Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí
September 15, 2012
© 2012 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania. Gbogbo ẹ̀tọ́ jẹ́ tiwa.
Ẹ̀dà Tó Wà Fún Ìkẹ́kọ̀ọ́
ÀWỌN ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́
OCTOBER 22-28, 2012
OJÚ ÌWÉ 3 • ÀWỌN ORIN: 133, 132
OCTOBER 29, 2012–NOVEMBER 4, 2012
Àlàáfíà Yóò Wà fún Ẹgbẹ̀rún Ọdún àti Títí Láé!
OJÚ ÌWÉ 8 • ÀWỌN ORIN: 55, 134
NOVEMBER 5-11, 2012
Kẹ́kọ̀ọ́ Látinú Sùúrù Jèhófà àti Jésù
OJÚ ÌWÉ 18 • ÀWỌN ORIN: 35, 90
NOVEMBER 12-18, 2012
“Ẹ Kò Mọ Ọjọ́ Tàbí Wákàtí Náà”
OJÚ ÌWÉ 23 • ÀWỌN ORIN: 43, 92
NOVEMBER 19-25, 2012
Jèhófà Ń Kó Àwọn Èèyàn Rẹ̀ Aláyọ̀ Jọ
OJÚ ÌWÉ 28 • ÀWỌN ORIN: 119, 118
OHUN TÁWỌN ÀPILẸ̀KỌ TÁ A MÁA KẸ́KỌ̀Ọ́ DÁ LÉ
ÀWỌN ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 1, 2 OJÚ ÌWÉ 3 sí 12
Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ mánigbàgbé máa tó wáyé. Ó ṣe pàtàkì pé ká mọ̀ nípa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ náà. A máa jíròrò mẹ́wàá lára wọn nínú àwọn àpilẹ̀kọ yìí. Márùn-ún ní í ṣe pẹ̀lú bí Ọlọ́run ṣe máa pa ayé Sátánì run, márùn-ún yòókù sì ní í ṣe pẹ̀lú ayé tuntun tí Ọlọ́run ń mú bọ̀.
ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 3 OJÚ ÌWÉ 18 sí 22
Gbogbo wa là ń retí ìgbà tí ètò àwọn nǹkan búburú yìí máa wá sópin tí Párádísè tí Ọlọ́run ṣèlérí yóò sì dé. Yálà o ti ń retí rẹ̀ fún ọ̀pọ̀ oṣù tàbí ọ̀pọ̀ ọdún, kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kó o ní sùúrù? Àpilẹ̀kọ yìí á jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè máa fi sùúrù dúró dè é.
ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 4 OJÚ ÌWÉ 23 sí 27
Gbogbo àwa èèyàn Ọlọ́run ń fojú sọ́nà fún ìgbà tí ètò búburú yìí máa wá sópin. Àpilẹ̀kọ yìí máa jẹ́ ká rí i pé àǹfààní wà nínú bí a kò ṣe mọ ọjọ́ tàbí wákàtí náà gan-an tí òpin máa dé.
ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 5 OJÚ ÌWÉ 28 sí 32
Ọjọ́ pẹ́ tí àwọn àpéjọ ti jẹ́ apá pàtàkì nínú ìjọsìn mímọ́. Àpilẹ̀kọ yìí ṣàlàyé díẹ̀ nípa bí àwọn àpéjọ tó wáyé nígbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì àti lóde òní ṣe máa ń gbéni ró nípa tẹ̀mí, ó sì tún sọ àwọn àǹfààní tó wà nínú pípésẹ̀ sáwọn àpéjọ náà.
ÀWỌN ÀPILẸ̀KỌ MÍÌ NÍNÚ ÌTẸ̀JÁDE YÌÍ
13 Àwọn Ilé Ẹ̀kọ́ Ètò Ọlọ́run—Ẹ̀rí Pé Jèhófà Nífẹ̀ẹ́ Wa
ÀWÒRÁN Ẹ̀YÌN ÌWÉ: Ní orílẹ̀-èdè Philippines, àwọn ará ń gbìyànjú láti mú ìhìn rere dé ọ̀dọ̀ gbogbo èèyàn, irú bí ọkùnrin tó wà lórí alùpùpù tí wọ́n so kẹ̀kẹ́ mọ́ lẹ́gbẹ̀ẹ́ yìí, ní apá àríwá erékùṣù Luzon
PHILIPPINES
IYE AKÉDE TÓ WÀ NÍ ORÍLẸ̀-ÈDÈ PHILIPPINES
177,635
IYE AṢÁÁJÚ-Ọ̀NÀ DÉÉDÉÉ
29,699
IYE ÀWỌN TÓ ṢÈRÌBỌMI LỌ́DÚN 2011
8,586
IYE ÈDÈ TÍ WỌ́N Ń TÚMỌ̀ ÌTẸ̀JÁDE SÍ
21