Kẹ́kọ̀ọ́ Látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
Kí Ni Yóò Ṣẹlẹ̀ ní Ọjọ́ Ìdájọ́?
Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a sọ̀rọ̀ lórí àwọn ìbéèrè tó o ti lè máa béèrè, a sì tún sọ ibi tó o ti lè rí ìdáhùn wọn kà nínú Bíbélì rẹ. Inú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yóò dùn láti bá ẹ sọ̀rọ̀ lórí àwọn ìdáhùn náà.
1. Kí Ni Ọjọ́ Ìdájọ́?
Ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń rò pé Ọjọ́ Ìdájọ́ máa rí bí wọ́n ṣe yà á sínú àwòrán tó wà lápá ọ̀tún yìí. Ìyẹn ni pé nígbà yẹn, ọ̀kẹ́ àìmọye ọkàn máa wá síwájú ìtẹ́ Ọlọ́run, kí ó lè fi iṣẹ́ ọwọ́ wọn látẹ̀yìn wá ṣe ìdájọ́ wọn. Wọ́n ní àwọn èèyàn rere yóò wá máa gbé ní ọ̀run, àwọn èèyàn burúkú yóò sì máa joró ní ọ̀run àpáàdì. Àmọ́ Bíbélì fi hàn pé ìdí tí Ọjọ́ Ìdájọ́ fi máa dé ni láti lè dá àwọn èèyàn nídè kúrò nínú ipò àìsí ìdájọ́ òdodo. (Sáàmù 96:13) Ọlọ́run ti yan Jésù gẹ́gẹ́ bí Onídàájọ́ tó máa mú kí ìdájọ́ òdodo pa dà gbilẹ̀ ní ayé.—Ka Aísáyà 11:1-5; Ìṣe 17:31.
2. Báwo ni Ọjọ́ Ìdájọ́ yóò ṣe mú kí ìdájọ́ òdodo pa dà gbilẹ̀?
Nígbà tí Ádámù ọkùnrin àkọ́kọ́ mọ̀ọ́mọ̀ ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run, ṣe ló ṣàkóbá fún gbogbo àtọmọdọ́mọ rẹ̀, tó sọ wọ́n di ẹlẹ́ṣẹ̀ tó ń jìyà tó sì ń kú. (Róòmù 5:12) Láti mú àìṣe òdodo yìí kúrò, ṣe ni Jésù máa jí ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn tó ti kú dìde. Ìwé Ìṣípayá fi hàn pé èyí máa wáyé nígbà ẹgbẹ̀rún ọdún ìṣàkóso Kristi Jésù.—Ka Ìṣípayá 20:4, 11, 12.
Kì í ṣe ohun tí àwọn tó jíǹde ṣe kí wọ́n tó kú ni Ọlọ́run máa fi dá wọn lẹ́jọ́ o, ohun tí wọ́n bá ṣe nígbà tí “àwọn àkájọ ìwé” tí Ìṣípayá orí 20 mẹ́nu kàn bá di èyí tí a ṣí sílẹ̀ ni. (Róòmù 6:7) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé “àwọn olódodo àti àwọn aláìṣòdodo” máa wà lára àwọn tí wọ́n máa jí dìde, tí wọ́n á sì láǹfààní láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run.—Ka Ìṣe 24:15.
3. Kí ni Ọjọ́ Ìdájọ́ máa mú kí ó ṣeé ṣe?
Àwọn tí ó kú láìjẹ́ pé wọ́n mọ Jèhófà Ọlọ́run kí wọ́n sì máa sìn ín, yóò láǹfààní láti yí pa dà kí wọ́n máa ṣe rere. Tí wọ́n bá dẹni tó ń ṣe rere, àjíǹde wọn yóò jẹ́ “àjíǹde ìyè.” Ṣùgbọ́n àwọn míì lára àwọn tí wọ́n máa jí dìde kò ní fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn ohun tó jẹ́ ìfẹ́ Jèhófà. Àjíǹde tiwọn yóò wá jẹ́ “àjíǹde ìdájọ́.”—Ka Jòhánù 5:28, 29; Aísáyà 26:10; 65:20.
Nígbà tí Ọjọ́ Ìdájọ́ tó jẹ́ ẹgbẹ̀rún ọdún náà bá fi máa parí, Jèhófà yóò ti sọ àwọn tó jẹ́ onígbọràn nínú aráyé di pípé pa dà gẹ́gẹ́ bó ṣe dá èèyàn ní ìpilẹ̀ṣẹ̀. (1 Kọ́ríńtì 15:24-28) Ìrètí àgbàyanu gbáà ni èyí máa jẹ́ fún gbogbo àwọn onígbọràn! Nígbà ìdánwò ìkẹyìn, Ọlọ́run máa tú Sátánì Èṣù sílẹ̀ kúrò nínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ tí yóò ti wà fún ẹgbẹ̀rún ọdún. Sátánì yóò tún gbìyànjú láti yí àwọn èèyàn pa dà kúrò lọ́dọ̀ Jèhófà. Àwọn olóòótọ́ tí wọn kò tẹ̀ lé Sátánì yóò máa gbádùn lọ títí láé ní orí ilẹ̀ ayé.—Ka Aísáyà 25:8; Ìṣípayá 20:7-9.
4. Ọjọ́ ìdájọ́ míì wo ló tún máa ṣe aráyé láǹfààní?
Bíbélì tún lo ọ̀rọ̀ náà “ọjọ́ ìdájọ́” láti fi tọ́ka sí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí yóò mú òpin dé bá ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí. Ọjọ́ ìdájọ́ yìí yóò dé lójijì gẹ́lẹ́ bí Ìkún-omi ọjọ́ Nóà ṣe dé, tó sì pa gbogbo ìran àwọn èèyàn burúkú ìgbà yẹn run. Ó dùn mọ́ni pé ìparun tó ń bọ̀ wá sórí “àwọn ènìyàn aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run” yìí yóò jẹ́ kí àwùjọ èèyàn tuntun lè máa gbé lórí ilẹ̀ ayé, àárín wọn ni “òdodo yóò sì máa gbé.”—Ka 2 Pétérù 3:6, 7, 13.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Àwòrán “Ìdájọ́ Ìkẹyìn,” látọwọ́ gustave doré, ọdún 1832 sí 1883
[Credit Line]
Àwòrán tí Doré yà