ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • 1 Àwọn Ọba 9:8
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 8 Ilé yìí á di àwókù.+ Gbogbo ẹni tó bá gba ibẹ̀ kọjá á wò ó tìyanutìyanu, á súfèé, á sì sọ pé, ‘Kì nìdí tí Jèhófà fi ṣe báyìí sí ilẹ̀ yìí àti sí ilé yìí?’+

  • 2 Kíróníkà 36:17
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 17 Nítorí náà, ó gbé ọba àwọn ará Kálídíà+ dìde sí wọn, ẹni tó fi idà pa àwọn ọ̀dọ́kùnrin wọn+ nínú ibi mímọ́ wọn;+ kò ṣàánú ọ̀dọ́kùnrin tàbí ọ̀dọ́bìnrin,* arúgbó tàbí aláàárẹ̀.+ Ohun gbogbo ni Ọlọ́run fi lé e lọ́wọ́.+

  • 2 Kíróníkà 36:19
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 19 Ó sun ilé Ọlọ́run tòótọ́ kanlẹ̀,+ ó wó ògiri Jerúsálẹ́mù lulẹ̀,+ ó sun gbogbo àwọn ilé gogoro tó láàbò, ó sì ba gbogbo ohun tó ṣeyebíye jẹ́.+

  • Sáàmù 74:8
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  8 Àwọn àti àwọn ọmọ wọn sọ nínú ọkàn wọn pé:

      “Gbogbo ibi ìpàdé tó jẹ́ ti Ọlọ́run* ní ilẹ̀ náà la máa dáná sun.”

  • Sáàmù 79:1
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 79 Ọlọ́run, àwọn orílẹ̀-èdè ti ya wọnú ogún rẹ;+

      Wọ́n ti sọ tẹ́ńpìlì mímọ́ rẹ di ẹlẹ́gbin;+

      Wọ́n ti sọ Jerúsálẹ́mù di àwókù.+

  • Jeremáyà 26:18
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 18 “Míkà+ ti Móréṣétì sọ tẹ́lẹ̀ nígbà ayé Hẹsikáyà+ ọba Júdà, ó sì sọ fún gbogbo èèyàn Júdà pé, ‘Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ nìyí:

      “Wọ́n á túlẹ̀ Síónì bíi pápá,

      Jerúsálẹ́mù á di àwókù,+

      Òkè Ilé* náà á sì dà bí àwọn ibi gíga nínú igbó.”’*+

  • Ìdárò 2:7
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  7 Jèhófà ti pa pẹpẹ rẹ̀ tì;

      Ó ti ta ibi mímọ́ rẹ̀ nù.+

      Ó ti fi ògiri àwọn ilé gogoro rẹ̀ tó láàbò lé ọ̀tá lọ́wọ́.+

      Wọ́n ti gbé ohùn wọn sókè ní ilé Jèhófà,+ bíi ti ọjọ́ àjọyọ̀.

  • Ìsíkíẹ́lì 24:21
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 21 ‘Sọ fún ilé Ísírẹ́lì pé: “Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí, ‘Mo máa tó sọ ibi mímọ́ mi di aláìmọ́,+ ibi pàtàkì tí ẹ fi ń yangàn, tí ẹ fẹ́ràn gidigidi, tó sì máa ń wù yín.* Idà ni wọn yóò fi pa àwọn ọmọ yín ọkùnrin àti obìnrin tí ẹ fi sílẹ̀.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́