ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w12 5/1 ojú ìwé 16-17
  • Ìròyìn Ayọ̀ Wo Ló Wà Nípa Ìsìn?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìròyìn Ayọ̀ Wo Ló Wà Nípa Ìsìn?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìròyìn Ayọ̀ Wo Ló Wà Nípa Ìsìn?
    Ìròyìn Ayọ̀ Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run!
  • Ẹ̀sìn Èké Kò Ṣojú fún Ọlọ́run
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
  • Òpin Ìsìn Èké Sún Mọ́lé!
    Òpin Ìsìn Èké Sún Mọ́lé!
  • Kọ Ẹ̀sìn Èké Sílẹ̀!
    Ìwọ Lè Di Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run!
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
w12 5/1 ojú ìwé 16-17

Kẹ́kọ̀ọ́ Látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run

Ìròyìn Ayọ̀ Wo Ló Wà Nípa Ìsìn?

Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a sọ̀rọ̀ lórí àwọn ìbéèrè tó o ti lè máa béèrè, a sì tún sọ ibi tó o ti lè rí ìdáhùn wọn kà nínú Bíbélì rẹ. Inú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yóò dùn láti bá ẹ sọ̀rọ̀ lórí àwọn ìdáhùn náà.

1. Ṣé gbogbo ìsìn ló dáa?

Àwọn èèyàn tó jẹ́ pé tọkàntọkàn ló fi wù wọ́n pé kí wọ́n múnú Ọlọ́run dùn wà nínú ọ̀pọ̀ àwọn ìsìn. Ọlọ́run rí gbogbo wọn, kò sì fọ̀rọ̀ wọn ṣeré. Àmọ́, ó ṣeni láàánú pé àwọn èèyàn kan ti fi ìsìn bojú láti máa hùwà ibi. Láwọn ìgbà kan sẹ́yìn, àwọn aṣáájú ìsìn ti fìyà jẹ àwọn tí kò bá wọn ṣe ẹ̀sìn kan náà. (2 Kọ́ríńtì 4:3, 4; 11:13-15) Gẹ́gẹ́ bá a ṣe gbọ́ ọ nínú ìròyìn, lóde òní, àwọn aṣáájú ẹ̀sìn kan wà lẹ́yìn ìwà ìpániláyà, ogun àti híhùwà àìdáa sáwọn ọmọdé.—Ka Mátíù 24:3-5, 11, 12.

Bíbélì fi kọ́ni pé oríṣi ìsìn méjì ló wà, ìsìn tòótọ́ àti ìsìn èké. Ìsìn èké kì í kọ́ àwọn èèyàn ní òtítọ́ nípa Ọlọ́run. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, Jèhófà Ọlọ́run fẹ́ káwọn èèyàn mọ òtítọ́ nípa òun.—Ka 1 Tímótì 2:3-5.

2. Ìròyìn ayọ̀ wo ló wà nípa ìsìn?

Ọlọ́run ò fẹ́ káwọn ìsìn tí wọ́n sọ pé àwọn nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àmọ́ tí wọn ò fi òtítọ́ nípa Ọlọ́run kọ́ni máa tan àwọn èèyàn jẹ. Kódà, inú àwọn ẹlẹ́sìn yìí máa ń dùn sí bí wọ́n ṣe jẹ́ ọ̀rẹ́ ayé, èyí tó wà lábẹ́ ìdarí Sátánì Èṣù. (Jákọ́bù 4:4; 1 Jòhánù 5:19) Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé àwọn ìsìn tó bá ń gbọ́ ti ìjọba èèyàn dípò kí wọ́n gbọ́ ti Ọlọ́run dà bí aṣẹ́wó. Bíbélì pe aṣẹ́wó yìí ni “Bábílónì Ńlá náà,” ìyẹn orúkọ ìlú kan ní ayé ìgbàanì níbi tí ìsìn èké ti bẹ̀rẹ̀ lẹ́yìn Ikún Omi tó wáyé ní ìgbà ayé Nóà. Láìpẹ́, Ọlọ́run yóò mú ìparun òjijì wá sórí ìsìn èyíkéyìí tó bá ń tan àwọn èèyàn jẹ, tó sì ń pọ́n wọn lójú.—Ka Ìṣípayá 17:1, 2, 5, 17; 18:8, 23, 24.

3. Báwo ni Ọlọ́run á ṣe sọ ọ̀rọ̀ gbogbo àwọn tó ń gbé ayé di ayọ̀?

Ìròyìn ayọ̀ ni ọ̀rọ̀ nípa ìdájọ́ tó ń bọ̀ wá sórí ìsìn èké. Ìdájọ́ yìí máa mú ìtura bá àwọn èèyàn tí ìsìn ń pọ́n lójú kárí ayé. Kò tún ní ṣẹlẹ̀ mọ́ láé pé ìsìn èké ń ṣi àwọn èèyàn lọ́nà tàbí kó mú káwọn èèyàn yapa síra wọn. Gbogbo èèyàn tó wà láyé yóò máa jọ́sìn Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà ní ìṣọ̀kan.—Ka Aísáyà 11:9; Ìṣípayá 18:20, 21; 21:3, 4.

4. Kí làwọn èèyàn tí wọ́n fẹ́ máa sin Ọlọ́run tọkàntọkàn lè ṣe?

Jèhófà kò gbàgbé àwọn tó ń wù láti máa sin òun tọkàntọkàn tí wọ́n wà káàkiri nínú ìsìn èké kárí ayé. Ó ti ń kó irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ jọ pọ̀ báyìí nípa kíkọ́ wọn ní òtítọ́.—Ka Míkà 4:2, 5.

Jèhófà ń tẹ́wọ́ gba àwọn tó fẹ́ láti sìn ín pé kí wọ́n di ara ìdílé òun. Bí inú àwọn ọ̀rẹ́ wa àtàwọn mọ̀lẹ́bí wa kò bá tiẹ̀ dùn nígbà tá a bẹ̀rẹ̀ sí í sin Jèhófà, ọ̀pọ̀ nǹkan, la ti jèrè. A di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run, a ní “ìdílé” tuntun tí wọ́n sì tún nífẹ̀ẹ́ wa, a tún ní ìrètí láti jèrè ìyè àìnípẹ̀kun.—Ka Máàkù 10:29, 30; 2 Kọ́ríńtì 6:17, 18.

Fún ìsọfúnni síwájú sí i, ka orí 15 àti 16 nínú ìwé yìí, Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 16]

Látinú ìwé The Complete Encyclopedia of Illustration látọwọ́ J. G. Heck

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́