ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w07 6/15 ojú ìwé 12-14
  • Ernst Glück Ṣe Iṣẹ́ Takuntakun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ernst Glück Ṣe Iṣẹ́ Takuntakun
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Bó Ṣe Gbára Dì fún Iṣẹ́ Ìtumọ̀ Náà
  • Ó Gba Ọ̀pọ̀ Ọdún àti Sùúrù
  • Iṣẹ́ Tó Ṣe Lẹ́yìn Ìgbà Náà
  • Ìṣẹ̀lẹ̀ Mánigbàgbé Fáwọn Tó Fẹ́ràn Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Ìtumọ̀ Ayé Tuntun Ọ̀kẹ́ Àìmọye Èèyàn Mọyì Rẹ̀ Kárí Ayé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
  • Jèhófà Máa Ń Bá Àwa Èèyàn Sọ̀rọ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
  • Bíbélì Tó Rọrùn Láti Lóye
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
w07 6/15 ojú ìwé 12-14

Ernst Glück Ṣe Iṣẹ́ Takuntakun

NÍ ÈYÍ tó ju ọ̀ọ́dúnrún [300] ọdún sẹ́yìn, ọ̀gbẹ́ni Ernst Glück dáwọ́ lé iṣẹ́ kan tó jẹ́ pé ìwọ̀nba èèyàn ló tíì dán irú ẹ̀ wò láyé yìí. Ó pinnu láti túmọ̀ Bíbélì sí èdè tóun alára ò mọ̀.

Nǹkan bí ọdún 1654 ni wọ́n bí Glück nílùú kékeré kan tó ń jẹ́ Wettin, nítòsí ìlú Halle nílẹ̀ Jámánì. Bàbá rẹ̀ jẹ́ pásítọ̀ nínú ìjọ Luther. Wọ́n fẹ́ràn ẹ̀sìn gan-an nílé àwọn Ernst, èyí sì mú kí Ernst nífẹ̀ẹ́ sí ẹ̀kọ́ nípa Ọlọ́run. Nígbà tó di ọmọ ọdún mọ́kànlélógún, ó parí ẹ̀kọ́ rẹ̀ nílé ẹ̀kọ́ ìsìn ní Jámánì, ó sì lọ síbi tí wọ́n ń pè ní Latvia lóde òní. Nígbà yẹn lọ́hùn-ún, ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn tó wà ní ìgbèríko ní Latvia ló jẹ́ púrúǹtù, ìwọ̀nba ìwé ló sì wà lédè Latvia tó jẹ́ èdè wọn. Glück kọ̀wé pé: “Bí mo ṣe dé ilẹ̀ yìí nígbà tí mo wà lọ́dọ̀ọ́, ohun àbùkù tí mo kọ́kọ́ ṣàkíyèsí ni pé ṣọ́ọ̀ṣì tó ń lo èdè Latvia kò ní Bíbélì . . . Èyí mú kí n pinnu níwájú Ọlọ́run pé màá kọ́ èdè yìí màá sì mọ̀ ọ́n dọ́ba.” Ó fẹ́ rí i dájú pé òun bá àwọn elédè Latvia túmọ̀ Bíbélì sí èdè wọn.

Bó Ṣe Gbára Dì fún Iṣẹ́ Ìtumọ̀ Náà

Láyé ìgbà yẹn, Livonia ni wọ́n ń pe ibi tí Glück lọ yẹn, orílẹ̀-èdè Sweden ló sì ń ṣàkóso ibẹ̀. Ẹni tó jẹ́ aṣojú ọba ilẹ̀ Sweden níbẹ̀ ni Johannes Fischer. Aṣojú ọba yìí fẹ́ káwọn èèyàn púpọ̀ sí i ní ilẹ̀ Livonia dẹni tó kàwé, ó sì tún fẹ́ rí towó ṣe. Ọ̀gbẹ́ni Glück bá Fischer yìí sọ̀rọ̀ nípa ìfẹ́ ọkàn rẹ̀ láti túmọ̀ Bíbélì sí èdè Latvia. Níwọ̀n bí Fischer sì ti ní ẹ̀rọ ìtẹ̀wé kan nílùú Riga tó jẹ́ olú ìlú ilẹ̀ náà, tó bá tẹ Bíbélì èdè Latvia yìí, yóò mú ìtẹ̀síwájú bá ìmọ̀ ẹ̀kọ́ tó fẹ́ káwọn èèyàn ibẹ̀ ní, ó sì tún lè tipa bẹ́ẹ̀ pawó sápò. Ni Fischer bá sọ fún Charles Kọkànlá tó jẹ́ ọba ilẹ̀ Sweden pé kó yọ̀ǹda kí Glück ṣe iṣẹ́ ìtúmọ̀ Bíbélì náà. Ọba yìí wá yọ̀ǹda kó ṣe é, ó sì tún lóun máa gbé ìnáwó rẹ̀. Ìwé àṣẹ kan tí ọba yẹn fọwọ́ sí ní ọjọ́ kọkànlélọ́gbọ̀n oṣù August ọdún 1681 ló fi yọ̀ǹda pé kó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìtumọ̀ Bíbélì náà.

Ní gbogbo ìgbà yìí, Glück ti ń gbára dì fún iṣẹ́ ìtumọ̀ náà. Níwọ̀n bó ti mọ èdè Jámánì dáadáa, ó lè lo Bíbélì tí Martin Luther túmọ̀ láti fi túmọ̀ Bíbélì sí èdè Latvia. Àmọ́ kò ṣe bẹ́ẹ̀, torí ohun tó ń fẹ́ ni pé kí ìtumọ̀ Bíbélì tóun máa ṣe dára ju gbogbo àwọn tó ti wà tẹ́lẹ̀ lọ. Ìyẹn ló fi wò ó pé Bíbélì ti èdè Hébérù àti Gíríìkì ìjímìjí ló máa dára kóun lò láti fi túmọ̀ rẹ̀. Ṣùgbọ́n Glück ò fi bẹ́ẹ̀ mọ èdè Hébérù àti ti Gíríìkì dáadáa, nítorí náà ó lọ sílùú Hamburg nílẹ̀ Jámánì láti lọ kẹ́kọ̀ọ́ nípa èdè Hébérù àti Gíríìkì. Ó jọ pé nígbà tó wà nílé ẹ̀kọ́ yìí, àlùfáà kan tó ń jẹ́ Jānis Reiters, ọmọ ilẹ̀ Livonia, kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ nípa èdè Latvia àti nípa èdè Gíríìkì tí wọ́n fi kọ Bíbélì.

Ó Gba Ọ̀pọ̀ Ọdún àti Sùúrù

Ọ̀gbẹ́ni Glück parí ẹ̀kọ́ èdè tó ń kọ́ lọ́dún 1680, ó padà sí Latvia, ó sì di pásítọ̀ ìjọ. Kò sì pẹ́ tó fi bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìtumọ̀ rẹ̀. Lọ́dún 1683, wọ́n yàn án ṣe pásítọ̀ ìjọ ńlá tó wà nílùú Alūksne, tó wá di ibi táwọn èèyàn mọ̀ gẹ́gẹ́ bí ibi tó ti túmọ̀ Bíbélì sí èdè Latvia.

Nígbà náà lọ́hùn-ún, èdè Latvia ò lọ́rọ̀ tí wọ́n lè fi túmọ̀ ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ àtàwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì inú Bíbélì. Ìyẹn mú kí Glück lo àwọn ọ̀rọ̀ kan látinú èdè Jámánì nínú ìtumọ̀ rẹ̀. Àmọ́ ó sa gbogbo ipá rẹ̀ láti rí i pé òun túmọ̀ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sí èdè Latvia, àwọn àgbà ọ̀mọ̀wé sì gbà pé ojúlówó iṣẹ́ ìtumọ̀ ló ṣe. Ọ̀gbẹ́ni Glück tiẹ̀ fúnra rẹ̀ hùmọ̀ ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ lédè Latvia, púpọ̀ irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ ló sì wá di èyí tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn tó ń sọ èdè Latvia ń lò lóde òní. Lára àwọn ọ̀rọ̀ tó hùmọ̀ lédè Latvia ni “àpẹẹrẹ,” “àsè,” “òmìrán,” “ṣíṣe amí,” àti “jíjẹ́ ẹ̀rí.”

Gbogbo bí iṣẹ́ ìtumọ̀ yẹn ṣe ń tẹ̀ síwájú ni Johannes Fischer fi ń tó ọba ilẹ̀ Sweden létí, ó sì hàn látinú ìwé tí ọba yìí àti Johannes Fischer ń kọ síra wọn pé nígbà tó fi máa di ọdún 1683, Glück ti tú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì tán. Ó parí ìtumọ̀ Bíbélì látòkèdélẹ̀ lọ́dún 1689, tó fi hàn pé ọdún mẹ́jọ péré ló fi ṣe iṣẹ́ takuntakun tó ṣe.a Ó pẹ́ gan-an kí wọ́n tó tẹ Bíbélì tó túmọ̀ jáde, àmọ́ lọ́dún 1694 ọwọ́ rẹ̀ tẹ ohun tó ń lépa, ìjọba yọ̀ǹda pé kí wọ́n máa ta Bíbélì èdè Latvia yìí fáwọn aráàlú.

Àwọn òpìtàn kan sọ pé bóyá ló fi máa jẹ́ pé Glück nìkan ló tú Bíbélì náà. Lóòótọ́, kò sí àní-àní pé ó kàn sí Bíbélì ti Luther, ó sì fi àwọn ẹsẹ Bíbélì kan táwọn èèyàn ti túmọ̀ sí èdè Latvia kún ìtumọ̀ tirẹ̀ lẹ́yìn tó ti ṣàtúnṣe sí wọn. Àmọ́ ìwọ̀nba díẹ̀ ni ìwọ̀nyẹn kàn jẹ́ lára iṣẹ́ ìtumọ̀ tó ṣe. Ǹjẹ́ olùtumọ̀ kankan bá a tú lára Bíbélì náà? Ẹnì kan wà tó ń ṣèrànlọ́wọ́ fún un nígbà tó ń tú Bíbélì yẹn, àwọn míì sì ń bá a yẹ̀ ẹ́ wò láti tọ́ka sí àtúnṣe tó bá yẹ àti láti wo bí ìtumọ̀ rẹ̀ ṣe péye sí. Àmọ́ ó jọ pé àwọn yẹn ò bá a ṣiṣẹ́ ìtumọ̀ ní tààràtà. Nítorí náà, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé Glück nìkan ló túmọ̀ rẹ̀.

Kò sí àní-àní pé ìtẹ̀síwájú pàtàkì ni iṣẹ́ ìtumọ̀ tí Glück ṣe mú bá bí wọ́n ṣe ń kọ èdè Latvia, àmọ́ ó tún yọrí sí ohun kan tó ṣe pàtàkì jù bẹ́ẹ̀ lọ. Ó jẹ́ káwọn èèyàn ilẹ̀ Latvia dẹni tó wá ń rí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kà lédè wọn, kí wọ́n sì máa kọ́ ẹ̀kọ́ inú rẹ̀ tó ń múni rí ìyè. Àwọn èèyàn náà ò gbàgbé ohun tí Ernst Glück ṣe fún wọn. Láti èyí tó lè ní ọ̀ọ́dúnrún [300] ọdún sẹ́yìn làwọn aráàlú Alūksne ti ń tọ́jú igi óákù méjì kan tí wọ́n sọ ní Glika ozoli, tó túmọ̀ sí igi óákù Glück. Ọ̀gbẹ́ni Glück ló gbìn wọ́n láti fi máa ṣèrántí wíwà tí Bíbélì wà lédè Latvia. Wọ́n fi ẹ̀dà kan lára àwọn tí wọ́n kọ́kọ́ tẹ̀ jáde nínú Bíbélì tí Glück túmọ̀ sí ilé ìkóhun-ìsèǹbáyé-sí kékeré kan tó wà nílùú Alūksne níbi tí wọ́n kó onírúurú ìtumọ̀ Bíbélì sí. Wọ́n tún yàwòrán Bíbélì, wọ́n sì kọ ọdún náà 1689, tó jẹ́ ọdún tí Glück parí iṣẹ́ ìtumọ̀ rẹ̀, sára àmì tó dúró fún ìlú Alūksne.

Iṣẹ́ Tó Ṣe Lẹ́yìn Ìgbà Náà

Láìpẹ́ lẹ́yìn tí Glück dé ìlú Latvia, ó bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ èdè Rọ́ṣíà. Lọ́dún 1699, ó kọ̀wé pé òun tún fẹ́ gbé iṣẹ́ míì ṣe, ìyẹn ni láti túmọ̀ Bíbélì sí èdè Rọ́ṣíà. Ó kọ ọ́ sínú lẹ́tà kan tó kọ lọ́dún 1702 pé òun ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe àwọn àtúnṣe sí Bíbélì èdè Latvia. Àmọ́ kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ ló ń di pé kò fi bẹ́ẹ̀ rọrùn mọ́ láti ṣe iṣẹ́ ìtumọ̀ Bíbélì níbẹ̀. Ilẹ̀ Latvia tó jẹ́ ibi tí àlàáfíà ti wà fún ọ̀pọ̀ ọdún wá di ibi tí ogun gbà kan. Lọ́dún 1702 àwọn ọmọ ogun Rọ́ṣíà ṣẹ́gun àwọn ọmọ ogun orílẹ̀-èdè Sweden, ìlú Alūksne sì bọ́ sábẹ́ ilẹ̀ Rọ́ṣíà. Ló bá di pé wọ́n fipá kó Glück àti ìdílé rẹ̀ lọ sí ilẹ̀ Rọ́ṣíà.b Ìgbà hílàhílo yìí ni àwọn ìwé àtúnṣe Bíbélì èdè Latvia tí Glück fọwọ́ kọ àti ìtumọ̀ tó ti ṣe lórí Bíbélì èdè Rọ́ṣíà sọ nù. Ọdún 1705 ni Glück sì kú nílùú Moscow.

Àdánù ńlá gbáà ló jẹ́ báwọn ìwé àtúnṣe Bíbélì èdè Latvia tí Glück fọwọ́ kọ àti ìtumọ̀ tó ti ṣe lórí Bíbélì èdè Rọ́ṣíà ṣe sọ nù. Ṣùgbọ́n títí dòní yìí, gbogbo àwọn tó bá ń ka Bíbélì lédè Latvia ló ń jàǹfààní iṣẹ́ ìtumọ̀ tí Glück ṣe nígbà náà lọ́hùn-ún.

Ńṣe ni Ernst Glück kàn jẹ́ ọ̀kan nínú ọ̀pọ̀ àwọn tó ti túmọ̀ Bíbélì sí èdè ìbílẹ̀, èyí tó jẹ́ iṣẹ́ ribiribi. Nípa báyìí, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo èdè làwọn èèyàn ti lè ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lédè wọn, kí wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ rí omi òtítọ́ tó ṣeyebíye mu. Láìsí àní-àní, Jèhófà ń tipa onírúurú Bíbélì tó wà ní èdè tó lé ní ẹgbàá [2,000] sọ ara rẹ̀ di mímọ̀ fáwọn èèyàn níbi gbogbo.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ní ìfiwéra, iṣẹ́ àṣekára ọdún méje làwọn ọ̀mọ̀wé mẹ́tàdínláàádọ́ta [47] ṣe kí wọ́n tó parí iṣẹ́ ìtumọ̀ Bíbélì èdè Gẹ̀ẹ́sì tí wọ́n ń pè ní King James Version lọ́dún 1611.

b Ọmọbìnrin kan tí Glück ṣe alágbàtọ́ rẹ̀ wá di ìyàwó Peter Ńlá tó jẹ́ olú ọba ilẹ̀ Rọ́síà nígbà tó yá. Lọ́dún 1725 tí Peter kú, ìyàwó rẹ̀ yìí wá di ọbabìnrin ilẹ̀ Rọ́síà, tí wọ́n ń pè ní Catherine Kìíní.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]

Bíbélì tí Glück túmọ̀

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń fi Bíbélì kọ́ni ní ìlú tí Glück ti túmọ̀ Bíbélì

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́