ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Léfítíkù 26:26
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 26 Tí mo bá run ibi* tí ẹ kó búrẹ́dì*+ yín jọ sí, obìnrin mẹ́wàá ni yóò yan búrẹ́dì yín nínú ààrò kan ṣoṣo, wọ́n á máa wọn búrẹ́dì fún yín;+ ẹ ó jẹ, àmọ́ ẹ ò ní yó.+

  • Diutarónómì 28:49
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 49 “Jèhófà máa gbé orílẹ̀-èdè kan tó wà lọ́nà jíjìn+ dìde sí ọ, láti ìkángun ayé; ó máa kì ọ́ mọ́lẹ̀ bí ẹyẹ idì+ ṣe ń ṣe, orílẹ̀-èdè tí o ò ní gbọ́+ èdè rẹ̀,

  • Diutarónómì 28:51
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 51 Wọ́n á jẹ àwọn ọmọ ẹran ọ̀sìn rẹ àti èso ilẹ̀ rẹ títí wọ́n fi máa pa ọ́ run. Wọn ò ní ṣẹ́ ọkà kankan kù fún ọ àti wáìnì tàbí òróró tuntun, ọmọ màlúù tàbí àgùntàn, títí wọ́n fi máa pa ọ́ run.+

  • Jeremáyà 37:21
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 21 Nítorí náà, Ọba Sedekáyà ní kí wọ́n fi Jeremáyà sínú àhámọ́ ní Àgbàlá Ẹ̀ṣọ́,+ wọ́n sì ń fún un ní ìṣù búrẹ́dì ribiti kan lójúmọ́ láti òpópónà àwọn tó ń ṣe búrẹ́dì,+ títí gbogbo búrẹ́dì ìlú náà fi tán.+ Jeremáyà kò sì kúrò ní Àgbàlá Ẹ̀ṣọ́.

  • Ìsíkíẹ́lì 4:16
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 16 Lẹ́yìn náà, ó sọ fún mi pé: “Ọmọ èèyàn, mi ò ní jẹ́ kí oúnjẹ wà* ní Jerúsálẹ́mù,+ ṣe ni wọ́n máa wọn búrẹ́dì tí wọ́n fẹ́ jẹ látinú ìwọ̀nba tí wọ́n ní,+ ọkàn wọn ò sì ní balẹ̀. Wọ́n máa wọn omi tí wọ́n fẹ́ mu látinú ìwọ̀nba tí wọ́n ní, ẹ̀rù á sì máa bà wọ́n.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́