ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w12 1/1 ojú ìwé 12-15
  • Ibi Tí Ààlà Orílẹ̀-Èdè Kò Ti Ṣèdíwọ́

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ibi Tí Ààlà Orílẹ̀-Èdè Kò Ti Ṣèdíwọ́
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìṣọ̀kan Wáyé Nínú Àfonífojì Tí Wọ́n Pín sí Méjì
  • Ìpìlẹ̀ Bí Ilẹ̀ Yúróòpù Ṣe Máa Wà Níṣọ̀kan
  • Bá A Ṣe Ṣètò Àwọn Ibi Ìjọsìn Wa
    A Ṣètò Wa Láti Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà
  • Ìmúgbòòrò Tí Ń Bá A Nìṣó Ń Mú Àìní fún Àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba Pọ̀ Sí I
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1997
  • Ibi Ìjọsìn Wa Rèé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
w12 1/1 ojú ìwé 12-15

Ibi Tí Ààlà Orílẹ̀-Èdè Kò Ti Ṣèdíwọ́

Àwọn Ẹlẹ́rìí máa ń rí i dájú pé àwọn kò gba ẹ̀mí kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà láyè. Ìlànà tí wọ́n ń tẹ̀ lé wà nínú ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Arákùnrin ni gbogbo yín jẹ́.” (Mátíù 23:8) A rí àpẹẹrẹ èyí ní ilé ìjọsìn méjì kan tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń lò. Ọ̀kan wà lórílẹ̀-èdè Potogí èkejì sì wà lórílẹ̀-èdè Sípéènì.

ÌGBÀ ogun tó le gan-an ni wọ́n mọ odi yí ká ìlú Valença do Minho, tó wà níhà àríwá orílẹ̀-èdè Potogí. Àwọn odi orí òrùlé rẹ̀ kọjú síhà Odò Minho, tó jẹ́ ààlà láàárín ilẹ̀ Sípéènì àti ilẹ̀ Potogí. Ìlú Tui wà ní òdì kejì odò yìí nílẹ̀ Sípéènì, ṣọ́ọ̀ṣì ńlá kan tó jọ ilé tí wọ́n kọ́ láti fi ṣe ibi ààbò sì wà níbẹ̀. Ní nǹkan bí irínwó [400] ọdún sẹ́yìn, wọ́n dìídì mọ odi, wọ́n sì kọ́ àwọn ibi ààbò sí ìlú Tui àti ìlú Valença nígbà tí ogun wà láàárín ilẹ̀ Sípéènì àti ilẹ̀ Potogí.

Lọ́dún 1995, wọ́n mú ibodè àti òfin ẹnubodè kúrò láàárín orílẹ̀-èdè méjèèjì yìí, tí wọ́n jẹ́ ara Àwùjọ Àwọn Orílẹ̀-Èdè Ilẹ̀ Yúróòpù. Ṣùgbọ́n, mímú ibodè àti òfin ẹnubodè kúrò nìkan kọ́ ló máa mú kí àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ wà níṣọ̀kan. Ó tún gba pé kí àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè wọ̀nyẹn lọ́kàn tó dáa síra wọn. Ilé kékeré kan tó dára rèǹtè-rente wà nílùú Valença tó jẹ́ ká rí bí àwọn èèyàn látinú ẹ̀yà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ṣe lè dẹni tó wà ní ìṣọ̀kan. Ilé ìjọsìn, ìyẹn Gbọ̀ngàn Ìjọba Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni ilé náà. Ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n ti ń sọ èdè Potogí àti èyí tí wọ́n ti ń sọ èdè Sípáníìṣì ni wọ́n jọ ń lo Gbọ̀ngàn Ìjọba náà.

Èyí wáyé lọ́dún 2001 nígbà tí àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà ní ìlú Tui, tí wọ́n ń sọ èdè Sípáníìṣì, rí i pé àwọn gbọ́dọ̀ wá Gbọ̀ngàn Ìjọba míì tí àwọn yóò máa lò. Ìdí ni pé ó di dandan kí wọ́n kúrò níbi tí wọ́n ń yá lò tẹ́lẹ̀, wọn kò sì lówó tí wọ́n máa fi kọ́ gbọ̀ngàn tiwọn. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, agbára wọn ò gbé e láti lọ háyà ibi tí wọ́n lè máa lò nítorí pé ìjọ wọn kéré. Torí náà, àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà ní ìjọ tí wọ́n ti ń sọ èdè Sípáníìṣì lọ bá àwọn arákùnrin wọn ní ìjọ tí wọ́n ti ń sọ èdè Potogí nílùú Valença pé kí wọ́n jẹ́ káwọn jọ máa lo Gbọ̀ngàn Ìjọba wọn, èyí tí kò fi bẹ́ẹ̀ jìnnà sí ìlú Tui.

Arákùnrin Eduardo Vila tó wà ní ìjọ Tui lórílẹ̀-èdè Sípéènì sọ pé: “A jọ jíròrò ọ̀rọ̀ yìí ní ìpàdé àwọn alàgbà kan tá a ṣe lóṣù December ọdún 2001. Nígbà tí ìpàdé yẹn parí, tí mò ń lọ sílé, mo rí i pé Jèhófà fi ẹ̀mí rẹ̀ darí àwọn arákùnrin wa tó wà ní ìjọ tí wọ́n ti ń sọ èdè Potogí. Bí wọ́n ṣe gbà tinútinú pé ká jọ máa lo Gbọ̀ngàn Ìjọba wọn rèǹtè-rente tí wọ́n náwó nára láti kọ́ yẹn, gbé ìgbàgbọ́ wa ró gidigidi.”

Arákùnrin Américo Almeida láti ìjọ tí wọ́n ti ń sọ èdè Potogí, tí òun náà wà níbi ìpàdé yẹn, sọ pé: “Inú wa dùn gan-an pé kí àwọn arákùnrin wa tó wà ní ìjọ tí wọ́n ti ń sọ èdè Sípáníìṣì wá máa bá wa lo Gbọ̀ngàn Ìjọba wa. Gbogbo wa la fohùn ṣọ̀kan lórí ìpinnu yìí, a sì mọ̀ pé Jèhófà yóò fi ìbùkún sí ètò tá a ṣe yẹn.” Ìrẹ́pọ̀ wà láàárín àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà nínú ìjọ méjèèjì yìí. Kódà, arákùnrin Paolo, tó wà ní ìjọ Valença sọ pé: “Ó lè ṣòroó gbà gbọ́ o, àmọ́ ká sòótọ́, kò tiẹ̀ hàn rárá pé orílẹ̀-èdè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni ìjọ méjèèjì wà. Ohun tá a ṣáà mọ̀ ni pé arákùnrin ni gbogbo wa jọ jẹ́.”

Ọ̀kan lára ohun tí àlejò tó bá wọnú Gbọ̀ngàn Ìjọba yẹn máa ń kọ́kọ́ kíyè sí lára ògiri lápá ẹ̀yìn, ni aago méjì tó jẹ́ irú kan náà àmọ́ tí wọ́n ń ka wákàtí ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Èyí jẹ́ nítorí pé ọ̀kan ń tẹ̀ lé aago ilẹ̀ Sípéènì tó fi wákàtí kan ṣáájú aago ilẹ̀ Potogí. Wákàtí ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí aago méjèèjì yẹn ń kà ni ohun kan ṣoṣo tó yàtọ̀ nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba yẹn. Nígbà tá a fẹ́ ṣàtúnṣe Gbọ̀ngàn Ìjọba yìí, Ìgbìmọ̀ Ìkọ́lé Ẹlẹ́kùnjẹkùn tó wà nílẹ̀ Sípéènì ló wá bójú tó iṣẹ́ tí àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn láti ìjọ méjèèjì fi tayọ̀tayọ̀ ṣe. Paolo sọ pé: “Ọ̀pọ̀ àwọn ará tó jẹ́ akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ ní ilẹ̀ Sípéènì ló wá ràn wá lọ́wọ́. Àwọn míì nínú wọn wá láti ibi tó jìnnà tó ọgọ́jọ [160] kìlómítà. Iṣẹ́ yẹn sì jẹ́ kí ìfẹ́ tó wà láàárín ìjọ méjèèjì túbọ̀ jinlẹ̀ sí i.”

Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ kejì nípa bí àwọn èèyàn láti orílẹ̀-èdè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ṣe lè dẹni tó wà ní ìṣọ̀kan.

Ìṣọ̀kan Wáyé Nínú Àfonífojì Tí Wọ́n Pín sí Méjì

Ìlú Puigcerdá nílẹ̀ Sípéènì wà láàárín àfonífojì ọlọ́ràá kan tí àwọn òkè ńláńlá Pyrenees yí ká, nítòsí ààlà ilẹ̀ Sípéènì àti orílẹ̀-èdè Faransé. Orúkọ àfonífojì yìí ni Cerdaña, ilẹ̀ Sípéènì ló sì ni gbogbo rẹ̀ tẹ́lẹ̀. Àmọ́ lọ́dún 1659 ilẹ̀ Sípéènì àti orílẹ̀-èdè Faransé ṣe àdéhùn àlàáfíà kan tí wọ́n pè ní Àdéhùn Pyrenees. Inú àdéhùn náà ni ilẹ̀ Sípéènì ti pín apá kan àfonífojì náà fún orílẹ̀-èdè Faransé.

Lóde òní, ìlú Puigcerdá tó tóbi jù nínú àwọn ìlú tó wà ní àfonífojì yẹn làwọn kan tó ń gbé ní orílẹ̀-èdè Faransé máa ń wá láti ra ọjà. Bákan náà, láti ọdún 1997 làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà nílùú Puigcerdá ti jẹ́ kí àwọn arákùnrin àti arábìnrin wọn tó wà ní orílẹ̀-èdè Faransé wá máa lo Gbọ̀ngàn Ìjọba wọn. Lọ́dún yẹn, ó di dandan pé kí àwọn ará ìjọ tó ń sọ èdè Faransé kúrò ní ibi tí wọ́n háyà tí wọ́n ti ń ṣèpàdé. Gbọ̀ngàn Ìjọba tó sì sún mọ́ wọn jù lórílẹ̀-èdè Faransé máa gbà tó ìrìn wákàtí kan kí mọ́tò tó débẹ̀, tó bá sì dìgbà òtútù, ṣe ni yìnyín máa ń bo ojú ọ̀nà tó wà láàárín òkè téèyàn máa gbà débẹ̀.

Nígbà tí àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà níjọ tí wọ́n ti ń sọ èdè Faransé ṣàlàyé pé ó jẹ́ kánjúkánjú pé kí àwọn ní ibi tí àwọn yóò ti máa ṣèpàdé, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà ní ìjọ tí wọ́n ti ń sọ èdè Sípáníìṣì sọ pé kí wọ́n máa wá lo Gbọ̀ngàn Ìjọba àwọn. Arákùnrin Prem tó wà ní ìjọ tí wọ́n ti ń sọ èdè Sípáníìṣì sọ pé: “Inú gbogbo àwọn ará ìjọ wa ló dùn gan-an pé kí àwọn ará wa láti orílẹ̀-èdè Faransé yìí wá máa bá wa lo Gbọ̀ngàn Ìjọba pọ̀. Ẹ̀kọ́ òtítọ́ tá a ti ń kọ́ láti ọ̀pọ̀ ọdún wá ló sì jẹ́ ká lè ṣe bẹ́ẹ̀. Ọ̀sẹ̀ mélòó kan lẹ́yìn náà la bẹ̀rẹ̀ sí í lo Gbọ̀ngàn Ìjọba wa pa pọ̀, ó sì ti lé ni ọdún mẹ́tàlá báyìí tá a ti jọ ń lò ó.”

Arákùnrin Eric tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn alábòójútó níjọ tí wọ́n ti ń sọ èdè Faransé sọ pé: “Ìlú Puigcerdá gan-an ló pé wa jù kí Gbọ̀ngàn Ìjọba wa wà. Kódà mo ṣì ń rántí bí àwọn ará wa ní ìjọ tí wọ́n ti ń sọ èdè Sípáníìṣì ṣe fi ọ̀yàyà gbà wá tọwọ́tẹsẹ̀. Wọ́n fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ òdòdó ṣe Gbọ̀ngàn Ìjọba wọn lọ́ṣọ̀ọ́, wọ́n sì kọ àkọlé gàdàgbà kan síbẹ̀ pé: ‘A fi tayọ̀tayọ̀ kí yín káàbọ̀ o, ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin wa.’”

Arákùnrin Eric tún sọ pé: “Nítorí a kò ní Gbọ̀ngàn Ìjọba tí a ti ń ṣe ìpàdé mọ́ ní orílẹ̀-èdè Faransé, ọ̀pọ̀ èèyàn rò pé ìjọ wa ti pa rẹ́. Àmọ́ bá a ṣe ń wàásù déédéé níbẹ̀, tá a sì ń fún àwọn èèyàn ní ìwé ìkésíni pé kí wọ́n wá sí ìpàdé wa ní ilẹ̀ Sípéènì, kò pẹ́ tí wọ́n fi rí i pé ìjọ wa ṣì wà níbẹ̀. Inú àwọn tó fẹ́ràn ẹ̀kọ́ òtítọ́ máa ń dùn láti wá sí Gbọ̀ngàn Ìjọba wa ní ilẹ̀ Sípéènì. Yàtọ̀ síyẹn, bí àwa àtàwọn ará wa ní ìjọ tí wọ́n ti ń sọ èdè Sípáníìṣì ṣe jọ ń lo gbọ̀ngàn kan náà, a túbọ̀ wá sún mọ́ra dáadáa. Tẹ́lẹ̀, a mọ̀ pé ìjọ kan wà lódì kejì ibodè, tí wọ́n ń sọ èdè Sípáníìṣì, àmọ́ a kì í sábà ríra. Bá a ṣe wá ń ríra déédéé báyìí, kò ṣe wá mọ́ bíi pé ìjọ wa kàn dá wà láàárín àfonífojì yìí.”

Ǹjẹ́ bí ìṣe àti àṣà ìlú méjèèjì ṣe yàtọ̀ síra fa ìṣòro kankan? Arábìnrin kan níjọ tí wọ́n ti ń sọ èdè Faransé, tó ti lé ní ẹni ọgọ́rin [80] ọdún, sọ pé: “Nígbà tí mo gbọ́ pé òdì kejì ibodè la ó ti lọ máa ṣèpàdé, ó kọ mí lóminú. Ṣùgbọ́n torí pé àwọn ará wa ní ìlú Puigcerdá fi ọ̀yàyà tẹ́wọ́ gbà wá, a kò níṣòro rárá. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ni ìyípadà yẹn jẹ́ ká lè túbọ̀ fi hàn pé àwa èèyàn Jèhófà kárí ayé wà níṣọ̀kan.”

Ìpìlẹ̀ Bí Ilẹ̀ Yúróòpù Ṣe Máa Wà Níṣọ̀kan

Àwọn olùdásílẹ̀ àjọ àwùjọ àwọn orílẹ̀-èdè ilẹ̀ Yúróòpù sọ pé, àwọn orílẹ̀-èdè tó wà nínú àjọ yìí “pinnu láti fi ìpìlẹ̀ bí àwọn èèyàn ilẹ̀ Yúróòpù ṣe máa túbọ̀ wà níṣọ̀kan lélẹ̀.” Torí kí ohun tí wọ́n fẹ́ ṣe yìí lè yá kíákíá ni wọ́n ṣe mú àwọn ibodè àti òfin ẹnubodè kúrò láwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyẹn láàárín ọdún 1980 sí 1999. Àmọ́, àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè wọ̀nyẹn gbọ́dọ̀ mú ẹ̀tanú kúrò lọ́kàn kí wọ́n tó lè kẹ́sẹ járí.

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń sapá gidigidi láti rí i pé wọ́n borí ẹ̀tanú àti àìfọkàntánni. Wọ́n mọ̀ pé bí àwọn ṣe wá láti onírúurú ẹ̀yà àti ìran tún fi kún adùn àárín àwọn, àti pé “Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú.” (Ìṣe 10:34) Nígbà àpéjọ àgbáyé tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń ṣe àti nígbà àwọn ìpàdé tí wọ́n máa ń ṣe nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba wọn, wọ́n máa ń rí i lóòótọ́ pé: “Ó mà dára o, ó mà dùn o, pé kí àwọn ará máa gbé pa pọ̀ ní ìṣọ̀kan!” (Sáàmù 133:1) Ìṣọ̀kan tó wà láàárín àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní ìlú Valença àti Puigcerdá àtàwọn arákùnrin wọn tó wà lórílẹ̀-èdè ìtòsí wọn sì fi hàn pé òótọ́ pọ́ńbélé ni ọ̀rọ̀ inú Bíbélì yìí.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 13]

“Ó lè ṣòroó gbà gbọ́ o, àmọ́ ká sòótọ́, kò tiẹ̀ hàn rárá pé orílẹ̀-èdè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni ìjọ méjèèjì wà. Ohun tá a ṣáà mọ̀ ni pé arákùnrin ni gbogbo wa jọ jẹ́”

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 14]

“Iṣẹ́ yẹn jẹ́ kí ìfẹ́ tó wà láàárín ìjọ méjèèjì túbọ̀ jinlẹ̀ sí i”

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 15]

“Ó mà dára o, ó mà dùn o, pé kí àwọn ará máa gbé pa pọ̀ ní ìṣọ̀kan!” SÁÀMÙ 133:1

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12, 13]

Ìlú Tui àti Odò Minho rèé téèyàn bá wò ó láti orí odi ìlú Valença do Minho

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]

Ìgbà tí wọ́n ń tún Gbọ̀ngàn Ìjọba ṣe rèé

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Òkè ńláńlá Pyrenees àti àfonífojì Cerdaña

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Alàgbà méjì rèé láti ìjọ méjèèjì tó ń lo Gbọ̀ngàn Ìjọba tó wà ní Puigcerdá, ìyẹn ìjọ tí wọ́n ti ń sọ èdè Faransé àti ìjọ tí wọ́n ti ń sọ èdè Sípáníìṣì

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́