ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w10 11/1 ojú ìwé 22
  • Adẹ́tẹ̀ Kan Rí Ìwòsàn Gbà!

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Adẹ́tẹ̀ Kan Rí Ìwòsàn Gbà!
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Bí Sódómù àti Gòmórà Ṣe Pa Run
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Jésù Borí Ìdẹwò
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • Jésù Fi Iṣẹ́ Ìyanu Mú Àwọn Aláìsàn Lára Dá
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Òye Jésù Ṣe Àwọn Tó Gbọ́rọ̀ Rẹ̀ Ní Kàyéfì
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
w10 11/1 ojú ìwé 22

Abala Àwọn Ọ̀dọ́

Adẹ́tẹ̀ Kan Rí Ìwòsàn Gbà!

Ohun tó o máa ṣe: Ibi tí kò sí ariwo ni kó o ti ṣe ìdánrawò yìí. Bó o bá ṣe ń ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà nísàlẹ̀ yìí, máa fojú inú wò ó bíi pé o wà níbi tọ́rọ̀ náà ti ń ṣẹlẹ̀, jẹ́ kó dà bíi pé ò ń gbọ́ bí àwọn èèyàn náà ṣe ń sọ̀rọ̀. Ronú nípa bí ohun tó ò ń kà yẹn ṣe máa rí lára àwọn èèyàn wọ̀nyẹn. Kó o sì máa fojú inú wò ó bí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́.

Àwọn tá a sọ̀rọ̀ nípa wọn: Náámánì, Èlíṣà àti ọmọbìnrin Ísírẹ́lì kan tí a kò dárúkọ rẹ̀

Àkópọ̀: Náámánì tó jẹ́ olórí ọmọ ogun Síríà tí àìsàn burúkú kan ń ṣe rí ìwòsàn gbà lẹ́yìn tí ọmọbìnrin Ísírẹ́lì kan sọ pé kó lọ rí Èlíṣà.

1 KA ÌTÀN NÁÀ DÁADÁA.—KA 2 ÀWỌN ỌBA 5:1-19.

Báwo lo ṣe rò pé ó máa rí lára ọmọdébìnrin tí wọ́n mú kúrò lọ́dọ̀ àwọn ará ilé rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ olùbẹ̀rù Ọlọ́run?

․․․․․

Ìjákulẹ̀ wo lo kíyè sí pé Náámánì ní, ìyẹn ọkùnrin alágbára tó ní àìsàn burúkú lára?

․․․․․

Ìṣarasíhùwà wo lo kíyè sí nínú ìjíròrò tó wáyé láàárín Náámánì àtàwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹsẹ 11 sí  13 ṣe sọ?

․․․․․

Ìyípadà wo lo kíyè sí pé ó bẹ̀rẹ̀ sí í wáyé nínú ìwà Náámánì gẹ́gẹ́ bí ẹsẹ 15 ṣe sọ?

․․․․․

2 ṢÈWÁDÌÍ KÓ O SÌ RONÚ JINLẸ̀.

Àwọn nǹkan wo ló ṣeé ṣe kó mú kí Náámánì máa gbéra ga? (Ka ẹsẹ 1.)

․․․․․

Lo àwọn ìwé ìwádìí tó o mọ̀, ṣèwádìí nípa àrùn ẹ̀tẹ̀ lákòókò tí wọ́n ń kọ Bíbélì.a (Bí àpẹẹrẹ, báwo ni àrùn náà ṣe burú tó? Ṣé ó lè ran èèyàn? Báwo ni wọ́n ṣe ń tọ́jú rẹ̀?)

․․․․․

Ipa wo lo rò pé ó ṣeé ṣe kí ìwòsàn tí Náámánì rí gbà ní lórí ọmọdébìnrin Ísírẹ́lì náà?

․․․․․

Ọ̀nà wo ló ṣeé ṣe kí èsì Èlíṣà gbà jẹ́ ìdánwò fún Náámánì? (Ka ẹsẹ 10.)

․․․․․

3 MÁA FOHUN TÓ O KỌ́ ṢÈWÀ HÙ. ṢÀKỌSÍLẸ̀ Ẹ̀KỌ́ TÓ O KỌ́ NÍPA . . .

Ewu tó wà nínú kéèyàn máa gbéra ga.

․․․․․

Fífi ìgboyà sọ̀rọ̀ nípa ohun tó o gbà gbọ́.

․․․․․

Agbára Jèhófà láti woni sàn.

․․․․․

4 KÍ LÓ WÚ Ẹ LÓRÍ JÙ LỌ NÍNÚ ÌTÀN YÌÍ, KÍ SÌ NÌDÍ?

․․․․․

KẸ́KỌ̀Ọ́ SÍ I NÍPA BÍBÉLÌ, LÓRÍ ÌKÀNNÌ WA www.watchtower.org ÀTI www.jw.org

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àrùn tá à ń pè ní àrùn Hansen lónìí wà lára àrùn ẹ̀tẹ̀ ní àkókò tí wọ́n ń kọ Bíbélì.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́