Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí
December 15, 2011
Ẹ̀dà Tó Wà Fún Ìkẹ́kọ̀ọ́
ÀWỌN ÀPILẸ̀KỌ TÁ A MÁA KẸ́KỌ̀Ọ́ NÍ Ọ̀SẸ̀:
January 30, 2012–February 5, 2012
Ṣé Àpẹẹrẹ Rere Ló Jẹ́ fún Ẹ àbí Àpẹẹrẹ Búburú?
OJÚ ÌWÉ 8
ÀWỌN ORIN TÁ A Ó KỌ: 61, 57
February 6-12, 2012
Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Jẹ́ Kí Ẹ̀mí Ọlọ́run Máa Darí Wa?
OJÚ ÌWÉ 13
ÀWỌN ORIN TÁ A Ó KỌ: 71, 63
February 13-19, 2012
Ẹ̀mí Ọlọ́run Darí Àwọn Olóòótọ́ Ayé Ìgbàanì
OJÚ ÌWÉ 18
ÀWỌN ORIN TÁ A Ó KỌ: 81, 51
February 20-26, 2012
Ẹ̀mí Ọlọ́run Darí Àwọn Kristẹni ní Ọ̀rúndún Kìíní Ó sì Ń Darí Àwa Náà Lónìí
OJÚ ÌWÉ 22
ÀWỌN ORIN TÁ A Ó KỌ: 69, 122
Ohun Táwọn Àpilẹ̀kọ Tá A Máa Kẹ́kọ̀ọ́ Dá Lé
ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 1 OJÚ ÌWÉ 8 sí 12
Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa àwọn èèyàn kan tí wọ́n jẹ́ àpẹẹrẹ rere fún wa, àmọ́ wọ́n tún lè jẹ́ àpẹẹrẹ búburú. Àpilẹ̀kọ yìí máa mú ká rí ọ̀nà tí Sólómọ́nì gbà jẹ́ àpẹẹrẹ rere àti àpẹẹrẹ búburú. Kí la lè rí kọ́ lára rẹ̀ tó máa ràn wá lọ́wọ́ láti gbé ìgbé ayé tó yẹ àwa Kristẹni?
ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 2 OJÚ ÌWÉ 13 sí 17
Agbára ńlá kan wà lágbàáyé tó lè darí wa nínú ayé búburú yìí ká bàa lè kẹ́sẹ járí. Kí ni agbára ńlá náà, kí nìdí tó fi yẹ ká fẹ́ kó máa darí wa, kí la sì lè ṣe ká lè jàǹfààní ní kíkún látinú bó ṣe ń darí wa?
ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 3, 4 OJÚ ÌWÉ 18 sí 26
Ọ̀pọ̀ àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run nígbà àtijọ́ kún fún ẹ̀mí mímọ́. Àwọn ọ̀nà wo ni ẹ̀mí Ọlọ́run gbà ṣiṣẹ́ lára wọn? Ohun tá a máa kọ́ nípa bí Jèhófà ṣe darí wọn á mú ká lè máa bá a nìṣó lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run.
ÀWỌN ÀPILẸ̀KỌ MÍÌ NÍNÚ ÌTẸ̀JÁDE YÌÍ
3 Mo Ti Jàǹfààní Látinú Àwọn Ìyípadà Tí Mo Ṣe
27 Má Ṣe Jẹ́ Kí Àìlera Ba Ayọ̀ Rẹ Jẹ́
32 Atọ́ka Àwọn Àkòrí Inú Ilé Ìṣọ́ 2011