ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w11 7/1 ojú ìwé 30-31
  • Bí O Ṣe Lè Dènà Ìdẹwò

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Bí O Ṣe Lè Dènà Ìdẹwò
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Wọ́n Fi Ẹ̀sùn Èké Kàn Án!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • Bí Sódómù àti Gòmórà Ṣe Pa Run
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Jésù Borí Ìdẹwò
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • Òye Jésù Ṣe Àwọn Tó Gbọ́rọ̀ Rẹ̀ Ní Kàyéfì
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
w11 7/1 ojú ìwé 30-31

Abala Àwọn Ọ̀dọ́

Bí O Ṣe Lè Dènà Ìdẹwò

JÓSẸ́FÙ—APÁ KÌÍNÍ

Ohun tó o máa ṣe: Ibi tí kò sí ariwo ni kó o ti ṣe ìdánrawò yìí. Bó o bá ṣe ń ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà nísàlẹ̀ yìí, máa fojú inú wò ó bíi pé o wà níbi tọ́rọ̀ náà ti ń ṣẹlẹ̀, jẹ́ kó dà bíi pé ò ń gbọ́ bí àwọn èèyàn náà ṣe ń sọ̀rọ̀. Ronú nípa bí ohun tó ò ń kà yẹn ṣe máa rí lára àwọn èèyàn wọ̀nyẹn. Kó o sì máa fojú inú wò ó bí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́.

Àwọn tá a sọ̀rọ̀ nípa wọn: Jósẹ́fù, ìyàwó Pọ́tífárì

Àkópọ̀: Jósẹ́fù kọ ìdẹwò láti ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ìyàwó Pọ́tífárì.

1 KA ÌTÀN NÁÀ DÁADÁA.—KA JẸ́NẸ́SÍSÌ 39:1-12.

Fojú inú wo ilé Pọ́tífárì kí o sì ṣàlàyé bó ṣe tóbi tó àti bó ṣe lẹ́wà tó.

․․․․․

Báwo ni Jósẹ́fù ṣe rí? (Ojútùú: Tún ẹsẹ 6 kà.)

․․․․․

Kí lo kíyè sí nínú ohùn Jósẹ́fù nígbà tó ń bá ìyàwó Pọ́tífárì sọ̀rọ̀ ní ẹsẹ 8 àti 9?

․․․․․

2 ṢÈWÁDÌÍ KÓ O SÌ RONÚ JINLẸ̀.

Kí lo rò pé ó lè mú kí ó rọrùn fún Jósẹ́fù láti ṣe ìṣekúṣe? (Ojútùú: Ka Fílípì 2:12, kí o sì ronú nípa ipò tí Jósẹ́fù bá ara rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ní àkókò yẹn, ibo ni àwọn ará ilé Jósẹ́fù àtàwọn olùjọ́sìn Jèhófà bíi ti Jósẹ́fù wà?)

․․․․․

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé nígbà ayé Jósẹ́fù, kò sí òfin Ọlọ́run tó sọ pé èèyàn kò gbọ́dọ̀ ṣe panṣágà, kí ló mú kó o gbà pé Jósẹ́fù mọ̀ pé téèyàn bá ṣe panṣágà, ẹ̀ṣẹ̀ ńlá ló jẹ́ sí Ọlọ́run? (Ojútùú: Ka Jẹ́nẹ́sísì 2:24; 12:17, 18; Róòmù 2:14, 15; àti Hébérù 5:14, kí o sì ronú lórí wọn.)

․․․․․

3 MÁA FOHUN TÓ O KỌ́ ṢÈWÀ HÙ. ṢÀKỌSÍLẸ̀ Ẹ̀KỌ́ TÓ O KỌ́ NÍPA . . .

Bí ìkóra-ẹni-níjàánu ṣe ń jẹ́ kéèyàn ní iyì.

․․․․․

Àǹfààní tí àwọn tó ń tẹ̀ lé ìlànà Ọlọ́run máa ń rí.

․․․․․

Ìdí tó fi yẹ kó o kọ́ “agbára ìmòye” rẹ. (Hébérù 5:14)

․․․․․

ÀWỌN OHUN MÍÌ TÓ O LÈ FI ṢÈWÀ HÙ.

Àwọn apá wo nígbèésí ayé rẹ ló yẹ kó o ti túbọ̀ ṣèpinnu tó lágbára, tó bá kan pé kó o dènà ìdẹwò ìbálópọ̀? (Ojútùú: Ka Jóòbù 31:1; Sáàmù 119:37; Éfésù 5:3, 4, kí o sì ronú lórí wọn.)

․․․․․

4 KÍ LÓ WÚ Ẹ LÓRÍ JÙ LỌ NÍNÚ ÌTÀN YÌÍ, KÍ SÌ NÌDÍ?

․․․․․

Kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa Bíbélì, lórí ìkànnì wa www.watchtower.org àti www.jw.org

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́