-
2 Kíróníkà 36:17-19Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
17 Nítorí náà, ó gbé ọba àwọn ará Kálídíà+ dìde sí wọn, ẹni tó fi idà pa àwọn ọ̀dọ́kùnrin wọn+ nínú ibi mímọ́ wọn;+ kò ṣàánú ọ̀dọ́kùnrin tàbí ọ̀dọ́bìnrin,* arúgbó tàbí aláàárẹ̀.+ Ohun gbogbo ni Ọlọ́run fi lé e lọ́wọ́.+ 18 Gbogbo àwọn nǹkan èlò ilé Ọlọ́run tòótọ́, ńlá àti kékeré pẹ̀lú àwọn ìṣúra ilé Jèhófà àti àwọn ìṣúra ọba àti ti àwọn ìjòyè rẹ̀, gbogbo rẹ̀ pátá ló kó wá sí Bábílónì.+ 19 Ó sun ilé Ọlọ́run tòótọ́ kanlẹ̀,+ ó wó ògiri Jerúsálẹ́mù lulẹ̀,+ ó sun gbogbo àwọn ilé gogoro tó láàbò, ó sì ba gbogbo ohun tó ṣeyebíye jẹ́.+
-