ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Jeremáyà 52
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Jeremáyà

      • Sedekáyà ṣọ̀tẹ̀ sí Bábílónì (1-3)

      • Nebukadinésárì dó ti Jerúsálẹ́mù (4-11)

      • Ìparun Jerúsálẹ́mù àti tẹ́ńpìlì rẹ̀ (12-23)

      • Wọ́n kó àwọn èèyàn lọ sí ìgbèkùn ní Bábílónì (24-30)

      • Wọ́n dá Jèhóákínì sílẹ̀ lẹ́wọ̀n (31-34)

Jeremáyà 52:1

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 24:17-20; 2Kr 36:11, 12
  • +2Ọb 23:31

Jeremáyà 52:2

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 24:1; 2Kr 36:5

Jeremáyà 52:3

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 26:33; Di 31:16, 17
  • +2Kr 36:11, 13; Isk 17:15

Jeremáyà 52:4

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “Nebukadirésárì,” ọ̀nà míì tí wọ́n ń gbà kọ orúkọ yìí.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 28:52; 2Ọb 25:1, 2; Ais 29:3; Jer 39:1; Isk 4:1, 2; 21:21, 22

Jeremáyà 52:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 39:2
  • +Di 28:53-57; 2Ọb 25:3-7; Ais 3:1; Isk 4:16

Jeremáyà 52:7

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 39:4-7

Jeremáyà 52:8

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 24:8; 34:21; 37:17; 38:18

Jeremáyà 52:10

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé, 5/2017,

    Jeremáyà, ojú ìwé 158-159

Jeremáyà 52:11

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 12:13

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Jeremáyà, ojú ìwé 158-159

Jeremáyà 52:12

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “Nebukadirésárì,” ọ̀nà míì tí wọ́n ń gbà kọ orúkọ yìí.

  • *

    Tàbí “ìránṣẹ́.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 25:8-10

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    3/15/2007, ojú ìwé 11

    “Kí Ijọba Rẹ Dé,” ojú ìwé 186

Jeremáyà 52:13

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ààfin.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 9:8; 2Kr 36:17, 19; Sm 74:8; 79:1; Jer 26:18; Ida 2:7; Isk 24:21

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Jeremáyà, ojú ìwé 159

Jeremáyà 52:14

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 39:8

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Jeremáyà, ojú ìwé 159

Jeremáyà 52:15

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 25:11, 12; Jer 39:9, 10

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 405

Jeremáyà 52:16

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 25:22

Jeremáyà 52:17

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 7:15, 21
  • +1Ọb 7:27
  • +1Ọb 7:23; 2Kr 4:11-15
  • +2Ọb 25:13-16; Jer 27:19, 22

Jeremáyà 52:18

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 7:45
  • +2Kr 4:19, 22

Jeremáyà 52:19

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 7:50
  • +1Ọb 7:48, 49
  • +2Kr 24:14; 36:18

Jeremáyà 52:20

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 7:23, 25

Jeremáyà 52:21

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ìgbọ̀nwọ́ kan jẹ́ sẹ̀ǹtímítà 44.5 (ínǹṣì 17.5). Wo Àfikún B14.

  • *

    Ìbú ìka kan jẹ́ sẹ̀ǹtímítà 1.85 (ínǹṣì 0.73). Wo Àfikún B14.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 7:15-20

Jeremáyà 52:22

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kr 3:15

Jeremáyà 52:23

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kr 3:16; 4:13

Jeremáyà 52:24

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Kr 6:14; Ẹsr 7:1
  • +Jer 21:1, 2; 29:25
  • +2Ọb 25:18-21

Jeremáyà 52:27

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 25:6; Jer 52:10
  • +Le 18:25; 26:33; Di 28:36; Ais 24:3; Jer 25:9

Jeremáyà 52:28

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “Nebukadirésárì,” ọ̀nà míì tí wọ́n ń gbà kọ orúkọ yìí.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 24:12, 14

Jeremáyà 52:29

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “Nebukadirésárì,” ọ̀nà míì tí wọ́n ń gbà kọ orúkọ yìí.

  • *

    Tàbí “ọkàn.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 32:1

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    “Kí Ijọba Rẹ Dé,” ojú ìwé 186

Jeremáyà 52:30

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “Nebukadirésárì,” ọ̀nà míì tí wọ́n ń gbà kọ orúkọ yìí.

  • *

    Tàbí “ọkàn.”

  • *

    Tàbí “ọkàn.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 6:9

Jeremáyà 52:31

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “gbé orí Jèhóákínì ọba Júdà sókè.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 24:8; Jer 24:1; 37:1; Mt 1:11
  • +2Ọb 25:27-30

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Jeremáyà, ojú ìwé 31

Àwọn míì

Jer. 52:12Ọb 24:17-20; 2Kr 36:11, 12
Jer. 52:12Ọb 23:31
Jer. 52:22Ọb 24:1; 2Kr 36:5
Jer. 52:3Le 26:33; Di 31:16, 17
Jer. 52:32Kr 36:11, 13; Isk 17:15
Jer. 52:4Di 28:52; 2Ọb 25:1, 2; Ais 29:3; Jer 39:1; Isk 4:1, 2; 21:21, 22
Jer. 52:6Jer 39:2
Jer. 52:6Di 28:53-57; 2Ọb 25:3-7; Ais 3:1; Isk 4:16
Jer. 52:7Jer 39:4-7
Jer. 52:8Jer 24:8; 34:21; 37:17; 38:18
Jer. 52:11Isk 12:13
Jer. 52:122Ọb 25:8-10
Jer. 52:131Ọb 9:8; 2Kr 36:17, 19; Sm 74:8; 79:1; Jer 26:18; Ida 2:7; Isk 24:21
Jer. 52:14Jer 39:8
Jer. 52:152Ọb 25:11, 12; Jer 39:9, 10
Jer. 52:162Ọb 25:22
Jer. 52:171Ọb 7:15, 21
Jer. 52:171Ọb 7:27
Jer. 52:171Ọb 7:23; 2Kr 4:11-15
Jer. 52:172Ọb 25:13-16; Jer 27:19, 22
Jer. 52:181Ọb 7:45
Jer. 52:182Kr 4:19, 22
Jer. 52:191Ọb 7:50
Jer. 52:191Ọb 7:48, 49
Jer. 52:192Kr 24:14; 36:18
Jer. 52:201Ọb 7:23, 25
Jer. 52:211Ọb 7:15-20
Jer. 52:222Kr 3:15
Jer. 52:232Kr 3:16; 4:13
Jer. 52:241Kr 6:14; Ẹsr 7:1
Jer. 52:24Jer 21:1, 2; 29:25
Jer. 52:242Ọb 25:18-21
Jer. 52:272Ọb 25:6; Jer 52:10
Jer. 52:27Le 18:25; 26:33; Di 28:36; Ais 24:3; Jer 25:9
Jer. 52:282Ọb 24:12, 14
Jer. 52:29Jer 32:1
Jer. 52:30Jer 6:9
Jer. 52:312Ọb 24:8; Jer 24:1; 37:1; Mt 1:11
Jer. 52:312Ọb 25:27-30
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
  • 24
  • 25
  • 26
  • 27
  • 28
  • 29
  • 30
  • 31
  • 32
  • 33
  • 34
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Jeremáyà 52:1-34

Jeremáyà

52 Ẹni ọdún mọ́kànlélógún (21) ni Sedekáyà+ nígbà tó jọba, ọdún mọ́kànlá (11) ló sì fi jọba ní Jerúsálẹ́mù. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Hámútálì+ ọmọ Jeremáyà ará Líbínà. 2 Ó sì ń ṣe ohun tó burú lójú Jèhófà, gbogbo ohun tí Jèhóákímù ṣe ni òun náà ṣe.+ 3 Ìbínú Jèhófà ló mú kí àwọn nǹkan yìí ṣẹlẹ̀ ní Jerúsálẹ́mù àti ní Júdà, títí ó fi gbá wọn dà nù kúrò níwájú rẹ̀.+ Sedekáyà sì ṣọ̀tẹ̀ sí ọba Bábílónì.+ 4 Ní ọdún kẹsàn-án ìjọba Sedekáyà, ní oṣù kẹwàá, ní ọjọ́ kẹwàá oṣù náà, Nebukadinésárì* ọba Bábílónì dé pẹ̀lú gbogbo ọmọ ogun rẹ̀ láti gbéjà ko Jerúsálẹ́mù. Wọ́n pàgọ́ tì í, wọ́n sì mọ òkìtì yí i ká.+ 5 Wọ́n sì dó ti ìlú náà títí di ọdún kọkànlá ìṣàkóso Ọba Sedekáyà.

6 Ní oṣù kẹrin, ní ọjọ́ kẹsàn-án oṣù náà,+ ìyàn mú gan-an ní ìlú náà, kò sì sí oúnjẹ kankan tí àwọn èèyàn ilẹ̀ náà máa jẹ.+ 7 Níkẹyìn, wọ́n fọ́ ògiri ìlú náà wọlé, gbogbo ọmọ ogun sì sá kúrò ní ìlú lóru, wọ́n gba ẹnubodè tó wà láàárín ògiri oníbejì nítòsí ọgbà ọba jáde kúrò nínú ìlú náà, lákòókò yìí, àwọn ará Kálídíà yí ìlú náà ká; wọ́n gba ọ̀nà Árábà lọ.+ 8 Àmọ́ àwọn ọmọ ogun Kálídíà lé ọba, wọ́n sì bá Sedekáyà+ ní aṣálẹ̀ tó wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jẹ́ríkò, gbogbo ọmọ ogun rẹ̀ sì tú ká kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀. 9 Lẹ́yìn náà, wọ́n gbá ọba mú, wọ́n mú un wá sọ́dọ̀ ọba Bábílónì ní Ríbúlà ní ilẹ̀ Hámátì, ó sì dá a lẹ́jọ́. 10 Ọba Bábílónì pa àwọn ọmọ Sedekáyà níṣojú rẹ̀, ó sì tún pa gbogbo àwọn ìjòyè Júdà níbẹ̀ ní Ríbúlà. 11 Lẹ́yìn náà, ọba Bábílónì fọ́ ojú Sedekáyà,+ ó sì fi ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ bàbà dè é, ó mú un wá sí Bábílónì, ó sì fi í sẹ́wọ̀n títí di ọjọ́ ikú rẹ̀.

12 Ní oṣù karùn-ún, ní ọjọ́ kẹwàá oṣù náà, ìyẹn, ní ọdún kọkàndínlógún Nebukadinésárì* ọba Bábílónì, Nebusarádánì olórí ẹ̀ṣọ́, tó jẹ́ ẹmẹ̀wà* ọba Bábílónì, wá sí Jerúsálẹ́mù.+ 13 Ó dáná sun ilé Jèhófà+ àti ilé* ọba pẹ̀lú gbogbo ilé tó wà ní Jerúsálẹ́mù; ó sì tún sun gbogbo ilé ńlá. 14 Gbogbo ògiri tó yí Jerúsálẹ́mù ká ni gbogbo àwọn ọmọ ogun Kálídíà tó wà pẹ̀lú olórí ẹ̀ṣọ́ wó lulẹ̀.+

15 Nebusarádánì olórí ẹ̀ṣọ́ sì kó àwọn kan lára àwọn aláìní nínú àwọn èèyàn náà àti àwọn tó ṣẹ́ kù sí ìlú náà lọ sí ìgbèkùn. Ó tún kó àwọn tó sá lọ sọ́dọ̀ ọba Bábílónì àti ìyókù àwọn àgbà oníṣẹ́ ọnà lọ sí ìgbèkùn.+ 16 Àmọ́ Nebusarádánì olórí ẹ̀ṣọ́ fi lára àwọn aláìní sílẹ̀ ní ilẹ̀ náà kí wọ́n lè máa rẹ́ ọwọ́ àjàrà, kí wọ́n sì máa ṣe lébìrà àpàpàǹdodo.+

17 Àwọn ará Kálídíà fọ́ àwọn òpó bàbà+ ilé Jèhófà àti àwọn kẹ̀kẹ́ ẹrù + àti Òkun bàbà+ tó wà ní ilé Jèhófà sí wẹ́wẹ́, wọ́n sì kó gbogbo bàbà náà lọ sí Bábílónì.+ 18 Wọ́n tún kó àwọn garawa, àwọn ṣọ́bìrì, àwọn ohun tí wọ́n fi ń pa fìtílà, àwọn abọ́,+ àwọn ife+ àti gbogbo nǹkan èlò bàbà tí wọ́n ń lò nínú tẹ́ńpìlì. 19 Olórí ẹ̀ṣọ́ kó àwọn bàsíà,+ àwọn ìkóná, àwọn abọ́, àwọn garawa, àwọn ọ̀pá fìtílà,+ àwọn ife àti àwọn abọ́ tí wọ́n fi ojúlówó wúrà ṣe àti àwọn tí wọ́n fi ojúlówó fàdákà ṣe.+ 20 Ní ti àwọn òpó méjèèjì àti Òkun, àwọn akọ màlúù méjìlá (12)+ tí wọ́n fi bàbà ṣe tó wà lábẹ́ Òkun náà àti àwọn kẹ̀kẹ́ ẹrù tí Ọba Sólómọ́nì ṣe fún ilé Jèhófà, bàbà tó wà lára gbogbo àwọn nǹkan èlò yìí kọjá wíwọ̀n.

21 Ní ti àwọn òpó náà, gíga ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn jẹ́ ìgbọ̀nwọ́* méjìdínlógún (18), okùn ìwọ̀n ìgbọ̀nwọ́ méjìlá (12) lè yí i ká;+ ìnípọn rẹ̀ jẹ́ ìbú ìka* mẹ́rin, ihò sì wà nínú rẹ̀. 22 Bàbà ni wọ́n fi ṣe ọpọ́n tó wà lórí rẹ̀; gíga ọpọ́n kan jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún;+ bàbà ni wọ́n fi ṣe àwọ̀n àti àwọn pómégíránétì tó yí ọpọ́n náà ká. Òpó kejì dà bíi ti àkọ́kọ́ gẹ́lẹ́, bákan náà sì ni àwọn pómégíránétì rẹ̀. 23 Àwọn pómégíránétì mẹ́rìndínlọ́gọ́rùn-ún (96) ló wà lẹ́gbẹ̀ẹ̀gbẹ́ rẹ̀; lápapọ̀, gbogbo pómégíránétì tó yí àwọ̀n náà ká jẹ́ ọgọ́rùn-ún (100).+

24 Olórí ẹ̀ṣọ́ tún mú Seráyà+ olórí àlùfáà àti Sefanáyà+ àlùfáà kejì pẹ̀lú àwọn aṣọ́nà mẹ́ta.+ 25 Ó mú òṣìṣẹ́ ààfin kan tó jẹ́ kọmíṣọ́nnà lórí àwọn ọmọ ogun láti inú ìlú náà àti àwọn ọkùnrin méje tó rí nínú ìlú náà tí wọ́n sún mọ́ ọba àti akọ̀wé olórí àwọn ọmọ ogun, tó máa ń pe àwọn èèyàn ilẹ̀ náà jọ àti ọgọ́ta (60) ọkùnrin lára àwọn èèyàn ilẹ̀ náà, tó tún rí nínú ìlú náà. 26 Nebusarádánì olórí ẹ̀ṣọ́ mú wọn, ó sì kó wọn wá sọ́dọ̀ ọba Bábílónì ní Ríbúlà. 27 Ọba Bábílónì ṣá wọn balẹ̀, ó sì pa wọ́n ní Ríbúlà+ ní ilẹ̀ Hámátì. Bí Júdà ṣe lọ sí ìgbèkùn láti ilẹ̀ rẹ̀ nìyẹn.+

28 Àwọn èèyàn tí Nebukadinésárì* kó lọ sí ìgbèkùn nìyí: ní ọdún keje, ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ó lé mẹ́tàlélógún (3,023) àwọn Júù.+

29 Ní ọdún kejìdínlógún Nebukadinésárì,*+ ó kó ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ ó lé méjìlélọ́gbọ̀n (832) èèyàn* láti Jerúsálẹ́mù.

30 Ní ọdún kẹtàlélógún Nebukadinésárì,* Nebusarádánì olórí ẹ̀ṣọ́ kó àwọn Júù lọ sí ìgbèkùn, àwọn èèyàn* náà jẹ́ ọgọ́rùn-ún méje ó lé márùndínláàádọ́ta (745).+

Lápapọ̀, ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (4,600) èèyàn* ni wọ́n kó lọ sí ìgbèkùn.

31 Ní ọdún kẹtàdínlógójì tí Jèhóákínì+ ọba Júdà ti wà ní ìgbèkùn, ní oṣù kejìlá, ní ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n oṣù náà, Efili-méródákì ọba Bábílónì, ní ọdún tó jọba, dá Jèhóákínì ọba Júdà sílẹ̀,* ó sì mú un kúrò lẹ́wọ̀n.+ 32 Ó bá a sọ̀rọ̀ pẹ̀lẹ́, ó sì gbé ìtẹ́ rẹ̀ ga ju ìtẹ́ àwọn ọba yòókù tó wà pẹ̀lú rẹ̀ ní Bábílónì. 33 Torí náà, Jèhóákínì bọ́ ẹ̀wù ẹ̀wọ̀n rẹ̀, iwájú ọba ló sì ti ń jẹun déédéé ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀. 34 Ó ń rí oúnjẹ gbà déédéé látọ̀dọ̀ ọba Bábílónì, lójoojúmọ́ ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀, títí di ọjọ́ ikú rẹ̀.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́