ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w11 5/1 ojú ìwé 22-23
  • Yẹra fún Ẹgbẹ́ Búburú!

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Yẹra fún Ẹgbẹ́ Búburú!
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Bí Sódómù àti Gòmórà Ṣe Pa Run
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Jésù Borí Ìdẹwò
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • Jésù Fi Iṣẹ́ Ìyanu Mú Àwọn Aláìsàn Lára Dá
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Òye Jésù Ṣe Àwọn Tó Gbọ́rọ̀ Rẹ̀ Ní Kàyéfì
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
w11 5/1 ojú ìwé 22-23

Abala Àwọn Ọ̀dọ́

Yẹra fún Ẹgbẹ́ Búburú!

Ohun tó o máa ṣe: Ibi tí kò sí ariwo ni kó o ti ṣe ìdánrawò yìí. Bó o bá ṣe ń ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà nísàlẹ̀ yìí, máa fojú inú wò ó bíi pé o wà níbi tọ́rọ̀ náà ti ń ṣẹlẹ̀, jẹ́ kó dà bíi pé ò ń gbọ́ bí àwọn èèyàn náà ṣe ń sọ̀rọ̀. Ronú nípa bí ohun tó ò ń kà yẹn ṣe máa rí lára àwọn èèyàn wọ̀nyẹn. Kó o sì máa fojú inú wò ó bí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́.

Àwọn tá a sọ̀rọ̀ nípa wọn: Dínà, Ṣékémù, Jékọ́bù, Síméónì àti Léfì

Àkópọ̀: Ṣékémù fipá bá Dínà lòpọ̀, àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ tí inú ń bí sì gbẹ̀san.

1 KA ÌTÀN NÁÀ DÁADÁA.—KA JẸ́NẸ́SÍSÌ 34:1-31.

Àwọn nǹkan wo lo rò pé ó ṣeé ṣe kí Dínà àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tó wà ní Kénáánì jọ máa ṣe?

․․․․․

Àwọn nǹkan wo lo fojú inú wò pé Ṣékémù sọ nígbà tó ń “sọ̀rọ̀ ṣáá lọ́nà tí ń yíni lérò padà” fún Dínà?

․․․․․

Kí lo kíyè sí nínú ohùn Jékọ́bù nígbà tó ń bá Síméónì àti Léfì sọ̀rọ̀ ní ẹsẹ 30?

․․․․․

2 ṢÈWÁDÌÍ KÓ O SÌ RONÚ JINLẸ̀.

Kí lo rò pé ó mú kí Dínà máa lọ sọ́dọ̀ àwọn ọmọbìnrin Kénáánì déédéé? (Bí àpẹẹrẹ, kí ló mú kí ọ̀rọ̀ rẹ̀ àti àwọn ọmọbìnrin náà wọ̀? Kí ló ṣeé ṣe kí Dínà rí lọ́dọ̀ àwọn èèyàn Kénáánì tí kò rí lọ́dọ̀ àwọn èèyàn rẹ̀?)

․․․․․

Àwọn ìwà tó fani mọ́ra wo ló ṣeé ṣe kí Dínà ti rí lára Ṣékémù? (Tún ẹsẹ 3, 12 àti 19 kà.)

․․․․․

Báwo ni Bíbélì ṣe jẹ́ ká mọ̀ pé, Dínà kó fẹ́ ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú Ṣékémù? (Tún ẹsẹ 2 kà.)

․․․․․

Ǹjẹ́ o rò pé ó yẹ kí Síméónì àti Léfì gbẹ̀san nípa pípa àwọn olùgbé ìlú Ṣékémù? Kí nìdí tó fi yẹ tàbí tí kò fi yẹ?

․․․․․

3 MÁA FOHUN TÓ O KỌ́ ṢÈWÀ HÙ. ṢÀKỌSÍLẸ̀ Ẹ̀KỌ́ TÓ O KỌ́ NÍPA . . .

Ìdí tó fi yẹ kó o fọgbọ́n yan àwọn ọ̀rẹ́ rẹ.

․․․․․

Ìdí tó fi yẹ kó o ní ìkóra-ẹni-níjàánu, àní tó bá tiẹ̀ yẹ láti bínú pàápàá.

․․․․․

ÀWỌN OHUN MÍÌ TÓ O LÈ FI ṢÈWÀ HÙ.

Àwọn nǹkan wo lo lè ṣe tí o kò fi ní kó sọ́wọ́ àwọn tí kò bọ̀wọ̀ fún àwọn ìlànà Ọlọ́run tí wọ́n lè fẹ́ fi ẹ̀tàn bá ọ lòpọ̀?

․․․․․

4 KÍ LÓ WÚ Ẹ LÓRÍ JÙ LỌ NÍNÚ ÌTÀN YÌÍ, KÍ SÌ NÌDÍ?

․․․․․

Kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa Bíbélì, lórí ìkànnì WA www.watchtower.org ÀTI www.jw.org

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́