pìtàn ṣe sì tún fi hàn pé àwọn ará Ẹ́bílà sọ àwọn babańlá tó wá láti ìdílé ọba di òrìṣà àkúnlẹ̀bọ, àgàgà ní ọ̀rúndún kejì ṣáájú Sànmánì Kristẹni.

Àwọn ará ìlú Ẹ́bílà ò gbẹ́kẹ̀ lé àwọn òrìṣà wọn pátápátá. Nígbà tí wọ́n tún ìlú náà kọ́, odi gìrìwò méjì ni wọ́n mọ yí po rẹ̀, èyí tó lè mú kọ́wọ́ àwọn ọ̀tá tó bá fẹ́ gbógun jà wọ́n rọ jọwọrọ. Téèyan bá rin èyí tó kángun síta nínú àwọn odi náà yí po, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó kìlómítà mẹ́ta. Téèyàn bá débẹ̀, èèyàn á ṣì rí i pé bó ṣe rí nìyẹn.

Bó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ìlú Ẹ́bílà tí wọ́n tún kọ́ náà tún padà pa run. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àwọn ọmọ Hétì ló pa ìlú tó ti fìgbà kan rí jẹ́ alágbára yìí run gbẹ̀yìn ní nǹkan bí ọdún 1600 ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Ewì ayé àtijọ́ kan tiẹ̀ sọ pé ńṣe ni wọ́n ‘fọ́ Ẹ́bílà yángá bí ohun èlò amọ̀.’ Kò pẹ́ lẹ́yìn tí wọ́n pa á run táwọn èèyàn fi gbàgbé rẹ̀. Àwọn ajagun ẹ̀sìn Kristẹni tí wọ́n wá sí Jerúsálẹ́mù lọ́dún 1098 torí àtigba ilẹ̀ mímọ́ padà sọ nínú ìwé kan tí wọ́n kọ, pé ìlú kéréje kan ló wà ní ibi tí Ẹ́bílà wà nígbà kan rí, Mádẹ́kì sì ni wọ́n ń pe ìlú ọ̀hún. Ká ní kì í ṣe pé wọ́n ṣàwárí Ẹ́bílà lẹ́yìn ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún tó ti pa run ni, ńṣe ni ì bá di ìgbàgbé pátápátá.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 14]

BÍ Ọ̀RỌ̀ OHUN TÍ WỌ́N RÍ NÍ Ẹ́BÍLÀ ṢE KAN BÍBÉLÌ

Nígbà táwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ nípa Bíbélì ka àpilẹ̀kọ táwọn kan tẹ̀ jáde lọ́dún 1976 nínú ìwé ìròyìn Biblical Archeologist, wọ́n fẹ́ láti mọ̀ sí i nípa ohun tí àpilẹ̀kọ náà ń sọ. Ó ṣẹlẹ̀ pé ẹni tó ka ọ̀rọ̀ tó wà lára àwọn wàláà tí wọ́n rí ní Ẹ́bílà tó sì túmọ̀ rẹ̀ sọ pé ó ṣeé ṣe káwọn wàláà náà dárúkọ àwọn èèyàn àti ìlú tí Bíbélì wá mẹ́nu kàn lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn. Ó dà bíi pé àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan sọ kọjá ohun tí ẹni yìí sọ, torí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í kọ̀wé pé ohun táwọn awalẹ̀pìtàn rí ní Ẹ́bílà jẹ́rìí sí i pé òótọ́ pọ́ńbélé ni àkọsílẹ̀ ìwé Jẹ́nẹ́sísì.a Ọ̀gbẹ́ni Mitchell Dahood tó jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ kan nínú ìjọ Kátólíìkì tiẹ̀ sọ pé “àwọn wàláà amọ̀ [tí wọ́n rí ní Ẹ́bílà] ń jẹ́ kéèyàn lóye àwọn ibi tó díjú nínú Bíbélì.” Bí àpẹẹrẹ, ó gbà pé wọ́n lè jẹ́ kéèyàn mọ “bó ṣe pẹ́ tó tí wọ́n ti ń lo orúkọ Ọlọ́run Ísírẹ́lì.”

Àyẹ̀wò ń lọ lórí àwọn ohun tí wọ́n kọ́ sára wàláà náà láti lè mọ ohun tí wọ́n ń sọ gan-an. Níwọ̀n bí èdè Hébérù àti èdè àwọn ará Ẹ́bílà ti jẹ́ èdè àwọn ẹ̀yà tó jẹ́ ìran Ṣémù, ó ṣeé ṣe kí orúkọ àwọn ìlú tàbí orúkọ àwọn èèyàn kan tí wọ́n rí lára àwọn wàláà náà jọ èyí tó wà nínú Bíbélì. Àmọ́ ìyẹn ò fi hàn pé àwọn èèyàn tàbí ìlú tí Bíbélì mẹ́nu kàn gẹ́lẹ́ làwọn tí wọ́n rí lára àwọn wàláà náà. Ká ṣì máa wo bí àwárí tí wọ́n ṣe ní Ẹ́bílà ṣe máa wúlò tó fún àwọn tó ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa Bíbélì. Lórí ọ̀rọ̀ ti orúkọ Ọlọ́run sì rèé, ẹni tó kọ àpilẹ̀kọ tá a mẹ́nu kàn lẹ́ẹ̀kan nínú ìwé ìròyìn Biblical Archeologist ti kó ọ̀rọ̀ ara rẹ̀ jẹ, ó ní òun ò sọ pé orúkọ náà “Yahweh” wà lára àwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n kọ sára àwọn wàláà tí wọ́n rí ní Ẹ́bílà. Àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan sọ pé lójú tàwọn, ńṣe ni ọ̀rọ̀ ara wàláà náà tí wọ́n túmọ̀ sí ja wulẹ̀ jẹ́ orúkọ ọ̀kan lára ọ̀pọ̀ òrìṣà táwọn ará Ẹ́bílà ń bọ, àwọn míì sì sọ pé ńṣe ni ja wulẹ̀ jẹ́ ọ̀rọ̀ kan nínú èdè àwọn ará Ẹ́bílà. Èyí ó wù ó jẹ́, ohun tá a mọ̀ ni pé ọ̀rọ̀ náà kò túmọ̀ sí orúkọ Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà, Jèhófà.—Diutarónómì 4:35; Aísáyà 45:5.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Tó o bá fẹ́ rí àlàyé lórí bí àwọn nǹkan táwọn awalẹ̀pìtàn rí ṣe fi hàn pé òótọ́ ni àkọsílẹ̀ Bíbélì, wo ojú ìwé 14 sí 17 nínú ìwé tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ìwé Kan Tí Ó Wà fún Gbogbo Ènìyàn. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.

[Map/Picture on page 12]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

ÒKUN ŃLÁ

KÉNÁÁNÌ

SÍRÍÀ

Alépò

Ẹ́bílà (Tẹli Mádẹ́kì)

Odò Yúfírétì

[Credit Line]

Awalẹ̀pìtàn: Missione Archeologica Italiana a Ebla - Università degli Studi di Roma ‘La Sapienza’

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12, 13]

Ẹ̀gbà ọrùn góòlù tí wọ́n ṣe ní nǹkan bí ọdún 1750 ṣáájú Sànmánì Kristẹni

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]

Àwókù ààfin ńlá

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]

Àwòrán bí àwọn wàláà tí wọ́n kó sínú yàrá ìtọ́jú-nǹkan-pamọ́ ṣe rí

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]

Wàláà tí wọ́n kọ ọ̀rọ̀ sí lára

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]

Ọ̀pá ọba Íjíbítì tí wọ́n lò lọ́dún 1750 sí 1700 ṣáájú Sànmánì Kristẹni

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]

Ọmọ ogun Ẹ́bílà kan tó gbé orí àwọn ọ̀tá tí wọ́n bẹ́ dání

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]

Òkúta tí wọ́n fi ṣe ìrántí abo-òrìṣà Íṣítà

[Credit Line]

Missione Archeologica Italiana a Ebla - Università degli Studi di Roma ‘La Sapienza’

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 13]

Ibi tá a ti mú gbogbo àwòrán tó wà ní ojú ìwé méjèèjì (yàtọ̀ sí àwòrán ilẹ̀): Missione Archeologica Italiana a Ebla - Università degli Studi di Roma ‘La Sapienza’

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́