ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w08 9/1 ojú ìwé 30
  • Mo Rí I Bí Ẹ̀mí Wa Ti Ṣeyebíye Tó

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Mo Rí I Bí Ẹ̀mí Wa Ti Ṣeyebíye Tó
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Bí Àwọn Èèyàn Ṣe Rí—Ìtùnú Gbà Lẹ́yìn Ìpakúpa Tó Wáyé Lọ́gbà Iléèwé Kan
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • Ọlọ́run Ti Nu Omijé Rẹ̀ Nù
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
  • Jèhófà Ń fi Bí a ó Ṣe Máa Ka Àwọn Ọjọ́ Wa Hàn Wá
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
  • Mimọriri Ẹbun Ṣiṣeyebiye Ti Iwalaaye
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
w08 9/1 ojú ìwé 30

Mo Rí I Bí Ẹ̀mí Wa Ti Ṣeyebíye Tó

NÍ ÀÁRỌ̀ APRIL 16, 2007, mo wà nínú ọ́fíìsì kan ní àjà kẹta gbọ̀ngàn kan tí wọ́n ń pè ní Norris Hall ní ọgbà ilé ìwé gíga Virginia Polytechnic Institute and State University, tí ìkékúrú rẹ̀ jẹ́ Virginia Tech. Bí mo ṣe bẹ̀rẹ̀ mọ́lẹ̀ sí kọ̀rọ̀ kan nínú ọ́fíìsì náà láti fara pa mọ́, ni mo tún rántí pé, ojoojúmọ́ tá a bá wà láyé, tá a sì wà láàyè, ló yẹ ká máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run pé ó dá ẹ̀mí wa sí.

Ohun tó ṣẹlẹ̀ ni pé, mo fẹ́ jáde látinú ọ́fíìsì mi ní àjà kẹta lọ sí àjà kejì ilé náà láti lọ mú lẹ́tà mi. Ọ̀jọ̀gbọ́n kan wá pè mí pé kí n wá bá òun wo ohun tó ń ṣe ẹ̀rọ kọ̀ǹpútà òun. Bí a ṣe fẹ́ wọ ọ́fíìsì rẹ̀ la bẹ̀rẹ̀ sí í gbọ́ròó ìbọn ní àjà kejì tí mo fẹ́ lọ. Níwọ̀n bí a ò ti mọ ohun tó fà á, a tètè sáré wọlé, a sì tilẹ̀kùn pa, a wá ń retí ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí wa. Bí mo ṣe rí kọ̀rọ̀ kan fara pa mọ́ sí, mo rọra gbàdúrà sí Jèhófà Ọlọ́run, mo bẹ̀ ẹ́ pé kó kọ́ mi lóhun tí máa ṣe nípa ohun yòówù kó ṣẹlẹ̀.

Bá a ṣe wà níbẹ̀ ni ìṣẹ̀lẹ̀ kan tó ṣẹlẹ̀ sí mi ní ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún sẹ́yìn bá wá sí mi lọ́kàn. Iṣẹ́ mẹ́káníìkì ni mò ń ṣe nínú ṣọ́ọ̀bù kan nígbà yẹn. Lọ́jọ́ kan, agolo epo bẹtiróò tó wà lọ́wọ́ ẹni tá a jọ ń ṣiṣẹ́ gbaná mọ́ ọn lọ́wọ́. Jíjù tó ju agolo náà báyìí, kòńgẹ́ ojú mi ló ṣe! Èéfín iná náà kó sí mi lágbárí, ó sì jó apá òkè ara mi ní àjóbàjẹ́. Ọkọ̀ òfuurufú ẹlikópítà ni wọ́n sáré fi gbé mi lọ sílé ìwòsàn tí wọ́n ti ń tọ́jú àwọn èèyàn tí iná jó. Mo wà níbẹ̀ bí ẹni máa kú, bí ẹni máa yè fún odidi oṣù mẹ́ta àtààbọ̀. Ẹ̀yìn oṣù márùn-ún tí wọ́n ti ń tọ́jú mi ni mo tó lè padà sílé, mo sì ń ṣọpẹ́ pé mi ò tiẹ̀ kú. Ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn jẹ́ kí n máa ka ọjọ́ kọ̀ọ̀kan tí mo fi wà láàyè sí ohun iyebíye. Ó tún jẹ́ kí ìpinnu tí mo ṣe láti jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ọlọ́run àti láti fi gbogbo ìgbésí ayé mi sìn ín túbọ̀ lágbára sí i.—Sáàmù 90:12; Aísáyà 43:10.

Nítorí ìpalára tí jàǹbá iná náà ṣe fún mi, mi ò lè ṣe iṣẹ́ mẹ́káníìkì mọ́. Ni mo bá lọ kọ́ bí wọ́n ṣe ń tún ẹ̀rọ kọ̀ǹpútà ṣe, wọ́n sì wá gbà mí síṣẹ́ nílé ìwé tí wọ́n ń pè ní Virginia Tech. Ohun tó jẹ́ kí n wà ní gbọ̀ngàn tí wọ́n ń pè ní Norris Hall láàárọ̀ ọjọ́ tá a gbọ́ròó ìbọn nìyẹn.

A kàn ń gbọ́ròó ìbọn ni, a ò mọ̀ pé ìpànìyàn tó tíì burú jù lọ nínú ìtàn orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ló ń lọ ní àjà kejì nísàlẹ̀ wa. Ìgbà tí ọkùnrin tó ń yìnbọn pààyàn náà pa ara ẹ̀ lẹ́yìn tó ti pa èèyàn méjìlélọ́gbọ̀n la ò gbọ́ ìró ìbọn náà mọ́. Lẹ́yìn nǹkan bí ogún ìṣẹ́jú tí ìró ìbọn náà ti ń dún la gbọ́ròó àwọn ọlọ́pàá láàárín ọ̀ọ̀dẹ̀ ilé náà. A wá pè wọ́n, wọ́n sì wá mú wa jáde.

Ìṣẹ̀lẹ̀ burúkú yìí ti wá jẹ́ kí n rí i pé ìgbésí ayé àwa èèyàn kúrú gan-an àti pé a ò mọ ohun tó lè ṣẹlẹ̀ síni nígbàkigbà. (Jákọ́bù 4:14) Ẹ ò rí i pé ó ṣe pàtàkì pé ká gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà Ọlọ́run tó jẹ́ Olùfúnni ní ìyè, ká sì máa wo ọjọ́ kọ̀ọ̀kan tá a fi wà láàyè bí ẹ̀bùn iyebíye kan látọ̀dọ̀ rẹ̀!—Sáàmù 23:4; 91:2.

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 30]

AP Photo/The Roanoke Times, Alan Kim

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́