ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Diutarónómì 28:53-57
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 53 O sì máa wá jẹ àwọn ọmọ* rẹ, ẹran ara àwọn ọmọ rẹ lọ́kùnrin àti lóbìnrin+ tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ fún ọ, torí bí nǹkan ṣe máa le tó nígbà tí wọ́n bá dó tì ọ́ àti torí wàhálà tí àwọn ọ̀tá rẹ máa kó bá ọ.

      54 “Ọkùnrin tí kò lágbaja rárá, tó sì lójú àánú láàárín rẹ kò tiẹ̀ ní ṣàánú arákùnrin rẹ̀ tàbí ìyàwó rẹ̀ tó fẹ́ràn tàbí àwọn ọmọ rẹ̀ tó ṣẹ́ kù, 55 kò sì ní fún wọn ní ìkankan lára ẹran ara àwọn ọmọ rẹ̀ tó máa jẹ, torí kò ní nǹkan kan mọ́ nítorí bí àwọn ọ̀tá ṣe dó tì ọ́ àti bí wàhálà tí wọ́n kó bá àwọn ìlú+ rẹ ṣe pọ̀ tó. 56 Obìnrin tí kò lágbaja tó sì lójú àánú láàárín rẹ, tí kò tiẹ̀ ní ronú rárá láti fi àtẹ́lẹsẹ̀ rẹ̀ kanlẹ̀ torí pé kò lágbaja+ kò ní ṣàánú ọkọ rẹ̀ tó fẹ́ràn tàbí ọmọkùnrin rẹ̀ tàbí ọmọbìnrin rẹ̀, 57 àní kò ní ṣàánú àwọn ohun tó jáde láàárín ẹsẹ̀ rẹ̀ méjèèjì lẹ́yìn tó bímọ àtàwọn ọmọ tó bí. Ó máa jẹ wọ́n níkọ̀kọ̀ torí bí nǹkan ṣe máa le nígbà tí wọ́n bá dó tì ọ́ àti wàhálà tí àwọn ọ̀tá rẹ máa kó bá àwọn ìlú rẹ.

  • 2 Àwọn Ọba 25:3-7
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 3 Ní ọjọ́ kẹsàn-án oṣù kẹrin, ìyàn mú gan-an+ ní ìlú náà, kò sì sí oúnjẹ kankan tí àwọn èèyàn ilẹ̀ náà máa jẹ.+ 4 Wọ́n fọ́ ògiri ìlú náà wọlé,+ gbogbo ọmọ ogun sì sá gba ẹnubodè tó wà láàárín ògiri oníbejì nítòsí ọgbà ọba lóru, lákòókò yìí, àwọn ará Kálídíà yí ìlú náà ká; ọba sì sá gba ọ̀nà Árábà.+ 5 Àmọ́ àwọn ọmọ ogun Kálídíà lé ọba, wọ́n sì bá a ní aṣálẹ̀ tó wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jẹ́ríkò, gbogbo ọmọ ogun rẹ̀ sì tú ká kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀. 6 Lẹ́yìn náà, wọ́n gbá ọba mú,+ wọ́n mú un wá sọ́dọ̀ ọba Bábílónì ní Ríbúlà, wọ́n sì dá a lẹ́jọ́. 7 Wọ́n pa àwọn ọmọ Sedekáyà níṣojú rẹ̀; Nebukadinésárì wá fọ́ ojú Sedekáyà, ó fi ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ bàbà dè é, ó sì mú un wá sí Bábílónì.+

  • Àìsáyà 3:1
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 3 Wò ó! Olúwa tòótọ́, Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun,

      Ó ń mú gbogbo ìtìlẹ́yìn àtàwọn ohun tí wọ́n nílò ní Jerúsálẹ́mù àti Júdà kúrò,

      Gbogbo ìtìlẹ́yìn oúnjẹ àti omi,+

  • Ìsíkíẹ́lì 4:16
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 16 Lẹ́yìn náà, ó sọ fún mi pé: “Ọmọ èèyàn, mi ò ní jẹ́ kí oúnjẹ wà* ní Jerúsálẹ́mù,+ ṣe ni wọ́n máa wọn búrẹ́dì tí wọ́n fẹ́ jẹ látinú ìwọ̀nba tí wọ́n ní,+ ọkàn wọn ò sì ní balẹ̀. Wọ́n máa wọn omi tí wọ́n fẹ́ mu látinú ìwọ̀nba tí wọ́n ní, ẹ̀rù á sì máa bà wọ́n.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́