ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w10 3/15 ojú ìwé 28-29
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ẹ Fi Ìdúróṣinṣin Tẹrí Ba Fún Ọlá Àṣẹ Ọlọ́run
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2002
  • Ṣé Jèhófà Mọ̀ Ẹ́?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • Kórà Ṣọ̀tẹ̀
    Àwọn Àwòrán Ìtàn Bíbélì
  • Wọ́n Ta Ko Jèhófà
    Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
w10 3/15 ojú ìwé 28-29

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ǹjẹ́ Ìsíkíẹ́lì 18:20, tó sọ pé “ọmọ kì yóò ru ohunkóhun nítorí ìṣìnà baba,” ta ko Ẹ́kísódù 20:5, tó sọ pé Jèhófà máa ń mú “ìṣìnà àwọn baba wá sórí àwọn ọmọ”?

Rárá o, wọn kò ta kora. Ọ̀kan ń sọ̀rọ̀ nípa bí ẹnì kọ̀ọ̀kan ṣe máa jíhìn ohun tó bá ṣe, ìkejì sì ń jẹ́ ká mọ̀ pé ìyà ẹ̀ṣẹ̀ ẹnì kan lè wá sórí àtọmọdọ́mọ rẹ̀.

Àwọn ọ̀rọ̀ tó wà ṣáájú Ìsíkíẹ́lì orí 18 àtèyí tó wà lẹ́yìn rẹ̀ fi hàn pé olúkúlùkù ló máa jíhìn ohun tó bá ṣe. Ẹsẹ 4, sọ pé: “Ọkàn tí ń dẹ́ṣẹ̀ òun gan-an ni yóò kú.” Ẹni tó “jẹ́ olódodo, tí ó sì ti mú ìdájọ́ òdodo àti òdodo ṣẹ ní kíkún” ńkọ́? “Yóò máa wà láàyè nìṣó.” (Ìsík. 18:5, 9) Torí náà, bí ẹnì kan bá ti dàgbà tó láti jíhìn iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀, a ó ṣèdájọ́ rẹ̀ ‘bí àwọn ọ̀nà rẹ̀ ti rí.’—Ìsík. 18:30.

Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ọmọ Léfì kan tó ń jẹ́ Kórà, jẹ́ ká túbọ̀ lóye ìlànà yìí. Nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì wà ní aginjù, àǹfààní iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ kò tẹ́ ẹ lọ́rùn mọ́. Kó bàa lè gba iṣẹ́ àlùfáà, òun àti àwọn míì ṣọ̀tẹ̀ sí Mósè àti Áárónì tí wọ́n jẹ́ aṣojú Jèhófà. Ìwà ọ̀yájú tí Kórà àtàwọn tí wọ́n jọ dìtẹ̀ hù, èyí tó mú kí wọ́n máa wá ipò tí kò tọ́ sí wọn, ló fà á tí Jèhófà fi pa gbogbo wọn. (Núm. 16:8-11, 31-33) Àmọ́, àwọn ọmọ Kórà kò bá a lọ́wọ́ sí ìdìtẹ̀ náà. Ọlọ́run ò sì ka ẹ̀ṣẹ̀ bàbá wọn sí wọn lọ́rùn. Ìdúróṣinṣin wọn sí Ọlọ́run mú kí Jèhófà dá ẹ̀mí wọn sí.—Núm. 26:10, 11.

Àmọ́, ìkìlọ̀ tó wà nínú Ẹ́kísódù 20:5, tó jẹ́ ara Òfin Mẹ́wàá ńkọ́? Ẹ jẹ́ ká tún wo àwọn ọ̀rọ̀ tó wà ṣáájú àti lẹ́yìn rẹ̀. Jèhófà bá orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì dá májẹ̀mú Òfin. Lẹ́yìn táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti gbọ́ ohun tó rọ̀ mọ́ májẹ̀mú náà, wọ́n polongo ní gbangba pé: “Gbogbo ohun tí Jèhófà sọ ni àwa ti múra tán láti ṣe.” (Ẹ́kís. 19:5-8) Gbogbo orílẹ̀-èdè yẹn lápapọ̀ sì wọnú àjọṣe àrà ọ̀tọ̀ kan pẹ̀lú Jèhófà. Torí náà, gbogbo orílẹ̀-èdè yẹn lápapọ̀ ni ọ̀rọ̀ inú Ẹ́kísódù 20:5 ń bá wí.

Bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà, gbogbo orílẹ̀-èdè yẹn ló máa ń jàǹfààní rẹ̀, tí wọ́n á sì gbádùn ọ̀pọ̀ ìbùkún. (Léf. 26:3-8) Tí wọ́n bá sì ṣàìgbọràn, gbogbo wọn náà ló máa jìyà rẹ̀. Nígbà kan tí orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì pa Jèhófà tì, tí wọ́n sì ń tọ àwọn òrìṣà lẹ́yìn, Jèhófà fa ọwọ́ ìbùkún àti ààbò rẹ̀ sẹ́yìn lọ́dọ̀ wọn, wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ kàgbákò. (Oníd. 2:11-18) Lóòótọ́, àwọn kan di ìṣòtítọ́ wọn mú, wọ́n sì ń pa àwọn àṣẹ Ọlọ́run mọ́, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn orílẹ̀-èdè náà ò dẹ́kun láti máa bọ̀rìṣà. (1 Ọba 19:14, 18) Síbẹ̀, ó ṣeé ṣe kí nǹkan nira fún wọn díẹ̀, nítorí ẹ̀ṣẹ̀ orílẹ̀-èdè náà, àmọ́ Jèhófà fi inú rere hàn sí wọn.

Nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì jingíri sínú títẹ àwọn ìlànà Jèhófà lójú, débi tí àwọn orílẹ̀-èdè tó yí wọn ká fi ń fi orúkọ Jèhófà ṣẹ̀sín, Jèhófà pinnu láti fìyà jẹ àwọn èèyàn rẹ̀, nípa yíyọ̀ọ̀da kí a kó wọn nígbèkùn lọ sí orílẹ̀-èdè Bábílónì. Jèhófà fìyà jẹ àwọn kan tí ìyà tọ́ sí lára àwọn èèyàn rẹ̀, ó sì tún fìyà jẹ gbogbo wọn lápapọ̀. (Jer. 52:3-11, 27) Kódà, Bíbélì fi hàn pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jẹ̀bi tó pọ̀ débi pé ó tó ìran mẹ́ta, mẹ́rin, tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ, tó jìyà ohun tí àwọn baba ńlá wọn ṣe, gẹ́gẹ́ bí Ẹ́kísódù 20:5 ṣe sọ.

Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tún ní àwọn àkọsílẹ̀ kan tó jẹ́ ká rí i pé àwọn ìdílé kan wà tó jìyà ohun táwọn òbí wọn ṣe. Élì, Àlùfáà Àgbà, ṣẹ Jèhófà torí pé ó fàyè gba àwọn ọmọ rẹ̀ “aláìdára fún ohunkóhun” láti máa ṣe iṣẹ́ àlùfáà nìṣó. (1 Sám. 2:12-16, 22-25) Torí pé, Élì ka àwọn ọmọ rẹ̀ sí ju Jèhófà lọ, Ọlọ́run sọ pé òun á mú ìdílé Élì kúrò lẹ́nu iṣẹ́ àlùfáà àgbà, èyí sì bẹ̀rẹ̀ látorí Ábíátárì tó jẹ́ ọmọ tí ọmọ ọmọ Élì bí. (1 Sám. 2:29-36; 1 Ọba 2:27) Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Géhásì tún jẹ́ kí ìlànà tó wà nínú Ẹ́kísódù 20:5 ṣe kedere sí i. Géhásì lo ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹmẹ̀wà Èlíṣà ní ìlòkulò, kó bàa lè rí ẹ̀bùn gbà látinú bí Èlíṣà ṣe wo Náámánì tó jẹ́ olórí àwọn ọmọ ogun Síríà sàn. Jèhófà gbẹnu Èlíṣà dá Géhásì lẹ́jọ́ pé: “Ẹ̀tẹ̀ Náámánì yóò lẹ̀ mọ́ ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ fún àkókò tí ó lọ kánrin.” (2 Ọba 5:20-27) Torí náà, gbogbo àtọmọdọ́mọ Géhásì pín nínú ìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.

Gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́dàá àti Olùfúnni-ní-ìyè, Jèhófà lẹ́tọ̀ọ́ láti pinnu ìyà tó tọ́ láti fi jẹ ẹnì kan, kó sì pinnu bí ìyà náà ṣe máa tó. Àwọn àpẹẹrẹ tá a ti gbé yẹ̀ wò yìí ti jẹ́ ká rí i pé àwọn ọmọ lè jìyà ẹ̀ṣẹ̀ táwọn baba ńlá wọn ti dá. Àmọ́, Jèhófà ń “gbọ́ igbe ẹkún àwọn tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́.” Tí ẹnikẹ́ni bá sì tọ̀ ọ́ lọ, ó lè rí ojú rere rẹ̀, kí ara sì tù ú dé ìwọ̀n àyè kan.—Jóòbù 34:28.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]

Kórà àtàwọn tí wọ́n jọ dìtẹ̀ jìyà ìwà ọ̀tẹ̀ wọn

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́