Orin 90
Ẹwà Orí Ewú
Bíi Ti Orí Ìwé
1. A ní àwọn àgbààgbà,
Wọn kìí ṣèwe mọ́.
Wọ́n ti ńfara dàá tipẹ́;
Síbẹ̀ láìṣàárẹ̀.
Kò sókun, ọkọ, aya
Mọ́ fún ọ̀pọ̀ wọn.
Baba, jọ̀ọ́ pín wọn lérè
Ní ayé tuntun.
(ÈGBÈ)
Baba, jọ̀ọ́ má gbàgbé
’Gbàgbọ́ tí wọ́n ní.
Fi dá wọn lójú pé
Wọn yóò gba, “Káre!”
2. Adé ẹwà ni ewú
Lọ́nà òdodo.
Jèhófà ńwo ẹwà wọn,
Rèǹtèrente ni.
Ẹ jẹ́ ká máa rántí pé
Wọ́n ṣe ọ̀dọ́ rí.
Wọ́n ti ṣe gudugudu
Nígbà téegun wà.
(ÈGBÈ)
Baba, jọ̀ọ́ má gbàgbé
’Gbàgbọ́ tí wọ́n ní.
Fi dá wọn lójú pé
Wọn yóò gba, “Káre!”
(Tún wo Mát. 25:21, 23; Sm. 71:9, 18; Òwe 20:29; Lúùkù 22:28; 1 Tím. 5:1.)