Ṣẹ́ni Gidi Kan Ni Ọlọ́run?
Àwọn kan lè dáhùn pé:
◼ “Kò síbi tí Ọlọ́run ò sí, àfi bí afẹ́fẹ́.”
◼ “Onílàákàyè àti alágbára tí ò ṣeé fojú rí ni Ọlọ́run, kì í sì í ṣẹni gidi kan.”
Kí ni Jésù sọ?
◼ Jésù sọ pé: “Nínú ilé Baba mi, ọ̀pọ̀ ibùjókòó ni ń bẹ.” (Jòhánù 14:2) Jésù sọ lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ pé Ọlọ́run nílé tàbí ibi tó ń gbé.
◼ Jésù sọ pé: “Mo jáde wá láti ọ̀dọ̀ Baba, mo sì ti wá sí ayé. Síwájú sí i, mo ń fi ayé sílẹ̀, mo sì ń bá ọ̀nà mi lọ sọ́dọ̀ Baba.” (Jòhánù 16:28) Jésù gbà gbọ́ pé Ẹni gidi kan ni Ọlọ́run àti pé ó níbi tó ń gbé.
JÉSÙ ò fìgbà kankan sọ̀rọ̀ Ọlọ́run bíi pé kì í ṣẹni gidi kan. Àmọ́, ó bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀, ó sì gbàdúrà sí i. Jésù sábà máa ń pe Jèhófà ní Baba rẹ̀ ọ̀run, èyí sì fi hàn pé ó ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run.—Mátíù 6:14, 26, 32.
Òótọ́ ni pé “kò sí ènìyàn kankan tí ó ti rí Ọlọ́run nígbà kankan rí” àti pé “Ọlọ́run jẹ́ ẹ̀mí.” (Jòhánù 1:18; 4:24) Àmọ́, èyí ò túmọ̀ sí pé Ọlọ́run ò ní irú ara kankan. Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé: “Bí ara ìyára bá wà, èyí ti ẹ̀mí wà pẹ̀lú.” (1 Kọ́ríńtì 15:44) Nítorí náà, ṣé ara ẹ̀mí ni Jèhófà ní?
Bẹ́ẹ̀ ni. Nígbà tí Jésù jíǹde, ó “wọlé . . . sí ọ̀run, nísinsìnyí láti fara hàn níwájú Ọlọ́run fúnra rẹ̀ fún wa.” (Hébérù 9:24) Èyí kọ́ wa ní ohun pàtàkì méjì nípa Ọlọ́run. Àkọ́kọ́ ni pé ó níbi tó ń gbé. Èkejì sì ni pé, Ẹnì kan ni. Kì í ṣe agbára àìrí kan tó kàn ṣáà wà níbi gbogbo.
Báwo ló ṣe wá ṣeé ṣe fún Ọlọ́run láti máa darí ohun gbogbo níbi gbogbo nígbà tí kò gbé níbi gbogbo? Ọlọ́run lè rán ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ níṣẹ́ lọ síbikíbi láyé yìí. Báwọn bàbá ṣe máa ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n bá lè ṣe láti tu àwọn ọmọ wọn nínú kí wọ́n sì ràn wọ́n lọ́wọ́, bẹ́ẹ̀ náà ni Ọlọ́run ṣe máa ń lo ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ láti mú ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ.—Sáàmù 104:30; 139:7.
Nítorí pé Ọlọ́run jẹ́ Ẹnì kan, ó láwọn nǹkan tó nífẹ̀ẹ́ sí, ó sì láwọn nǹkan tí kò nífẹ̀ẹ́ sí, kódà ó máa ń nímọ̀lára. Bíbélì sọ fún wa pé ó fẹ́ràn àwọn èèyàn rẹ̀, inú rẹ̀ máa ń dùn sí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀, ó kórìíra ìbọ̀rìṣà, inú rẹ̀ sì máa ń bà jẹ́ táwọn èèyàn bá ń hùwà búburú. (Jẹ́nẹ́sísì 6:6; Diutarónómì 16:22; 1 Àwọn Ọba 10:9; Sáàmù 104:31) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù pé Ọlọ́run ní “Ọlọ́run aláyọ̀” nínú ìwé 1 Tímótì 1:11. Abájọ tí Jésù fi sọ pé a lè kọ́ bá a ṣe máa fi gbogbo ọkàn wa nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run yìí!—Máàkù 12:30.a
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Fún àlàyé síwájú sí i lórí kókó yìí, wo orí 1 nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 5]
Báwọn bàbá ṣe máa ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n bá lè ṣe láti tu àwọn ọmọ wọn nínú kí wọ́n sì ràn wọ́n lọ́wọ́, bẹ́ẹ̀ náà ni Ọlọ́run ṣe máa ń lo ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ láti mú ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ