ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w11 1/1 ojú ìwé 30-31
  • Mọrírì Àwọn Ohun Mímọ́!

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Mọrírì Àwọn Ohun Mímọ́!
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Bí Sódómù àti Gòmórà Ṣe Pa Run
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Jésù Fi Iṣẹ́ Ìyanu Mú Àwọn Aláìsàn Lára Dá
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Òye Jésù Ṣe Àwọn Tó Gbọ́rọ̀ Rẹ̀ Ní Kàyéfì
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Mósè Gba Iṣẹ́ Pàtàkì Kan
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
w11 1/1 ojú ìwé 30-31

Abala Àwọn Ọ̀dọ́

Mọrírì Àwọn Ohun Mímọ́!

Ohun tó o máa ṣe: Ibi tí kò sí ariwo ni kó o ti ṣe ìdánrawò yìí. Bó o bá ṣe ń ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà nísàlẹ̀ yìí, máa fojú inú wò ó bíi pé o wà níbi tọ́rọ̀ náà ti ń ṣẹlẹ̀, jẹ́ kó dà bíi pé ò ń gbọ́ bí àwọn èèyàn náà ṣe ń sọ̀rọ̀. Ronú nípa bí ohun tó ò ń kà yẹn ṣe máa rí lára àwọn èèyàn wọ̀nyẹn. Kó o sì máa fojú inú wò ó bí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́.

Àwọn tá a sọ̀rọ̀ nípa wọn: Ísákì, Rèbékà, Jékọ́bù àti Ísọ̀

Àkópọ̀: Ísọ̀ ta ẹ̀tọ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àkọ́bí fún Jékọ́bù tó jẹ́ ìbejì rẹ̀.

1 KA ÌTÀN NÁÀ DÁADÁA.—KA JẸ́NẸ́SÍSÌ 25:20-34.

Irú ìwà wo ni Jékọ́bù àti Ísọ̀ fi hàn nígbà tí wọ́n wà nínú ìyá wọn?

․․․․․

Ṣàpèjúwe ìrísí Jékọ́bù àti Ísọ̀ nígbà tí wọ́n ti dàgbà.

․․․․․

Kí lo kíyè sí nínú ohùn Jékọ́bù àti Ísọ̀ nígbà tí wọ́n ń bá ara wọn sọ̀rọ̀ ní ẹsẹ 30 sí 33?

․․․․․

ṢÈWÁDÌÍ KÓ O SÌ RONÚ JINLẸ̀.

Lo àwọn ìwé ìwádìí tó o mọ̀ láti fi ṣèwádìí nípa ẹ̀tọ́ tí ọmọkùnrin tó jẹ́ àkọ́bí ní. Kí nìdí tí ẹ̀tọ́ náà fi ṣe pàtàkì? Kí ló máa jẹ́ àbájáde títa ẹ̀tọ́ náà nítorí àwo ọbẹ̀ kan?

․․․․․

2 KA ÌTÀN NÁÀ DÁADÁA.—KA JẸ́NẸ́SÍSÌ 27:1-10, 30-38.

Kí lo kíyè sí nínú ohùn Ísọ̀ nígbà tó mọ̀ pé arákùnrin òun ti gba ìbùkún tó jẹ́ ti àkọ́bí?

․․․․․

ṢÈWÁDÌÍ KÓ O SÌ RONÚ JINLẸ̀.

Ǹjẹ́ ohun tí Rèbékà àti Jékọ́bù ṣe burú, bí wọ́n ṣe dá ọgbọ́n sí ọ̀ràn náà kí Jékọ́bù lè gba ìbùkún náà? Kí nìdí tó o fi sọ pé ó burú tàbí pé kò burú? (Ojútùú: Ka Jẹ́nẹ́sísì 25:23, 33.)

․․․․․

3 MÁA FOHUN TÓ O KỌ́ ṢÈWÀ HÙ. ṢÀKỌSÍLẸ̀ Ẹ̀KỌ́ TÓ O KỌ́ NÍPA . . .

Àkóbá tó máa ń wà fún ìgbà pípẹ́, èyí tí ìgbádùn ojú ẹsẹ̀ máa ń ṣe fúnni.

․․․․․

ÀWỌN OHUN MÍÌ TÓ O LÈ FI ṢÈWÀ HÙ.

Àwọn ohun mímọ́ wo ni wọ́n ní kó o máa bójú tó?

․․․․․

Àwọn ọ̀nà pàtó wo lo lè gbà fi hàn pé o mọrírì àwọn ohun mímọ́?

․․․․․

4 KÍ LÓ WÚ Ẹ LÓRÍ JÙ LỌ NÍNÚ ÌTÀN YÌÍ, KÍ SÌ NÌDÍ?

․․․․․

Kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa Bíbélì, lórí ìkànnì wa www.watchtower.org ÀTI www.jw.org

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́