ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w08 2/1 ojú ìwé 8-9
  • Kí Ni Ká Máa Retí Lọ́jọ́ Ọ̀la?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kí Ni Ká Máa Retí Lọ́jọ́ Ọ̀la?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Bí Ohun Tí Bíbélì Sọ Ṣe Lè Jẹ́ Ká Ní Ojúlówó Ìbàlẹ̀ Ọkàn
  • Kí Ni Ìjọba Ọlọ́run?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • Walaaye Titilae Ninu Paradise Ori Ilẹ̀-ayé Kan
    Ki Ni Ète Igbesi-Aye? Bawo Ni Iwọ Ṣe Le Rí I?
  • Paradise Ilẹ-aye Naa
    Ẹmi Awọn Oku—Wọn Ha Le Ran ọ Lọwọ Tabi Pa Ọ Lara Bi? Wọn Ha wa Niti Gidi Bi?
  • Ìgbésí Ayé Nínú Ayé Tuntun Alálàáfíà Kan
    Ìgbésí Ayé Nínú Ayé Tuntun Alálàáfíà Kan
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
w08 2/1 ojú ìwé 8-9

Kí Ni Ká Máa Retí Lọ́jọ́ Ọ̀la?

KÍ NÌDÍ TÓ FI ṢE PÀTÀKÌ PÉ KÁ RÍ ÌDÁHÙN ÌBÉÈRÈ YÌÍ? Ohun téèyàn ń retí lọ́jọ́ ọ̀la máa ń nípa lórí bó ṣe ń gbé ìgbé ayé rẹ̀ lónìí. Bí àpẹẹrẹ, àwọn tí kò nírètí pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa, lè máa sọ pé: “Ẹ jẹ́ kí a máa jẹ, kí a sì máa mu, nítorí ọ̀la ni àwa yóò kú.” (1 Kọ́ríńtì 15:32) Irú ìwà bẹ́ẹ̀ kì í jẹ́ kí wọ́n ní ìbàlẹ̀ ọkàn. Ńṣe ló máa ń sọ wọ́n di alájẹkì àti ọ̀mùtípara, ó sì tún máa ń kó àníyàn bá wọn.

Láìsí àní-àní, tó bá jẹ́ pé èèyàn la gbẹ́kẹ̀ lé pé ó máa mú kí ayé yìí dáa, asán ni ìgbẹ́kẹ̀lé wa máa já sí. Ńṣe làwọn ọmọ èèyàn túbọ̀ ń ba afẹ́fẹ́, omi àti ilẹ̀ jẹ́ sí i. Ẹrù sì túbọ̀ ń ba àwọn èèyàn pé ogun ọ̀gbálẹ̀gbáràwé lè wáyé nígbàkigbà àti pé àwọn apániláyà lè ṣọṣẹ́ lójijì. Àrùn àti ipò òṣì tún ń bá ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn yí ká ayé fínra. Àmọ́ o, ìrètí ṣì ńbẹ.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn ò lè sọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ ọ̀la kó sì rí bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́, Jèhófà Ọlọ́run fi hàn pé òun ni “Ẹni tí ó ń ti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ sọ paríparí òpin, tí ó sì ń ti ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn sọ àwọn nǹkan tí a kò tíì ṣe.” (Aísáyà 46:10) Kí ni Jèhófà wá sọ nípa ohun tá a lè máa retí lọ́jọ́ ọ̀la?

Ohun Tí Bíbélì Sọ

Jèhófà kò ní gbà kí ọmọ èèyàn ba ayé àtàwọn ohun tó dá sínú rẹ̀ jẹ́ kọjá àtúnṣe. Bíbélì tiẹ̀ ṣèlérí pé Ọlọ́run yóò “run àwọn tí ń run ilẹ̀ ayé.” (Ìṣípayá 11:18) Jèhófà yóò lo Ìjọba rẹ̀ tí yóò ṣàkóso látọ̀runwá láti fi mú ìwà ibi kúrò lórí ilẹ̀ ayé, yóò sì fi sọ ayé di Párádísè bó ṣe fẹ́ kó rí níbẹ̀rẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 1:26-31; 2:8, 9; Mátíù 6:9, 10) Àwọn ẹsẹ Bíbélì ìsàlẹ̀ yìí, tó sọ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí yóò kan gbogbo aráyé láìpẹ́, jẹ́ ká mọ ohun tá a lè máa retí lọ́jọ́ ọ̀la.

Sáàmù 46:8, 9. “Ẹ wá wo àwọn ìgbòkègbodò Jèhófà, bí ó ti gbé àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ayanilẹ́nu kalẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé. Ó mú kí ogun kásẹ̀ nílẹ̀ títí dé ìkángun ilẹ̀ ayé. Ó ṣẹ́ ọrun sí wẹ́wẹ́, ó sì ké ọ̀kọ̀ sí wẹ́wẹ́; ó sun àwọn kẹ̀kẹ́ nínú iná.”

Aísáyà 35:5, 6. “Ní àkókò yẹn, ojú àwọn afọ́jú yóò là, etí àwọn adití pàápàá yóò sì ṣí. Ní àkókò yẹn, ẹni tí ó yarọ yóò gun òkè gan-an gẹ́gẹ́ bí akọ àgbọ̀nrín ti ń ṣe, ahọ́n ẹni tí kò lè sọ̀rọ̀ yóò sì fi ìyọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀ ké jáde. Nítorí pé omi yóò ti ya jáde ní aginjù, àti ọ̀gbàrá ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ aṣálẹ̀.”

Aísáyà 65:21, 22. “Dájúdájú, wọn yóò kọ́ ilé, wọn yóò sì máa gbé inú wọn; dájúdájú, wọn yóò gbin ọgbà àjàrà, wọn yóò sì máa jẹ èso wọn. Wọn kì yóò kọ́lé fún ẹlòmíràn gbé; wọn kì yóò gbìn fún ẹlòmíràn jẹ.”

Dáníẹ́lì 2:44. “Ọlọ́run ọ̀run yóò gbé ìjọba kan kalẹ̀ èyí tí a kì yóò run láé. Ìjọba náà ni a kì yóò sì gbé fún àwọn ènìyàn èyíkéyìí mìíràn. Yóò fọ́ ìjọba wọ̀nyí túútúú, yóò sì fi òpin sí gbogbo wọn, òun fúnra rẹ̀ yóò sì dúró fún àkókò tí ó lọ kánrin.”

Jòhánù 5:28, 29. “Wákàtí náà ń bọ̀, nínú èyí tí gbogbo àwọn tí wọ́n wà nínú ibojì ìrántí yóò gbọ́ ohùn [Jésù], wọn yóò sì jáde wá.”

Ìṣípayá 21:3, 4. “Ọlọ́run fúnra rẹ̀ yóò sì wà pẹ̀lú wọn. Yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́. Àwọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ.”

Bí Ohun Tí Bíbélì Sọ Ṣe Lè Jẹ́ Ká Ní Ojúlówó Ìbàlẹ̀ Ọkàn

Tó o bá ka ohun táwọn ẹsẹ Bíbélì yìí sọ, wọ́n lè kọ́kọ́ dà bí àlá tí kò lè ṣẹ. Àmọ́ Ọlọ́run ló ṣe àwọn ìlérí yẹn, kì í ṣe èèyàn. Bẹ́ẹ̀, Jèhófà Ọlọ́run “kò lè purọ́.”—Títù 1:2.

Tó o bá gba àwọn ìlérí Ọlọ́run gbọ́, tó o sì ń pa àwọn òfin rẹ̀ mọ́, wàá ní ìbàlẹ̀ ọkàn bó o tiẹ̀ ní òkè ìṣòro. Àwọn nǹkan bí ogun, ipò òṣì, àìsàn tàbí ìnira ọjọ́ ogbó kò ní lè gba àlàáfíà ọkàn mọ́ ọ lọ́wọ́, kódà bí ipò téèyàn wà bá tiẹ̀ lè yọrí sí ikú pàápàá. Kí nìdí? Ìdí ni pé yóò dá ọ lójú pé Ìjọba Ọlọ́run yóò mú gbogbo nǹkan wọ̀nyí àtohun tí wọ́n ti fà kúrò.

Báwo lo ṣe lè nírú ìrètí yìí? Ńṣe ni wàá ‘yí èrò inú rẹ padà, kí o sì ṣàwárí ìfẹ́ Ọlọ́run tí ó dára, tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà, tí ó sì pé.’ (Róòmù 12:2) Ó ṣeé ṣe kó o fẹ́ rí àwọn ẹ̀rí míì tó fi hàn pé àwọn ìlérí inú Bíbélì ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé. Tó o bá ṣèwádìí nípa rẹ̀, ó tó bẹ́ẹ̀, ó jù bẹ́ẹ̀ lọ. Wàá sì ní ìbàlẹ̀ ọkàn gan-an.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8, 9]

Kí ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ nípa ọjọ́ ọ̀la?

Aísáyà 35:5

Aísáyà 35:6

Jòhánù 5:28, 29

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́