ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w09 3/1 ojú ìwé 10-12
  • Àwọn Tí Ìjì Òjò Ṣàkóbá Fún Lórílẹ̀-Èdè Myanmar Rí Ìrànlọ́wọ́ Gbà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Tí Ìjì Òjò Ṣàkóbá Fún Lórílẹ̀-Èdè Myanmar Rí Ìrànlọ́wọ́ Gbà
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Ìṣe Ìgbàlà Jehofa Nísinsìnyí
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Ohun Kan Tí Ìjì Kò Lè Gbé Lọ
    Jí!—2003
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Tá A Fi Ń Ṣe Ìrànwọ́
    Ìjọba Ọlọ́run Ti Ń Ṣàkóso!
  • Àkúnya Omi Ní—Mòsáńbíìkì Bí Àwọn Kristẹni Ṣe Bójú Tó Àwọn Tí Àjálù Náà Bá
    Jí!—2001
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
w09 3/1 ojú ìwé 10-12

Àwọn Tí Ìjì Òjò Ṣàkóbá Fún Lórílẹ̀-Èdè Myanmar Rí Ìrànlọ́wọ́ Gbà

NÍ MAY 2, ỌDÚN 2008, ìjì òjò tí wọ́n ń pè ní Nargis wáyé lórílẹ̀-èdè Myanmar, ká sì tó ṣẹ́jú pẹ́, ó ti di kókó inú àwọn ìròyìn kárí ayé. Lẹ́yìn tí ìjì alágbára yẹn gbé alagbalúgbú omíyalé dé agbègbè ibi tí odò Irrawaddy ti ya wọnú òkun, àpapọ̀ iye èèyàn tó kú àtàwọn tó sọ nù tó nǹkan bí ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogóje [140,000].

Ó yà wá lẹ́nu láti rí i pé kò sẹ́nì kankan tó fara pa lára ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lágbègbè yìí. Ọ̀pọ̀ wọn ló jẹ́ pé inú àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba wọn, tí wọ́n kọ́ dáadáa, ni wọ́n sá lọ nígbà tí ìjì yẹn dé. Lábúlé kan, àwọn Ẹlẹ́rìí tí wọ́n tó ogun [20] àtàwọn tó tó ọgọ́rin [80] lára àwọn ará abúlé náà ló lọ sá sórí òrùlé Gbọ̀ngàn Ìjọba tó wà lábúlé náà, wákàtí mẹ́sàn-án ni wọ́n fi wà níbẹ̀ bí àkúnya omi yẹn ṣe mu ògiri ilé náà dé ìwọ̀n ẹsẹ bàtà mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15] látilẹ̀. Kò sẹ́nì kankan tó bómi lọ nínú gbogbo wọn, àmọ́ ó ṣeni láàánú pé ọgọ́rùn-ún mẹ́ta [300] èèyàn ló bómi lọ lábúlé náà. Lọ́pọ̀ àwọn abúlé tí ìjì òjò náà ti jà Gbọ̀ngàn Ìjọba nìkan nilé tó ṣẹ́ kù.

Ọjọ́ méjì lẹ́yìn tí ìjì òjò yẹn jà, ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà nílùú Yangon rán àwọn ará wa kan láti lọ ran àwọn tí jàǹbá ìjì òjò náà ṣẹlẹ̀ sí lọ́wọ́ ní ìjọ Bothingone lágbègbè tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti wáyé. Àwọn ojú ọ̀nà ti rí gbágungbàgun, àwọn dánàdánà sì tún wà lọ́nà, bẹ́ẹ̀ lòkú àwọn èèyàn sùn lọ jàra, síbẹ̀ àwọn òṣìṣẹ́ tí ẹ̀ka ọ́fíìsì rán lọ la gbogbo ọ̀nà yẹn kọjá wọ́n sì gbé ìrẹsì, àwọn oúnjẹ oníhóró, omi àti àbẹ́là dé abúlé Bothingone. Àwọn ló kọ́kọ́ dé sí àdúgbò yẹn láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́. Lẹ́yìn tí wọ́n ti fún àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà lágbègbè náà láwọn nǹkan tí wọ́n mú wá, wọ́n sọ àsọyé látinú Bíbélì láti fún àwọn èèyàn wọ̀nyẹn níṣìírí, wọ́n sì fún wọn ní Bíbélì àtàwọn ìwé tó dá lórí Bíbélì, torí pé gbogbo nǹkan tí wọ́n ní ló ti bómi lọ.

Báwọn Ẹlẹ́rìí tí jàǹbá yìí ṣàkóbá fún ṣe hùwà pa dà wúni lórí gan-an ni. Ọ̀kan lára wọn tó wà nínú ìjọ kan lágbègbè Irrawaddy níbi tí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ti wáyé sọ pé: “Gbogbo nǹkan tá a ní ló ti bómi lọ. Gbogbo ilé wa ló ti wó. Gbogbo ohun ọ̀gbìn wa ló ti dàwátì. Omíyalé yẹn ti ba gbogbo omi tá à ń mu jẹ́. Àmọ́ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa ò dààmú bíi tàwọn tó kù. Wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà àti ètò rẹ̀. A ti ṣe tán láti ṣe ohun tí ètò Ọlọ́run bá ní ká ṣé, yálà wọ́n ní ká lọ síbòmíì ni o, tàbí wọ́n ní ká dúró sínú abúlé yìí.”

Àwọn Ẹlẹ́rìí kan tí wọ́n tó ọgbọ̀n [30] ti pàdánù gbogbo nǹkan tí wọ́n ní, àmọ́ tayọ̀tayọ̀ ni wọ́n fi ń kọrin Ìjọba Ọlọ́run nígbà tí wọ́n ń rìnrìn àjò oníwákàtí mẹ́wàá lọ síbi táwọn tó fẹ́ ràn wọ́n lọ́wọ́ ti ṣètò ibùgbé, oúnjẹ àti aṣọ sí fún wọn. Ojú ọ̀nà ni wọ́n ti gbọ́ pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà nílùú kan tí ò jìnnà síbi tí wọ́n wà fẹ́ ṣe àpéjọ àyíká wọn. Ni wọ́n bá pinnu pé àpéjọ yẹn làwọn máa kọ́kọ́ lọ, káwọn lè jẹ oúnjẹ tẹ̀mí, káwọn sì lè gbádùn ìfararora pẹ̀lú àwọn táwọn jọ jẹ Kristẹni.

Ní gbogbo àgbègbè tí ìjì òjò yẹn ti jà, ilé márùndínlógójì [35] tó jẹ́ tàwọn Ẹlẹ́rìí ni ìjì òjò yẹn bà jẹ́ nígbà tí ilé márùnlélọ́gọ́fà [125] tó jẹ́ tàwọn Ẹlẹ́rìí àti Gbọ̀ngàn Ìjọba mẹ́jọ kò fi bẹ́ẹ̀ bà jẹ́ púpọ̀. A dúpẹ́ pé ìjì òjò yẹn ò fi bẹ́ẹ̀ ṣàkóbá fún ẹ̀ka ọ́fíìsì wa tó wà níbẹ̀.

Nígbà tí ìjì yẹn kọ́kọ́ dáwọ́ dúró, gbogbo ojú ọ̀nà tó wọ ẹ̀ka ọ́fíìsì wa àtàwọn ọ̀nà téèyàn lè gbà jáde ló ti dí pa torí pé àwọn igi ńláńlá kan ti wó dí àwọn ọ̀nà táwọn èèyàn lè gbà kọjá. Wákàtí mélòó kan lẹ́yìn ìgbà yẹn làwọn òṣìṣẹ́ tó lé ní ọgbọ̀n [30] láti ẹ̀ka ọ́fíìsì wa jáde láti lọ gé àwọn igi tó wó dí àwọn ojú ọ̀nà náà, wọ́n sì gbé wọn kúrò. Tìyanutìyanu làwọn èèyàn fi ń wò wọ́n. Ká tó ṣẹ́jú pẹ́, àwọn obìnrin kan tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí ti gbé àwọn nǹkan mímu ẹlẹ́rìdòdò tó tutù àtàwọn èso tó ti pọ́n dáadáa wá fáwọn tó ń ṣiṣẹ́ yẹn títí kan àwọn ará àdúgbò tó wà ńbẹ̀. Gbogbo nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ yẹn jọ àwọn ará àdúgbò yẹn lójú gan-an ni. Nígbà tí akọ̀ròyìn kan kíyè sí ohun tó ń ṣẹlẹ̀, ó béèrè pé, “Àwọn èèyàn wo ni iṣẹ́ rọ̀ lọ́rùn tó báyìí?” Lẹ́yìn tó ti wá mọ̀ wọ́n, ó ní “Ì bá wù mí tí ọ̀pọ̀ èèyàn bá lè máa fi tọkàntọkàn ṣe iṣẹ́ ìlú báwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ń ṣe!”

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yára ṣètò ìgbìmọ̀ méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ láti lọ bójú tó àwọn nǹkan táwọn tí jàǹbá yẹn ṣàkóbá fún máa nílò láwọn àgbègbè tó yàtọ̀ síra lórílẹ̀-èdè náà. Ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn Ẹlẹ́rìí ló yọ̀ǹda ara wọn láti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn ìgbìmọ̀ yẹn. Láàárín ọjọ́ bíi mélòó kan, wọ́n ti kọ́ àwọn ilé míì fáwọn Ẹlẹ́rìí tí ìjì òjò yẹn gbé ilé wọn lọ. Nígbà táwọn tó ń ṣèrànwọ́ dé láti kọ́lé tuntun fún arábìnrin kan, ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fáwọn ará àdúgbò ẹ̀. Obìnrin kan ládùúgbò yẹn sọ pé: “Àwọn ará ṣọ́ọ̀ṣì obìnrin ajẹ́rìí yìí ló ń bá a túnlé ẹ̀ kọ́. Èmi ò tiẹ̀ rí ìkankan lára àwọn tá a jọ jẹ́ onísìn Búdà láti wá ràn mí lọ́wọ́. Ká ní mo mọ̀ ni, ǹ bá ti di Ajẹ́rìí lọ́jọ́ tó wàásù fún mi!”

Nígbà táwọn òṣìṣẹ́ tó ń báwọn túnlé kọ́ àti ìgbìmọ̀ tó ń bójú tó iṣẹ́ wọn lọ ṣàyẹ̀wò ilé àwọn Ẹlẹ́rìí kan tí ìjì òjò ti bà jẹ́ nílùú Thanlyn, ohun táwọn Ẹlẹ́rìí tó nilé yẹn sọ wú wọn lórí gan-an ni, wọ́n ní: “Ẹ má ṣèyọnu nítorí tiwa. Ilé tiwa ò ṣáà tíì wó pátápátá, a ṣì lè máa gbénú ẹ̀. Àwọn ará wa kan wà tílé tiwọn tiẹ̀ ti wó pátápátá, ẹ ò ṣe kọ́kọ́ lọ ràn wọ́n lọ́wọ́!”

Lágbègbè kan nílùú Yangon, àwọn kan sáré lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì kan ládùúgbò wọn nígbà tí ìjì yẹn ń jà. Àmọ́ wọn ò rọ́nà wọlé torí pé wọ́n ti tilẹ̀kùn ṣọ́ọ̀ṣì yẹn pa. Inú bí àwọn èèyàn wọ̀nyẹn gan-an, wọ́n sì fẹ́ fipá jálẹ̀kùn ṣọ́ọ̀ṣì yẹn. Àmọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ nígbà tí ìjì yẹn ń jà, ọ̀pọ̀ èèyàn ló sá wọnú àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba wọn. Bí àpẹẹrẹ, lákòókò tí ìjì yẹn ń jà, àwọn tọkọtaya kan gba àwọn ará àdúgbò wọn tí wọ́n tó ogún [20] láyè láti sá wọnú Gbọ̀ngàn Ìjọba tó wà nílùú Dala. Nígbà tílẹ̀ mọ́ kò síbi táwọn èèyàn wọ̀nyẹn máa lọ, ebi sì tún ń pa wọ́n. Ọkọ yẹn rí ẹnì kan tó ń ta ìrẹsì, ó sì ra ìrẹsì fún gbogbo àwọn èèyàn wọ̀nyẹn.

Ìdílé kan wà nílùú Yangon táwọn kan lára wọn jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà, nígbà táwọn tó kù lára wọn máa ń lọ sáwọn ṣọ́ọ̀ṣì míì. Lẹ́yìn tí ìjì yẹn jà tán, gbogbo wọn pátá ló wá sí Gbọ̀ngàn Ìjọba. Kí nìdí tí wọ́n fi wá? Ọ̀kan lára wọn ṣàlàyé pé: “Àwọn ará ṣọ́ọ̀ṣì wa sọ pé àwọn máa wá wò wá nígbà tíjì yẹn bá dá, àmọ́ a ò rí wọn. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nìkan ló wá wò wá. Ẹ̀yin náà lẹ sì tún fún wa ní ìrẹsì àti omi. Ẹ̀yin ò dà bí àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì yòókù!” Àwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà nínú ìdílé yẹn gbádùn àpilẹ̀kọ tá a jíròrò látinú Ilé Ìṣọ́ lọ́jọ́ yẹn, wọ́n tiẹ̀ tún dáhùn dáadáa nínú ìpàdé yẹn pẹ̀lú. Àkòrí àpilẹ̀kọ yẹn ni: “Jèhófà Ń Gbọ́ Igbe Wa fún Ìrànlọ́wọ́.”

Ọ̀dọ́mọbìnrin kan tó ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà wá sípàdé lọ́sẹ̀ tó tẹ̀ lé ọ̀sẹ̀ tí ìjì yẹn jà. Nínú ìpàdé yẹn, wọ́n ka lẹ́tà kan tí ẹ̀ka ọ́fíìsì kọ sáwọn ìjọ láti fi ṣàlàyé àwọn nǹkan tí wọ́n ti ṣe láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ àtàwọn ìrírí àwọn èèyàn tí ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn ti ṣàkóbá fún. Ńṣe ni ọ̀dọ́mọbìnrin yẹn bẹ̀rẹ̀ sí í sunkún nígbà tí wọ́n ń ka lẹ́tà yẹn. Orí ẹ̀ wú gan-an nígbà tó gbọ́ pé gbogbo àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn ṣàkóbá fún ni wọ́n ti bójú tó. Lẹ́yìn ìpàdé yẹn, wọ́n fún un láwọn nǹkan díẹ̀ tó nílò, wọ́n sì kọ́ ilé kékeré kan fún un sẹ́gbẹ̀ẹ́ ilé ẹ̀. Ó ní inú òun dùn gan-an pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ran òun lọ́wọ́.

Jésù sọ pé: “Nípa èyí ni gbogbo ènìyàn yóò fi mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín, bí ẹ bá ní ìfẹ́ láàárín ara yín.” (Jòhánù 13:35) Jákọ́bù tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù sì tẹnu mọ́ ọn pé ẹni tó bá ní ìgbàgbọ́ tòótọ́ á máa ṣe rere fáwọn ẹlòmíì. (Jákọ́bù 2:14-17) Ọwọ́ pàtàkì làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi mú àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, wọ́n sì ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti fi hàn pé àwọn nífẹ̀ẹ́ àwọn èlòmíì nípa ríran àwọn tí wọ́n ṣaláìní lọ́wọ́.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 11]

Bíbélì sọ pé ẹni tó bá ní ìgbàgbọ́ tòótọ́ á máa ṣe rere fáwọn ẹlòmíì

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́